Go Back
Communicating for Change

Document Body Page Navigation Panel

Pages 1--15


Page 1 2
1
Vol. 11 No. 22 CHANGE Radio November, 2000. (Yoruba) Vol. 11 No. 22 CHANGE Radio November, 2000. (Yoruba)
Idagbasoke
IMO ERO
Ikilo lori Imo-ero to je mo ilo awon Eweko ati Eranko 5mins. 6secs. 6
Ti ile Afirika ko ba lowo ninu igbesoriosuwon lona imo ijinle
sayensi, o seese ko padanu awon anfani to nbo pelu imo ero.

AWON AJO IROYIN
A da awon Olootu lola pelu Aami Eye Ominira Ise Iroyin 12mins. 9secs. 3
Iwe Iroyin to nse agbeyewo ise iroyin ni agbaye ti da awon olotu
iwe iroyin orile-ede Sierra Leone meta lola nitori won fi emi won
wewu lati gbe opagun ominira ise iroyin ati eto eda eniyan soke ni
orile-ede won ti ogun ti baje.

Awon Ajafitafita fun Awon Ajo Iroyin ti se igbekale Itankale Ifitoni leti
jakejado Ile Afirika 9mins. 8
Meji ninu awon ajo Iroyin to tobi ju laye ti se igbekale ibudo tuntun kan
fun itankale ifiweranse lori komputa (e-mail) jakejado ile Afirika lati se
atileyin ominira ise iroyin. Sugbon iberepepe si niyen......

Ajo WorldSpace fun Awon Olugbohunsafefe Ile Afirika ni Imo ero titun. 6mins. 5secs. 5
O seese fun awon Olugbohunsafefe Ile Afirika lati rekoja awon aala won ati
agbegbe ti won gba iwe ase fun lati kan awon olugbo jakejado aye lara latari
imo ero ti ibudo inu ofurufu agbaye titun kan.

AWON OBIRIN
Mimo nipa ipo ti Ige Abe Obirin ni Igekuge wa (Oro Olootu) 10mins. 10
Nje o seese lati so asoju lori oro kan? Eyi ko seese niwongba ti oro na ba kan
ilera, eto eda eniyan ati isedale. Bi ifitonileti ti po repete to lori ige abe obirin
ni igekuge, ohun iyalenu ni wipe imo wa lori re si kere.....

Iroyin Titun se ifojusi Iyasoto nipa Eya 12mins. 8secs. 9
Iroyin Ajo Agbaye kan tenumo wipe aidogba laarin awon eya si wa jakejado aye.

Awon Obirin orile-ede Naijiria ni Eto kan fun Odun 2003 10mins. 5
Awon obirin orile-ede Naijiria ngbaradi fun ikopa to ga si ninu idibo
gbogbogboo to nbo.

ILERA
Onimo ijinle kan nipa kokoro-arun bu enu ate lu idoko-owo to lo sile
ninu iwadi lori abere ajesara fun Arun Kogboogun Eedi. 7mins. 4
Aimu iwadi fun abere ajesara lati dena kokoro-arun HIV ati Arun Kogboogun
Eedi ni ile Afirika ni okunkundun ni enikan ti bu emi ate lu ninu idanileko

onifioroweoro kan to waye ni orile-ede Senegal.

Ayika
IDOTI
Ipe fun ofin lati dabobo kurukuru Efin alagbara fun idabobo ofurufu 4mins. 7
Ajo kan ti ko lowo ijoba ninu ti kepe ijoba orile-ede Ghana lati se agbekale
awon ilana ofin lori Kurukuru Efin Alagbara Ofurufu labe Akosile Ilana Ise ti
Montreal lati dabobo Agbeka Kurukuru Alagbara to ndabobo ofurufu.

AJALU
Eya-ile pa eniyan metadilogun ni ipinle Anambra, o si so odunrun 3mins. 7

iyan di alanilelori.
Eya-ile kan to waye latari ijele ogbara repete ni abule kan ni orile-ede
Naijiria ti yorisi ijanba.
1
1 Page 2 3
Vol. 11 No. 22 CHANGE Radio November, 2000. (Yoruba)
2
ITOJU
Awon omo orile-ede Tanzania yio koju Ipagborun ni Ojo kini Odun Titun 6mins. 9
Awon igbese titun ni won ngbe ni orile-ede Tanzania lati se idapada ibori
igbo orile-ede na to ti dinku.

Ajo Olutoju Awon Eda Abemi ti se atileyin fun Igbesele lori Irin Titanium 6mins. 16secs. 11
Ajo Olutoju Awon Eda Abemi Egan ni orile-ede Kenya ti soro lati faramo ipinnu
ijoba lati dawo iwakusa irin Titanium duro ni agbegbe Kwale

Bi mo se rii si......
'Lati inu irisi oju obirin kan' 6mins. 6secs. 11
Eka titun wa yi nwo awon oro to kanpa lori ayika ati idagbasoke lati irisi eniyan
kan. Arabirin Owusua kowe lori ise asewo.

A ti gbo......
AWON AJO IROYIN
A se itungbedide Ile-ise igbohunsafe 'Voice of Nigeria' 7mins. 6secs. 12
Ajo Igbohunsafe ti orile-ede Najiria si ehin-odi ni a ti se itungbedide re ni iwo titun
ati isesi to mu iwuri wa.

ITOJU
Orile-ede Sweden gbe owo kale fun Itoju Iseda Aye ni orile-ede Namibia. 3mins. 12
Asoju ijoba orile-ede Sweden si orile-ede Namibia ti fi owo si iwe atileyin kan
eledegberin o le adota milionu owo dola Namibia fun itoju iseda aye.

Akojo Owo bi adojo milionu owo dola America lati gba awon agbegbe aye ti
awon eranko ati eweko ibe wa labe ewu la. 1min. 5secs. 13
Banki Agbaye ati awon ajo meji fun itoju iseda aye ti se ikede igbekale akojo
owo titun kan to wa fun idabobo to dara si fun awon agbegbe aye ti awon
eranko ati eweko ibe wa labe ewu iparun.

Ojo ati Akoko....
ILERA
Apero Ile Afirika lori Arun Kogboogun Eedi ni won ti sun siwaju di osu kejila odun 5mins. 13
Apero pataki kan ti Ile Afirika lori Arun Kogboogun Eedi ati idagbasoke eyiti
o ye ko waye ni ilu Addis Ababa ni osu kewa ni won ti sun siwaju.

ILUJARAAYE
Apero Ile Afirika lori Atunse Ofin Ifiyajeni 1min. 14
Orile-ede Cameroon yio gba apero pataki kan lori ikolu ilujarawon aye lori awon
atunse ofin ifiyajeni ni alejo.

Eto Awon Omode
Mboma ati Ketekete na 10mins. 7secs. 13
Erinmi fihan ketekete wipe oro akoda koda bi adagbeyin.

Oro Asokagba
Se ayeye ogbon iriri ile Afirika pelu awon oro manigbagbe ati oro lori itoju 14 2
2 Page 3 4
3
Vol. 11 No. 22 CHANGE Radio November, 2000. (Yoruba) Vol. 11 No. 22 CHANGE Radio November, 2000. (Yoruba)
Iroyin
A da awon Olootu lola pelu Aami Eye Ominira Ise Iroyin 12mins. 9secs. Awon olootu iwe iroyin meta ni orile-ede Sierra Leone ni Iwe Iroyin to nse agbeyewo ise iroyin ni agbaye
ti da lola fun fifi emi won wewu lati gbe ominira ise iroyin ati awon eto eda eniyan ro laarin odun mesan ti ogun ti fi nja ni orile-ede won. Paul Kamara, olootu iwe iroyin For Di People, Philip Neville, olootu iwe
iroyin Standard Times ati David Tam-Baryoh, olootu iwe iroyin Punch gba Aami Eye Olootu Kariaye ti
Odun na ni Ajo Agbaye ni ilu New York lati owo Olara Otunmu to je Akowe Agba Kekere ati Asoju Pataki fun Awon Omode ati Rogbodiyan Ologun. Otunmu so wipe on ko le ronu awon elomiran to ye fun

eye na ju awon eniyan na lo. Awon ati orile-ede won ti jiya ju ohun ti enu le so lo, sibe awon ogboju ati olufaraji onise iroyin ti se iwuri, won si se asiwaju awon eniyan lati fi ijoba ologun kan sabe atako.

Olootu Iwe Iroyin to nse agbeyewo Ise Iroyin ni agbaye, Alice Chasan gbe oriyin fun ikosemose awon okunrin metata na, O ni: "Labe awon ipo to buru jayi, Paul Kamara, Philip Neville ati David Tam Baryoh
ti koju isoro gbogbo won si ti se agbero idiwon ise na to ga julo. Won ti fi gbogbo ara gba ipa ti onise iroyin lati se agbekale awon ipo to dara fun ijoba tiwantiwa ati imu-ofin-sise ni ile won, won si ti la ewu nla koja
lati se aseyori awon ifojusi wonyi. Akikanju gidi ni won." Philip Neville da Standard Times sile ni odun
1994, won si mu, won ti mole ni opolopo igba laarin awon odun to telee. Ni odun 1997 oun ati awon osise re farasoko sugbon won tesiwaju lati ma gbe iroyin jade biotilejepe leyin eyi Neville ni lati sa kuro ni ilu.

