Document Body Page Navigation Panel
AWON OBIRIN ATI ODO
Merkel lo di olori egbe oselu ni orile-ede Germany 1min. 6secs. 6 Igbese
ti iru re ko waye ri kan ni orile-ede Germany fi obirin
se olori egbe oselu to nse ijoba lowolowo.
Awon obirin ile Afrika ni a fojusi ninu Ipolongo lati tako ifi-iyato-si
2mins. 30secs. 18
Awon akitiyan titun lati pa ifi-iyato-si to nkoju awon
obirin ile Afrika re ni o bere ni ilu Nairobi
Awon obirin orile-ede Spain wo inu iwe itan. 51secs. 21 Awon obirin
lo je olori ni ile asofin agba ati kekere
ninu ijoba orile-ede Spain nisisiyi.
O setan ko setan: Awon odo orile-ede Naijiria ni ohun lori ero asoromagbesi
redio. 2mins. 51secs. 22
Ere ori itage titun kan lori redio dojuko awon nkan to nsele
lowolowo to je koko fun idagbasoke orile-ede Naijiria.
Ifojusona fun Beijing and marun 1min. 30secs. 23 Igbaradi fun Apejo
nla ti awon obirin ti yio waye ni ilu New York.
Awon Ijoba dahun si Iwe Iwadiotito 1min. 35secs. 24 Awon orile-ede
nfi iwoye won ranse lori oro awon obirin.
A yan alaga titun fun Igbimo Eleto 1min. 14secs. 24 Omo ile Afrika
ni o je alaga fun igbimo to nseto Apejo nla ti Beijing ati marun.
Eredi Beijing ati Marun? 1min. 30secs. 24 Kini awon koko ifojusona
si ninu ipade na?
OUNJE
Won ti ri igbado to nle kokoro olubaje danu 1min. 49secs. 8 Won ti
se awari eya agbado kan to nle kokoro abagbado je to banileru danu.
Won se awari Iresi iyanu 2mins. 33secs. 13 O seese ki awon idagbasoke
enu ojo meta yi ninu imo ero
nipa ajogunba iseda ohun alaaye se iranwo lati gbejako ebi.
A nfe iranlowo fun awon olufaragba iyan 1min. 9secs. 10 Bi opo eniyan
sii ni orile-ede Ethiopia se ni idojuko ebi beni
a nteramo ipe fun iranwo lati odo awon orile-ede agbaye.
AWUJO
Monomono nkolu orile-ede Ethiopia lekeji 3mins. 4secs. 18 Orile-ede
na tun ni idojuko iyan elekeji laarin odun medogun si ara won. 1
1 Page 2 3
Vol. II No. 18 (Yoruba) CHANGE Radio July, 2000
2
Ijoba tiwantiwa gba alekun ni orile-ede Senegal 1min. 12secs. 22 Fun
igba akoko lati odun 1960, idibo yi ijoba pada ni orile-ede Senegal.
ETO EDA ENIYAN
Orile-ede Algeria silekun sile fun awon egbe ajijagbara fun eto eda eniyan
1min. 42secs. 9
Ipe wa si orile-ede Algeria kan ti won ti nbere
fun lemolemo tele ni o mu inu awon egbe fun eto eda eniyan dun.
Eto Eda Eniyan ni ile Afirika 1min. 48secs. 23 Aibale okan lo soke
laarin awon ajo ti ko
lowo ijoba ninu nipa ipo ti eto eda eniyan wa ni ile na.
ORO AJE
Orile-ede Germany ngbero lati fagile gbese orile-ede Mozambique 57secs. 10
Omiyaleyaona ati ipadanu emi ti se
okunfa igbese kan lati fagile gbese ti orile-ede Mozambique
Iderun Gbese fun orile-ede Tanzania 41secs. 20 Irapada oro-aje orile-ede
Tanzania gba alekun.
Orile-ede Japan mu Eto Iderun -Gbese gbooro si 1min. 6secs. 16 Orile-ede
Japan ti se alekun eto iderun-gbese re si ilopo meji.
O seese ki won ma le fi koko orile-ede Naijiria sowo si ile okeere mo
laipe yi 47secs. 21
O seese ki ikuna lati tele awon ofin kariaye ni ikolu
lori atita okan ninu awon ogunna gbogbo ohun ogbin ti a nta si ile okeere.
Ajo Agbaye fun Idagbasoke fe se idasile akojo-owo fun Imukuro osi ni orile-ede
Naijiria. 1min. 19secs. 21
Awon akitiyan atungbedide lati pa osi run ni orile-ede Naijiria gba alekun.
ILERA
Eroja ajogunba eya eda alaaye se alekun ewu arun okan ninu awon to nmu siga
1min. 19secs. 20
Iwadi siwaju sii se ifesemule ikilo Dokita Oniseabe Agba lori taba.
Ogbeni Bill Gates gbe milionu metadinlogota
owo dola amerika sile lati fi gbejako arun kogboogun eedi. 1min. 55secs. 20
Okunrin to lowo ju laye se igbeowosile to poju
titi di oni yi lati fi gbejako arun apani na.
Egbogi agbejako kokoro bakteria le se idena awon ikolu to je mo Kokoro-Arun
HIV. 1min. 42secs. 15
O seese ki Cotrimoxazole, egbogi agbejako arun iredodo fukufuku funni
ni ojuutu olojo-kukuru ninu itoju awon ikolu to je mo Arun kogboogun Eedi.
2
2 Page 3 4
Vol. II No. 18 (Yoruba) CHANGE Radio July, 2000
3
O seese ki imole Oorun fa arun ebo-oju 1min. 34secs. 16 A ti ri ilowosi
orisun pataki fun agbara ina ni
agbaye ninu okunfa arun pataki kan.
Erekusu Taiwan yio se ifojusi Igbonriri ati Eya Ile apani ninu ibere lati
di omo egbe Ajo Agbaye fun Oro Ilera. 1min. 56secs. 21
Orile ede Taiwan tun se itiraka miran lati wa ninu Ajo Agbaye fun Oro
Ilera.
Asewo pelu taba igbo yio bere lori awon alaisan 1min. 34secs. 16 Ilo
taba igbo lati koju irora to ga lara awon alaisan ni yio bere laipe.
O seese ki aseyori lori egbogi kan se iranlowo fun iranti opolo ninu awon
arugbo 1min. 48secs. 17
Egbogi titun le mu ki opolo awon agbalagba sise pipe bi ti awon odo.
Ayika
AFEFE ILE
Ojuutu si imoorusi-aye ko si ninu agbara ina Nuclear 3mins. 7secs. 6 Ajo
WWF tanmo lilo awon orisun agbara to wa lona to dara si to si mu
alafia wa dipo ninawo lori agbara ina nuclear to lewu pupo.
Awon atole ibori-igbo teereteere nse idinku isodiasale ni orile-ede China
1min. 16secs. 7
Orile-ede China ni ipinnu lati bori ogun re si isodiasale to nwonuilebo.
Awon Orile-ede G-8 si ni ireti fun Adehun lori Ayika 2mins. 37secs. 17
Egbe eleni-mejo na ngbe igbese lati fi owo si adehun pataki kan lori
imoru-si-aye.
Imorusi ile Arctic nmu irokeke ewu ba awon eye 3mins. 23secs. 8 O
seese ko je wipe awon eye ni imorusi aipe yi ti won se
akosile re ni ile Arctic yio mu irokeke ewu ba julo.
EDA ABEMI EGAN
Orile-ede Egypt ati Thailand gba awon eru ehin erin to po 2mins. 33secs.
13 Isigunti airotele laipe yi si awon onisowo ehin erin ni
orile-ede Egypt ati Thailand fihan wipe owo ti ko bofin mu na
si ngberu -eyi jasi ori buruku fun awon erin ile Afirika.
Ajo CITES dabobo eja aye igbaani 3mins. 59secs. 10 Ipade Ajo Agbaye
to sese pari fi eya miran to wa labe
ewu iparun kun akosile re.
Igbesele isowo ninu ijapa okun si wa sibe ni orile-ede Cuba 2mins. 59secs.
11 Orile-ede Cuba kuna ninu itiraka re lodo Ajo CITES lati
gba isowo laaye ninu awon ijapa okun re. 3
3 Page 4 5
Vol. II No. 18 (Yoruba) CHANGE Radio July, 2000
4
Ajo CITES fi ake kori wipe igbesele isowo ninu ehin erin gbodo tesiwaju 2mins.
45secs. 12
Igbesele isowo ninu ehin erin si wa biotilejepe
awon orile-ede die faramo isowo labe ofin.
Orile-ede Australia fi ehonu re han lori pipa ti orile-ede Japan npa abuibutan
2mins. 15secs. 12
Orile-ede Australia nparowa fun orile-ede Japan wipe
ki o ma mu iwadi re ninu eyiti o ti npa abuibutan gbooro si.
Ogba awon eranko kan ni orile-ede China yio ya orile-ede Amerika ni beari
panda meji 1min. 47secs. 19
Ogba Eranko ti orile-ede Amerika to wa ni ilu Washington
ni yio gba beari panda meji gegebi ara akitiyan lati gba
awon beari panda nlanla na la.
Abuibutan to gunle si eti okun ni orile-ede Japan ti ku 1min. 22secs. 19
Abuibutan kan to won to iwon toonu medogbon ni o ku ni
etikun arigbungbun orile-ede Japan biotilejepe akitiyan lo lati
wakati-de-wakati lati gbaala.
Awokose SAVANNA fi imole titun han lori iwontunwonsi laarin eda abemi egan
ati eda eniyan 1min. 43secs. 15
Agbekale awokose kan lori ero komputa yio le sotele iru
awon ayipada ti yio wa ninu ayika Ila-oorun Afirika to takoko,
yio si se iranwo lori awon ipinnu lori itoju iseda aye.
OMI MIMO ATI OMI OKUN Isakoso ati Ilana lori oro Omi ni awon agbegbe ologbele
1min. 31secs. 19
Apero nla kariaye kan ti kepe fun idasile igbimo alagbara kan
lati bojuto owongogo omi ni awon agbegbe ologbele.
Orile-ede Amerika nkepe fun Adehun Aabo lori Omi Agbaye 1min. 15secs. 6
Orile-ede Amerika tanmo idasile ifowosowopo aabo kan ni
agbaye lati saami Ojo Ile Aye.
Awon Afenifere ayika gbe igbese lati se italaya si awon iwe pelebepelebe
to so wipe ohun ti a le mo
ko ni eya ara eja dolphin ninu. 3mins. 1sec. 9 Awon afenifere ayika
tapa si ofin kan to tun le tubo fi emi
awon eja dolphin sabe ewu.
IDOTI AYIKA
Idoti ayika ni a ti fi esun kan wipe on lo fa ipadanu agbeka kurukuru fun
idabobo ofurufu ni ile Arctic. 1min. 57secs. 7
Idoti ayika ti eda eniyan nfa ni o nni ikolu to buru jayi lori
agbeka kurukuru fun idabobo ofurufu ni ile Arctic.
Ajo Greenpeace bori ijakadi lati dena ikojade eru aloku ohun ose nuclear
1min. 27secs. 7
Ase ile ejo kan ti dena igbiyanju lati ko aloku alotunlo
ohun ose nuclear lati orile-ede Faranse lo si orile-ede Belgium. 4
4 Page 5 6
Vol. II No. 18 (Yoruba) CHANGE Radio July, 2000
5
Ifojusi: Aseyori Iwadi
Awon idagbasoke enu ojo meta yi ninu iwakiri fun
ilana eto emi ninu itupale eya ara eda eniyan.
Awon Onimo ijinle Sayensi se agbejade awari lori bi emi se bere. 2mins.
8secs. 14
Imo denudenu si itupale eya ara eda eniyan le je awari ti yio yi aye
pada.
Ifojusona si osu kefa fun itupale ajogunba eya ara eda eniyan 2mins.
42secs. 14 Akoko ti aye yio ka "iwe emi" nyara bo kankan.
Eto Awon Omode
Bi Ketekete Abila se gba awon ila re. 3m ins. 22secs. 24
Oro Asokagba Awon oro manigbagbe lori ayika ati idagbasoke
25 5
5 Page 6 7
Vol. II No. 18 (Yoruba) CHANGE Radio July, 2000
6
IROYIN
Orile-ede Amerika nkepe fun Adehun Aabo lori Omi Agbaye 1min. 15secs.
Akowe Agba fun orile-ede Amerika, Madeleine Allbright ti tanmo idasile ifowosowopo
aabo kan lori omi agbaye. Eyi je idahun si awon rogbodiyan ti ologun ati ti
oloselu to le waye lori owongogo omi.
