Go Back
Communicating for Change

Document Body Page Navigation Panel

Pages 1--14


Page 1 2
Vol. 11 No. 21
October, 2000 (Yoruba)
CHANGE Radio

1
OUNJE
Ajo EU gbe owo Euro milionu metala sile fun Eto Agbaye lori Ounje ni ile Afirika. 3mins. 7secs. 3
Atileyin fun Eto Ajo Agbaye lori Ounje ni ile Afirika gba igbelaruge pelu
igbowosile lati odo Ajo Apapo Ile Europe.

AWON OBIRIN ATI ODO
Awon obirin orile-ede se ihale iyerakuro 5mins. 6secs. 3
Awon obirin orile-ile Liberia fi dandan le igbekale awon ofin to da lori
awon eto won lori ogun jije.

Awon Omode bi milionu mokanla lo nku lati owo awon arun to se dena. 5mins. 16secs. 5
Awon isiro se ifiwerawon ipo ti iku awon omode wa ni agbaye pelu ijabo oko-ofurufu
Boeing 747 to kun fun awon omode ti ojo ori won ko ti ito odun marun ni wakati kookan.

Awon olori ninu awon obirin ile Afirika fikunlukun lori oro awujo. 11mins. 6
Apero kariaye kan ti awon obirin to wa sopin laipe yi ni orile-ede Namibia pari pelu
ipinnu lati ko ipa daradara ninu iyipada eto awujo.

ORO AJE
Awon Talika wa pelu wa 7mins. 5secs. 4
Biotilejepe igbe aye eda eniyan ti dara sii, Ajo Agbaye fun Akojopo Owo
(International Monetary Fund) so wipe aisiki ko iti kari aiye.

Awon Oko-owo keekeeke gegebi ero fun idagbasoke ni orile-ede Naijiria. 11mins. 2secs. 10
Ilana kan lati se iwuri fun idoko-owo ni o nlo lowolowo lati se iranlowo
fun imupadabosipo oro-aje orile-ede Naijiria

ILERA
Orile-ede Zimbabwe yio bere idanwo awon Egboogi fun Arun Kogboogun Eedi. 4mins. 3secs. 5
Orile-ede Zimbabwe nfojusona fun awon itoju ti ko nanilowo pupo eyiti a ti ri wipe o
nkoju ajakalearun Eedi.

Ayika
IDOTI
Asilo awon kemikali ise-ogbin npa awon eran-osin. 3mins. 9secs. 3
Orile-ede Burkina Fasso ti gbesele ilo awon egboogi ipakokoro kan fun itoju awon
eran-osin leyin ti majele ti pa ogorun maalu.

Imorusi Aye: Irokeke Ewu si Awon Ilana Ilolupo Eda Abemi ati Agbegbe won to gbelege. 5mins. 4secs. 7
Iroyin kan laipe yi kilo wipe iyaramorusi aye le yorisi iparun opolopo eya eda abemi
egan ati eweko.

Mimu awon Ile-ise Isenkanjade se iranwo lati yera fun Idoti 9mins. 7secs. 11
Ona titun lati fi koju idoti ni Ajo Agbaye fun Eto Ayika ti gbekale, awon iroyin to si koko
jade lori re nso ti aseyori to wunilori.

Ajo UNEP dawole ise agbese olopolopo milionu owo dola Amerika lori Awon 8mins. 2secs. 8
Oro Kemikali
Ajo Agbaye ti setan lati dawole ise agbese oni milionu marun owo dola Amerika lati
se ayewo ikolu awon idoti ni gbogbo ekun aye.
1
1 Page 2 3
Vol. 11 No. 21
October, 2000 (Yoruba)
CHANGE Radio

2
ITOJU
Eweko Iwosan ti fere parun tan. 6mins. 6
Itanna lili impala ti akoko otutu ni iha gusu ile Afirika ni o wa ni bebe iparun,
eyi yio si yori si adanu nla fun awon afenifere ayika ati awujo awon onisegun.

Orile-ede Egypt nja fitafita lati gba Ijapa re to wa labe ewu iparun la. 11mins. 9secs. 9
Ajo Itoju kan ti ko lowo ijoba ninu ni o ti nse aseyori si rere to yanilenu ninu
idabobo awon akojopo ijapa orile-ede Egypt to wa labe ewu iparun.

Isiro......
ILERA
Eelo ni ilera pipe nna eniyan ni ile Afirika? 2mins. 12
Opolopo orile-ede ile Afirika ni ko iti mu oro ilera ni okunkundun.

AJALU
Sisiro iye adanu ti omiyaleyaona muwa ni orile-ede Mozambique 4mins. 12
Eto Ajo Agbaye lori Ounje ya aworan to buru lori iparun ti omiyalegaona aipe
yi fa ni orile-ede Mozanbique.

A ti gbo......
ILERA
Awon Oludije Olympic lati ile Afirika se atileyin Ipolongo lati koju Arun Ako Iba. 3mins. 9secs. 12
Ni lilo anfani idije Olympics to nbo yi, Ajo Agbaye fun Oro Ilera lo awon oludije
lati ru imo soke lori idaloro ti ako iba nfa ni ile Afirika.

Igbogunti Arun Kogboogun Eedi gba igbelaruge ni orile-ede Naijiria. 2mins. 13
Ajo orile-ede Geesi kan ti seleri milionu meje Owo Poun ti Geesi lati se atileyin
igbogunti Arun Kogboogun Eedi ni orile-ede Naijiria.

Ojo ati Akoko....
IDOTI
Orile-ede Canada yio gba alejo Apero lori isenkanjade lona to mo sii. 1min. 13
Ni itele Ipade Ile Aye to waye ni ilu Rio, orile-ede Canada gio gba gbogbo
aye ni alejo ninu apero alagbara kefa lori Isenkanjade lona to mo sii.

Eto Awon Omode
Ologbon Ehoro ni idojukoju pelu Erin ati Erinmi. 9mins. 5secs. 13
Ehoro fihan wipe ogbon ju agbara lo.

Oro Asokagba Se ayeye ogbon iriri ile Afirika pelu awon owe manigbagbe die. 14 2
2 Page 3 4
Vol. 11 No. 21
October, 2000 (Yoruba)
CHANGE Radio

3
Iroyin
Awon obirin orile-ede Liberia se ihale iyerakuro 5mins. 6secs.
Ni ilu Monrovia, awon obirin orile-ede Liberia, lara eyiti iyawo aare, Jewel Howard-Taylor wa, ti hale wipe awon yio yera kuro ninu gbogbo ayeye ijoba ti a ba pe won si titi ti a ba se agbekale awon ofin to da

lori eto won lori ijogun. Awon obirin na se ihale na ni Ile Igbimo Asofin ninu ijirebe elese-mefa ti won gbe siwaju awon omo igbimo asofin. Ijirebe alagbara na ni o wa leyin iwode olopo-eniyan to waye ninu ojo
repete kakiri awon opopona ilu Monrovia.
Laarin awon nkan miran, awon obirin na so wipe wiwa awon ofin otooto to se akoso eto awon opo ati iyawo oloruka ati awon opo ati iyawo labe ofin isedale ni o nse ifi-iyato-si ni ilodisi ilana isokan ati idogba
to wa ninu ofin orile-ede. Nitorina, awon obirin na nfe idapo gbogbo ofin to jemo awon opo yala ti igbeyawo oloruka tabi ti igbeyawo labe ofin isedale.