Nigbati won da ijoba Ahmed Tejan Kabbah ti won doju re bole pada ni odun 1998, o pada silu. Sugbon awon omo-ogun olote RUF ya wo olu-ilu Freetown won si gbogun ti iwe iroyin Standard Times fun iroyin
re lori iwa ti awon olote nhu. Won jo ile ise iwe iroyin na won si gun olootu re pa. Nwon fi ipa ba iyawo
re sun won si pa, bena ni won si pa awon omo re. Neville ni lati sa pada lo seyin odi ki o to tun pada si orile-ede Sierra Leone ni odun to koja.

Paul Kamara, ti kole wa sibi ayeye na, ni won ti deruba ti won si ti fi sewon fun ominira ise iroyin re. Ijoba ologun dena de won si ta nibon, eyi si yorisi awon ifarapa to le pupo, paapa ni ese re. Nigbati o pada lati
ibiti o ti ngba itoju loke okun ni odun 1997, won doju ijoba ti a dibo yan dele, o si mu iwe iroyin re lo si ipamo, won ko si ri mu, biotilejepe won fi ohun ose abugbamu fo ile-ise re, awon olote si gba ile gbigbe re.

David Tam-Baryoh se agbekale iwe iroyin Punch ni odun 1996, laipe o di ohun ifojusi lati owo ijoba ologun ati awon olote RUF. Leyin ti won ti ti i mole ni emeta o salo si ipamo, nigbati o si di wipe won nwa
awon onise iroyin kiri won si npa won nitori iroyin won lori ogun na, o salo seyin odi, lakoko si orile-ede Guinea, leyinna si orile-ede Ghana. Nigbati o ngba aami eye re, Tam-Baryoh so wipe on fe gba a gegebi
asoju awon onise iroyin medogun to ku ninu rogbodiyan orile-ede Sierra Leone, mesan lati owo awon olote, meta ninu atimole ijoba, okan ti won yinbon pa ati awon meta to je omo egbe onise iroyin ile-okeere.
Bi o se nsoro teduntedun nipa bi ohun to sele si awon elegbe on ati ojulumo on se kan on gegebi onise
iroyin, Tam-Baryoh so wipe on gbodo ye okan on wo daradara ki on to le kowe pelu irorun lori ibalaja. Fun odun mewa ni o ti nko itan ogun ti "o si nso itan kanna leralera -itan irora" O fee le ma ranti mo bawo

ni o se dara lati se ise akoroyin. O se efe nigbati o wipe: "So fun mi lati ko itan kan lori oro aje -mo ti luko niyen."

Iwe iroyin atigbadegba to nse agbeyewo ise iroyin ni agbaye a ma fi aami oye Olootu Odun na lododun fun awon olootu to wa leyin odi orile-ede Amerika ni ijewo "ijafafa, igboya ati isiwaju ninu imutesiwaju ominira
ati ojuse ise iroyin, igbelaruge awon eto eda eniyan ati imusele iperegede ninu ise iroyin." Lara awon omo ile Afirika to ti gba aami eye na ri ni a ti ri Dapo Olorunyemi, omo orile-ede Naijiria to je olootu iwe iroyin
The News ni ilu Eko ati Fred M'membe ti iwe iroyin The Post ni orile-ede Zambia, awon mejeji ni odun 3
3 Page 4 5
Vol. 11 No. 22 CHANGE Radio November, 2000. (Yoruba)
4
1995. Iwe iroyin atigbadegba na ni Ajo Amuludun Stanley ti ilu Muscatine, Iowa to nlepa alafia, pelu ominira ati idajo ododo nipase awon eto ajo iroyin ati igbeko, ntejade lososu.
All Africa. com
Onimo ijinle kan nipa Kokoro-arun bu enu ate lu idoko-owo to lo 7mins. sile ninu iwadi lori abere ajesara fun Arun Kogboogun Eedi.

Aare Itankale Iwadi lori Arun Kogboogun Eedi ni iha Iwo-oorun ati Arigbungbun ile Afirika, Ojogbon Souleymane Mboup ti orile-ede Senegal ti bu enu ate lu aimu iwadi fun abere ajesara lati dena kokoro-arun
HIV ati Arun Kogboogun Eedi ni ile Afirika ni okunkundun. Arun na lo ni ikolu lara iye eniyan ti a siro si milionu merinlelogun o le egberun lona oodurun ni iha abe asale Sahara. Onimo ijinle agba na nipa
kokoro-arun so fun awon olukopa ni ibere idanileko oniifioroweoro olojo-meta fun awon oluwadi lori Arun Kogboogun Eedi lati awon orile-ede merinla ni iwo-oorun Afirika to waye ni ilu Dakar wipe boya ni
o to iko eyo kansoso ninu ogorun gbogbo inawo ti won nse lori igbejako Arun Kogboogun Eedi ti won
dojureko iwadi fun abere ajesara. Mboup, ti a mo gegebi okan ninu awon onimo ijinle sayensi to koko se iyasoto iru kokoro-arun HIV keji eyiti o gbile ni iwo-oorun Afirika ati orile-ede India, kedun nipataki lori

ailowosi awon oloko-owo aladani ninu awon akitiyan lati ri abere ajesara kan.
O da ikuna awon onimo ijinle sayensi lati ri abere ajesara to munadoko fun Arun Kogboogun Eedi lori
"pipo ti awon Kokoro-arun HIV ati awon amugbalegbe won" to nfa Arun Kogboogun Eedi to nja ni ile Afirika po repete. O woye sa wipe o ju ogun awon asewo abere ajesara ti won nse iwadi lori re lowolowo,

awon abajade alakoko ti ipa kinni ninu idanwo onipameta na ni yio di mimo laarin odun kan.
Nigbati o nsoro lori awon egboogi agbejako imupada kokoro-arun eyiti o ti se iranwo lati din awon iku to
jemo arun Kogboogun Eedi ku pelu idameta ni awon orile-ede ariwa aye to ti dagbasoke, Mboup so wipe awon egboogi na ko ti wopo ni ile Afirika nitori owo won to ga pupo lati bi egberun mewa si egberun

medogun owo dola Amerika fun alaisan kokan lodoodun. O tewogba gbigba ti awon ile-ise iwadi awon ajo oloko-owo elegbogi nlanla marun gba laarin osu kaarun odun yi lati din iye owo awon egboogi won ku
gan an fun awon orile-ede to talika. O gbe oriyin fun Ajo Amuludun Rockfeller to gbe owo sile fun
idanileko na fun ife-inu re lati keko lodo awon oluwadi lati orisirisi agbegbe ile Afirika lati le gbe eto tire kale fun ilowosi ninu oran kokoro-arun HIV ati Arun Kogboogun Eedi ni ile-aye na.

Ninu oro to fi ranse, Minisita orile-ede Senegal fun Ilera, Abdou Fall, tokasi osi ati awon rogbodiyan ologun gegebi awon okunfa to nlowosi itankale kokoro-arun HIV ati Arun Kogboogun Eedi. Minisita na
ta awon orile-ede laya lati pa awon isele oro aje to dapo mo awujo eda eniyan to nse iranwo lati tan ajakaye-arun na kale run. Nigbati o ntokasi Senegal ati Uganda gegebi awon orile-ede to ni awon eto
igbogun-ti Arun Kogboogun Eedi ti a ri wipe o lese nile, Fall so wipe opo ise lo si ku lati se lati se idena to kesejari ni orile-ede Afirika kokan.
Panafrican News Agency
Ajo WorldSpace fun awon Olugbohunsafefe 6mins. 5secs. Ile Afirika ni Imo Ero Titun

Nisisiyi awon olugbohunsafefe ni ile Afirika le rekoja awon aala ati awon agbegbe ti won gba iwe ase fun
lati kan awon olugbo lara jakejado aye. Eyi waye latari imo-ero titun kan ti ibudo inu ofurufu eyiti ajo oloko-owo orile-ede Amerika kan ti a mo si Worldspace Corporation, gbe jade, eyiti o funni ni igbohun-lati

inu-afefe taara lati inu ibudo inu ofurufu.
Gegebi oludari ajo na fun awon ise to je mo imo ero, Daniel Obam, se so, WorldSpace ni agbekale fun
igbohunsafefe olona-pupo eyiti a se, ti a si yasoto fun ile Afirika nikan lati inu imo wipe awon ero asoromagbesi redio ko tii le noya koja awon agbegbe won. O so fun Ogbeni Wednesday ti ajo PANA wipe imo oro 4
4 Page 5 6
5
Vol. 11 No. 22 CHANGE Radio November, 2000. (Yoruba) Vol. 11 No. 22 CHANGE Radio November, 2000. (Yoruba)
Worldspace ni won se nitori ile Afirika pelu awon arooko re to jinna rere ati awon agbekale amuludun re ti ko dagbasoke tobe. Obam ni: "Ti ofurufu ba ti wa loke re wa le gbo eyikeyi ibudo redio yiowu ti o ba
fe lori ero redio re, a si setan lati mu awon olugbe ati agbegbe ile Afirika wonu orundun kokanlelogun."
Ajo oloko-owo na, eyiti Noah Samora da sile ni odun 1990 gegebi Afrispace lati dojuko awon isoro ile Afirika, papa kokoro-arun HIV ati Arun Kogboogun Eedi, ni o nse ipese igbohunsafefe olohun kerekete
taara lati inu ibudo inu ofurufu ati iseto igbohunsafefe olona-pupo fun awon oja to sese nyoju ti a ko si pese
fun tobe ni agbaye. Nigbati o nse alaye bi imo ero na se nsise, Obam so wipe ilana na nlo igbohunsafefe taara lati inu ibudo inu ofurufu to kariaye nipa eyi ati nlo awon ohun elo imohundun kerekete lara eyi ti a ti