Ninu oro re to ka lati saami Ojo Ile Aye ni ilu Washington. Allbright so wipe
awon isoro to jemo omi nmu ikalara to ga wa lori Eto Imulo lori Oro Ile Okeere
ni awon agbegbe to gbelege ni aye. O se afikun wipe orile-ede
Amerika yio kopa asiwaju ninu agbekale ifowosowopo titun na.
Gegebi oro re: "Ohun ti mo ni lokan ki ise ifowosowopo bi Ajo NATO eyiti o wa
fun awon orile-ede kan ...... sugbon ifowosowopo ti ko mu kanpa wa eyi to si
sile fun gbogbo awon to ba moye bose se pataki to lati sise
papo lati toju omi to lo lati orile-ede de orile-ede, ki a sakoso re pelu ogbon,
ki a si lo daada." The Guardian
Merkel lo di olori egbe oselu ni orile-ede Germany 1mins. 6secs Oloselu
ti ila-oorun orile-ede Germany tele ni won ti dibo yan gegebi olori titun fun
egbe oselu Christian
Democrats ni orile-ede Germany. On lo ropo olori ijoba teletele Helmut Kohl,
eyi si so di okan ninu awon
obirin die to wa ni awon ipele to ga julo ninu ijoba ni ile alawo funfun Europe.
Yiyan re ni a ri gegebi idagbasoke rere ninu idande awon obirin to nlo lowolowo
ni gbogbo aye.
Arabirin Merkel to je omo odun marun-din-ladota ni oloselu akoko lati ila-oorun
orile-ede Germany tele to di olori egbe oselu na to je egbe oselu to se pataki
julo lehin ogun ajakaye keji. Gegebi oro to so nigbati o ngba
awon itanna leyin idibo na, "mo dupe lowo yin fun atileyin yin mo si ni ireti
wipe yio lo fun igba pipe." The Guardian
Ojuutu si imorusi-aye ko si ninu agbara ina Nuclear 3mins. 7secs. Awon
ogbon imulo to peye lati se idinku awon efin alagbara lati inu igbejade agbara
ina ilentriki eyi to nfa
imorusi-aye ko gbodo da lori agbara ina nuclear. Eyi wa lara iroyin kan lati
owo ajo Akojo Owo ni Agbaye fun Iseda Aye (Worldwide Fund for Nature (WWF) eyi
ti a se agbejade re lati owo Ajo Ifitonileti ni Agbaye
lori Agbara Ina (World Information Service in Energy) ni ilu Paris.
Iroyin na so wipe piposi agbara ina nuclear ko yorisi ilosile itujade efin oloro
CO 2 -to je ogunna gbongbo efin
alagbara to nfa imorusi aye. Eyi jasi be ni apakan nitoripe igbarale awon ero
agbara ina nlanla ma nse alekun ilo ina ilentriki dipo ki o se igbelaruge imudarasi
ninu ipese ati ilo agbara ina to munadoko.
Iroyin na woye wipe agbara ina nuclear ma ngbe ina ilentriki nikan jade, nigbati
o je wipe opo ninu agbara ni a nilo gegebi igbona. Eyi jasi wipe a o tun ni
lati jo afikun awon ohun idana lati inu ile, eyiyi yio se alekun
itujade efin oloro CO 2 de ipele kanna gegebi apapo igbona ati agbara ina to
nlo efin alagbara fun idana.
Jennifer Morgan to je Oludari Ajo WWF fun Ipolongo lori Iyipada Afefe Ile so
wipe "awon ijoba ko gbodo fi aye gba igboriyinfun agbara ina nuclear. Akosile
ilana na gbogbo je keke fun imuwasaye ayipada titun ati ti
imugborosi oja fun awon orisun agbara ina to mo to si munadoko nitoto."
Awon orile-ede alagbara-ina Nuclear bi Canada, Faranse ati Japan ti nse ipolowo
agbara ina nuclear fun awon orile-ede to si ndagbasoke. Sugbon apeere orile-ede
China ti fihan wipe sise imudarasi imunadoko
agbara ina je ona to dara julo fun awon orile-ede to si ndagbasoke dipo agbekale
agbara ina nuclear. Siso ina 6
6 Page 7 8
Vol. II No. 18 (Yoruba) CHANGE Radio July, 2000
7
lo ni orile-ede China yorisi wipe orile-ede na yera fun itujade iwon ogbonlenirinwo
milionu toonu efin oloro CO 2 laarin odun 1980 ati 1997.
Iroyin na tesiwaju lati ya aworan okoowo agbara nuclear gegebi eyi to ti nlo
sile. Ko ni anfani oro aje mo
latari igba gbogbo eniyan laaye to ti gbile ninu okoowo agbara ina. Eyi tun
ribe latari itekuro ni lilo awon ile ero agbara ina nlanla si awon ile ero agbara
ina kekeke to nlo efin alagbara, to si nmunadoko, ati ti idije agbara
ategun to sese nyoju. Isoro iwalalafia to nkoju okoowo agbara ina nuclear
na tun lowosi ilosile ninu igbajumo orisun agbara ina yi.
WWF
Awon atole ibori-igbo teereteere nse idinku isodiasale ni orile-ede China
1min. 16secs. Itankale awon atole ibori-igbo eyiti a se idasile re ni ekun
Jilin to wa ni iha ila-oorun ariwa orile-ede China ni
o ti se iranwo lati din awon ile ti isodiasale nda laamu ku lati milionu meje
o le iko meta ninu mewa saare hektari si milionu meji o le iko marunleladota
ninu ogorun.
Ekun na se ifilole ise agbese atole ibori-igbo pataki merin lati odun 1990
lo. Laarin odun mejo to koja, ekun na gbin saare hektari ile igi egberun lona
ogofa. Eyi si se alekun ibori igbo iko mewa o le die si iko mejila o le
die ninu ogorun.
Isodiasale je okan pataki ninu awon isoro ayika to dojuko aye, to si nmu irokeke
ewu ba emi awon eniyan to ju edegberun milionu lo. Ni orile-ede China, iko merindinlogun
o din die ninu ogorun gbogbo ile won ni o ni
ikolu isodiasale eyi si nlo soke pelu egberun meji ibuso kilomita lododun. The
Guardian
Ajo Greenpeace bori ijakadi lati dena ikojade eru aloku ohun ose nuclear.
1min. 27secs.
Ile ejo kan ni orile-ede Belgium ti dena idapada eru aloku ohun elo ohun
ose nuclear ti won se ayipada re lati orile-ede Faranse si orile-ede Belgium
nitori orile-ede Belgium ko ni awon eto nipa ijamba oko oju irin.
Ile ejo dajo ni igbelese iwe ehonu ti ajo Greenpeace ko lati jirebe fun gbigbesele
kiko eru na lati ibudo atunlo to wa ni La Hague ni orile-ede Faranse nitori
awon egbe ajafitafita lori ayika na salaye wipe orile-ede Belgium
ti kuna lati se agbekale eto pajawiri fun ijanba ninu irin-ajo na.
Eru na ni yio je akoko ninu medogun iru re lati ko awon aloku lati ile ero agbara
ina nuclear ti orile-ede Belgium ti won ti fi ranse si ariwa orile-ede Faranse
fun ayipada. Orile-ede Belgium gbero lati gba iwon mita
onigun merin marun-din-logorin aloku ti won ti fi igbona nla so di gilasi, iyen
ni awon epo idana ti won ti se
ayipada re ti won si ko sinu agolo fun itoju fun ojo pipe. Aloku na yio si lewu
pupo fun opolopo orundun. CNN. com
Idoti ayika ni a ti fi esun kan wipe on lo fa ipadanu agbeka kurukuru fun
idabobo ofurufu ni ile Arctic. 1min 57secs.
Igba otutu gigun kan ni ile Arctic fa okan ninu awon ipadanu agbeka kurukuru
fun idabobo ofurufu to si poju ninu akosile. Gegebi awon onimo ijinle sayensi
lati ajo NASA ati Ajo Isokan Ile Alawo funfun Europe se so,
idoti ayika lati owo eda eniyan lo fa.
Awon iwon ti awon oluwadi won fihan wipe agbeka kurukuru idabobo ofurufu na
to wa ni ekun Arctic ti dinku
pelu bi iko ogota ninu ogorun laarin osu kini ati idaji osu keta. Awon imo miran
ti oko inu ofurufu gba gbe eyi lese. Idinku agbeka kurukuru idabobo ofurufu
ti a se akosile re ninu odun yi fihan wipe awon eroja kemikali 7
7 Page 8 9
Vol. II No. 18 (Yoruba) CHANGE Radio July, 2000
8
'chlorine' to wa ninu awon idoti ayika kan si nrababa ni iha ariwa to jina.
Die ninu awon eroja kemikali 'chlorine' yi le ba agbeka kurukuru idabobo ofurufu
ile aye je ti won ba wa ninu otutu to ga pelu itansan oorun
-gegebi o se sele ni akoko otutu yi.
Biotilejepe igbejade awon idoti yi ti dinku, ti eyi si din iye kemikali 'chlorine'
to wa ninu ofurufu ayika ku, ipadabosipo kikun ti agbeka kurukuru idabobo ofurufu
ni ekun Arctic ko le waye fun opolopo ewadun.
Iroyin na tun woye wipe idinku agbeka kurukuru idabobo lori ekun arctic yi
ti fa idinku die ninu agbeka kurukuru idabobo ni gbogbo iha ariwa aye eyi to
lo lati ariwa ile Europe titi de ariwa orile-ede Amerika.
CNN. com
Imorusi ile Arctic nmu irokeke ewu ba awon eye 3mins. 23secs. Nibayi,
Ajo Akojo Owo fun Iseda Aye (Worldwide Fund for Nature) ti kilo wipe o seese
ki ayipada ninu
afefe ile ge akojopo awon eye to wa ni ile Arctic si idaji.
Pelu ilo awon awokose afefe ile, awon onimo ijinle sayensi lati Ibudo Iwoye
Itoju Iseda Aye ni Agbaye se agbeyewo awon ikolu igbonatutu ati idinku ibugbe
lori awon eye to wa ni ekun arctic.
Awon oluwadi na ri wipe ninu orundun to koja lo, igbonatutu ni aye lo soke
pelu iko mesan ninu mewa ipele
Farenheit kan. Ko si ibomiran ni aye ti imorusi na ti farahan pupo ju ti ekun
arctic lo nibiti iwontunwonsi igbonatutu ti lo soke to ipele meji ati iko meje
ninu mewa ipele kan Farenheit laarin ewadun kokan lati odun
1960. Laarin adorin si ogorun odun to nbo, awon onimo ijinle sayensi sotele
wipe akojopo efin oloro CO 2 ninu ayika le di ilopo meji. Awon olugbe arctic
ni yio wa lara awon eni akoko lati fi ikolu iyipada afefe ile na
han.
Iroyin na kilo wipe awon igbonatutu to ba ga soke le fa awon igbo onigi lati
sun soke si iha ariwa ki o si ropo ile perese ti ko ni igbo (tundra), eyi to
je agbegbe ibisi to se pataki fun egbegberun lona egbegberun awon eye.
Lara awon eye-omi ekun arctic ti imorusi aye fi sabe ewu julo ni a ti ri pepeye-odo
alaya pupa eyi to wa labe ewu to ga pupo, pepeye-odo ti ewa tundra, pepeye-odo
spoon-billed ati pepeye-odo emperor.
Pelu ilosoke igbonatutu laye ti ko ju ipele kansoso ati iko meje ninu mewa
ipele farenheit nigbati yio ba fi di odun 2070, gbogbo awon eye yi lo le padanu
idaji ibugbe won. Eyi to ju iko meji ninu meta gbogbo pepeye-odo
ati eyi to fere to iko marun-din-logorun ninu ogorun eye ako ti a ni ni ekun
arctic. Iwadi na sotele wipe ipadanu iko ogoji si marun-din-logota ninu ogorun
ile perese ti ko ni igbo (tundra) laarin orundun to nbo yio
yorisi ipadanu ibugbe fun milionu marun pepeye-odo ati milionu meje ati abo
eye ako.