Awon obirin na so wipe: "A tun nfe ki ojo ori fun igbeyawo okunrin ati obirin labe igbeyawo oloruka ati ti isedale je odun mokanlelogun fun awon okunrin ati odun mejidinlogun fun awon obirin." Awon obirin na
tun hale wipe awon ko ni se atileyin idiboyan awon okunrin fun ipo ijoba kokan, paapa si ile igbimo asofin, ti won ko ba ri wipe awon okunrin na nwa, won si nteramo awon ohun anfani fun awon obirin. Iyawo
Aare, Jewel Howard-Taylor, to soro ninu ayeye na, so wipe inu awon obirin ko dun nitoripe ijirebe na ti wa lowo awon asofin na fun odun kan o le si nisisiyi.

Nigbati o nfesi ni igbenuso fun Ile Igbimo Asofin, Olori ile igbimo Asofin Nyudueh Morkonmana ati Aare Ile Igbimo Asofin Agba Keikura Kpoto fi da awon obirin na loju wipe awon o se ohun gbogbo to wa ni ipa
won lati gbe ofin na jade laipe. Awon ayeye iwode ati ijirebe ti a fi saami ayeye keji Ojo Ise ati Imo lori Eto Ijogun fun awon Obirin, ni a se labe koko oro ti a pe ni "Eto Dogbandogba fun Gbogbo Eniyan."
The News
Ajo EU gbe Owo Euro Milionu metala sile fun Eto Agbaye lori 3mins. 7secs. Ounje ni ile Afirika.

Ajo Apapo Ile Europe ti kede igbesile milionu metala owo Euro gegebi afikun inawo lori Eto Ounje ni
Agbaye (World Food Programme (WFP) ni orisirisi awon orile-ede ile Afirika. Gegebi ikede kan lana, milionu metala owo Euro na je afikun si Adorun milionu ti Ajo Igbimo Europe (European Commission)

gbe sile ni osu keje. Igbimo na tun ti se ipese opolopo ounje nipase awon ona miran yato si ti WFP. Ni ojo kejidinlogun osu keje, Igbimo na pinnu lati gbe Adorun Milionu owo Euro fun WFP lati kaju inilo ounje
ni lowolowo yi ni ile Afirika. Gegebi ikede na ti so owo yi yio fi aye sile fun ipese milionu merinleladojo
iwon tonnu oka, milionu meje ati aabo ororo ati milionu kan suga ati awon nkan miran.

Ikede na tun so wipe igbimo na se ipese owo to ju milionu meta ati egberun lona metaleladorin owo Euro lati ipase Ajo Agbaye fun Awon Asasala Ajalu (United Nations High Commission for Refugees (UNHCR)
gegebi iranwo aanu fun awo asasala ajalu ni orile-ede Zambia lati orile-ede Democratic Republic of Congo
ati lati orile-ede Angola. Igbeowosile na ni lati se aridaju awon iranwo ti ajo UNHCR nse kokari re fun ipese itoju ilera, omi fun awon asasala ati irinna.

The Post of Zambia
Asilo awon kemikali ise-ogbin npa awon eran-osin 3mins. 9secs. Ijoba orile-ede Burkina Fasso ti gbesele ilo awon egboogi ipakokoro kan fun itoju eran-osin. Igbesele na

waye leyin ti ogorun maalu ti ku latari majele laarin osu kefa ati ikeje ni agbegbe Mouhoun, gegebi oludari 3
3 Page 4 5
Vol. 11 No. 21
October, 2000 (Yoruba)
CHANGE Radio

4
ekun fun ise-osin eran ni ekun aringbungbun iwo-oorun se so. Alexandre Sawadogo so wipe awon egboogi ipakokoro na wa fun ise-ogbin nikan, o si wa kilo wipe enikeni to ba te ase na loju yio jiya.
Ninu ikede kan ti a gbesafefe lori awon ibudo igbohunsafefe agbegbe, eka ti oro eranko ni ekun na so wipe
awon eranko na ku leyin ti won ti gba itoju pelu tabi gba awon egboogi ipakokoro na sara. Ikede na so wipe awon eleran-osin ma nlo awon egboogi na lati toju awon eran-osin ati lati dabobo won kuro lowo

eegbon. Ile-ise na tun fa ifojusi awon eleran-osin si awon ikolu buburu ti awon egboogi na ni si ilera awon eranko ati eda eniyan. Gegebi ile-ise fun ilera awon eranko fun agbegbe na se so, mokandinladota maalu
lo ku ni agbegbe Kossi, to je ogoji-dinnirinwo ibuso kilomita si iwo-oorun Quagadougou, ati medogbon ni
Bale (adota-lerugba ibuso kilomita si iwo-oorun Quagadougou) leyin ti a ti se itoju won pelu egboogi 'Cypercal 50', kemikali kan ti a ma nlo fun eweko owu-otutu. Ni agbegbe Sourou (bi odunrun ibuso

kilomita ni iwo-oorun Quagadougou) maalu mejidinlogbon lo tun ku leyin ti won ti se itoju won pelu kemikali 'Bazudin 600'.
Pan African News Agency

Awon Talika wa pelu wa 7mins. 5secs. Biotilejepe igbe aye eda eniyan ti dara sii laarin ogorun odun to koja, ilosoke aisiki ni agbaye ko ti mu
anfani ba gbogbo orile-ede ati ekun gegebi iwe iroyin World Economic Outlook eyi ti Ajo Agbaye fun Akojo Owo (International Monetary Fund (IMF) nte jade se so. Idarasi ninu igbe aye yi waye latari
ayipada ti a ko ri ru re ri ninu imo-ero ati oro-aje. Gegebi iroyin na se so, apapo gbogbo nkan ti a se ni agbaye fere di ilopo meta ni idaji akoko ti ogun orundun, o si lo soke ni ilopo mesan ninu idaji keji, eyi si
rekoja ilosoke ninu akojopo eda eniyan. Ni afikun, ifojusi emi gigun, eko ati awon aami miran fun igbe aye rere na tun dara si, paapa ni awon orile-ede to talika.