ri ohun ti a le gbe kiri, aworan fidio onila teere ati igbohun-lati-inu afefe olona-pupo ni a nlo lati saseyori isopo igbohunsafe mo ibudo inu ofurufu lati inu awon ibudo ero asoromagbesi to wa ni ibi to jinna si aarin
ilu. Bi o se nro awon ibudo ero asoro-magbesi ti orile-ede ati ti elekunjekun lati lo imo ero titun na lati
rekoja awon aala won fun olugbo to gbooro si, Obam woye wipe awon imo ero to wa fun igbesaye ifitonileti nisisiyi ni awon aikunoju-iwon to nkonilomimu ni akoko ilujara-won aye yi. O ni "Eyi yio fun ile

Afirika ni anfani lati dije laisi idanilowoko pelu iyoku aye nitori ifitonileti je agbara."
Nibayi, Afristar, eto kan to kari ile Afirika, nfun awon olugbo ni asayan ibudo ero asoromagbesi ile Afirika
mejelelogoji ninu itansan kansoso, eyi si le di ilopo meji tabi meta nibiti awon itansan meji tabi meta ba ti koja laarin ara won; pelu ibudo asopo ni orile-ede Benin, Egypt (isokan Redio ati Telifisonu ti orile-ede

Egypt), Ghana, Kenya, Senegal ati South Afirika. Awon ibudo asopo miran lo wa ni orile-ede Australia, China, Faranse, Germany, Indonesia, Singapore ati ile Geesi.
Panafrican News Agency

Awon Obirin orile-ede Naijiria ni Eto kan fun Odun 2003 10mins. Ni ojo kerinla ati ikedogun osu kesan odun 2000, ajo Awon Alabasisepo Agbegbe fun Idagbasoke
(Community Partners for Development (CPD) se eto idanileko onifioroweoro olojo-meji lori ikopa to munadoko ninu iselu fun awon obirin ni orile-ede Naijiria. Idanileko na waye ni igbaradi fun idibo gbogboogbo
ti yio waye ni odun 2003. Idanileko na ti akori re je Eto Awon Obirin fun odun 2003 ni awon eniyan lati orisirisi eka orile-ede na gegebi awon osise ijoba, oloselu, osise ile ifowopamosi, awon obirin onisowo,
awon onise iroyin, amofin ati awon asoju awon ajo ti ko lowo ijoba ninu pese si.
Aare ajo CPD, Arabirin Ime Essien Udom, so wipe won pe apejo na lati wa awon ona lati se iwuri fun opo
awon obirin sii lati darapo mo iselu ki won si di awon ipo to nkopa daradara mu. Lara awon koko pataki idanileko na a ti ri wiwo aworan fiimu kan ti a pe ni Ni idojuko Isoro gbogbo. Aworan na ni ajo Ibanisoro

fun Iyipada (Communicating for Change) se gegebi okan ninu awon oro Asotunso si Otito ti ajo Igbekele Amohunmaworan fun Ayika (Television Trust for the Environment) eyiti o nse afihan awon italaya ti awon
obirin ndojuko ninu iselu.
Awon obirin to wa ni ipo oloselu ni awon ipele ti orile-ede ati ti ipinle so awon iriri won gegebi oloselu ninu agbo ti awon okunrin nje gaba nibe. Okan ninu won, Oloye (Iyaafin) Josephine Anenih, olori awon obirin
ni orile-ede fun egbe Peoples Democratic Party (PDP) to nse ijoba, soro lori atako ti oun dojuko lati odo awon elegbe re okunrin laarin egbe na. Ohun to yanilenu nibe ni wipe eyito poju ninu awon atako to
dojuko o wa lati odo awon obirin elegbe re Iyaafin Anenih ro awon obirin lati lowo ninu iselu si i ki won si dekun ati ma duro ki awon okunrin pe won lati darapo mo iselu. O woye wipe biotilejepe awon obirin ni
lati jijakadi ni ilopo meta ti awon okunrin, won gbodo ma gbiyanju titi won o fi saseyori. Obirin miran to so itan tire, Oloye (Iyaafin) Nkechi Nwaogwu ti Advanced People's Party (APP) soro lori awon ewu iselu bi
ipania ati irokeke iwa ipa lati odo awon alatako. 5
5 Page 6 7
Vol. 11 No. 22 CHANGE Radio November, 2000. (Yoruba)
6
Sugbon idanileko na gbe oriyin fun ijoba to wa lori aleefa fun yiyan awon obirin si awon ipo pataki ni ipele ti orile-ede lapapo ati ti ipinle. Akosile ti isisiyi se afihan ilosoke ati idarasi ikopa awon obirin ninu ijoba,
pelu minisita agba obirin meji, minisita kekere merin, omo ile asofin agba meta to je obirin , awon omo ile
aseofin ipinle meedogun ninu gbogbo ipinle merindinlogoji ati obirin kan to je alase eka ile-ise ijoba ni gbogbo awon ipinle. Bi awon isiro na tile wunilori, ipohunpo ni wipe o si i kere.

Ninu oro re si apero na, Minisita kekere fun oran Awon Obirin ati Idagbasoke Odo, Dokita Bekky Igwe, tokasi wipe ikopa awon obirin ninu idibo gbogboogbo to koja lo ni odun 1998 ati 1999 kere pupo. O gba
awon obirin ni imoran lati lo anfani ijoba tiwantiwa lati jeki a gbo ohun won. Onsoro miran ninu ayeye na, Dokita Reuben Abati to je onise iroyin, so wipe awon ajo iroyin ti lowosi eta'nu si awon obirin ati ninu
riroyin nipa won. Nitorina, o gba awon egbegbe obirin nimoran lati sopomo awon ajo iroyin ki won si gba awon onise iroyin lokunrin ati lobirin saarin won. O si tun ro awon obirin lati darapo mo iselu ni iberepepe
yato si nigbeyingbeyin. O so wipe won gbodo lowosi awon akitiyan lori ofin ati eto eda eniyan.
Leyin ipade olojo-meji na, awon olukopa faramo awon ogbon imusenkan ti yio se alekun ninu ikopa awon obirin ninu idibo gbogboogbo to nbo. Lara awon ogbon imusenkan yi ni a ti ri igbeko fun awon omodebirin
lati kekere, imu awon obirin wa ni imurasile lati owo awon obirin ati idari okan awon okunrin ati awon molebi lati gbaruku ti awon obirin to ba nife ninu iselu.
CFC
Ikilo Lori Imo-ero To Je Mo Ilo Awon Eranko Ati Eweko 5mins. 6secs. Nje o seese ki ile Afrika padanu awon anfaani to nbo pelu imo ero? Apero kan lenu ojo meta yi ni orile-ede
South Afrika lori Imo Ero to jemo ilo Eweko ati Eranko fun Ounje se afihan wipe awon ilana alafia ni
a gbodo fi sipo. Awon itoni gbogbo gbodo da lori imo ijinle sayensi, ki won mo kedere, ki won si se te sihun tabi sohun. Imo-ero to je mo ilo awon Eranko ati Eweko le se alekun imunadoko ninu ise ogbin ki

o si se aridaju aabo lori ounje, sugbon awon onimo ijinle sayensi ni ekun na ti ro awon eniyan ki won se pele nigbati won ba nse imulo awon eto imulo to se itoni lori ilo re.