Awon oluwadi na ko wipe: "Iwadi yi tun se ifesemule bi o se se pataki to lati
se idinku awon itujade awon efin alagbara to nfa imorusi aye ki a si din iye
bi afefe ile se nyipada ku ni kiakia. Lati le mu iyirapada si afefe ile to
yipada wa, a ni lati fi iyipada ninu isakoso ibugbe sinu ero ni kiakia." ENN
Won ti ri agbado to nle kokoro danu 1min. 49secs. Bi eya agbado ti
a mo si B-96 tile tinrin pelu igi ti ko lagbara ati itakun ti ko dagba pupo,
o ni ohun kan ti awon
eya agbado miran nfe. Eya agbado na lati orile-ede Argentina ni won ti se awari
wipe o ni kemikali kan to ndi
abo kokoro abagbadoje ti ile Europe lowo lati y eyin. 8
8 Page 9 10
Vol. II No. 18 (Yoruba) CHANGE Radio July, 2000
9
Gegebi oro Bradley F. Binder to je onimo ijinle sayensi nipa awon kokoro to
si wa pelu ile ise iwadi lori ise ogbin ti orile-ede Amerika se so, "Ijakadi
pelu kokoro abagbadoje ile Europe na ti le fun awon agbe, paapa
awon to nsogbin lailo tabi to nlo die pere ninu awon egbogi ipakokoropaeku onikemikali.
Kokoro abagbadoje ile Europe yi a ma na awon to ngbin agbado ni orile-ede na
ni owo to to adota-din-nirinwo milionu owo dola
Amerika lododun. Laisi kemikali tabi awon ona itoju miran, awon ipadanu na le
ju bilionu (milionu lona egberun) kan owo dola Amerika lo.
Nisisiyi awon olugbin ma nlo agbado ti a ti fi imo ero ajogunba eya gbe jade
lati ni awon kemikali to npa awon omo kokoro, sugbon agbado B-96 ni kemikali
oludabobo kan to nse idiwo fun abo kokoro abagbadoje lati
ye eyin. Nibayi agbado onimo ero ajogunba eya na ti a mo si Bt ndi awon
omo kokoro lowo lati pa jade kuro ninu eyin ti a baye.
CNN. com
Awon Afenifere Ayika gbe igbese lati se italaya si awon iwe
pelebepelebe to so wipe ohun ti a le mo ko ni eya ara eja dolphin ninu. 3mins.
1sec. Awon afenifere ayika ti ro adajo orile-ede Amerika kan lati da ijoba
Aare Clinton lowo ko ki o ma le so iwe
pelebepelebe orile-ede na to njeri wipe ohun ti a le mo ko ni eya ara eja
dolphin ninu di yepere nipa jijeki won lo fun awon eja tuna ti won fi awon ko
pelu eja dolphin ti won ju sile. Eyi ni ohun to tun sese yoju ninu ija ti ofin
ati ti oloselu olojo pipe. Fun odun mewa o le die seyin, awon oko apeja to npa
eja tuna to ba fe iwe ijerisi
pelebepelebe na ni won dena re lati maselo awon awon alakopo nla to nko eja
tuna po mo eja dolphin to ma nwe pelu awon eja tuna onilebe alawo ofefe ni iha
ila-oorun okun nla pacific.
Ile igbinmo asofin koko gbesele iru ipeja be ti awon oko orile-ede Amerika
ba se ni odun 1972, won si wa fi ofin kanna de awon oko ipeja ile okeere to
nko eja wasi orile-ede Amerika. Awon idajo ateyinwa ti fi agbara
sii fun awon ilana to kepe fun igbesele oja lati awon orile-ede ti ko kun awon
oju osuwon na. Lilo iwe ijerisi pelebepelebe na yio yipada lati osu kerin odun
nigbati eka ile ise ijoba fun okowo gbero lati fi
aye gba eja tuna ti awon oko apeja orile-ede Mexico ba pa lati gba iwe ijerisi
na niwongba ti awon oluwoye lori awon oko na ko ba ri wipe a pa eja dolphin
tabi pa eja dolphin lara ninu awon awon alakopo na.
Oro na ti pin awon afenifere ayika si meji. Awon egbe bi ajo Greenpeace ati
Ajo Akojo owo fun Iseda Aye (Worldwide Fund for Nature) fi ara mo ofin odun
1997 kan to gbe igbesele kuro lori eja tuna ti a ba kopo pelu
eja dolphin. Ofin gbani laaye lati lo iwe ijerisi na fun awon eja ti won pa
eyiti Ile ise ijoba orile-ede fun Ipeja ninu okun ko ri wipe o pa awon dolphin
lara. Lara awon to pejo na ni Egbe orile-ede Amerika fun Idena Iwa
Ika si awon Eranko (American Society for the Prevention of Cruelty to Animals)
ati Egbe Alanu (Humane
Society). CNN. com
Orile-ede Algeria silekun sile fun awon egbe ajijagbara fun eto eda eniyan
1min. 42secs.
Ninu ayipada ojiji kan ninu eto imulo, Aare orile-ede Algeria, Abdeaziz
Bouteflika, ti pe awon egbe ajijagbara fun eto eda eniyan merin lati be orile-ede
re wo. Eyi je ayipada eto imulo to bere ise ni odun 1992 eyi to dena
awon egbe ile okeere lati wo orile-ede na lati se iwadi lori iteloju eto eda
eniyan lakoko idite awon elesin musulumi.
Ni odun 1999 orile-ede na ko gba awon omo orile-ede Amerika alanu to fe wa
se iwadi awon esun ifiyajeni ati pipa eniyan danu lati owo awon omo ogun ijoba.
Titi di isisiyi, bi egberun mewa enia loti ku ninu iwa ipa na to bere ni odun
1991. Ijoba ti debi iwa-ipa na lori 9
9 Page 10 11
Vol. II No. 18 (Yoruba) CHANGE Radio July, 2000
10
awon onijagidijagan esin musulumi to dihamora. Sugbon sa, awon iroyin wa to
fihan wipe awon omo ogun ijoba na ti hu awon iwa ipa ninu eyiti awon ara ilu
ti ku.
Ni ilu Paris, aare Ajo Alasepo Kariaye fun Eto Eda Eniyan (International Federation
of Human Rights) ti
tewogba isele titun na eyiti o fi aye gba awon egbe ajifitafita fun eto eda
eniyan lati wo orile-ede Algeria.
Iwe ipe na ni a gbe jade ni ojo'ru ni oruko Aare Bouteflika ni ile ise orile-ede
Algeria si Ajo Agbaye ni ilu New York.
Times
A nfe iranlowo fun awon olufaragba iyan 1min. 9secs. Awon ajo kariaye
fun iranlowo nlakaka lati ri wipe opo iranwo sii ni o de agbegbe ti a npe ni
iwo Afirika nibiti
awon milionu mewa eniyan wa labe ewu iyan eyiti o waye latari ogbele olojogbooro.
Ni okan ninu awon ibiti oro na kan ju, iyen ekun Ogaden ni gusu Ethiopia, ajo
agbegbe kan fun iranlowo royin wipe omo mefa ti ojo ori won ko to odun marun
lo nku lojojumo. Agbegbe Gode ati awon ayika re ni awon
oku eran-osin kun kakiri.
Ajo Agbaye fun Eto Ounje (UN World Food Programme) ati awon ajo miran ntiraka
lati se ipese ounje fun
awon to nilo re sugbon iroyin nso wipe awon akitiyan won lo nni idena latari
awon titi ti ko dara. Awon iroyin tun so wipe awon olote ati awon adigunjale
ti nsi lo si awon agbegbe ti iyan na kan.
CNN. com
Orile-ede Germany ngbero lati fagile gbese orile-ede Mozanbique 57secs.
Minisita orile-ede Germany fun oro ile okeere, Joschka Fischer so wipe orile-ede
on nkepe fun ifagile gbese orile-ede Mozanbique eyi to fere to bilionu kan ati
abo owo dola Amerika.
Minisita oro ile okeere na so wipe o ye ki won gbe igbese lori oro na lesekese
paapa leyin omiyaleyaona eyiti o ti ba orile-ede na je.
Ni osu keji odun, die ninu awon ti Mozanbique je ni gbese fowosi idaduro odun
kan laisan gbese sugbon ijoba Mozanbique so wipe ifagile gbese ni iba ti dara
ju.
Nibayi sa, awon omo ogun ti awon orile-ede Amerika, Geesi ati Germany ko lo
lati se iranwo ninu akitiyan
akoyo ni Mozanbique ni o ti bere si kuro. BBCNEWS
Ajo CITES dabobo eja aye igbaani 3mins. 59secs. Eja kan ti a mo si
coelacanth, to je eja aye igbaani eyiti a ti ro tele wipe o ti parun
patapata pelu awon omiran
eranko aye igbaani ti a mo si dinosaurs ni o gba idabobo nigbati Ajo
Agbaye fun Adehun lori owo kariaye ninu awon Eya to wa labe ewu iparun (UN Convention
on International Trade in Endangered Species (CITES)
gbesele owo ninu re. Apero nla olorileede adojo na eyiti won se ni ilu Nairobi
orile-ede Kenya tun fohunsokan lati gbesele owo ninu malu okun orile-ede Australia
kan ti a npe ni dugong. Ijapa okun ile Asia ti a npe ni box
ati awon ijapa oni patako lese ti ile Afirika na ni won fi si ori akosile
awon eya to wa labe ewu, apero na si
seleri lati teramo idabobo won. Ajo CITES tun fowosi igbesele olojo pipe to
ti wa lori owo ninu erin, abuibutan ati awon ijapa okun. Adehun
na ti fi aabo olorisirisi ipele sori awon eya eweko ati eranko to ju egberun
lona ogbon lo. 10
10 Page 11 12
Vol. II No. 18 (Yoruba) CHANGE Radio July, 2000
11
Ipinnu lati dabobo eja coelacanth to ti wa fun irinwo egberun odun ko
ni atako kokan rara. Akojopo coelacanth meji pere ni a ti se awari won
nibiti gbogbo eja na to wa nibe ko ju edegbeta lo.
Awon onimo ijinle sayensi ti ri eya ara eja na ti a wu jade lati inu ile, won
si ti gbagbo wipe o ti di awati pelu
awon omiran eranko dinosaurs sugbon awon eja to si wa laaye ni won ri nitosi
erekusu Comoros ni okun kariaye ti India ni odun 1938. Ni odun meji seyin, won
tun ri awon eja miran nitosi erekusu Manado Tua ni
orile-ede Indonesia.
Ibere wa fun awon eja na lati awon ajo to ntoju awon ohun isenbaye ati lati
awon orile-ede nibiti won ti rohin
eja na wipe o nse alekun agbara okunrin fun ibalopo. Pelu bi o se je wipe eja
na die lo wa, awon afenifere itoju fe ki a gbesele owo ninu eja na to wa labe
ewu iparun ati eya eja na ti a ba se awari ni ojo iwaju.
Awon asoju ninu ipade ajo CITES tun fenuko lati se agbekale ilana kan labe
eyiti a o gba isowo laaye ninu awon ijapa okun ile Asia ti a mo si box ati
ninu eya urial to je agutan egan ti a ma nri ni orile-ede mejo ni
aringbungbun ile Asia.
Awon ikepe fun igbesele patapata lori owo ninu awon eja dolphin onimu-bi-igo
ti okun dudu ati gbogbo eya agbonrin kekere olorun-didun ti a mo si musk
ni won ko gba wole. Dipo re ni won se awon ipinnu to kepe
awon orile-ede to je omo egbe lati se iwopale isowo ti ko bofin mu to nlo lowolowo
ninu awon eya na. CNN. com
Igbesele isowo ninu ijapa okun si wa sibe ni orile-ede Cuba 2mins. 59secs
Aba orile-ede Cuba lati ju okun igbesele olodun medogbon lori isowo ninu
awon ijapa okun sile die ni o kuna
ninu ipade Ajo Agbaye fun Adehun lori owo kariaye ninu awon Eya to wa labe ewu
iparun (UN Convention
on International Trade in Endangered Species (CITES) eyiti o sese pari ni ilu
Nairobi. Ajo CITES ko lati jeki orile-ede Cuba ta awon akojo igba eyin awon
ijapa okun ti a mo si hawksbill to si sowon gidigidi.
Aba na ni lati gba orile-ede Cuba laaye lati ta egberun medogun o le igba
iwon igba eyin hawksbill fun orile-ede Japan ninu itaja eleyokansoso. Orile-ede
Cuba nilo ifowosi lati odo iko meji ninu meta awon to wa si
ipade sugbon o kuna pelu aami kekere nigbati orile-ede merindinladorun dibo
faramo aba na ti awon mejidinlogoji dibo tako. Awon medogun ko dibo rara.
Orile-ede Cuba tun bere fun ase lati mu edegbeta hawksbill lododun fun tita
lati inu awon omi re sugbon o fa ibere na seyin nigbati atako po pupo lori re.