Sugbon ipinkiri owo to wole ni agbaye -ti a ba se idiwon re ni iye iwontunwonsi owo to nwole kakiri awon orile-ede -si ri wogowogo, gegebi iroyin na se so. Ikuna lati kojopo soju kan yi ni a le fi oju olojo-pipe
ninu ilosoke wo. Iko meta ninu merin awon orile-ede to sese ndagbasoke ni o ni ilosoke owo to wole ni ori-o-jori ti ko yara lo soke yato si bi o se wa ninu awon orile-ede to ti dagbasoke laarin ewadun meta to
koja. O so wipe owo to nwole ni ori-o-jori lo sile ninu awon orile-ede mejilelogbon to wa ninu akosile na,
nigbati orile-ede meje pere ninu awon to sese ndagbasoke lo yara lo soke to lati din alafo ku, ki o si fere ba awon orile-ede to ti dagbasoke gegebi egbe. O se afikun wipe o din ni idamewa awon olugbe awon

orile-ede to sese ndagbasoke to ngbe awon orile-ede nibiti iwontunwonsi owo to nwole ti lo sile, nigbati iko adorin ninu ogorun lo ngbe ni awon orile-ede nibiti ilosoke ninu owo to wole ni ori-o-jori ti ju ti awon
orile-ede to ti dagbasoke lo.
Sugbon sa, awon talika si wa pelu wa. Iroyin na so wipe iye awon olugbe to wa ni awon orile-ede to sese ndagbasoke ti ki iri to to owo dola Amerika kansoso lojumo ti lo sile lati iko ogbon si iko merinlelogun
ninu ogorun ninu ewadun to koja (eyi si nse afihan idinku ninu osi ni Ila-oorun ile Asia ati laitoyentan ni Gusu Asia). Sugbon o se afikun wipe iriri osi si ga lona ti ko tenilorun. Ajo IMF tenumo wipe ko iti si
itesiwaju ninu dindin osi ku ni ile Afirika ati ni Iwo-oorun Aye. Paapa o jiyan wipe iye osi tile lo soke ninu awon orile-ede to nlo lati igbe aye kan si omiran. Gebebi oro re: "A gbodo fokansi wipe osi pin si ipa
orisirisi, o si nse afihan awon nkan miran, yato si aini awon nkan ilo, bi aisi aabo ati ona si awon ohun inilo fun igbesi aye lara eyiti a ti ri ilera, eko ati imototo. Awon igbesi ilera (fun apeere, ifokansi emi gigun) ti
yara parapo lati orile-ede kan si ekeji ju iwontunwonsi owo to nwole lo, latari ipinkakiri imo ero lori ilera,
lara awon ohun miran. Iha ilujarawon-aye yi, laisianiani, ti ran awon orile-ede to talika ju lowo. All Africa. Com. 4
4 Page 5 6
Vol. 11 No. 21
October, 2000 (Yoruba)
CHANGE Radio

5
Orile-ede Zimbabwe yio bere idanwo awon Egboogi fun Arun 4mins. 3secs. Kogboogun Eedi
Awon asewo ni ile iwosan yio bere ni osu kesan lori awon itoju ti ko nani lowo pupo eyiti a si ti ri wipe o
munadoko ninu didaduro ati yiyipada seyin ilosiwaju kokoro-arun HIV, kokoro to nfa arun kogboogun Eedi. Awon ona itoju na, eyiti o da lori awon egboogi to wa ni arowoto bi aspirin, selen ati adalu-opo-eroja

amuarawanideede, ni Ile-ise fun Isegun Idakeji to fikale si orile-ede Amerika ti ri wipe o nran awon to ni ikolu Arun Eedi lowo lati mu ilana igbogunti-oro ninu ara won dara si, ati lati din itesiwaju kokoro na
ku. Snorre Westgard to je oludari ise agbese fun Ajo Hope Humana to je ajo kariaye kan ti ko lowo ijoba
ninu fun itiraka lati se igbejade awon ona itoju olowopooku ni orile-ede Zimbabwe, so ninu ose yi wipe eka Isegun ni ile-eko giga Yunifasiti ti orile-ede Zimbabwe ni yio se kokari awon asewo na. Gegebi

Westgard se so fun Iwe Iroyin lori Isuna na, apa kinni ninu asewo alapameta na ni yio gba osu meta sugbon gbogbo eto na le gba to odun kan gbako. Ajo Hope Hunana lero lati se awon egboogi na ni ilu
Bindura ti won ba ti fi ase si awon asewo na, o si ti nko owo ati awon ohun elo jo ni orile-ede Zimbabwe
ati ni kariaye. Eto fun ona Itoju miran na ni a ti ri wipe o munadoko gegebi awon ona itoju onipameta to won pupo sugbon to wopo ni awon orile-ede to ti dagbasoke fun itoju Arun Kogboogun Eedi.

Orile-ede Zimbabwe, ti Ajo Agbaye fun Ilera royin wipe o ni, o kere tan, eniyan kan laarin agbalagba marun, to ni kokoro-arun HIV, ni o ni ikolu to le ju ni iha gusu ile Afrika.
The Financial Gazettee
Awon Omode bi Milionu Mokanla Lo nku Lati Owo Awon Arun To Se Dena 5mins. 16secs. Gegebi awon isiro ti a gbekale ninu idanileko kariaye oni-ifiorowero kan lori ilera to waye ni Bamako, olu-ilu
orile-ede Mali, awon omode bi milionu mokanla lo nku lododun ni aye lati owo awon arun to se dena ati
airi ounje to dara to je. Sugbon awon olukopa ninu idanileko na fun igbaninimoran lori "Asewonuarawon Isakoso Arun Omode" gbo wipe o seese lati din iku awon omode ku pelu idamewa si idamarun nipa awon

ihuwasi ninu ebi ati laarin awujo to dara si. Ipade Bamako na je ajose Ile-ise ekun ile Afrika ti Ajo Agbaye fun oro Ilera ati ti Ile-ise ijoba orile-ede Mali fun oro Ilera. O wa fun ati se agbekale ogbon imusenkan fun
isakoso awon arun omode ni ile aye na, nipa didaba awon ona ise to yanju lati se kokari awon ilowosi lati
owo orisirisi awon to nipa ninu oro na.