Imo-ero to jemo ilo awon Eranko ati Eweko ni ilo awon igbese imo lori eweko ati eranko lati se orisirisi awon nkan nipa lilo awon ona igbasenkan to mu ilo ati idari awon nkan elemi dani. Awon nkan wonyi ni a
le se fun tita lopo yanturu. Lara re ni a ti ri imo ero to je mo imo ijinle lori ijogunba ati iyato laarin awon eranko ati eweko, nibiti ati nmu awon eroja ijogunba lati eya kan si omiran ti a si nyasoto lati se igbedide
awon eya ohun kanna to dara pupo si i. Awon ona igbasenkan to wopo ni imuposi seeli tabi awon ohun
alaaye, sise agbelero awon eda abemi ati awon ona itupale awon ohun elemi nipa ilo bakteria, imuwonu ara won seeli ati imu-ojele-lati-ohun kan si ikeji ati imo ero lori ajogunba eya. A tun nlo imo ero to jemo

ilo awon eranko ati eweko lati se awon egboogi agbejako kokoro-arun ati orisirisi awon ohun ogbin to tete ngbo.
Awon onimo ijinle sayensi to pese si apero kan laipe yi lori "Imo-Ero to je imo ilo Eweko ati Eranko fun
Ounje. Awon otito, ati ojo Iwaju" ni ilu Midrand, orile-ede South Africa, eyiti Africabio, ajo kan ti ko lowo ijoba, ninu seto re, tokasi wipe o ye ki a se agbekale awon ilana alafia lori ilo imo ijinle lori eweko ati

eranko ni awon ipele ti orile-ede ati ti kariaye. Awon onimo ijinle sayensi na gba wipe awon ohun to nwa ninu ilana alafia to nsise daada ni awon itoni, eyiti o fi awon eniyan sero, to ni ona ayewo ati idaesipada.
Biotije wipe opolopo awon orile-ede ni ekun na ni ko iti bere eto alafia lori ilo imo ijinle lori eweko ati
eranko, apero na gba wipe awon itoni gbodo da lori imo ijinle sayensi, ki won mo kedere ki won si se te sihin ati sohun. A nilo lati se agbero ijafafa ati idaraeniloju ninu awon eniyan ti oran na kan. Nigbati o nba

apero na soro, Dokita John Kilama to je Aare Ile-Ise fun Iwadi lori Ipinsiyeleyele Eweko ati Eranko ni Agbaye (Global Bio-Diversity Institute) to fikale si orile-ede Amerika, so wipe "Ile Afrika gbodo lowo 6
6 Page 7 8
7
Vol. 11 No. 22 CHANGE Radio November, 2000. (Yoruba) Vol. 11 No. 22 CHANGE Radio November, 2000. (Yoruba)
ninu igbesoriosuwon imo-ero to jemo ilo Eweko ati Eranko lona imo ijinle sayensi, nitoripe ti ko ba se be, ile aye na le padanu awon anfani to le wa pelu imo-ero na".
Newslink Africa

Ipe Fun Ofin Lati Dabobo Kurukuru Efin Alagbara Fun Idabobo Ofurufu 4mins. Awon Ore Aye (Friends of the Earth (FOE) ti orile-ede Ghana, ati Egbe orile-ede fun Awon onile-ise fun
Itunse Ero Amunkantutu ati Ero Amuletutu (National Association for Refrigeration and Air Conditioning Workshops Owners (NARWOA) ti kepe ijoba lati gbe awon ofin kale lori Kurukuru Eefin Alagbara to
ndabobo ofurufu labe Akosile Ilana Ise ti Montreal lati dabobo ofurufu. Ninu akojade iroyin kan, ajo na so wipe awon ofin wonyi ni yio fun Ajo fun Idabobo Ayika ni agbara lati se imulo eto re lati mu awon eroja
to ndin kurukuru efin alagbara fun idabobo ofurufu ku kuro patapata. Ajo FOE so wipe awon iwadi re
fihan wipe awon oloko-owo ti oro na kan lo ti ndena iru ofin be eyiti o ti wa ni aba lati odun meta seyin. Ajo FOE so wipe awon eniyan na gbagbo wipe iru ofin be yio dena won lati ko awon aloku ero amunkantutu

ati ero asoomidiyinyin wole. Ajo FOE so wipe ijoba ti je anfani igbeowosile to ju irinwo-le-adota egberun owo dola Amerika lo lati ran an lowo lati se agbedide ipa lati se iru eto be, sugbon o ti kuna patapata lati
se ohun ti o ye. Ajo NARWOA kedun wipe ijoba ko iti fi ifaramo ati ipinnu ti iselu ti o nilo lati koju awon
isoro ati ohun aigbodomase to je mo Akosile Ilana Ise ti Montreal han. Awon ajo mejeji ro ijoba lati kun oju iwon ojuse re nipa gbigbedide awon igbese ti yio yori si igbekale ofin to ye. Labe Akosile Ilana Ise ti

Montreal, o di dandan fun awon orile-ede to sese ndagbasoke lati gbesele ilo gbogbo awon eroja to ndin kurukuru eefin alagbara to ndabobo ofurufu ku leyin eyi ki won wa dinku titi won o fi ke gbogbo re kuro
nigbati yio ba fi di odun 2010. Accra Mail

Eya-ile Pa Eniyan Metadinlogun Ni Ipinle Anambra, 3mins. O Si So Odunrun Eniyan Di Alainilelori
Eya-ile kan ti pa eniyan metadinlogun o si ti so awon eniyan bi odunrun di alainilelori ni abule kan ni orile-ede
Naijiria. Ijanba na wa latari ojo nla kan to ro, a si ti debi na lori ijele ogbara ni agbegbe ti awon eniyan ngbe. Eya-ile na kolu abule Amakor, Nanka, ni agbegbe ijoba ibile Ariwa Orunba ni ipinle Anambra. Ojo

na wo opolopo ile sinu koto nla. Yato si adanu emi, awon ohun elo inu ile ti owo re to opolopo milionu naira ni o parun ninu ijanba na, gegebi kansilo to nsoju Agbegbe keji ninu Igbimo ijoba ibile Ariwa Orunba,
Ogbeni Peter Adakah, to mu Alaga ijoba ibile na, Oloye Hyacinth Onwuchekwe kakiri awon agbegbe ti
oran na kan se so. O kedun nitori adanu nla ti ijele ogbara na fa. O fi edun okan re han lori wahala awon eniyan abule na, o si wa ro alaga ijoba ibile na lati fa oju ijoba apapo ati ti ipinle ati ti awon ajo kariaye si

isoro na fun iranlowo ni kiakia. Kansilo na woye wipe awon eniyan agbegbe Nanka ti figbakanri kebosi lori irokeke ewu ijele ogbara ti o nti nje wonu awon ibugbe won, o si wa nkominu lori idi ti awon ijoba to
ti koja ni orile-ede na ko se nkankan.
Komisona ipinle na fun oro Ile-Gbigbe ati Ayika, Oloye Nkwo Nnabuchi ti kebosi ninu apero kan fun awon oniroyin lori bi isoro ijele ogbara ti nburu si ni ipinle na. O si kepe teduntedun si ijoba apapo lati dide

fun iranlowo ipinle na ni kiakia nitoripe ipinle na ko ni owo lati fi koju awon isoro ayika ati agbegbe na. All Africa. Com

Awon Ajafitafita Fun Awon Ajo Iroyin Ti Se Igbekake Itankale 9mins. Ifitonileti Jakejado Ile Afirika
Meji ninu awon ajo totobiju laye to nsoju awon ajo iroyin ti se igbekale ibudo titun fun itankale ifiweranse
lori ero komputa (e-mail) jakejado ile Afrika lati se atileyin ominira ise iroyin ki o si se agbero awon ajo iroyin aladani to lagbara si i ni ile aye na ni Ojobo. Ajo Egbe awon Iwe Iroyin ni Agbaye (The World

Association of Newspapers (WAN) ati Ajo Awon Akoroyin ti ko ni Aala (Reporters Sans Frontiere (RSF) so ninu oro kan wipe itankale RAP 21 titun ni o je egbe ajumosoro ti ile aye kan akoko iru re, a si
da sile pelu iranlowo Ajo Alasepo awon Ate iweroyin jade ni Aringbungbun Ile Afrika (Central African 7
7 Page 8 9
Vol. 11 No. 22 CHANGE Radio November, 2000. (Yoruba)
8
Union of Press Publishers) jakejado ile Afrika. Igbese na waye latari aseyori igbese elekunjekun iru re lati owo Ile-Ise Awon Ajo Iroyin ti Iha Gusu Ile Afrika (Media Institute of Southern Afrika (MISA) eyiti o so
awon iwe iroyin ati awon onise iroyin po ninu Agbajopo fun idagbasoke Iha Gusu Afrika. Ajo RAP 21 eyiti o je ageso oruko ni ede Faranse fun Itankale Ise Iroyin ni Ile Afrika fun orundun kokanlelogun
(African Press Network for the 21st Century) ni yio se akopo awon onise iroyin ati logaloga to nsise fun awon ajo iroyin aladani, yio si tun pese asopo akoko iru re to wa laaye si gbogbo aye fun ogogorun awon
akosemose to nsise nisisiyi ni iyakuro lodo awon egbe ati ojulumo won nibomiran lori ile aye na. Gegebi oro na se so, itankale na yio tun sise gegebi ilana itanilolobo lori igbejako ominira ise iroyin ni ile aye na, yio
si tun pese ifitonileti lori awon anfani isakoso ati idanileko.
Gegebi Oludari-Agba fun ajo WAN, Timothy Balding se so, "Ikuna lati se idasile akojopo ife-inu ati asoyepo laarin awon ateweroyinjade, awon olootu ati awon onise iroyin ni ile aye na ti je isoro nla fun ise
iroyin aladani ni ile Afrika. Ilosoke to yanilenu ninu ilo e-mail olowo pooku ati itankale internet ni a le lo nisisiyi lati se idasile asopo ti yio wa titi laarin awon ajo iroyin ile Afrika. Akowe Agba fun ajo RSF se
afikun wipe awon ajo ajafitafita yio le se imudarasi lori iye akoko to ngba won lati fi ikobiarasi won han ati lati se idalagara fun awon ijoba ile Afrika pelu iranlowo awon onise iroyin ati ajafitafita fun ise iroyin ni ile
Afrika.
Awon ogorun omo-egbe to da ajo RAP 21 sile ti fi ajo na ji lati mu awon onise iroyin ni ile Afrika wa ni
imurasile lati dabobo ki won si se igbelaruge ominira ise iroyin nipa fifi ohun won kun awon afihan ehonu. Yio tun se kokari ifuni ni aami eye ti ile Afrika lododun nipa sise idalola awon eniyan kokan tabi ajo to ba