Hawksbill le won to iwon mejileladoje. Igba eyin won si ma ni awon ila alawo
osan, ofefe and kofi, eyi si mu ki won di eya ti awon eniyan fe julo ninu eya
meje ijapa okun to wa laye. Igba eyin re ti won npe ni "bekko"
ni orile-ede Japan ni won ma nlo fun awon ohun ona ati eso ara. Awo ara hawksbill
ni won ma nsagbe lati fi se bata alawo.
Awon afenifere itoju gba wipe orile-ede Cuba ni ilana isakoso to dara fun
awon ikore re sugbon won kilo wipe hawksbill je eya to wa labe ewu iparun to
ga, ti won ba si gba owo ninu re laaye labe ofin eyi yio se
irusoke ibere ti yio yorisi ijiodese re nibomiran. Cuba ma nse ikore bi edegbeta
hawksbill lododun sugbon igba eyin re ni won nfi sinu akojopo ti orile-ede
nigbati eran ara won ma nlo sodo awon ara ilu gegebi ounje. Awon ijapa okun
ti ngbe ninu awon okun kariaye fun irinwo egberun odun sugbon iye won ti lo
sile pupopupo ni awon ewadun to koja lo. Ajo CITES gbesele 11
11 Page 12 13
Vol. II No. 18 (Yoruba) CHANGE Radio July, 2000
12
isowo kariaye lori opolopo ijapa okun ni odun 1971, o si fi awon eya to ku kun
akosile na ni odun 1981. CNN. com
Ajo CITES fi ake kori wipe igbesele isowo ninu ehin erin gbodo tesiwaju
2mins. 45secs.
Inu awon afenifere itoju dun si abajade apero ti awon egbegbe si Ajo Agbaye
fun Adehun lori owo kariaye ninu awon Eya to wa labe ewu iparun (UN Convention
on International Trade in Endangered Species (CITES)
eyiti o waye ni ilu Nairobi ni orile-ede Kenya.
Bi ariyanjiyan to gbona tile wa, awon asoju si ipade fohun sokan lati fi edidi
di igbesele kariaye lori isowo ninu
ehin erin, o si ko awon aba ti iba yorisi idinku ninu idabobo to wa lori awon
abuibutan gray ati minke.
Ninu igbese ti a ko fokansi, gbogbo ibere fun isowo ninu ehin erin ni won
fawo won seyin ninu apero na. Awon orile-ede Botswana, Namibia ati Zimbabwe
gba ibere won lati sowo ninu ehin erin pada. Ni idahun,
orile-ede Kenya ati India fagile aba won lati se igbesoke akojopo erin to wa
ni awon orile-ede meteta.
Gbogbo awon orile-ede na lo gba lati dawo ise duro lori awon ipinnu won yi titi
ti won o fi fi ilana iwoye fun ijiodese ati isowo to dara lele.
Nibayi, aba alajose lati orile-ede Britain, Amerika ati Australia kuna lati
ri ifowosi iko meji ninu meta lati fi eja
yanyan funfun nla sinu awon eya to wa labe ewu iparun. Iru itosile yi ni iba
fi idabobo akoko labe ajo CITES frun awon eya eja okun ti won npa fun isowo.
Opo ninu awon atako si aba na da lori ariyanjiyan lori boya Ajo
Agbaye fun oro Ounje ati Ise Ogbin tabi Ajo CITES ni ko ma se kokari isakoso
awon eya eja to wa labe ewu.
Karen Stener to je oludari ilo awon eranko egan fun isowo fun Akojo Owo ni
Kariaye fun Itoju Eranko (International Fund for Animal Welfare) so wipe: "o
han gedege wipe awon ajo olusakoso ipeja ni awon
elekunjekun ti kuna lati toju awon akojopo eja yanyan, eyi si je ohun to banininuje
fun itoju eja yanyan."
Bi apero na ti wa sopin, o han gedege wipe ipo awon erin dara pupo ju ti opolopo
awon eya eranko to wa
labe ewu iparun lo. ENN
Orile-ede Australia fi ehonu re han lori pipa ti orile-ede Japan npa abuibutan
2mins. 15secs. Orile-ede Australia ti fi ehonu re han si iroyin wipe orile-ede
Japan ngbero lati mu eto iwadi re lori abuibutan
to nfa iku dani gbooro si.
Minisita fun Ayika, Robert Hill so wipe o ya on lenu lati gbo ninu iroyin wipe
orile-ede Japan nfe lati tesiwaju pelu pipa to npa abuibutan minke ki
o si tun mu ise na gbooro de odo eya meji miran, iyen abuibutan Bryde
ati abuibutan Sperm ni iha ariwa okun kariaye pacific.
Ninu oro re, Hill so wipe: "ko si idi to munadoko ninu imo ijinle sayensi lati
pa awon abuibutan nitori ati se iwadi lori won."
Hill tesiwaju lati so wipe orile-ede Australia yio fi ehonu re han ni kiakia
ni ona olorilede sorileede ni ilodisi re si oro yi ki o si wa opin si pipa awon
abuibutan. Orile-ede Australia yio tun se kokari fun alekun idabobo fun
awon abuibutan ninu ipade olododun kejileladota ti Ajo Kariaye fun Abuibutan
ni ilu Adelaide, ni iha gusu orile-ede Australia laarin ojo keta ati ikefa osu
keje odun yi. 12
12 Page 13 14
Vol. II No. 18 (Yoruba) CHANGE Radio July, 2000
13
Orile-ede Japan lo nje eran abuibutan julo ni agbaye. Biotilejepe o ti gbesele
pipa abuibutan ni onirepete fun isowo ni ibamu pelu awon ofin kariaye, orile-ede
na si npa abuibutan fun iwadi ti imo ijinle sayensi. Eyi si
nyorisi mimu abuibutan minke bi edegbeta lododun ninu okun kariaye Antarctic
ati iha ariwa okun kariaye pacific: Eran ara won lo ma nlo sinu oja fun jije
awon eniyan.
Orile-ede Japan jiyan wipe awon abuibutan minke po tobe ti won fi nmu irokeke
ewu ba iruula awon eya eja miran, ati wipe o seese lati pa egbaa abuibutan lododun
lai fi awon eya na sabe ewu iparun.
CNN. com Nature
Orile-ede Egypt ati Thailand gba awon eru ehin erin to po 2mins. 33secs.
Awon asobode ti gba egberun-o le-mejidinlogorun iwon ehin erin ni idiko
baalu ni ilu Bangkok. Won ko ri eyi
to po to be gba ri. Eniti won mu gegebi onifayawo na ni won ti ju sile. Ehin
erin mejileladofa na ti iye owo re ju egberun lona mokanleladoje owo dola Amerika
lo ni won ri ninu apoti meta eyiti a gbe lati orile-ede
Zambia. Ehin erin na ni won fi pamo sabe eru awon okuta iyebiye ti won ko tii
sise lo lori.
Mohammed Tailo to je omo iha iwooorun Afirika ni won damo gegebi onifayawo na
nigbati o wa si idiko baalu na lati gba awon eru na. Won fi sile leyin na nigbati
o ti gba lati kowe fi gbogbo ehin erin na fun ijoba
Thailand.
Labe ofin orile-ede Thailand, eniti o ba ni eru ti a ko wole lona ti ko bofin
mu yio bori ti o ba fi gbogbo eru na fun ijoba. Won ko iti pinnu lori ohun ti
yio sele si awon ehin erin na sugbon iroyin so wipe won yio ba gbogbo
re je tabi ki won ko fun eka ile-ise ijoba kan lati se afihan re.
Bakanna, awon olopa orile-ede Egypt gba eru ehin erin, iye ti won ko iti gba
ri, ti iye owo re ni ita ju oke
mewa owo dola Amerika lo. Ni ojo kokandinlogbon osu keta odun yi, Ile ise ijoba
orile-ede Egypt fun oro Ayika kede wipe ehin erin mejidinlogorin ni awon ri
gba ni ile ikerusi kan ni ilu Aswan.
Isowo kariaye ninu ehin erin ni won ti gbesele lati odun 1990. Ile ise ijoba
orile-ede Egypt fun oro ayika to nse agbero ofin na so wipe lati aringbungbun
ile Afirika ni won ti ko ehin erin na wa. Ile ise na so wipe onileikerusi
kan ni ilu Aswan ti gba awon ehin erin na fun pinpin fun awon onisowo ehin erin
jakejado orile-ede na. BBCNEWS/ CNN. com Asianow
Won se awari Iresi iyanu 2mins. 33secs. Orisi iresi kan ti won fi imo
ero nipa ajogunba eya gbekale eyiti o le se afikun ikore to bi iko marundinlogoji
ninu ogorun ni awon onimo ijinle sayensi ni orile-ede Amerika ti se awari re.
Irugbin titun na ni won siso loju re ninu apero kariaye lori imo ero iresi ni
orile-ede Philippines.
Iresi je ounje kosemani fun bi idameta awon olugbe aye. Iresi titun na ni
a lero wipe yio ko ipa pataki ninu igbogunti ebi. Eweko na ni awon onimo ijinle
sayensi ni ile iwe giga Yunifasiti ti ipinle Washington ati awon
oluwadi lori ise ogbin ni orile-ede Japan gbe jade.
Onimo ijinle sayensi to je asiwaju ise agbese na, Ojogbon Maurice Ku se alaye
wipe eroja ajogunba eya lati ara agbado ni won fi sinu iresi na pelu eroja eya
fun irugbin ti a mo si pyruvate orthonophosphate dikinase.
Eyi se alekun iye ilana iseda aye fun imudagba eweko -iyen ona ti awon eweko
ngba lati fi se aye won.
Asewo ni oko mu ki ikore fo lo soke lona iyanu, biotilejepe Ojogbon Ku kilo
wipe awon abajade na si wa ni iberepepe. 13
13 Page 14 15
Vol. II No. 18 (Yoruba) CHANGE Radio July, 2000
14
Gegebi oro re "Lati so di pipe, a gbodo se awon idanwo sii, ki ise ninu oko
nikan sugbon ayipada sii pelu afikun awon eroja miran lati mu dara si." O wa
fikun wipe o le gba won to odun meta si marun ki won to le
fi iresi titun na le awon agbe lowo.
Nibayi, awon amoye ti Ile-ise Iwadi kariaye lori Iresi (International Rice Research
Institute) so wipe alekun to nyara deba iye awon olugbe ti sare ba awon idagbasoke
ninu iye ikore awon oka ti o ti waye laarin odun
merinlelogbon to koja. Awon agbe gbodo gbe alekun milionu mefa o le oke marundinlogoji
iwon tonnu iresi jade lododun. Won gbodo se eleyi pelu ile to kere si ati omi
to kere si lati le mu ki ounje to peye wa ni awon
ipele to wa nisisiyi. BBCNEWS
Ifojusi
Awon onimo ijinle sayensi se agbejade awari lori bi emi se bere 2mins.
8secs. Fun igba akoko awon onimo ijinle sayensi le woye gbogbo ilana ajogunba
eya eda eniyan lati wa awon idi tabi
bawo ni a se le mo ki a si se iwosan awon arun. Aseyori yi na ni a le ro wipe
yio ni abajade olojo pipe gegebi agbejade agba keke.
Eroja Chromosome 22, eyiti awon egbe onimo ijinle sayensi ni kariaye kan se
itumo re, je okan ninu awon adipo eroja DNA merinlelogun to wa ninu seeli eda
eniyan to ni ifitonileti toto lati so fun ni on to wa ninu eda
eniyan. O gba egbe na ni gbogbo ewadun to koja lati fi se itumo gbogbo leta
by milionu metalelogbon to wa ninu Chromosome 22. Ise na se afihan ogogorun
awon eya eda ara eniyan titun.
O ju ogbon aidogba ilera lo ti a mo nisisiyi pe eroja chromosome na ma nse
okunfa re, lara eyiti a ti ri ibaje okan, idibaje eya ara ati arun opolo "schizophrenia."
Igbese kini ninu iwoye eroja chromosome yio je lilo ifitonileti ti a ti kojo
lati fi mo arun ninu awon eniyan. Bi a ba si nmo sii nipa awon itumo adiitu
na, awon egbogi ati ona igbasewosan titun ni a lero wipe yio yoju.
Nigbeyigbeyin a o se idiwon itoju aisan si bi eya eda eniyan kokan ba se ri
gan an.
Gegebi oro Dokita Francis Collins lati ile ise orile-ede Amerika fun oro Ilera,
to je alaga Ise Agbese lori Eda Eniyan na se so, "Eyi ni igba akoko ti ani ori
kan to kun ninu iwe ifuninimo lori eda eniyan, o si yanilenu
gidigidi." BBCNEWS
Ifojusona si osu kefa fun itupale ajogunba eya ara eda eniyan 2mins. 42secs.