Nipa fifi bi iku awon omode se wa ni ode oni we ijabo oko ofurufu Boeing 747 kan to kun fun awon omode ti ojo ori won ko to odun marun ni wakati kookan, awon amoye na se afihan wipe ni opolopo orile-ede,
okan ninu awon omode marun lo ma nku ki won to pe omo odun marun lati owo awon arun to se
dena bi iredodo fukufuku, igbe gbuuru, ako iba, arun eyi ati airi omije to dara to je. Asoju ajo WHO ni orile-ede Mali, Helene Mabu Ma Disu, so wipe ti a ba sakoso iredodo fukufuku daradara, awon omode

bi milionu kan ni a le gbala lododun jakejado aye. O so wipe idaduro igbe gbuuru ati ako iba na le se iranwo lati dabobo awon omode bi milionu merin o le egberun lona egberin ati egberun lona edegbeta ni
iha kinni ati ekeji.
Abdrahmane Tomkara to je Akowe Agba fun Ile-ise ijoba orile-ede Mali fun oro Ilera ni reti wipe "nipase awon abajade idanileko yi, awon eniyan yio le lo lati aibikita olulo nkan si ifowosowopo-se-nkan laarin
ilana PCIME." Ipade Bamako na ni awon ojogbon lori ilera lati orile-ede Senegal, Benin, Code d'Ivoire, Niger, Democratic Republic of Congo, Burkina Fasoso ati olugbalejo, Mali kopa ninu re.
Pan African News Agency 5
5 Page 6 7
Vol. 11 No. 21
October, 2000 (Yoruba)
CHANGE Radio

6
Eweko Iwosan Ti Fere Parun Tan 6mins. Eya iha gusu ile Afrika to sese wa labe ewu iparun ni lili impala ti akoko otutu, eweko kan ti awon onisegun
ibile nlo lati se itoju awon aisan agbedu. Awon afenifere ayika kilo wipe ise-ogbin ati idagbasoke ti fere pa eweko na run ninu egan, ati pe bi a ko ba gbe igbese to le, yio parun laipe.

Akosemose lori itoju fun Igbimo Alase ti awon Ogba Egan Mpumalanga, Gerhard Strydom, ke ibosi oro na leyin ti iwadi olosu-merin ni ekun Onderberg ni ila-oorun Mpumalanga ti se afihan eweko ti ko ju mejila
pere lo. O ni: "Bi iko ogorin ninu ogorun ibugbe lili na ni idagbasoke ti parun ti won si ti nro iko ogun ninu ogorun to ku lati fi gbin ireke ati gbaguda.

Iha Gusu ile Afrika lo wa ni ipo keta ibi to ni iye awon eya eweko to pojulo to wa labe ewu iparun ni gbogbo aye leyin orile-ede Amerika ati Australia. O kere tan, eweko metaleladota ni a mo wipe o ti parun
patapata ni ekun na larin orundun to koja. Lili impala ti akoko otutu na je okan lara awon eweko iha Gusu ile Afrika bi egbokonla o le medogun ti a ko sile gegebi eyi to wa labe ewu iparun ninu Akosile Pupa to je
akosile gbogbo aye lori awon eya to sowon to si wa labe ewu ti Egbe Isokan Agbaye fun Itoju Iseda Aye (World Conservation Union (IUCN) nse akoso re.

Iwadi Strydom fihan wipe irunla ojo iwaju fun lili impala ti akoko otutu na, eyiti a ma nri ni iha ila-oorun Mpumalanga ati awon ibi melo kan ni iha ariwa orile-ede Swaziland at Gusu orile-ede Mozambique nikan,
ni o ti gbelege ju bi a ti ro tele lo. Awon lili impala ti akoko otutu yi ma nni itanna alawo resuresu ti ko tan yan an ati isu nla labe ile. Won feran ooru ati ile amo -awon nkan ibaramu fun idagbasoke ireke ati
gbaguda. Lili na ti a tun mo si lili Swazi ati nunankulu, gbajumo laarin awon onisegun ibile. Awon isu re ni
majele, nitorina iwonba eya ara re to wa laarin awon itakun ati igi re nikan ni won nlo.

O seese ki awon agbegbe ti a dabobo je ona ona igbala kansoso fun lili na, sugbon eyi paapa ko daju. Iwonba bi eweko na mejila pere ni won ti ri ni iha Gusu ogba Egan Orile-ede Kruger ati ti Egan
Iyasoto ti agbegbe Mawewe to wa nitori re. Mail and Guardian (Johannesburg)

Awon Olori Ninu Awon Obinrin Ile Afrika Fikunlukun Lori Oro Awujo 11mins. Awon gbajumo obinrin ile Afrika ati awon obinrin miran kariaye to fere to egberun kan to pejo si Windhoek,
olu-ilu orile-ede Namibia ni osu keje ni o jade ni gbogan apero na pelu ipinnu lati kopa to dara si ninu
awujo aye to nyipada. Gegebi Nafis Sadik to je oludari Alase fun Ajo Akojo Owo ni Agbaye fun Awon Olugbe Aye se so: "Fun obinrin iwoyi, akoko yi kii ise akoko fun oro aheso ninu iyara idana tabi ti iregbe.

Akoko lati ni ilowosi to dara si awujo aye to nsare yipada ni "Apero olojo-merin na, to waye ni opin osu keje, ni ekerin Apero Elekunjekun ti Awon Obirin ile Afirika to je Minisita ati Omo ile Igbimo Asofin.

Apero na ti a se labe koko oro "Awon Italaya lati koju Awon Inilo odo lori Ibalopo ati Isabiyamo," lo ta awon ijoba ile Afirika laya lati mu ise se ni kiakia lori orisirisi awon oran lara eyi ti a ti ri ti awon odomode
obirin, idabe fun obirin, awon obirin jagunjagun, iloyun awon omodebirin ati igbekale owo isuna to joju lori itoju ilera. Awon minisita ati omo ile igbimo asofin to je obirin na to wa lati orile-ede ile Afirika marundinladota
eyiti awon obirin logaloga lati awon ajo ti ko lowo ijoba ninu ati awon ajo kariaye ati awon alakoso gbe
lese, ni o fi taratara ta awon ijoba ile Afirika laya lati fun awon obirin ni aaye lati sise ninu awon ipo giga ninu iselu ati ipase. Won woye wipe yato si awon orile-ede to wa ninu Agbajopo fun Idagbasoke Iha Gusu

Afirika to ti de oju aami iko mejidinlogun o di die ninu ogorun awon obirin ninu awon omo ile igbimo asofin, iyoku awon orile-ede Afirika si din si idamewa pere. 6
6 Page 7 8
Vol. 11 No. 21
October, 2000 (Yoruba)
CHANGE Radio

7
Lori awon oro to je mo awon iwa bi idabe obirin ati "ibalopo onipajawiri", eyiti o nfa afikun iya ati ewu fun awon obirin, Sadiq so pe: "Isedale ati asa je ohun to niyelori pupo lati dabobo ijogun wa ati lati fun awon
odo wa ni awon eko to niyelori pupo. Sugbon opolopo igba ni a ma nyiipada lati ba ife awon egbe kekere kan mu." Gegebi oro Ajo Agbaye fun oro Ilera (World Health Organisation (WHO), awon obirin bi
milionu meji ni abe asale Sahara ile Afirika, ti eyito poju ninu won wa ni iwo-oorun Afirika, lo wa labe ewu igekuge abe obirin, eyiti o nwaye ni nkan bi orile-ede metadinlogbon ni ekun na. Lati se atunse oran yi,
Igbimo Ajo WHO lori ile Afirika ti beresi sise pelu awon ijoba orile-ede mewa ni abe asale Sahara lati fi opin si idabe fun obirin nipa sise iranlowo fun won lati fi opin si iwa ibile na.