ni ilowosi to dayato si ipa ominira ise iroyin. Awon ohun ikanigbongbon miran ni iranlowo ati atileyin fun awon onise iroyin ti a ba fi si ewon tabi ti a ba se irokeke ipalara fun, idasile pasiparo ifitonileti ti yio wa titi
ati awujo fun ohun imulo fun awon olootu laarin awon iwe iroyin aladani ni ile Afrika. Lara eyi ni a o ti ri
sise iwuri fun awon ajo iroyin ile Afrika lati so ara won po mo ibudo ifitonileti ori internet won. Awon alakoso RAP 21, lara eyiti ajo WAN ati RSF wa, yio tun pese imoran ati atileyin lori imo-ero ati isakoso

fun awon iwe iroyin aladani ni ile Afrika ninu itiraka lati se alekun ninu awon oluka, lati se imudarasi awon ona imusenkan lori itaja, ipolowo, isakoso isuna owo ati oro eda eniyan. A o se iwuri fun awon iwe iroyin
lati lowo ninu awon ise agbese lori eko ati igbero asepo nigbati ajo RAP 21 yio pese ona fun ifitonileti lati
odo awon ajo fun idagbasoke si awon ise iroyin ile Afrika nipa pipese ifitonileti nigbakugba lori awon igbese leyin odi lati ran idagbasoke ise iroyin ni ile Afrika lowo. Awon to ba fe kopa ninu RAP 21 le bere

fun idiomoegbe nipa fifi iwe ranse lori komputa si Coordinator, Gamal Niang ni rap21@ wan. asso. fr. African Eye News Service (South Africa)

Awon Omo Orile-ede Tanzania Yio Koju Ipagborun Ni Ojo Kini Odun Titun 6mins. Awon igbese titun ni won ngbe ni orile-ede Tanzania lati se idapada ibori igbo orile-ede na to ti baje ti o si
tun wa labe ewu nigbagbogbo lati owo owo gedu lona ti ko bofin mu ati ilo awon oro igbo lona ti ko se gbero. Ijoba ti ya ojo kini odun 2001 soto gegebi ojo Igi gbingbin ni orile-ede ninu eyiti a ni reti wipe awon
omo orile-ede na jakejado yio gbin awon igi, won yio si tun lowo ninu awon akitiyan idagbopada miran.
Minisita fun Oro Adayeba ati Irin-ajo Afe, Zakia Meghji so wipe won nreti ase Aare Benjamin Mkapa ti
yio kede ojo na eyiti o bo si ojo kini odun titun. Ibori igbo ni orile-ede Tanzania ti ndinku gan an latari ise gedu lona ti ko bofin mu ati ilo awon nkan igbo lona ti ko se gbero. Igi lo si je orisun agbara to se pataki

julo ni orile-ede na, nitori pe o ga ju iko adorun ninu ogorun gbogbo ipese agbara ina ni orile-ede na lo. Ina ti awon agbe elero-giga ma nda sile lati le gba ogunlogo ile mo lekansoso ni o tun ti nmu irokeke ewu ba
ibori igbo orile-ede na. 8
8 Page 9 10
9
Vol. 11 No. 22 CHANGE Radio November, 2000. (Yoruba) Vol. 11 No. 22 CHANGE Radio November, 2000. (Yoruba)
Sugbon nisisiyi, gegebi Meghji se woye, ohun gbogbo yio yipada. O ni ojo igi gbingbin ni orile-ede na je
ifojusi ati idari titun lati odo ijoba ninu awon igbese idagbopada. O ni ojo igi-gbingbin na yio se igbelaruge awon akitiyan ijoba lati se kokari ipolongo fun igi gbingbin ni orile-ede na eyiti Mkapa fi lole ni osu kerin

odun. Nisisiyi, orile-ede Tanzania npadanu iye igbo to lo lati odunrun egberun si irinwo egberun saare hektari ile lododun latari igi gige lule. Iparun ibori igbo koni lominu pupo ni awon igberiko nibiti ise-ogbin
orisirisi ati ogbin eran osin ti je awon koko igbe aye. Awon agbegbe aringbungbun ati iwo-oorun ariwa
orile-ede na ni o ti wa labe ewu iyarasare di asale.

Meghji so wipe awon ekun ti oran na kan, ninu eyiti awon die ninu won nni iriri ogbele nilowolowo yi, lo wa labe ewu idi asale ti a ko ba gbe awon igbese lati yi ewu na pada lesekese. Mkapa ti tenumo isepataki igi
gbingbin ati itoju gegebi ona lati se igbelaruge itoju, o si ti ta awon omo orile-ede laya lati gbin igi si i. Awon
alase ti se italaya kanna si egbegbewa awon asasala to do si ekun iwo-oorun Kigoma, awon to je wipe gegebi awon olugbalejo won omo orile-ede Tanzania, awon na darale igi idana fun ilo agbara ina won.

Panafrican News Agency
Iroyin Titun Se Ifojusi Iyasoto Nipa Eya 12mins. 8secs. Aidogba laarin awon okunrin ati obirin nse idinku igberu eniyan kokan, awon ebi, awon agbegbe ati awon

orile-ede. Eyi ni abajade iroyin titun kan lati owo Ajo Akojo Owo ni Agbaye fun Awon Olugbe (United Nations Population Fund (UNFPA). Nigbati o nse akosile bi iyasoto nipa eya ti po to ninu "Bi Iye Awon
Olugbe Aye se wa ni Odun 2000, ajo UNFPA so wipe fifi opin si iyasoto awon eya je ohun agbese ni
kiakia lori eto eda eniyan ati idagbasoke. Gegebi UNFPA se so, "Bi iyipada se po to ninu ogun orundun, iyasoto ati iwa-ipa si awon obirin ati odobirin si fidi mule ninu awon isedale kakiri aye. Lati iran kan si ikeji

awon imo nipa okunrin gidi ati obirin ni a ti nfun awon eniyan lati kekere, eyi si soro lati yipada.
Gegebi iroyin na se so, awon odobirin ati awon obirin jakejado aye ni a ndu ni ona si eko ati itoju ilera.
Awon milionu ni o ni iriri ilokulo ati iwa-ipa, bena si ni eto won labe ofin ni a ko dabobo, oran isegun won ni ako mu ni okunkundun bi ti awon okunrin, bena si ni a ndu won ni anfani lenu ise ti won si ngba owo to

din si ti okunrin fun ise kanna. Nigbati o nsoro nibi ifilole iroyin na ni ilu London, Dokita Nafis Sadik to je Oludari Alase fun ajo UNFPA so wipe "Bi Iye Awon Olugbe Aye se wa" ti odun yi ni ise to rorun lati so.
A le pa gbogbo re po wipe iye ti a nsan fun aidogba ga ju ohun ti a le san lo" O se afikun wipe "O fihan
wipe ni gbogbo orile-ede jakejado aye, aidogba eya, iyasoto ati iwa-ipa nse ifaseyin, ki ise fun awon obirin nikan, sugbon fun awon okunrin, ki ise fun awon ebi nikan, sugbon fun awon agbegbe ati gbogbo awon

orile-ede".
Bi iko adorin ninu ogorun awon eniyan to ngbe ninu osi lo je obirin, won si ti siro wipe laarin akoko bi ogun odun, iye awon talika obirin ninu awon orile-ede to sese ndagbasoke mokanlelogoji yio fi iko metadinlogun

ninu ogorun le si alekun ninu awon talika okunrin. Awon obirin ti ko mooko mooka je ilopo meji awon okunrin besi ni niwontunwonsi, a ma nsan owo to fi iko ogbon si ogoji ninu ogorun din si iye ti a nsan fun
awon okunrin, fun awon obirin fun iru ise kanna. Iko meji ninu meta awon omode bi odunrun milionu ti ko
ni anfani eko jakejado aye lo je omobirin. Ni kariaye, o kere tan okan ninu obirin meta ni ati lu, ti a ti fi agbara mu fun ibalopo tabi ti a ti reje ni awon ona miran, gegebi iroyin na se so. O so wipe iwa-ipa to da

lori eya je irokeke ewu ni gbogbo ojo aye awon milionu odomobirin ati obirin kakiri aye. O tun so siwaju wipe ohun kan ti o je iriri to koni lominu julo ni wipe iwa-ipa ma nsaba wa lati odo elemo tipetipe tabi
molebi.
Gegebi iroyin na se so, "Idalare fun iwa-ipa ma nwa lati inu ikobiarasi awon eya ati ero ti ko gun rege lori ipa ati ojuse awon okunrin ati obirin ninu ibasepo". Iroyin na so wipe iwadi jakejado aye ti fi "awon ilana