Agbeleko ikini lori adiitu ajogunba eya ara fun emi eda eniyan ni yio wa
lori Itankale Ero Asisebiopolo
komputa lori ero Ibanisoro, iyen Internet lati osu kefa odun yi. Ifilo yi lati
odo Ise Agbese lori Itupale Ajogunba Eya Ara eda eniyan (Human Genome Project
HGP) eyiti gbogbo ara ilu nse inawo re ti se idinku si
ojo ti egbe alafowosowopo-se-nkan ti kariaye yio te iko mesan ninu mewa itupale
ajogunba eya ara eda
eniyan jade. Ifilo na wa leyin awuyewuyewuye lori boya gbogbo ajogunba eya ara
eda eniyan ti a ba tu pale ni ki gbogbo
eniyan ni eto lati mo tabi ki o seese fun awon ajo oloko-owo lati dabobo awon
imo na labe ofin.
Nisisiyi HGP ti se itolerawon lesese eyi to ju bilionu (milionu lona egberun)
meji lo ninu bilionu meta leta to wa
ninu itupale ajogunba eya ara eda eniyan. 14
14 Page 15 16
Vol. II No. 18 (Yoruba) CHANGE Radio July, 2000
15
O sese pe osu merin ni leyin to koja bilionu kan. Nitoto, ni ogun odun seyin,
yio gba eniyan ni akoko to ju odun kan lo lati se akojopo egberun mejila awon
ipile. Loni, iseju kan pere ni yio gba.
Gegebi oro Dokita Francis Collins to je oludari HGP, "Iroyin rere ni wipe a
nyara lo sugbon iroyin to tun dara
ju ni wipe awon oluwadi jakejado aye nlo imo yi lati fi se iwadi iru ipa ti
ajogunba eya ara eda eniyan nko ninu ilera."
Ninu isele kan to farako eyi orile-ede Amerika ati Britain ti so ninu oro
ajogbejade ikede wipe awon onimo ijinle sayensi jakejado aye gbodo ni anfani
lati lo iwadi lori itupale ajogunba eya ara eda eniyan.
Pelu ifohunsokan wipe iwadi sinu ilana-eto ajogunba eya ara eda eniyan je okan
ninu awon ohun to se pataki julo lati igba iwase, awon orile-ede mejeji tesiwaju
lati so wipe lati le ri ileri kikun iwadi na, "imo ipilese lori
itupale ajogunba eya ara eda eniyan ati itolerawon lesese ati ipinsi orisirisi
re ni a gbodo jeki o wa ni arowoto gbogbo onimo ijinle sayensi nibi gbogbo laisi
idena kokan."
The Financial Standard/ BBC News
Egbogi agbejako kokoro bakteria lo se idena awon ikolu to je mo kokoro-arun
HIV. 1min. 42secs.
Egbogi agbejako kokoro bakteria ti ko won to si wa yanturu ni o seese ki
won fun bi awon omo ile Afirika
milionu meji to nni awon ami kokoro arun HIV tabi ti arun kogboogun Eedi nitori
o le dena awon afomo ikolu lona ara ko si gba emi la.
Ajo UNAIDS ati Ajo Agbaye fun oro Ilera (World Health Organisation) yio gbaniniyanju
lati lo egbogi agbejako iredodo fukufuku ti a mo si cotrmoxazole. Ni apakan,
eyi da lori awon awari egbe amoye kan wipe
idaji ninu awon to ni arun Eedi to lo egbogi na lo ku, sugbon gbogbo awon miran
to ni arun na ti ko lo egbogi
na lo ku. Egbogi na le dena awon orisi iredodo fukufuku ti kokoro bakteria to
nni ikolu lara eje ati ilana dida ounje nfa Ajo "Life Initiative", eyiti Ile-ise
Aare orile-ede Amerika gbe owona ogorun milionu owo dola
Amerika sile fun ti so wipe on le ra egbogi na fun orile-ede merinla ti oro
na kan. Sugbon sa, ajo UNAIDS tenumo wipe egbogi na je ojuutu onigba-die ni,
ati pe on ko iti pinnu iye ewu to wa ninu lilo egbogi na kakiri
le yorisi igbaagbarasi lati owo awon kokoro bakteria tintintin to nfa arun.
Associated Press
Awokose SAVANNA fi imole titun han lori iwontunonsi laarin eda abemi egan
ati eda eniyan. 1min. 43secs.
Awokose ori ero asisebiopolo komputa kan to le sotele iru awon ayipada ti
yio wa ninu ayika ila-oorun ile
Afirika to takoko yio jeki imo wa ni arowoto awon eniyan ilu to ntiraka lati
koju isoro ilo ile ati isakoso eda abemi egan.
Awokose komputa na ni a pe ni SAVANNA. Awokose na eyiti Ajo orile-ede Amerika
fun Idagbasoke ni kariaye gbe owo sile fun, ni won ti wa lenu e lati odun medogun
seyin. SAVANNA ni awokose kini to ni
agbara lati koju gbogbo orisirisi ilo ile ati eto imulo to dojuko awon agbegbe
ti ijoba dabobo ni awon ile perese orile-ede Kenya ati Tanzania to lo salalu.
Gegebi Robin Reid to je amoye lori ilo komputa nipa ilolupo awon eda abemi ni
agbegbe won, to nsise pelu Ile-ise Iwadi kariaye lori Eran-osin (International
Livestock Research Institute (ILRI) to wa ni ilu Nairobi ni
orile-ede Kenya se so, aini ona si imo to se gbokanle ti ge opolopo eniyan kuro
ninu awon ipinnu to kan ojo
iwaju won gbongbon. Nibayi, awokose na ni won nse agbekale re ni ajo ILRI.
Reid so siwaju wipe: "Ayafi ti a ba ri awon imo to dara to si je otito lati
fi siwaju awon to nse ipinnu awujo ki 15
15 Page 16 17
Vol. II No. 18 (Yoruba) CHANGE Radio July, 2000
16
won le ni orisun miran lati da ipinnu won le, bikose be o ko le ri ohunkohun
yato si oro oloselu to ro mo ohun to nsele."
Lara awon irokeke ewu si awon agbegbe ti ijoba dabobo ni ila-oorun ile Afirika
ni ilosoke ninu iye awon
olugbe, osi, ijiodese ati ojukokoro oloselu. Awon nkan wonyi ti lowosi ilosile
iko marundinladorun ninu ogorun ninu iye awon erin to wa ni orile-ede Kenya.
Pelu SAVANNA awon ti oro naa kan yio le mo awon ikolu olojo-kukuru ati olojo-gigun
ti iru iwa bi idako-ogbin, sisin maalu, ilosoke iye awon olugbe ati ile kiko
yio mu wa.
Lowolowo, ILRI ni eto idanileko fun awon omo orile-ede Kenya, Tanzania ati Uganda
lati se afihan iye iru isele eto imulo ati isakoso ti SAVANNA le koju e.
CGIARNEWS
Asewo pelu taba igbo yio bere lori awon alaisan 1min. 34secs. Awon
asewo ti isegun pelu awon egbogi ti taba igbo wa ninu won lori awon alaisan
to ni awon ikolu lile-sodi
awon eran inu ago ara, ifarapa si egungun eyin, ati orisi irora to ga miran
ni ijoba ile Geesi ti fun ni ase lati tesiwaju.
Ajo oloko-owo Glaxo Wellcome Pharmaceuticals, ti Ile-ise Ijoba Ile Geesi fun
oro abe-ile fun ni ase lati se iwadi ki won si gbe awon egbogi to ni taba igbo
ninu fun ifunni lati owo awon dokita, ni yio se awon asewo na.
Ti won ba yorisi rere, won le yorisi mimu awon egbogi to ni taba igbo ninu wa
repete laarin odun meta. Iwonba awon alaisan die ni yio kopa ninu awon asewo
alakoko. Sugbon sa, a lero wipe awon eniyan bi egbaa
kan ni yio darapo mo eto asewo na laarin odun meji si meta to nbo. Ijoba ti
so wipe ti awon asewo na ba
yorisi rere, on setan lati se atunse si Ofin Asilo Egbogi lati gba ifunni ni
egbogi to ni taba igbo ninu laaye. Ajo Glaxo Wellcome ni ireti lati ta awon
egbogi oniyanfunni lati owo Dokita nikan lati odun 2003.
BBC NEWS Online
O seese ki imole oorun fa arun ebo-oju 1min. 34sec
Awon onimo ijinle sayensi ti se awari wipe isirasile si imole oorun le se
alekun ewu lati ni arun ebo-oju. Awon oluwadi to woye awon olugbe ilu Sete ni
orile-ede Faranse ri wipe awon egbaa ole edegbeta ati merinlelogorin
eniyan to sirawon sile si imole oorun to ga tabi si itansan oorun ni o fi
ilopo merin wa labe ewu ati ni arun ebo-oju ju awon ti ko sirasile si oorun.
Bi isududu se nnipon si yio di itansan imole lowo lati koja ninu awo oju ki
o si lo sara ate inu oju fun iriran. A ro wipe itansan alagbara to wa ninu itansan
oorun le mu ki isududu awo oju
tete sele.
Biotilejepe won ko ni imo pupo lori awon ona lati fi din ewu ebo-oju to ro
mo imole oorun ku, Dokita Delcourt to je olori egbe oluwadi na, gba awon eniyan
nimoran ki won ma yera fun isirasile si imole oorun ni
ojo kanri, ki won si de fila tabi lo awo oju to su dudu. Ikolu imole oorun na
ni a ro wipe o se akojo lerawon,
besi ni isirasile nigba omode se pataki bi isirasile nigba agba na. BBC News
Online
Orile-ede Japan mu Eto Iderun Gbese gbooro si 1min. 46secs. Orile-ede
Japan ti se alekun si eto iderun gbese re lati dariji iko adorun ninu ogorun
si gbogbo eyawo ti won
se fun awon orile-ede to talaka julo laye. Ifilo yi to waye ni bi osu melo saju
igba ti orile-ede Japan yio gba Egbe awon orile-ede mejo to ni oko-owo julo
laye ni alejo ni osu keje odun, ni o kan awon eyawo ti ko si lara
awon eyawo iranlowo ijoba orile-ede na fun idagbasoke. 16
16 Page 17 18
Vol. II No. 18 (Yoruba) CHANGE Radio July, 2000
17
Eto iderun gbese na kan ogoji orile-ede ti eyawo won po gidigidi. Iru awon eyawo
be ti iye re to bilionu (milionu lona egberun) kan o le okoolelodunrun milionu
owo dola Amerika ni o wa fun idojuti ofo lori isowo
tabi eyiti awon ajo ara ilu bi awon banki fun iko-oja-losi-ile-okeere ati ikojawole
ya sita. Orile-ede Japan ti dari gbogbo eyawa ti ijoba se fun idagbasoke ji.
Orile-ede na tun seleri idawo sii si Akojo owo Banki
Agbaye fun iderun gbese, eyiti yio mu idawo re di igba milionu owo dola Amerika.
Ifilo orile-ede Japan yi se imugbooro si si ileri to se ni odun to koja si ipade
awon orile-ede alagbara mejo ni ilu Cologne, orile-ede
Germany, nibiti awon orile-ede aye to lowo ju ti fohunsokan lati fun awon orile-ede
to talaka ju lagbaye ni iderun gbese to to adorun bilionu owo dola Amerika.
Associated Press
Awon orile-ede G. 8 si ni ireti fun Adehun lori Ayika 2mins. 37secs. Egbe
olorile-ede mejo (G. 8) ninu eyiti ati ri orile-ede Amerika, Canada, Faranse,
Itali, Japan, Geesi, Germany
ati Russia pari ipade olojo-meji ni iha iwo-oorun orile-ede Japan pelu oro asokagba
wipe awon lero lati fowosi adehun pataki lori imorusi aye nigbati yio ba fi
di odun 2002.
Bi atako tile wa lati odo orile-ede Amerika ati Canada, nipa akoko wo pato
ni ifowosi na yio waye, awon minisita fun oro Ayika faramo adehun kan to nkepe
orile-ede Amerika lati din awon efin oloro to nfa imorusi
aye si iye to fi iko meje ninu ogorun din si bi won se wa ni odun 1990. Orile-ede
Japan ati ile Europe na yio se idinku oni iko meje ati mejo ninu ogorun si bo
se wa ni odun 1990. Awon ajo oloko owo oko irinna ati epo
robi ni orile-ede Amerika ti won wa lara awon to ntu eyi to poju ninu awon efin
oloro na jade so wipe adehun na yio pa oko-owo awon ati oro aje orile-ede won
lara nipa fifi agbara mu won lati na owo to po si lori irin-ise
ati imo ero.