Nigbati o nsi ipade na Aare orile-ede Namibia, Sam Nujoma, se afihan wipe iko marundinladota ninu ogorun awon odomobirin orile-ede na lo ti nbimo nigbati won o ba fi di omo odun mokandinlogun. Nigbati
o mu otito jade lati inu iwadi aipe kan lori ilera, Aare na so fun ipade na wipe iko meji ninu ogorun awon odomobirin omo odun medogun lo nloyun, o si da ebi oro na lori aisi ise ilera to to, eyiti awon odo ko tile
ni anfani re. Lara awon okunfa ti Aare na daruko ni iberu wipe awon osise ilera yio tu asiri, aisi asiri ninu
ipese ilera ati iwa ti ko dara to si nleniyan sa lati odo awon osise ilera, paapa nigbati eniyan ba nbere ifitonileti lori oro ilera to je mo isabiyamo, apo ato ati awon ona ifietosomobibi. O so wipe ijoba on ti pinnu

lati se imudarasi ipo awon odo ninu oran ilera lori ibalopo ati isabiyamo. Latari eyi, o ti se agbekale eto ilera orile-ede lori isabiyamo lati dojuko inilo awon odo orile-ede Namibia.

Ipade na tun pegan awon olori ile Afirika fun nina owo to kere pupo lori ilera nigbati won nko opolopo owo ati agbara lori didihamora lori awon ota to le yoju. Awon isiro ti won gbekale ninu ipade na fihan wipe
ni odun 1997, orile-ede Angola na egbeta o le marundinlogota milionu owo dola Amerika tabi iko mesan o din die pere gbogbo owo to nwole labele lori awon nkan ija ogun. Gegebi Igbesoriosuwon Oro Ologun
ti odun 1998 si 1999 eyiti Ile-ise Kariaye fun Igbeko lori Ogbon Ijagun to fikale si ilu London te jade,
orile-ede Eritrea na milionu marunlelogota tabi iko mejo o le die ninu ogorun gbogbo owo to wole labele re nigbati ile-oba kekere, Lesotho, na iye to to iko merin ati abo o le die gbogbo owo to wole labele lori

nkan ija ogun.
Iwulo ipade na ni minisita orile-ede Namibia fun oro Obirin ati Omode, Netunbo Ndatwah, tenumo nigbati
o so wipe "fun ojo merin to koja ni a ti nse pasiparo iriri lati iha pupo. A npada lo si awon ile igbimo asofin ati igbimo minisita wa pelu igbaradi to ga ju ti teletele lo."

Pan African News Agency

Imorusi Aye: Irokeke Ewu si Awon Ilana Ilolupo Eda Abemi 5mins. 4secs.
ati Agbegbe won to gbelege.
Oju ojo aye nyara morusi tobe ti opolopo awon eya eda abemi egan ati eweko ko le ru ilosoke itansan na

la, won o si parun. Eyi ni ikilo iroyin kan lori ayika. Ipadanu awon eya le ga to iko marun ninu ogorun ninu awon ilana ilolupo awon orisirisi eda abemi ni awon agbegbe to gbelege gegebi iha ariwa Canada, Oke
perese Tibet ati ni iha ila-oorun gusu orile-ede Australia, gegebi iroyin ti Ajo Akojo Owo ni Agbaye fun
Eda Abemi Egan ati Ajo Amuludun Suzuki ti orile-ede Canada gbe jade. Iroyin na kilo wipe iko marundinlogoji ninu ogorun awon ibugbe adayeba lori ile aye ni "o le yipada ni dabiara" larin ogorun odun

to nbo.
Awon onimo ijinle sayensi gba wipe aye ti nmorusi diedie laarin ogorun odun to koja, sugbon ariyanjiyan
wa lori okunfa ati boya o je itesi olojo pipe. Awon egbegbe afenifere ayika to gbe iroyin na jade ni apero oniroyin kan ni ilu Toronto ati London so wipe o je eri siwaju fun yiye to ye lati dena itujade awon eefin 7
7 Page 8 9
Vol. 11 No. 21
October, 2000 (Yoruba)
CHANGE Radio

8
oloro orisirisi eyiti a so wipe o nfa imorusi oju ojo. Gegebi Dokita David Suzuki to je oluwadi ati afenifere ayika ni ile-eko giga Yunifasiti Toronto se so: "Ilosiwaju imorusi le ga pupo ju ti bi egberun metala odun
seyin nigbati awon ekun eleyin-ganganran ati awon eranko-bi-oke onirun-aguntan-lara si nrin kiri lori ile aye. A o kan le joko ki a si gba ipadanu nla yi mora."

Iroyin na jewo wipe awon eranko ati eweko to le mu ara won ba oju ojo dogba yio le gbile sii pelu afefe ile to moorusi, sugbon o so wipe opo ninu won lo je awon eya "elegbin" bi ajara Kudzu ati "honeysuckle'
ti orile-ede Japan. Awon asoju lati ogosan orile-ede ni yio pade ni ilu Lyons, orile-ede Faranse ni osu to nbo lati wo bawo ni won se le mu Ilana Agbese Kyoto to je Adehun Kariaye lati dena itujade awon eefin
oloro sise. Adehun Kariaye ti odun 1997 na ni yio tun je oro agbeso ninu oro awon minisita ni Kariaye ni ilu Hague ni osu kokanla.
Reuters

Ajo UNEP dawole ise agbese olopolopo milionu owo dola 8mins. 2secs.
Amerika lori awon Oro Kemikali
Lati le mo daradara nipa awon ewu si ayika ati ilera to wa ninu igbejade awon kemikali oloro nigbagbogbo

ati awon ona lati g ba koju won, Eka Ajo UNEP to wa fun Kemikali yio se ise agbese oni-milionu marun owo dola Amerika lati se ayewo awon oludoti yi ni gbogbo ekun aye. Eyi ni ohun ti Paul Whylie to je
alakoso ise agbese na so. Awon abajade ise agbese olodun-meji na ti yio bere ni osu kesan ni yio lowosi
ipinnu lori isepatakisi ni ojo iwaju lati odo Ajo Agbaye fun Ipese Ayika (Global Environment Facility (GEF) eyiti o fi ase fun iwadi asekale ni osu keje odun yi. Gegebi ajo UNEP se so ninu akojade fun awon

oniroyin, niti ojo iwaju gbogboro, abajade ise agbese na yio wa lati dari ise ni kariaye lati dabobo ilera eda eniyan ati ayika kuro lowo itujade awon kemikali oloro nigbagbogbo.