to dogba" han lori awon isele to nfa ihuwasi iwa-ipa. O ni lara awon wonyi ni "aiko teriba fun oko, sisoro
pada si oko, kiko ibalopo, aiko wa ounje ni akoko, aise itoju awon omo tabi ile, bibi okunrin lere nipa owo 9
9 Page 10 11
Vol. 11 No. 22 CHANGE Radio November, 2000. (Yoruba)
10
tabi awon orebirin tabi lilosi ibikan laigba ase oko" Fun apere, iwadi kan ni orile-ede Ghana fihan wipe awon okunrin bi iko metalelogoji ninu ogorun ati idaji awon obirin so wipe okunrin ni eto lati lu iyawo re to
ba lo ohun elo ifietosomobibi laigbase oko re. Akosile ti Ajo Agbaye fun Ilera (World Health Organisation (WHO) gbe jade ni osu kefa odun yi so wipe iwa-ipa laarin awon eniyan lo je idi kewa to yori si iku awon
obirin ti ojo ori won lo lati odun medogun si merinlelogoji ni odun 1998. Iroyin ajo UNFPA so wipe okan ninu merin awon aboyun ni a ti silo ninu oyun. Ni orile-ede Naijiria, isiro bi iko ogbon ninu ogorun awon
obirin lo ti je olufaragba iru asilo ti eya ara lona kan tabi ekeji nigbati isiro kanna fun orile-ede Ugauda je iko metadinlogota ninu ogorun. Sugbon awon wonyi ni awon oran ti won royin won. Biotilejepe ifipabanilopo
ati awon orisi iwa ipa miran lori ibalopo npo si i, opolopo isele ifipabanilopo ni won ki i iroyin re nitori
abuku ati ibalokanje to sopo mo won, ati aisi itoju to banikedun ninu awon ilana ofin. Iroyin na so wipe o din ni iko meta pere ninu ogorun gbogbo isele ifipabanilopo ti won nroyin re ni orile-ede South Africa.

Orile-ede South Africa lo ni okan ninu awon isele ifipabanilopo to ga ju ni agbaye. Iroyin ajo UNFPA na ni a le ri ni htto// www. unfpa. org/ swp/ swpmain. htm.
UN Integrated Regional Information Network
Mimo Nipa Ipo Ti Ige Abe Obirin Ni Igekuge Wa (Oro Olootu) 10mins. Opolopo awon awujo ni ile Afrika ati iwo-oorun Asia lo ni asa Ige Abe obirin ni Igekuge (Female Genital

Multilation (FGM) ti won ma nsaba pe ni idabe obirin. Jakejado aye awon omobirin ati odobirin bi adoje
milionu lo ti la asa to lewu to si ni irora yi koja, pelu awon bi milionu meji to tun wa labe ewu re lododun.

Asa FGM yi ni won nse ni awon orile-ede mejidinlogbon ni ile Afrika nibiti igbile iwa na ti yato si ara won pupopupo, pelu bi iko marun ninu ogorun ni orile-ede Democratic Republic of Congo si iko mejidinlogorun

ninu ogorun ni Somalia ati ni ile Arabia ti omi fere yika ati ni ekun Gulf. O tun nsele laarin awon eya
keekeeke miran ni ile Asia, ati awon obirin alasikiri ni ile alawo funfun Europe, orile-ede Canada ati Amerika. Ni pataki, FGM ntokasi imukuro gbogbo tabi apakan ido ati awon eya abe miran. Awon to nse

iru asa yi to buru julo ti a npe ni Infibulation ni ede Geesi a ma ge gbogbo ido ati isu enu abe mejeji kuro won a si wa ran enu abe mejeji po. Eyi a wa fi oju kekere sile lati fi aye fun ito ati eje nkan osu. Asa
Infibulation yi lo je bi iko medogun ninu ogorun gbogbo isele FGM, ati iko ogorin si adorun ninu ogorun
gbogbo isele na to wa ni awon orile-ede Djibouti, Somalia ati Sudan. Ninu awon asa yi ti ko buru pupo, won a ma ge gbogbo ido tabi apakan re, tabi ido ati enu inu abe. Bi iko meta ninu merin gbogbo awon

omodebirin to ti ni iriri iwa to nrenisile yi ti koja laarin iru awon asa na ti ko buru pupo yi. Iteloju buruku fun eto awon omobirin ati odobirin yi lo da le awon igbagbo wipe idide ara obirin ni a gbodo dari, ki a si
dabobo ibale won titi ti igba igbeyawo. Awon okunrin ninu awon awujo die ko ni fe obirin ti won ko dabe
fun nitori won ri won be 'alaimo' tabi onisekuse. O fere je gbogbo igba ni abe gige ma nsele ninu ipo ti ko ni imototo to, ti ko si si egbogi ikunilorun. O tun wa nmu irora to po wa, o si le yori si ikolu arun, ijaiya nla

tabi iku paapa. Ti omobirin na ba ruula, o le ma ni iriri ibalopo to mu irora wa, eyi yio si ba igbadun aye re je.
Idinku iriri ibalopo ti awon obirin ma nni pelu FGM je isoro ilera nipa ti ara ati nipa ti opolo fun awon obirin ati idiwo si idagbasoke ibasepo to jinle to si tenilorun laarin awon alabasepo mejeji. Lara awon ewu ilera

FGM to nsele lesekese ni idaejenu ninu isan eje inu abe, ikolu arun, ida ito-duro-sinu, ati ifi-oro-sinu-eje lati ara awon abe ti ko dara ti a ko si fi igbona so di alailewu. Awon isoro to nwa leyin eyi ma nwaye latari
oju abe to ti pade die, eyi ti o ma nfa arun to le sinu ile ito, arun igbagbogbo sinu ile omo ati irora eyin ati ibadi. Paapa, nibiti iru asa yi to buru pupo ba ti waye, omobirin na yio wa labe ewu to ga lati ni ibimo to le
pupo ati lati ku ninu ibimo, paapa ni igbamiran FGM le yorisi ailesabiyamo. Iwadi kan ti won se ni orile-ede Sudan ri wipe awon obirin to ti la FGM koja wa labe ewu ailesabiyamo ni ilopo meji awon ti ko ni iru
iriri be. Eyi nwaye latari awon arun iredodo odo abe ti ikolu igbagbogbo nfa latari ida-ito-duro-sinu ati eje
nkan osu to sare koja ninu ile omo, to si wa fa iredodo ati ogbe sinu awon ona to lo si ile omo. Ni awon awujo ibile, ailesabiyamo je ikolu to banilokanje pupo nitori iyi obirin ninu opolopo awon awujo wonyi da

lori agbara re lati sabiyamo. The Independent (Banjul) 10
10 Page 11 12
11
Vol. 11 No. 22 CHANGE Radio November, 2000. (Yoruba) Vol. 11 No. 22 CHANGE Radio November, 2000. (Yoruba)
Awon Olutoju Awon Eda Abemi Egan ti se atileyin fun 6mins. 16secs. Igbesele Titanium
Ajo Olutoju Awon Eda Abemi Egan ni orile-ede Kenya (Kenya Wildlife Service (KWS) ti soro ni ifaramo ipinnu ijoba lati dawo iwakusa irin Titanium duro ni agbegbe Kwale. Nigbati o nsoro lehin abewo kukuru
to se si agbegbe Mwatate ni Ibudo iwojopo agbami nla Kighombo, ni ekun Taita Taveta, Oludari ajo KWS, Nehemiah Rotich so wipe iwakusa yio fa ibaje ayika. Dokita Rotich so wipe awon egbegbe
olominira yio se apilese iwadi lori ikolu ise na si ayika, won o si pin abajade iwadi na kiri ki ise na to bere.
Gegebi oro re, "Ni ibamu pelu ofin lori Ayika, ise agbese ti o ba le ni awon ikolu ti ko dara lori ayika, ti yio
si tipa be fi emi awon eniyan sinu ewu, ni won gbodo se iwadi olominira lekunrere lori iru ikolu to le ni. Ibi ti ajo KWS duro si niyi". Iwadi ikolu ti ajo Tiomin Resources, ajo oloko-owo orile-ede Canada to nife si

iwakusa na se ni ko iti gbe jade si gbogbo awon ti oran na kan, lara awon ti a ti ri awon amoye lori ayika ati awon olori agbegbe fun ayewo. O seese ko je ife-inu to tako ara won. Nitori idi eyi, o ni oro na ti mu
ifura wa wipe iwadi ti won se na ko fi aworan otito han lori iru ibaje ti ise na le fa ni ekun na. O ni, "Emi ko
iti ni anfani lati ye iroyin iwadi Tiomin wo, nitorina nko le so pato boya o pon si apakan tabi beko. Sugbon o se pataki ki iru iwadi be wa lati owo awon egbe amoye olominira ti oran na ko kan rara. Lati se ipinnu

latari iroyin Tiomin nikan ko boju mu rara. Nse lo dabi wipe ki a ni ki eniti a fi esun kan se idajo ara re". Oga ajo KWS na so wipe won ko iti se 'apejuwe to doju aami' lori ise agbese titanium na fun awon ti oran
na kan lara eyiti a ti ri awon afenifere ayika ati awon olori, eyi si mu ifura wa lori kini ero-okan ajo oloko-owo
na gan an. Ni ose meji seyin, Minisita Agba, Marsden Madoka so wipe ijoba ti pinnu wipe ise iwakusa na ko ni bere bi won ti lero tele titi ti a ba yanju oran to dikoko ninu re. Madoka so wipe on ko

faramo gbigbe ile na fun ajo oloko-owo Canada nitori yio tun dakun isoro awon atipo to ti buru nibe tele. The Nation (Nairobi)