Awon onimo ijinle sayensi gbagbo wipe ilosoke ninu efin oloro CO 2 lati inu
jijo epo ati awon ohun idana miran
lati inu ile ni o nmu ayika ile aye gbona sii. Awon miran nkominu wipe awon
yinyin ori oke to nyo ni ekun ariwa aye patapata ti a mo si polar le fa omiyaleyaona
ni awon ile perese to yi won ka, nigbati oju ojo to gbona si ni
awon ibomiran le yorisi ogbele to gbooro. Igbimo kan ti ajo agbaye gbe dide
ti sotele wipe iwontunwonsi igbonatutu ni agbaye yio lo soke pelu ipele meji
si mefa laarin ogorun odun sii ti a ko ba din itujade awon efin
oloro na ku. Associated Press
O seese ki aseyori lori Egbogi kan se iranlowo fun iranti opolo ninu awon
arugbo 1min. 48secs.
O seese ki aseyori kan lori ajogunba eya ara eda eniyan yorisi awon itoju
ti yio mu ki okan awon agbalagba
mu yanyan bi ti awon odo. Biotilejepe itoju titun na ni a sese danwo lara awon
ekute, awon abajade re ntokasi wipe o seese ki iru itoju be waye fun eda eniyan.
Nigba pupo awon agbalagba ma npadanu agbara won lati keko ati lati ranti,
sugbon awon onimo ijinle sayensi gbogbo wipe awon ti mo eroja ajogunba eya eda
eniyan to nmu ki eleyi sele. Ninu awon odo eroja yi ma nse
iranlowo fun ilana ikeko nigbati o ma nsise seyin ninu awon agbalagba. Sugbon
nipa 'pipana' eroja yi ti a mo si KVBI, o ti seese fun awon oluwadi lati mu
ki awon ekute to ti dagba se daradara bi awon odo ninu ikeko
ati iranti. Awon oluwadi ni Ile-Ise Wolfson ni ilu London gbagbo wipe o seese
ki awon awari won fun won ni imo lori awon ohun to nfa Arun to ngba iranti eniyan
lo ti a mo si arun Alzheimer. Ni lowolowo bayi, ile-ise na
ndan egbogi kan wo eyiti o le dena ise eroja na nipa lilo imo ijinle sayensi
nipa ikolu egbogi ninu ara lati sin
ikolu na je. Bayen, won le se agbedide horo oogun fun iranti fun awon arugbo.
BBC News 17
17 Page 18 19
Vol. II No. 18 (Yoruba) CHANGE Radio July, 2000
18
Awon obirin ile Afirika ni a fojusi ninu Ipolongo lati tako ifi-iyato-si
2mins. 30secs.
Ifi-iyato-si to nkoju awon obirin si wa gegebi ofin ni ile Afirika, sugbon
sa awon ajafitafita nse ipolongo lati yi eyi pada ninu ipolongo jakajado ile
na fun awon atunse.
Yiyan awon agbegbe ifojusi fun egbe obirin ni ile Afirika na fonilaya: iha
ariwa orile-ede Naijiria, nibiti a fi ase fun nina awon iyawo, sugbon ki o ma
si 'ifarapa to buru': orile-ede Ethiopia, to gbesele ipelejo awon afipaba-obirin-
lopo ti won ba fe olufaragba won: ati awon asa ayebaye jakejado ile na eyiti
o fi agbara ati ohun ini sowo okunrin nikan.
Sugbon gbogbo eyi ko se idilowo fun egbe ajafitafita fun awon eto eniyan na
to fikale si orile-ede Amerika ti a mo si "Ibadogba Nisisiyi", eyiti o si ile-ise
re kan ni Afirika si ilu Nairobi ni osu kerin odun lati se iranlowo fun
akitiyan lati koju ifi-iyato-si. Ohun ti ipolongo na dale ni lati se ibewo iparowafun
si ile-ise asoju awon orile-ede Afirika merinla ti won si ni awon ofin to fi
awon obirin se eda onipo-keji. Ifojusi pataki ni lati mu ki awon
omo ile Afirika ri imole, laarin gbogbo isoro miran to koju ile na, wipe akoko
ti to lati mu oro awon obirin ni okunkundun.
Ipolongo na fa die lara awon obirin die ti o wa nipo agbara ni ile Afirika
wa, lara awon ti a ti ri omo ile igbimo asofin ni orile-ede Uganda, Winnie Byanyima.
O nlo pupo ninu akoko re lati se eto fun awon obirin ti awon
ofin eya lori ijogun ti so di alaini bugbe mo. Awon opo titun ni awon arakunrin
oko won ma nle kuro lori ile won leyin iku oko won. Orile-ede Uganda, gegebi
awon orile-ede die miran, ti ri awon iyipada die. Awon
obirin ni ijoko die ninu ile igbimo asofin, eyiti a ya soto fun won ninu ipin
funni. Nwon tun ni ile-ise ijoba fun oro obirin.
Associated Press
Monomono nkolu orile-ede Ethiopia lekeji 3mins. 4secs. Ni odun medogun
seyin, iyan gba emi awon eniyan to ju milionu kan lo ni orile-ede Ethiopia.
Nisisiyi, itan tun
ntun ara re so. Loni, awon onise aanu siro wipe awon milionu mejo eniyan lo
wa labe ewu lati owo airiounjeje. Eyi to yorisi ikepe si iha iwo-oorun aye lati
dide ni kiakia pelu iranlowo ounje, lati le yera fun iru opo yanturu
iku kanna.
Gegebi Ethiopia si ti wa ninu ogun jija ni odun medogun seyin, bena ni o tun
wa ninu omiran nisisiyi. Iyato nisisiyi ni wipe ogun aala ile ni pelu orile-ede
Eritrea. Nitoto awon alase ni orile-ede mejeji ni won ti so fun
wipe ki won gbe ija ti segbe kan lati jeki o seese ki won mu iranlowo ounje
de awon agbegbe ti ikolu na wa ni Ethiopia.
Osise Ajo orile-ede Amerika fun Idagbasoke kariaye ba awon akoroyin soro leyin
ibewo olose-meji si die lara awon agbegbe ti iyan na ti nja. Gegebi oro re:
"Mo lero wipe egbe mejeji yio le wa awon ona, laarin ija
won lori awon ohun miran, lati ro ti inilo ise aanu to ga, paapaa ni iha gusu
orile-ede Ethiopia." Osise na, Hugh Palmer, so wipe idahun si ibere fun iranlowo
oko la ona to dara ju lo si ibudoko-oju-omi Assab ni orile-ede
Eritrea ni ko mu iwuri wa. Ni ibere ose kini ni osu kerin odun, orile-ede Eritrea
ti so wipe on gba ki won lo ibudo-ko-ojuomi na lati se
ipinkiri iranlowo ounje. Orile-ede Ethiopia ko oro na danu bi oro isoju-aye.
Orile-ede Ethiopia tun fi esun kan Eritrea wipe o ji opolopo iwon tonnu iranlowo
ounje lati Assab ni awon igba to ti koja.
Oludari Eto Iranlowo Ounje ni Agbaye ti Ajo Agbaye, Judith Lewis so fun ajo
BBC wipe awon nse gbogbo 18
18 Page 19 20
Vol. II No. 18 (Yoruba) CHANGE Radio July, 2000
19
ohun ti awon le se lati lo awon ibudo-ko-oju omi ti Djibouti ati Somaliland
to si sile sugbon ti ko to.
Nibayi, ni awon ilu bi Gode, isiro eniyan bi irinwo lo ku ni osu keta. Opolopo
ninu won lo je omode. Obirin kan to ni omo kan ti ara re ko ya so wipe ni osu
meji seyin, on ni omo meta. O padanu meji ninu won laarin
osu meji. Bi isoro na ti buru to niyi, a si nilo iranlowo lati yera fun ajalu
eda eniyan bi ti odun medogun seyin. BBC News
Ogba awon Eranko kan ni orile-ede China yio ya orile-ede Amerika ni beari
panda meji 1min. 47secs.
Ogba Eranko ti orile-ede Amerika to wa ni ilu Washington ti ntun ile beari
panda re to sofo se lati gbaradi fun awon ayalegbe titun meji lati orile-ede
China. Awon beari panda na ni yio de si ilu Washington ni odun to nbo
nitori ogba na gbodo se atunse ibugbe awon beari panda, ki o yan awon eranko
to fe ko si gba iwe ase lati ko won wole. Awon osise ogba eranko na pada lati
orile-ede China ni osu to koja pelu iwe a-gba-lati-se-be
labe eyiti orile-ede China yio ya ogba na ni beari panda meji. A si so wipe
yio na won to milionu mejo owo
dola Amerika lati ya awon eranko na, ti eya won wa labe ewu iparun, fun odun
mewa. Awon onimo ijinle sayensi lori ogba eranko yio se iranlowo to po lati
gba awon beari panda nlanla na to si wa ninu egan la. Awon
omo ti awon beari na ba bi laarin akoko na si le wa ni ogba Eranko orile-ede
Amerika na biotilejepe ohun ini ijoba China ni won yio je. Ni odun 1972, orile-ede
China fun orile-ede Amerika ni beari panda meji, Ling-Ling
ati Hsing-Hsing, awon ni won si di ohun ifanimora to gbajumo julo ninu ogba
na titi di ojo iku won laarin
ewadun to koja. Washington Post/ Associated Press
Isakoso awon orisun Omi: Ilo ati Eto Imulo ni awon agbegbe ologbele 1min.
31secs
Opolopo awon ajo olomi ni orile-ede Jordan ati Iran ni o seto apero kariaye
kan lori "Isakoso Awon Orisun Omi, Ilo ati Eto Imulo ni Awon agbegbe ologbele."
Apero na to waye ni orile-ede Jordan ni o ni awon
olukopa to ju ogoje lo lati orile-ede mejidinlogbon, ati awon to wa lati ajo
elekunjekun ati ti kariaye mejo. Laarin awon akoko eto pataki mefa na, o ju
iwe apileko merinlelogoji lo ti won ka eyiti o nse afihan awon
koko pataki ti yio dari bi a o se ma se akoso omi ni ojo iwaju: ilosoke to ga
ninu iye awon olugbe awujo, aini
imoye to to fun awon ara ilu lori idaamu to le waye lori ipese omi, aisi awon
ohun imusakoso to peye ati aisi ifowosowopo to ni ipele elekunjekun ati ni kariaye.
Apero na kepe fun idasile igbimo alagbara kan ti yio ma
koju owongogo omi ni awon agbegbe olegbele, paapa pelu bi awon olukopa se
muratan lati tenumo eto gbogbo eniyan lati ni omi to to fun awon ilo to se pataki
ati fun ipese ounje.
Consultative Group on International Agricultural Research (CGIAR)
Abuibutan to gunle si eti okun ni orile ede Japan ti ku 1min. 22secs. Abuibutan
kan to to iwon tonnu medogbon ni o ku ni etikun aringbungbun orile-ede Japan
biotilejepe akitiyan
lo lati wakati de wakati lati gbaa la. Abuibutan na eya ti Sperm, ti
o gun ju ese bata metaleladota lo, ni won ri ni etikun oniyanrin kan ni ilu
Osuka ni arigbungbun etikun pacific to wa ni bi ibuso marundinladoje si ilu
Tokyo. Gbogbo ara re lo si sile nitori iyo omi lo sile. Awon osise agbegbe ati
awon afinufedo-jura-eni-sile fun ise lati agbegbe ati leyin odi ilu sise ni
gbogbo oru lati da abuibutan na pada sinu omi. Nigbati won so wipe
abuibutan na ti ku, awon onise igbala duro ni idakeje pelu omije loju won. Tomio
Miyashita to je amoye lori abuibutan ni Ile-ise orile-ede Japan fun Ise ogbin,
Isogbo ati Ipeja, so wipe o je ohun ti o sajeji fun abuibutan
nla ti eya Sperm lati gunle setikun, ati wipe o seese ko je wipe iye
ati mona re ti ra. Kyodo News Agency/ Associated Press 19
19 Page 20 21
Vol. II No. 18 (Yoruba) CHANGE Radio July, 2000
20
Eroja ajogunba Eya eda eniyan se alekun ewu arun okan ninu awon to nfa siga
1min. 19secs.