Ise GEF je ajose nipase Ajo Agbaye fun Idagbasoke (UN Development Programme (UNEP) ati Banki Agbaye. Iwadi yi ni yio je ise-agbese GEF asekale ti o da lori iru awon Kemikali wonyi. Iwadi yi ni yio se
afikun ise ti won nse ni ajose pelu idunadura fun adehun Kariaye lori awon atosile awon oludoti olojojumo ti eefin oloro mejila to nlo lowolowo. Awon Kemikali oloro yi ni ase igbimo alase ajo UNEP ni odun 1997
dojuko fun ise. Ise agbese titun GEF yi yio se agbeyewo awon isoro to je mo ti awon oludoti olojojumo
ti eefin oloro ni ona to gbooro sii. Gegebi oro Klans Toepfer, oludari Alase Ajo UNEP, dajudaju, a nilo agbeyewo onimo ijinle sayensi lori iru ati iye awon irokeke ewu si ayika ati ilera ara ilu lati owo awon

oludoti olojojumo yi to koja awon mejila pere ti a daruko.
Awon abajade lati inu ise agbese asekale na yio ran GEF lowo lati se agbekale awon ise pataki si ojo
iwaju, lati ran awon orile-ede ati ekun lati se agbekale idahun si awon ewu lati inu awon oludoti wonyi, ati ni ti olojo-gbooro, ki o tun lowosi idamo awon afikun oludoti olojojumo ti eefin oloro fun ise ni kariaye.

Awon oludoti oloro olojojumo nse irokeke ewu to ga si awon eda eniyan ati ayika. Won ma nwa ninu ayika fun ojo pipe, a si le gbe won lo sibi to jina rere si ibiti won ti se. Won le kojopo gegebi eda abemi
tintintin nipase okun ounje ki won si wa ninu ounje ni ipele to nkonilominu fun ilera eda eniyan. Imo nlosoke wipe awon oludoti to farajo mejila ti a to sinu iwe ase UNEP lo pa ayika lara ati pe, lati ipase
ayika, ki o fi ilera eda enia sinu ewu. Ni afikun, imo nlosoke wipe awon ikolu awon oludoti oloro olojojumo yi seese ko yato si ara latari awon iyato ilana ati okunfa ayika to mu ikolu lara idasile won ati itankale ninu
ayika. Ni akoko kanna sa, ifitonileti lori ilo ati awon ikolu awon oludoti wonyi sowon ni opolopo ekun. Ise
agbese na yio se iranwo lati di awon alafo ifitonileti na to se pataki pupo. Pan African News Agency 8
8 Page 9 10
Vol. 11 No. 21
October, 2000 (Yoruba)
CHANGE Radio

9
Orile-Ede Egypt Nja Fitafita Lati Gba Ijapa re to wa labe ewu 11mins. 9secs. Iparun La
Ijapa kan fi igara fa ara re goke si igbo suru elegun kan ninu asale gbigbe, o si nrora fi enu so igi eweko na ninu itiraka lati fa orinrin die. Ile gbalasa gbigbe lori eyi ti a ti ri awon koriko gbigbe kakiri ko le fun ijapa
orile-ede Egypt na, eyiti a ni idojuko iparun ninu egan ni ounje to joju kokan. Awon eniyan nmu won, won si nfi won sowo gegebi eranko ibagbenu ile. Ijekoju ati imugbooro si ise ogbin ati irin-ajo igbafe nmu
irokeke ewu ba iwalaaye won, besini ibugbe abalaye won ninu awon asale etikun orile-ede Egypt, Ila-oorun
orile-ede Libya ati iwo-oorun Neger ni orile-ede Israel, ni a nparun. Sherif Baha el-Din to je olugbanini imoran lori imo Ijinle Sayensi fun Ajo orile-ede Egypt fun Ayika so wipe: "Iye won ti dinku

pupopupo laarin ogbon odun to koja. O ni iwadi takuntakun ti won se ni orile-ede Egypt ni odun 1994 kuna lati ri ijapa egan kokan rara.

Ijapa orile-ede Egypt na, ti oruko imo ijinle sayensi re nje Testudo Kleinmanni ni o je okan ninu awon ijapa to kere ju laye to si tun wa labe ewu iparun to ga ju laye. Eyi to tobi ju ninu re ko gun ju iwon sentimita
metala odin die (eyi din die ni idaji ese bata kan). Awon abo ma ntobi ju ako lo. A ma nri won ninu awon ibugbe to je oniyanrin tabi apata, ara re si je awon kofi ti ko di pupo, eyi si ba awon ile ibugbe re mu. Ni
odun 1996, Ajo Isokan ni Kariaye fun Itoju Iseda Aye (International Union for the Conservation of Nature
(IUCN) fi ijapa orile-ede na sori akosile awon eranko to wa labe ewu iparun. Ajo Agbaye fun Adehun lori Owo Kariaye ninu awon Eya to wa labe ewu iparun (Convention on International Trade in Endan-gered

Species of Wild Fauna and Flora (CITIES) gbesele isowo ni kariaye ninu awon eya na ayafi to ba je fun oran imo ijinle sayensi. Ofin orile-ede Egypt de tita, rira ati gbigbekiri awon eya na laigba ase,
sugbon igbero ofin na soro.
Ni osu kini odun 1997, awon olopa lo ko awon onisowo ti ko bofin mu to nta ogogorun awon ijapa na ninu oja eranko ibanigbenule ti Tunsi ni aringbungbun Cairo eyi ti won ko lati orile-ede Libya. Leyin eyi ni awon
alase wa ba Baha el-Din to nsise ni eka itoju Ajo fun oran Ayika pelu awon apo to kun fun ijapa, opolopo ninu awon to ti di alaare leyin ti won ti gbe won rinrinajo fun opolopo ose laisi omi tabi ounje. Won bi i
boya o le gba won ko si lo won gegebi ipilese fun eto itoju, o si gba. Eyi lo je ibere Ajo Itoju Ijapa ni orile-ede Egypt (Tortoise Care Egypt) to je egbe awon ajo kariaye ati ti agbegbe pelu awon eniyan kokan to
parapo lati se iranlowo lati toju ijapa orile-ede Egypt. Pelu igbeowosile lati odo ijoba orile-ede Holland, won se itoju awon ijapa na pelu iranlowo Egbe Afenifere Ogba Eranko ti ilu London, sugbon isoro si wa
lati ri ibiti o dara lati fi jowo won sile ninu egan.
Baha el-Din so wipe: "A fi awon ijapa mewa ti a so ero redio mo lara sori erekusu kan ni agbegbe idabobo na gebebi ibere eto imupada won, a si topinpin ihuwasi won. Ni akoko kanna, a bere eto ibisi ninu igbekun
fun awon ijapa na. Ninu odunrun eyin ti won ye, igba pa, eyi si so di iru ise agbese be to yorisi rere julo fun awon eya na. Ogba meji miran ti okokan won le gba adota ijapa ni a tun ti gbekale leyin eyi lara eyiti a ti
ri okan to wa ninu oko-ogbin ounje aladani ti Wadi ni oju ona laarin asale lati ilu Cairo lo si Alexandria ati oko-ogbin Sekem, to nse idako ogbin lailo ajile onikemikali ati idagbasoke agbegbe.