Bi Mo Se Ri i Si
"Lati Inu Irisi Obirin Kan" 6mins. 6secs. Nigbati mo ba ri 'arabirin' mi to wo yeri penpe, buba penpe to fi aya sile debi wipe o fe fenu ko ori yeri
na, bata to ga bi petesi alaja-kan ati ikunjukura to ju ti oku eniyan lo, mo wa nro lokan mi wipe "lo mu won, omobirin!" Awon oro yi ki ise oro iwuri, besi ni ko seese fun mi yala lati mu irewesi ba won tabi yi won
lokan pada kuro ninu ise-oojo won -yala ti won yan tabi ti a yan fun won. Beni, awon ise-oojo die ma ndi dandan funni latari ikuna kan tabi awon isele layika lowolowo, besi ni wipe opolopo isele layika lo wa
lowolowo ninu awujo wa loni. Mo ma nri awon obirin ti awon funrarawon ko ni igbagbo ninu eko ti won ko si ni wu awon omo won lori lati duro si ile-eko, sugbon dipo eyi won a ma daba abele, won a ma so oro
bi "lo ri ogbeni lagbaja, ile ifowopamosi lo ti nsise". Kini omo re obirin olodun-meedogun to ti kuro ni ile-iwe
ni i se pelu ogbeni lagbaja? se o nwase ni, tabi? Ise to je wipe ara nikan lo ni lo, ko nilo iwe-eri kokan rara?.

Ni ida keji? Iya ni arun ti ko se wosan, omobirin re olodun medogun lo ti di baale ile ti yio ma toju ebi. Bi omode yi ba tile pinnu lati duro si ile-eko, ko si ona lati fi san owo eko re nitori iya paapa ko kawe yori, o
si bimo nigbati o wa ni odo, nitorina ko si ise kan to lese ... (nje ibi to dara niyi lati so wipe itan ntun ara re so?) Sugbon bi o tile dabi enipe oro alailanu ni, otito ni, otito si ma nkoro. Bi mo se so, emi o le fa irewesi
fun won, nitori ohun kan ni lati da awon mejeji leko lori awon ewu to wa lona ti won nto, ohun miran ni lati ri nkan se nipa re. Boya won lo si opopo ona won ko ri awon 'onibara'? Boya ohun ti mo nbere lowo
awon okunrin wa ga ju? Biotiwu kori, ipe na ti jade, gegebi o si se ri gan ninu ijoba tiwantiwa, o le yan lati
wa lara ojuutu na tabi lara isoro na. Akosun Owusua in the Accra Mail 11
11 Page 12 13
Vol. 11 No. 22 CHANGE Radio November, 2000. (Yoruba)
12
A Ti Gbo ...
A se itungbedide Ile-Ise Igbohunsafefe Voice of Nigeria (VON) 7mins. 6secs.
Ajo Igbohunsafefe ti orile-ede Naijiria si eyin-odi ni a ti se itungbedide re. Ayeye olojo-kan na lo waye ni ojo kokanlelogun osu kesan odun 2000 ni ilu Abuja, olu-ilu orile-ede Naijiria. Ayeye na ni opolopo asoju

ipele-ipele ijoba orile-ede Naijiria pese sibe, lara awon ti a ti ri Igbakeji Aare, Alhaji Atiku Abubakar, awon olugbohunsafefe ati awon omowe. Ajo VON se igbekale aworan idanimo titun fun ile-ise won,
awon itoni titun, ajosepo kariaye titun fun imusese, awon eto titun ati igbohun lati-inu-eto won to dara si
kariaye. Oludari Agba fun ajo Voice of Nigeria, Ogbeni Taiwo Alimi so wipe iran ajo VON titun na ni lati di ibudo igbohunsafefe ni kariaye ti awon eniyan to ba ni ife-inu tooto ninu orile-ede Naijiria ati ile Afrika

yio koko ma yan. O tun so wipe ise pataki ajo VON titun na "ni lati fi irisi orile-ede Naijiria ati ile Afrika han ninu awon igbesafefe wa .... ki a si gba, ki a si di ikobiarasi, ibowo ati ifenifere awon olugbo jakejado
aye ... mu paapa ti awon omo orile-ede Naijiria ati ile Afrika to funkakiri aye .... ki a si jeki a gbo ohun
orile-ede Naijiria ni rere ninu yiya aworan aye wa"

Ajo VON ni won da sile ni odun 1961. Ipa orile-ede Naijiria ninu awon isele ni ile Afrika mu ki o di dandan lati ni ona kan seyin odi nipase eyiti a le ma gba ifitonileti to wa lati orisun taara pelu igbohunsafefe

oni wakati meji pere lojojumo si iwo-oorun Afrika. Nigbati yio fi di odun 1990, ajo VON da duro, nigbati o si di odun 1996 o bere si gbohunsafefe si gbogbo aye. Gegebi ara ilana imugboroosi re, ajo VON sese
fowo si ifowosowopo kan ni awon eka ti idanileko fun awon osise ati pasiparo awon eto pelu awon ajo
iroyin ile okeere bi i Radio France International, Voice of America ati ajo Radio Deutsche Welle ti orile-ede Germany. O ti nsise pelu imo-ero World Space lati se imudarasi igbohunlati-ile-ise-re si awon olugbo

ni ayika ati ni kariaye lati le kan awon olugbo kakiri aye ti a si siro won si bilionu (milionu lona egberun) merin o le egbeta milionu eniyan lara.

Nigbati o nsoro lori awon nkan to fa inilo fun idanimo titun na wa, Alimi so wipe, "mo mo wipe o se pataki lode oni wipe a gbodo wonu ajosepo pelu awon olugbohunsafefe ni kariaye lati le ni ohun ti mo pe ni ajopin
iran lori nkan ti igbohunsafefe jakejado aye gbodo je. Nigbati mo ti faramo eyi, mo wa ri wipe o se pataki lati ni ifikunlukun pelu awon olugbohunsafefe jakejado aye lori iran wa wipe koko igbohunsafefe wa
gbodo yi kuro ninu itenumo awon ogun ati rogbodiyan si igbelaruge alaafia ni aye CFC

Orile-ede Sweden Gbe Owo Sile Fun Itoju Iseda Aye Ni 3mins. Orile-ede Nambia
Asoju ijoba orile-ede Sweden si orile-ede Nambia Gunilla Hesselmark ati Oludari Alase ti Ajo Amuludun fun Iseda Aye ti orile-ede Nambia, Chris Brown fowo si iwe adehun oni egberun lona ogorun o le meje ati
edegberun o le metala owo dola Amerika fun itoju iseda aye. Hesselmark so wipe owo na ni won o gbe fun awon omo orile-ede Namibia ati awon ajo to ni ife si itoju awon ayika won. O ni Akojo owo ni orile-ede
Sweden fun Ayika Agbegbe nfe lati pese owo diedie fun awon eniyan agbegbe ni orile-ede na to le jeki won kojusi awon oran ayika laarin ibugbe won nipase itoju awon eda abemi egan ati idagbasoke.
Asoju na ta awon eniyan agbegbe laya lati ma ri ounje ooojo won nipa dida ise itoju ayika tiwon sile, eyiti
yio jeki won le ma sise sin ara won. Hesselmark woye siwaju wipe owo dola Amerika bi egberun lona igba o le mokandinlogota, lara eyiti isuna owo ti odun 2000 wa, ni won ti na lori awon ise agbese lori ayika

ni orile-ede Namibia. Ni odun 1999, nkan bi awon Imuwa fun Ifiyesi lori ise marundinladorin ni won ri gba, ti Ajo Amuludun Namibia fun Iseda Aye lati ipase Ile-Ise Asoju Ijoba orile-ede Sweden gbe owo sile
fun mejidinlogun ninu won, ti gbogbo owo won je adorun egberun o le irinwo ati okandinlogota owo dola
Amerika. Lara awon ise ti won gbe owo sile fun ninu apa kini ni a ti ri idasile ogba eranko ti ebi kan ni Wanaheda, Windhoek, awon ibi itoju awon itanna ni agbegbe awon ogba eweko ti orile-ede.