Awon to nfa siga to ba ni eroja ajogunba eya eda eniyan to ti so mo awon
arun to so mo ifasiga ni o dojuko ewu ilopo meji fun arun okan ju awon ti ko
nii. Eyi ni abajade iwadi aipe yi kan to jade ninu atejade iwe iroyin
atigbadegba kan ti a mo si Atherosclerosis.
Awon eniyan ti ko ni eroja GSTT1 ni iko ogota ninu ogorun ewu arun okan
ti won ba nfa siga nigba ti awon to ba ni eroja na ni iko ogosan lori ogorun
ewu.
Iwadi na ri eroja na ninu iko merin ninu marun awon egberun o le igba ati
adorun eniyan ti won ye wo. Eroja GSTT1 na ni a lero wipe o je okun isopo pataki
lati le mo bawo ni ago ara se nlo awon kemikali to wa ninu
eefin taba. Eroja na ni won ti sopo mo awon arun to je mo siga fifa bi idibaje
apo-ito. CNN. com
Iderun Gbese fun orile-ede Tanzania 41secs. Ajo orile-ede Agbaye fun
Akojopo Owo ati Banki Agbaye ti kede edidi iderun gbese kan fun orile-ede
Tanzania. Edidi na ni owo re to bilionu (milionu lona egberun) meji owo dola
Amerika.
Banki Agbaye yio na owo to ju bilionu kan owo dola Amerika lo lori gbese na
nipase ajo re fun Idagbasoke
ni Kariaye. Iyoku ni awon ayanilowo olorilede pupo ati olorilede meji-meji yio
fara ro.
Iye gbogbo gbese ti orile-ede Tanzania je ju bilionu merin ati aabo owo dola
Amerika lo. BCC News
Ogbeni Bill Gates gbe Milionu metadinlogota owo dola Amerika sile lati
fi gbejako Arun Kogboogun Eedi 1min. 55secs.
Oga patapata fun ajo Microsoft, Ogbeni Bill Gates ti seleri milionu metadinlogota
owo dola Amerika laarin odun marun to nbo gegebi iranlowo lati le dabobo awon
omode ni ile Afirika kuro lowo ewu arun Kogboogun
Eedi. Igbeowosile na lati odo Ajo Amuludun Bill ati Melissa Gates ni o tii tobi
ju lati odo ajo amuludun aladani
lati se atileyin fun idena arun Kogboogun Eedi laarin awon odo. Awon odo lo
ko eyi to ju idaji lo ninu awon ikolu kokoro-arun HIV jakejado aye. Ajo Akojo
Owo ni
Agbaye fun Awon Olugbe (The UN Population Fund (UNFPA) ni yio na owo lori
ikojopo awon odo fun idanileko, idanileko lori Arun Kogboogun Eedi ni awon ile-eko
ati ipolongo ifinkanhan ti a doju re ko awon
odo. Ajo Agbaye si ti yan Botswana, Ghana, Uganda ati Tanzania nitori ife-inu
awon olori oloselu awon
orile-ede na lati dojuko oro Arun Kogboogun Eedi.
Orile-ede Tanzania yio gba milionu merindinlogun ati abo, Uganda yio gba milionu
medogun o le oke medogun, Ghana yio gba milionu merinla nigbati Botswana yio
gba milionu mejo o din oke marun, gbogbo re je owo
dola Amerika.
Eyi to ku ninu owo na ni yio wa fun owona fun ajo UNFPA ati awon ajo meji ti
ko lowo ijoba ninu-ajo Eto fun Imo Ero to sedeede fun Ilera (the Programme for
Appropiate Technology in Health) ati Asewariona ni
Kariaye (Pathfinder International). BBC News 20
20 Page 21 22
Vol. II No. 18 (Yoruba) CHANGE Radio July, 2000
21
O seese ki won ma le fi koko orile-ede Naijiria ranse si ile okeere mo laipe
yi 47secs.
O seese ki awon onikoko ni orile-ede Naijiria ma le ta oja won si ile okeere
mo laipe yi. Eyi waye nitoripe titi di isisiyi, orile-ede Naijiria ti kuna lati
yipada si lilo awon apo ti ko ni kemikali hydrocarbon. Awon apo na
lo je eyiti o se itewogba ni kariaye fun didi koko fun ifiranse si ile okeere.
Awon to nfi koko ranse lati orile-ede Naijiria si nlo apo idoho ti Ajo Onikoko
ni Kariaye ti gbesele lati odun to koja.
The Punch
Erekusu Taiwan yio se ifojusi Igbonriri ati Eya Ile apani ninu
ibere re lati di omo egbe Ajo Agbaye fun Oro Ilera. 1min. 56secs. Erekusu
Taiwan setan lati se ifojusi Igbonriri ati Eya Ile buruku to sele ni osu kesan
odun to koja nigbati o ba
tun tiraka lati darapo mo Ajo Agbaye fun Oro Ilera (World Health Organisation
(WHO). Osise kan so fun ajo oniroyin Agence France Presse wipe igbaradi ti nlo
lowolowo lati lo Igbonriri ati Eya Ile na to won to ipele
meje o le ikomefa ninu mewa lori ohun elo iwon janba na ti a npe ni richter
scale gegebi ategun lati di omo
egbe ajo WHO. Igbonriri ati Eya Ile na, to je eyi to lagbara ju ninu awon to
kolu erekusu na ni orundun yi ni o mu emi irinwo le egbaa kan lo, o pa egberun
mokanla eniyan lara o si so egberun lona ogorun eniyan di
alainilelori mo.
Osise na so wipe "Ajo Agbaye ko nawo iranlowo re jade laarin wakati merinlelogun
ti isele na sele ...... eyi
tilekun mo Taiwan kuro ninu ajo WHO to je ajo to farako Ajo Agbaye, eyi ko si
mu ise aanu ba awon millionu mejilelogun eniyan to ngbe ni erekusu na."
Erekusu Taiwan, ti orile-ede China ka si ekun kan to ya lo sugbon ti won nduro
de ipadabo re, ni won le jade kuro ninu Ajo Agbaye fun oro Ilera ni odun 1972,
odun kan leyin ti orile-ede China gba ipo erekusu na ninu
Ajo Gbogbo Orile-ede Agbaye. AFP
Ajo Agbaye fun Idagbasoke fe se idasile akojo-owo fun Imukuro osi ni orile-ede
Naijiria 1min. 19secs.
Ajo Agbaye yio se agbekale Akojo owo fun Imukuro osi (Poverty Alleviation
Trust Fund (PACTF) ninu akitiyan kan lati mu osi kuro ni orile-ede Naijiria.
Eniti o se afihan eleyi ni asoju ajo na ni orile-ede Naijiria,
Ojogbon Mkaya Kankuenda ninu apejo oloko-owo kan ti Ajo awon oloko-owo ti nsise
ni orile-ede Naijiria ati ile Geesi (Nigeria British Chamber of Commerce).
Akojo owo na ni a o doju re ko sise igbelese fun awon ilana idinku osi nipa
lilo awon afikun owo ti a toju fun ise oojo awon talaka ni awujo. Akojo owo
yio tun fun awon eniyan tabi ajo to ba nife lati se igbelaruge awon
eto idagbasoke agbegbe won ni anfani nipase awon ise awon amoye eyiti a se lati
ba inilo won mu. Eyi na ni a tun fokansi wipe yio se igbelaruge ise ajo UNDP
gegebi ajo ti a le fokantan to si munadoko ninu imukuro osi
ati idagbasoke eda eniyan. The Guardian
Awon obirin orile-ede Spain wo inu iwe itan 51secs. Luisa Feranda Budi
ati Esperanza Aguirre ni won kede won gegebi Olori ati Agbenu so fun ile igbimo
Asofin
kekere ati agba ti orile-ede Spain ninu osu kerin odun 2000. Eyi so orile-ede
Spain di ikarun ni agbaye nibiti
awon obirin ti nse olori awon ile igbimo asofin mejeji. Awon miran ni South
Africa, Bermuda, Belize ati 21
21 Page 22 23
Vol. II No. 18 (Yoruba) CHANGE Radio July, 2000
22
Jamaica, gegebi Egbe Alasopo awon Ile Igbimo Asofin se so.
Ni orile-ede Spain, o je igba akoko ti won yan obirin gegebi olori fun ile igbimo
Asofin kekere eleniyan odunrun-le-mokandinladota, biotilejepe Aguirre ti nse
olori Ile Igbimo Asofin Agba lati osu keji odun 1999.
The Punch
O setan ko setan: Awon odo orile-ede Naijiria ni ohun lori ero asomagbesi
redio 2mins. 51secs.
Ibanisoro fun Ayipada (Communicating for Change (CFC) awon olutejade iwe
iroyin Change Radio ti se
ifilole ere itage atigbadegba ori redio kan ti a pe ni O setan ko setan.
Awon ere ori itage na ni a beresi gbe safefe lati ojo kini osu kerin odun
2000 lori awon ile-ise redio jakejado orile-ede na.
O setan ko setan nfi awon odo orile-ede Naijiria (awon ti ojo ori won lo lati
odun merinla si mokandinlogbon) han lona to fa ogbon yo, ati imoye won to dayato
lori inilo fun idagbasoke orile-ede na. Awon ere na fojusi
iyanju ija, airiisese, igbeko, ayika, ilera ati eto oloselu gbogbo ara ilu ati
isejoba rere. Awon oro yi ni a ngbejade lori ipilese awon italaya to nkoju awon
odo orile-ede Naijiria lojojumo.
Gegebi oro Sandra Obiago to je Oludari Alase ajo CFC, "Ohun ti O setan ko
setan wa fun ni lati je ategun fun awon odo lati ba ara won soro, ki a le gbo
won, ki won si ri wipe awon ero won nlowosi ona orile-ede
Naijiria si imupadabo sipo." O tesiwaju lati so wipe on to mu awon ere na dayato
ni wipe "awon odo lo se e fun awon odo." Opolopo ninu awon osere ati osise ere
na ni won je awon odo olopolopipe ti ojo ori won ko
ju odun mejidinlogbon lo.
O setan ko setan je abajade iwadi to jinle lori agbejade re lara eyiti a ti
ri ibaraenisoro legbegbe mejilelogun ti
a se jakejado orile-ede na lori oro na. Ise na tun seto apejo pelu iranlowo
awon egbegbe odo mokanla nibiti opolopo odo lati oniruru igbesi aye ba ara won
soro lori ero won lori ipo ti orile-ede Naijiria wa nisisiyi, ati
awon ireti re fun ohun rere ni ojo iwaju.
Nibayi, awon atolera ere na ni awon eniyan ti nsoro re daradara gegebi ere to
lagbara to si so oju abe niko,
eyiti o fi bi awujo se wa pelu opolopo ilodisirawon inu re han. Sugbon ju gbogbo
eyi lo, awon atolera ere na nfi awon oluworan sile pelu emi ireti, o si ntoka
ona siwaju ninu orile-ede to nfi taratara nwa ona idagbasoke.
CFC
Iji lile Alajayika pa ogun eniyan ni Madagascar 55secs
Iji lile alajayika kan ti won pe ni 'Cyclone Hudah" ni o pa ogun eniyan
to si ni awon ikolu buruku miran lara awon egberun lona odunrun eniyan miran
ni iha ila-oorun ariwa Madagascar, gegebi Igbimo orile-ede fun
Igbanila (National Rescue Council (CNS) se so. Awon isiro na ni o wa lati
inu ibewo awon osise ijoba ati ti Ajo Agbaye si awon agbegbe ti iji na to ja
ni ojo keji osu kerin odun 2000 kan.
Gegebi oro Adama Guido ti Ajo Agbaye fun Eto Idagbasoke nigbati o se ibewo
si Antalaha to je olu-ilu ni agbaye fun eweko vanilla, "ko si ile ti
ajalu yi ko baje."
The Punch
Ijoba Oloselu tiwantiwa gba alekun si ni orile-ede Senegal 1min. 12secs
Awon ondibo bi iko ogota ninu ogorun ni o yan Abdou Wade ninu idibo fun
ipo aare orile-ede Senegal ninu osu keta odun. Eyi je ajabori pataki fun ijoba
oloselu tiwantiwa ni ile Afirika. Biotilejepe ninu akosile, 22
22 Page 23 24
Vol. II No. 18 (Yoruba) CHANGE Radio July, 2000
23
Senegal je orile-ede elegbe oselu pupo, a ti ma nse apejuwe orile-ede na bi
alafarajo ijoba oloselu tiwantiwa nitori ko si idibo to tii yorisi ayipada ninu
ijoba lati odun 1960.
Ni ogunjo osu keta nigbati aare to wa lori oye fi tiyiteye gba wipe Wade ti
bori, on ni o di olori ijoba ile Afirika
keta to se be laarin ewadun merin.