Fun ise agbese na lati le ma ri owo to to lati fi gbo bukata ara re, egbe na mu imoran kan wa fun ise-owo awon olugbe asale ti a npeni bedouin ninu eyiti awon obirin bedouin yio ma se awon nkan bi apo owo
keekeeke, apo ikeru ati apo irori to ni aworan ijapa lara won fun tita ki won si lo apakan owo na se iranwo fun awon ijapa na: Eyi ru itara soke laarin awon bedouin na lati se iranlowo lati toju ibugbe adayeba awon
ijapa na, o si mu won mo nipa ewu to wa ni agbegbe won. Won tun ri owo to to lati fi ma toju awon ijapa na. Ajo Itoju so lori ifitonileti ori Ilana Internet won wipe: "Awon ibugbe to se pataki fun awon eya ni a 9
9 Page 10 11
Vol. 11 No. 21
October, 2000 (Yoruba)
CHANGE Radio

10 .
gbodo so di agbegbe idabobo. Awon agbegbe idabobo nikan lo je awon agbegbe adayeba to wa ni orile-ede Egypt nibiti awon eranko na le gbe laisi ewu ati idaamu lati odo eda eniyan"
CNN. com

Awon Oko-Owo Keekeeke Gegebi Ero Fun Idagbasoke 11mins. 2secs. Ni Orile-Ede Naijiria
Fun eniti o ba kan sakiyesi ayika oko-owo ni kariaye, o rorun lati ro wipe eyi ti o poju ninu itaja ati ere lo nwa lati odo awon ajo oloko-owo nlanla. Sugbon, odikeji eyi ni o je otito. Awon oko-owo keekeee, ki
ise awon ajo oloko owo nlanla, ni egungun eyin tooto fun oro-aje ki-oro-aje. Ti a ba mu orile-ede
Amerika gegbebi apeere, awon oko-owo keekeekee lo nse idaji gbogbo nkan ti ko lowo ijoba ninu jade, awon ni won ni iko mejileladota ninu ogorun oja tita, awon na ni won si ngba eyi to ju idaji lo sise ninu

gbogbo osise ti ko sise fun ijoba. Iwadi kakiri aye lori ipa ti awon oko-owo keekeeke ati awon to tobi diedie nko fihan wipe won ma ngbe ilopo meji ohun tuntun jade lori osise kokan ju ti awon ajo oloko-owo
nlanla. Ni afikun, awon iwadi ti won se ni orile-ede Amerika fihan wipe awon oko-owo keekeeke lo ko
ipa to le lati yo orile-ede na kuro ninu idojudele oro-aje to waye laarin 1980 ati 1990. Gegebi Alakoso Oko-owo keekeeke to je ajo ti ijoba Amerika nse inawo re lati se atileyin awon oko-owo keekeeke se

so, laarin 1980 ati 1990, awon ajo oloko-owo ti iye osise won din ni ogun lo pese bilionu (milionu lona egberun) merin o le die awon ise titun nigbati awon ajo oloko-owo nlanla padanu edegbeta milionu ise
laarin akoko kanna.
Bawo ni awon oko-owo keekeeke se ni ipa to po toyen lori oro-aje Amerika? Igberu won ni o waye lati inu awon akitiyan atileyin lati owo awon ajo ti ko lowo ijoba ninu jakejado orile-ede na, atileyin lati odo
awon ayanilowo ati awon ogbon imulo ati ilana ise ti Eka Ijoba Amerika fun Akoso fun oko-owo keekeeke gbekale.

Ni orile-ede Naijiria, opolopo awon oko-owo keekeeke lo nsise ni eka oro-aje ti ko ni akosile eyi to nda iye toto ogun bilionu owo dola Amerika sinu gbogbo owo to nwole labele: O seni laanu wipe awon oko-owo
keekeeke yi ko ti ni iru igberu ati aseyori ti awon oko-owo keekeeke orile-ede Amerika. Ohun to fa eyi ni wipe awon oko-owo yi ko sise ninu ayika to ni atileyin. Ifojusi ati atileyin to kere pupo ni won nri lati
odo awon alase. Awon oloko-owo keekeeke ko ni anfani pupo lati yawo lodo awon ile ifowopamosi, won si ni idiwo pupo lori isakoso ati imo ero nitoripe won ko lowo to lati san fun idanileko. Siwaju sii,
won ko ni anfani pupo fun ifowosowopo ati atileyin, eyi si mu ki won ma sise ni ipele ti ko to iye agbara won.

Ni afikun, ni afiwe awon oko-owo nlanla ni awujo, awon akitiyan won lo nni idena pupo latari ipo buruku ti awon nkan amayederun wa ni awujo.
Pelu ipadabo ijoba tiwantiwa, orile-ede Naijiria ti beresi ni iriri iyaradide awon igbese lati odo awon ajo ijoba ati ti aladani lati ran awon oko-owo keekeeke ni orile-ede na lowo. Apeere itesi yi kan ni ti ajo
Amuludun FATE, okan ninu awon ajo titun ti ko lowo ijoba ninu ni orile-ede Naijiria. Ajo na lo ti fokansi ati se idasile oro nipa sise igbelaruge idagbasoke oko-owo ati idoko-owo laarin awon odo orile-ede
Naijiria. Ero okan re ni lati fun awon omo orile-ede Naijiria ni agbara pelu awon ikosemose, ohun elo, ifowosowopo ati isuna owo lati da awon oko-owo keekeeke to kesejari sile. Iran re ni lati se atileyin fun
idasile egberun oko-owo titun ni orile-ede Naijiria nigbati yio ba fi di odun 2005 ati egberun marun oko-owo
titun nigbati yio ba fi di odun 2015. Lati se eleyi doju aami, ajo FATE pa idanileko lori idoko-owo po 10
10 Page 11 12
Vol. 11 No. 21
October, 2000 (Yoruba)
CHANGE Radio

11
mo itoni ati atileyin eyawo fun awon omo orile-ede Naijiria. Paapa, igbese titun yi ki ise wipe yio ran awon oko-owo keekeeke lowo lati sa se yori nikan sugbon yio tun wa gegebi ohun ija lati koju awon isoro osi,
airisese ati awon ibaje awujo miran. Pelu idide awon ajo ti ko lowo ijoba ninu bi ajo Amuludun FATE,
atileyin ilana imulo lati odo awon ijoba ibile, ti ipinle ati ti apapo, ati atileyin lati iha awon aladani, awon oko-owo keekeeke yio gbaradi lati sa ipa to yen won lati ru igberu ati idagbasoke soke ni orile-ede na.

Lati mo si nipa idoko-owo lapapo ati Ajo Amuludun FATE ni pataki, o le be won wo ni ile-ise won ni Ile
Omi, Ajo Olomi fun Ipinle Eko, Opopona Ijora, Ijora, Eko, Naijiria. The Fate Foundation, Lagos.