Panafrican New Agency 12
12 Page 13 14
13
Vol. 11 No. 22 CHANGE Radio November, 2000. (Yoruba) Vol. 11 No. 22 CHANGE Radio November, 2000. (Yoruba)
Akojo Owo Bi Adojo Milionu Owo Dola Amerika lati gba 1min. 5secs. Awon Agbegbe Aye ti awon Eranko Ati Eweko ibe wa labe ewu la
A ti se ifilose akojo owo oni adojo milionu owo dola Amerika fun idabobo to dara si i fun awon agbegbe aye ti awon eranko ati eweko ibe wa labe ewu iparun. Eyi je ajosepo ajo Itoju ni Kariaye (Conservation
International (CI), Bank Agbaye ati Ajo Agbaye fun Awon nkan Iwulo ni Ayika (Global Environment Facility (GEF). Akojo owo na ti a pe ni Akojo owo fun Ajosepo lori Ilolupo Eda Abemi ati Agbegbe won
to gbelege (Critical Ecosystem Partnership Fund (CEPF) ni yio fojusi, nipataki, awon agbegbe ilolupo awon eda abemi to wa labe ewu. Awon wonyi ni awon ekun to wa labe ewu to ga nibiti a ti le ri iko ogota
ninu ogorun gbogbo eya abemi to wa laye, ni ibiti o je iko kan o le o din die laabo ninu ogorun gbogbo oju ile aye. WWF

Ojo ati Akoko . . . . . .
Apero Ile Afrika lori Arun Kogboogun Eedi ni a ti sun siwaju di osu kejila odun 5mins. Apero pataki kan ti Ile Afrika lori Arun Kogboogun Eedi ati Idagbasoke, eyiti o ye ko waye ni ilu Addis
Ababa ni osu kewa ni won ti sun siwaju si ojo keta si ikeje osu kejila odun 2000. Apero na ti a mo si Apero keji Ile Afrika lori Idagbasoke ti odun 2000 African Development Forum 2000 (ADF 2000) labe
koko-oro "Arun Kogboogun Eedi: Italaya to ga fun Awon Asiwaju" ni isunsiwaju re waye lati le jeki opolopo awon asoju lati orisirisi ekun ile Afrika kopa. Eni to siso loju oro na ni Ajo Agbaye fun oran Oro-Aje
Ile Afrika (United Nations Economic Commission for Africa (ECA) to je alajumoseto ipade na. Apero na ti yio waye labe ase ajo ECA pelu ifowosowopo awon ajo UNAIDS, UNDP, UNICEF ati
Banki Agbaye, lara awon miran, ni a gbekale lati je "pepe iso soke kan fun ifaramo lotun si ise ajumose si
i lati dojuko Kokoro-arun HIV ati Arun Kogboogun Eedi ni ile Afrika. Awon bi edegbejo olori ile Afrika, awon oluseto imulo, awon ajo ilu, awon eniyan to ni kokoro arun HIV lara, awon omowe, awon eka

aladani ati awon alabasisepo ile Afrika lori idagbaso keni yio kopa ninu apero na. Gegebi ajo ECA se so, ipade na yio fojusi "ipa ati ojuse to munadoko fun awon olori ile Afrika ni ipele gbogbo lati le se igbedide
idahun ti ile Afrika se asiwaju re si ajakaye-arun na". Siwaju si i, ajo so wipe, "Ilana ADF 2000 yi yio se
asekun lori awon akitiyan ti o ti nlo lowolowo lati owo awon orile-ede Afrika ati awon alabasisepo won fun idagbasoke lati koju kokoro-arun HIV ati Arun kogboogun Eedi, yio si dojuko awon alafo to ba ku".

O so wipe apero na je "anfani to se koko kan" fun ile Afrika ati awon alabasisepo re lati sise lori igbaradi ti o waye lati inu apero kariaye lori Arun Kogboogun Eedi to waye laipe yi ilu Durban, orile-ede South
Africa. O ndu lati ran awon omo ile Afrika ni gbogbo ipele ti won lowo ninu igbejako kokoro-arun HIV
ati Arun kogboogun Eedi lowo lati se ajopin iriri ki won si keko lara awon eto imulo daradara lori ajakaye-arun na ni awon orile-ede to ti dide si italaya na pelu aseyege.

Panafrican New Agency
Apero Ile Afrika lori awon Atunse Ofin Ifiyajeni 1min. Apero Ile-Afrika kan lori awon atunse Ofin Ifiyajeni ni yio waye ni olu-ilu Cameroon lati ojo ketalelogun si

ikeedogbon osu kokanla odun 2000. Akori apero na yio je "Awon ipa ti ilujarawon aye ni lori awon atunse
ofin ifiyajeni ni ile Afrika" A leri ifitonileti si i gba lati owo alakoso: Mukete Tahle Itoe ni: www. geocities. com/ tmukete.

The Courier

Eto Fun Awon Omode
Mboma ati Ketekete na 10mins. 7secs. Ni opolopo odun seyin Ketekete ati Erinni je ore timotimo, won a si ma je oko papo ni bebe odo kanna.

Ni ojo kan omi odo na lo sile, ketekete gboju soke wo odikeji o si ri awon irugbin to tutu yoyo to si 13
13 Page 14 15
Vol. 11 No. 22 CHANGE Radio November, 2000. (Yoruba)
14
fanimora. Ki Erinmi to de ni owuro ojo yen, Ketekete da omi ru lo si odikeji o si je eyi to te lorun ninu
awon irugbin aladidun na. Nigbati o pada ni asale ojo na Erinmi wo ikun re to tobi o si bere, "Nibo lo ti lo?.

"Ore mi, mo rekoja odo nibiti awon irugbin to dara ti nhu. Iwo na o se ba ni lo ni owuro ola?" "O di dandan,". Erinmi dahun, "mase lo laimu mi dani".

"Ni owuro, Ketekete ati Erinmi pade won si rekoja odo na. Bi won se nlo, Ketekete gba Erinmi ni imoran wipe oluso kan wa to nso awon irugbin na losan ati loru. Sugbon o fun ni idaniloju: "Iwo sa farabale, ore
mi, Emi yio ma sona, ngo si ke ti nba ti ri oluso na to nbo. Bi o ba ti gbo ti mo ke, sa kuro ninu oko na ni kiakia." Erinmi dupe lowo Ketekete fun aanu re o si sare je ohun to ni je titi o gbo ti Ketekete nke. O si
sare kuro ninu oko na ni itopa eti odo na o si rekoja si odikeji lo sinu aabo adagun kekere nibiti o gbe
mookun sabe omi ti enikan ko le ri. Eyi tun sele ni ojo keji ati iketa, tiit ti Erinmi fi woye wipe Ketekete ki isi niwaju tabi leyin on nigbati on ba nsalo nitori oluso ti o ni o wa nibe. Lojiji, o han si gbangba wipe ore

on ndogbon lati fi eyi to ju ninu ounje na sile funrare ni nipa jijeki Erinmi je die pere ki on si ke lati le kuro ninu oko na. Ko si oluso kokan besi ni Ketekete ko salo -o ti o -nse ni o duro seyin to njeun lo de ibi to fe.

Erinmi ko so nkankan nipa ifura pe, won si nba a lo be titi ti ojo fi de ti odo tun ga soke pada.
Nisisiyi Ketekete ni lati duro si odikeji odo nitori odo na jin, isan re si lagbara, on ko si le we. O bere si
tinrin si bi ebi se npa si i lojojumo nitori ko si eweko pupo leba odo na, won ko si dun lenu bi awon irugbin odikeji.

Ni akoko yi, Erinmi beresi tobi si bi oun se tesiwaju lati jeun ni awon oko irugbin ni ajeyo lojojumo.
O so fun Ketekete. "O ye ko pada wa si ibi awon irugbin yen. Wo ara re bi o se ntinrin si lojojumo, ti ounje to dara si wa ni irekoja odo."

Ketekete dahun teduntedun. "O wu emi na, sugbon o mo wipe nko le we."
"Iyen o soro o, "Erinmi dahun. "bi o se je ore mi ngo gbe o koja si odikeji".
Bayi, ketekete gun eyin Erinmi won si bere si rekoja lo. Ohun gbogbo lo deede titi ti won fi de arin odo na nigbati Erinmi kigbe soke. "O jin nibiyi, ese mi o si le kanle mo". O ri lo si isale pelu Ketekete. Erinmi bere
si rin lo ni isale o si jade si odikeji sugbon Ketekete ti ko le we tabi se emi bi Erinmi, ri sinu odo na.
Titi di oni yi, ore laarin awon Ketekete ati Erinmi ko ti tun waye.

Oro Asokagba
Se ayeye ogbon iriri ile Afrika pelu awon oro manigbagbe wonyi.
Lori Iyorisi
Eniti o ba ta yepe bi iyo yio gba okuta gegebi owo Orile-ede Naijiria

Eniti a ba fi ori re fo agbon ko ni je ninu re Orile-ede Naijiria 14
14 Page 15
15
Vol. 11 No. 22 CHANGE Radio November, 2000. (Yoruba) Vol. 11 No. 22 CHANGE Radio November, 2000. (Yoruba)
Lori Itanje Ti o ba fe dana sun ile re, ota re yio ya o ni isana
Orile-ede Zimbabwe
Erin muse ni ohun ija to lagbara ju ninu ijakadi aye Orile-ede Ghana
More African proverbs
Ati oro ipari kan lori Itoju Ariyanjiyan to lagbara kan wa wipe iseda aye ni eto tire lati wa ni ominira si ilo eda eniyan .....

Ariyanjiyan to da lori ibojumu tun wa nipa ewa iseda aye, sugbon ipari ni wipe o lewa tabi ko lewa,
eya kan ni eto lati ruula nitori wipe o sa wa nibe.
Peter Kramer

Oludari Itoju fun Ajo WWF The New Road 1988. 15

Page Navigation Panel

1 2 3 4 5 6 7 8 9
10 11 12 13 14 15

 

© 2002 Communicating for Change. All Rights Reserved
Developed by George Mbuagbaw