Lati igba ajabori yi, Abdou Wade ti seleri lati ri wipe ijoba oloselu tiwantiwa
tubo fese mule ni orile-ede Senegal nipa gige iye akoko ti aare le lo lori oye
lati odun meje si odun marun ki o ma si le lo ju akoko ijoba
meji lo. The Economist
Awon Eto Eda Eniyan ni ile Afirika 1min. 48secs Gegebi iwe iroyin alatigbadega
African Research Bulletin se so, awon ajo afenifere ti ko lowo ijoba
ninu ti
nkominu wipe o ye ki a gbe igbese to sekoko lori ipo ti eto eda eniyan wa ni
ile Afirika. Ni osu kokanla odun
to koja ni ilu Kigali ni orile-ede Rwanda, akoko ise ninu ipade kerindinlogbon
ti Ajo Ile Afirika fun Awon Eto Eda Eniyan (African Commission for Human and
People's Rights (ACHPR) ni o wa sopin pelu akosile
onikoko-oro merindinlogbon eyiti o bu enu ate lu awon iteloju ni awon orile-ede
to wa labe ogun. Lara awon iteloju yi ni idajo oni-paja-wiri, ogba ewon ti ko
dara fun eda eniyan, isikiri opo eniyan ati awon iba-eto-eda-eniyan-
je, paapa fun awon obirin, awon odo ati awon agbalagba.
Awon oluwadi otito ni won yio ran lo si orile-ede Burundi, Djibouti, Kenya ati
Sierra-Leone. Akokoko ilana ajo ACHPR lori eto awon obirin ni won yio fi ranse
si olu-ile-ise ajo OAU pelu ibere fun ise sise siwaju lori
re.
Ipade ketadinlogbon ti ajo ACHPR ni o waye ni orile-ede Algeria lati ojo ketadinlogbon
osu kerin si ojo kokanla osu karun. Ibere to yanilenu ti wa lati odo olori ijoba
ni orile-ede Rwanda -nibiti awon ibaje eto eda
eniyan ti waye ni odun 1994 -lati gba Ile Ejo Ile Afirika lori Awon Eto Eda
Eniyan ti a ndaba re ni alejo. The Courier
Ifojusona si Beijing ati Marun 1min. 30secs Beijing ati Marun ni yio
je ipade pataki ti gbogbo omo egbe Ajo Agbaye ti a pe ni "Awon Obirin ni odun
2000: Iwanidogbandogba Eya, Idagbasoke ati Alafia fun Orundun kokanlelogun".
A o see lati ojo karun si ikesan osu kefa odun 2000 ni olu-ile-ise Ajo Agbaye
ni ilu New York.
Ipade pataki ti ajo agbaye na ni yio se ayewo itesiwaju to ti wa ninu imuse
Awon Ogbon Imusenkan to fojusi ojo iwaju fun Ilosiwaju awon obirin eyiti a faramo
ni ilu Nairobi ni odun 1985 ati Itepepe Beijing funIse eyiti
a faramo ninu Apero Gbogbo Agbaye lori Awon Obirin ni odun 1995. Ipade na yio
tun ji roro lori awon igbese ati ise ojo iwaju fun odun 2000 ati siwaju.
Ipade yi ko jo ti Apero Beijing eyiti o fa awon olukopa wa lati gbogbo aye
si orile-ede ti a ti see. Eyi yio je ipade ti a se ni olu-ile-ise Ajo Agbaye
ni New York, awon olukopa yio si je omo egbe, awon alabasisepo
awon ajo oro-aje elekunjekun, awon ajo Agbaye fun awon Ise pataki, awon Ajo
ti ko lowo ijoba ninu ati awon Ajo Ijoba ni Kariaye.
WomenWatch 23
23 Page 24 25
Vol. II No. 18 (Yoruba) CHANGE Radio July, 2000
24
Eredi Beijing ati Marun? 1min. 30secs. Ikede ati Itepede fun Ise ti Beijing
ni won faramo ni Ipade Agbaye kerin lori oro awon obirin ni odun 1995.
Itepepe na se afihan ifaramo kariaye si ifojusi iwani-dogbandogba, idagbasoke
ati alafia fun awon obirin nibi gbogbo. O da lori awon ifaramo ti a se ninu
Ewadun Ajo Agbaye fun Awon Obirin lati odun 1976 de 1985:
Awon ifaramo to farako eyi waye ni apero to waye ni ilu Nairobi ati awon miran
ti a se ninu awon apero gbogbo aye ti Ajo Agbaye ti a waye lati odun 1990.
Itepepe fun Ise so awon ifojusi fun ogbon imusenkan o si se alaye awon ise
ti o ni lati waye lati owo awon ijoba, awujo kariaye, awon ajo ti ko lowo ijoba
ninu ati awon ajo aladani Odun marun leyin Beijing, ipade
pataki na ti osu kefa yio fun gbogbo awon ti oro kan ni anfani lati se ajopin
ati ifiwera won iriri won. Won yio tun se atunse awon ifaramo ti teletele ki
won si se awon titun miran. Won yio se ayewo awon idiwo ti won ba
pade ati awon ise rere ninu imuse itepepe fun ise na. WomenWatch
Awon Ijoba dahun si Iwe Iwadiotito 1min. 35secs. Ni igbaradi fun ajo
pataki to nbo idahun ti de odo Ajo Agbaye lati orile-ede merinlelogoje lori
iwe Iwadiotito
ti won fi ranse si awon ijoba lori imuse Itapepe Beijing fun Ise. Iwe Iwadiotito
na eyiti won se lati fi gba ifitonileti lati odo awon ijoba ni won yio tu pale
ki won si kojopo ninu iroyin ayewo ti won yio gbe siwaju ipade
pataki ti gbogbo omo egbe eyiti a pe ni Beijing ati Marun.
Iwe Iwadiotito na je alapameta. Ni apa kini awon oludahun ni won ni ki won se
itupale agbeyewo awon itesi ati iriri won lori imuse Itapepe fun Ise na. Apa
keji fojusi imuse funrarare ti a ba foju wo lati ibi awon ilana ise
ti orile-ede ati ni pataki iye oro ti won lo ati awon eto ti won gbekale. Apa
keta iwe iwadiotito na da ni pataki lori imuse awon ohun mejila to je ohun ikalara
fun Itapepe fun Ise na.
Eka fun Ilosiwaju awon obirin lo ko awon iwadiotito na sita ni osu kewa odun
1999. Nigbati yio fi di ojo kini osu karun odun 2000 awon orile-ede merinlelogoje
to je omo egbe ati awon oluworan meji lo ti da esi pada.
DAW
A yan alaga titun fun Igbimo Eleto 1min. 14secs. Ni ogunjo osu kerin
odun 2000, Igbimo to nseto Igbaradi fun Ipade pataki ti Ajo Agbaye na ti yan
Arabirin
Christine Kapalata gegebi alaga. Eniti on gba ipo lowo re ni Arabirin Roselyn
Odera ti orile-ede Kenya to ti je alaga igbimo eleto na lati ojo kejidinlogbon
osu kefa odun 1999. Arabirin Aicha Afifi ti orile-ede Morocco
ni awon Egbe Ile Afirika ti yan gegebi Igbakeji Alaga igbimo eleto na, iyen
ipo ti Arabirin Kapalata fi sile.
Nibayi, Igbimo Olugbalejo ti awon Ajo ti ko lowo ijoba ninu (NGO) fun Beijing
ati Marun ni won ti gbe dide lati se kokari orisirisi akitiyan awon NGO ni ilu
New York eyiti yio ma lo ni akoko ipade na. Igbimo olugbalejo
na yio tun ran awon asoju awon NGO lowo nipa gbigba iwe ase iwoorile-ede. Awon
eniyan to ba nife ni won ti ro lati kan si Arabirin Promita Sengupta lori ero
ifi iweranse e-mail: psbeijing@ earthlink. net.
DAW
Eto Awon Omode
Bi ketekete abila se gba awon ila teretere re 3mins. 22secs. Ni
ojo kan to ti pe pupo seyin, obo Ilaburu nla kan to roro sokale kuro lori awon
igi lati ma gbe ni eti bebe odo
nla Umfolozi. Nibiyi lo se ile re si, o si wa kede fun awon eranko to ku wipe
ti on ni gbogbo ile to wa ni ayika, 24
24 Page 25 26
Vol. II No. 18 (Yoruba) CHANGE Radio July, 2000
25
won ko si gbodo lo omi odo na. On nikan lo leto ati mu omi.
Okan ninu awon eranko pinnu lati koju Ilaburu onroro na. Eyi ni ako odo ketekete
abila onigberaga kan to nje Dube.
Ni awon igba ti a nsoro re yi, awon ketekete abila je funfun balau bi esin
inu itan isenbaye ti a mo si Unicorn. Dube laya o si ta Ilaburu laya
si ija. Ilaburu to je ogbontarigi ninu opolopo ogun gba. O mo nipa ija gan an
ni.
O so wipe: "Eni to ba padanu ninu ija na ni won o le lo patapata titi laelae
si asale perese to wa ni irekoja odo
na." O si so fun ketekete abila lati wa si ogba ile on ni owuro ojo keji.
Ija na gun o si buru pupo. Awon eranko mejeji fi gbogbo agbara won ja, won
si lo awon ohun-ija ti eleda fun won. Dube lo awon patako ese re ati eyin re
to mu nigbati Ilaburu lo eyin re gigun ati iyara re.
Nigbeyingbeyin owo Ilaburu lo soke, o si ju Dube seyin sinu awon gedu to njo
ninu ina ninu ogba na. Awon owo ina lile na jo kakiri ara o si ba awo onirun
re funfun daradara je. Irora buruku na fun Dube ni agbara otun,
pelu itapa alagbara kan o si gbe Ilaburu fo koja odo kolu awon apata to wa nibi
oke kekere to wa nibe. Ilaburu jabo pelu agbara nla tobe ti apa na si wa nidi
re titi di oni oloni.
Sugbon Dube na ti gba aami ayeraye. Ijoni lati inu awon gedu to njo bulabula
ninu ina Ilaburu fi ila teretere si gbogbo ara awo onirun ara re to funfun bi
ojo-didi. Sugbon boti-wu-kori o ti bori, lati ojo na lo ni odo na ti
si sile fun gbogbo awon eranko na.
Lati igbana ketekete abila ngbe ila ara re kiri pelu ola. Nigbati a si le awon
ilaburu lo si ori awon oke kekeke
olokuta, awon ketekete abila ngbe lori awon ile perese, won si nlo won nbo si
odo na bi o ti wu won. When the hippo was hairy
Awon Oro Asokagba
Awon oro manigbagbe lori ayika ati idagbasoke
"Eda ko dabi wipe o le fi ohunkohun sile to je ehanna ati adayeba." Olwen
Frost
Omo odun medogun lati orile-ede Barbados.
"Fun awon igba ti a fi nduro de awon ohun iranti titun, e jeki a toju awon ohun
iranti aye atijo." Victor Hugo
Onkowe ere itage ati iwe itan aroso, omo orile-ede Faranse, 1802 -1885.
"Gbogbo eran ara dabi koriko, besi ni gbogbo ogo eda eniyan dabi itanna koriko."
Bibeli
Peteru kini, ori kini Ese kerinlelogun si ikedogbon. 25
25 Page 26
Vol. II No. 18 (Yoruba) CHANGE Radio July, 2000
26
"Ti a ba gbiyanju lati fa ohun kan tu funrarare, wa ri wipe o so po mo ohun
gbogbo to ku." John Muir
Afenifere itoju iseda aye, omo orile-ede Amerika to bere ilana Ogba Eranko
ti
orile-ede, 1838 -1914.
"Kini anfani ile ti o ko ba ri aye to se gbe lati fi sori re." Henry David
Thoreau
Onkowe ati Alariwisi lori awujo,
1817 -1862.
"O ku sowo imo ijinle sayensi lati se itankale imo wipe yiyan ki ise laarin
awon ibi egan tabi awon eniyan inu egan, sugbon o wa laarin ojo iwaju eda eniyan
to ni oro tabi eyiti o kuuse."
Tom Lovejoy
Igbakeji Aare Ajo WWF nigbakanri fun Imo Ijinle sayensi.
"Imo bi gbogbo wa se lowosi idari emi aye sese nhan si opolopo wa ni, eyi
si jasi ayipada miran ninu ero eda eniyan."
Lewis Thomas Onkowe, Awon Emi seeli kan. 26
© 2002 Communicating for Change. All Rights Reserved
Developed by George Mbuagbaw