Mimu awon Ile-ise Isenkanjade se iranwo lati yera fun Idoti 9mins. 7secs.
Ajo Agbaye fun Idagbasoke Ayika (The United Nations Environment Programme (UNEP) ti nlo ota re kan tele -iyen awon ile-ise Isenkanjade lati koju idoti. Iyeraeniwo, isenkanjade lona to mo je ohun amuse

oloju-meji ti yio mu owo wole sinu apo awon oko-owo nigbati yio tun fun won ni ere lori ayika lekanna. Eyi je ayipada to ga lati bi nkan se wa tele nibiti awon ihuwasi ile-ise to ba ayika mu ti nje wonu ere.
Laiseaniani, Ajo Agbaye lo ngbe aba kale ninu igbeyawo yi, eyi to ntanmo lati ro awon ile-ise lati faramo
awon ona isenkanjade to mo, ni iyipada to le si ona ipase ati idari ninu eyiti Ajo Agbaye ti nba awon ijoba nikan se. Ajosepo titun yi ngbero lati gbe ifowosowopo dide fun ipo ninu eyiti gbogbo eniyan yio jere:

alekun ere nipase ona isenkanjade to munadoko sugbon to ba ayika mu ati awon ere lori ayika lati ipase idinku ninu idoti.

Ipade kini ti ile Afirika lori nsenkanjade lona mimo (cleaner production (CP) ni o waye ni olu ile-ise ajo UNEP ni ilu Gigiri, orile-ede Kenya lati ojo kesan si ikokanla o fa awon afenifere ayika, awon oga ile-ise
isenkanjade, awon oluwadi, awon asoju lati awon ajo ti ko lowo ijoba ninu ati awon alase lati ogun orile-ede papo. Awon igbese lori ayika ni a gbodo sopo, ki a si mu wonu awon ere idagbasoke ti won o ba je
itewogba. Lati se asopo to se pataki yi ni ise awon ibudo fun ona isenkanjade mimo (cleaner production centres (CPC) -lati mu awon to nse nkan jade gbagbo ninu awon anfani olojogbooro to wa ninu idoko-owo
ninu CP.
Ibudo fun onaisenkanjade mimo ti orile-ede Kenya (The Kenya Cleaner Production Centre (KCPC) je
okan ninu awon CPC mejilelogun to wa jakejado aye eyiti Ajo Agbaye fun Idagbasoke Ise Isenkanjade (United Nations Industrial Development Organisation (UNIDO) nse alatileyin won. Ile-ise orile-ede Kenya

fun Iwadi ati Idagbasoke Ise Isenkanjade (Kenya Industrial Research and Development Institute) lo gba KCPC ni alejo: O bere ise ni osu keje odun yi, won o si filole pelu ayeye ni osu kewa odun. Kenya lo je
orile-ede ogoji to fowosi Ikede Kariaye lori Isenkanjade mimo ni ibere idanileko oni-iforoweoro na ni ojo
kesan osu keje. Gegebi Jane Nyakango to je Oludari KCPC se so, "CP je ipo anfani fun ise isenkanjade ati ayika. Titi di isisiyi, a ti sise pelu awon ile-ise bi ogorun, gbogbo won lo si ti ni iriri ere ti iwontunwonsi

re je iko marunlelogota ninu ogorun leyin ti won ti tele awon ilana CP, ti opo re je ona fun isakoso egbin to munadoko." Sugbon, kini awon inawo to ro mo yiyipada si CP?

Mrs. Nkayango dahun: "Nigbamiran ko si inawo kokan rara. O le je ohun to kere bi dide ohun elo idiwon, didi alafo, didin itudanu ku tabi atunlo awon aloku lati se nkan jade lona to mu iwuri wa. Awon
onile ise to nse nkan jade yio ni iyalenu ti isiro ba fihan iye ti won npadanu nitori won ko tele ilana CP."
O seese ki ere oko-owo to ga je anfani ti yio fa oko-owo isenkanjade sinu isenkanjade mimo, sugbon eleyi
na si le je idalagara re nipa mimu gbooro de odo opo awon oloko-owo sii. Die ninu awon ajo oloko-owo to ti ri anfani ninu titele awon ilana CP ko fe ki won polongo awon ilana na pupoju. Ajopin imo pelu awon

elegbe eni ninu oko-owo isenkanjade ni a ri gegebi "sisun pelu ota eni" nigbati won si ka CP gegebi afikun ohun-elo abele lati fi se alekun ere, ki isi se fun ire gbogbo ara ilu. 11
11 Page 12 13
Vol. 11 No. 21
October, 2000 (Yoruba)
CHANGE Radio

12
CP nse idinku tabi ko dena idoti patapata lati orisun nipa didena re ko to sele. Ilana idena lo je dipo atunse eyi je iyato si amukuro idoti, ni ipekun opa, eyiti o tun ma nna ni lowo pupo.
The Nation

Isiro.....
Eelo ni ilera pipe nna eniyan ni ile Afirika? 2mins. Iwadi titun kan ti Ajo Agbaye lori inawo ni awujo fihan wipe ni odun 1999 orile-ede meta pere ni ile Afirika
lo nya eyi to ju iko ogun ninu ogorun isuna won soto fun ilo lori itoju ilera, eko ati jije ounpe to peye, awon aseyege ti Ipade lori Awujo filele ni ilu Copenhagen ni odun 1995.

Iwadi na, eyiti ajo UNICEF ati Ajo Agbaye fun Eto Idagbasoke jijo se, fihan wipe orile-ede Namibia nna bi iko ogbon ninu ogorun owo isuna re lori awon ise awujo, orile-ede Mali, iko metalelogun ninu ogorun ati
Kenya, iko ogun ninu ogorun. Awon yoku ninu awon otosi orile-ede Afirika lara eyiti a ti ri Cameroon (iko mejo ninu ogorun), Cote d'Ivoire (iko mesan ninu ogorun), Tanzania (idamewa), ati Benin (iko mejidinlogun
ninu ogorun) nna eyiti o din ni iko ogun ninu ogorun. Pan African News Agency

Sisiro iye adanu ti omiyaleyaona muwa ni orile-ede Mozambique 4mins. Iroyin enu ojo meta yi lati odo Ajo Agbaye fun Eto Ounje (UN's World Food Programme (WFP) ni orile-ede
Mozambique ya aworan to sokundudu lori iparun ti omiyaleyaona fa ni iha ariwa orile-ede na. Ni Gaza, agbegbe ti o ni ikolu julo, iroyin na so wipe awon orinlenirinwo eniyan lo ku nigbati awon egberun
lona adotalenigba ati meji o le medogbon ni ko ni ile mo lara awon egberun lona egbeta ati merin o le igba eniyan ti omi ya kun ile won. Gegebi iroyin na ti so, ise ilana ifiomi rin ile-ogbin to wa ni ilu Chokwe ni o ti
ri nigbati won padanu egberun lona igba sare hektari ile. Ajo INGC so wipe afara mesan ni ko se lo mo nigbati egbejo o le meta ibuso kilomita oju ona oko ni o baje.

Iroyin so wipe "Bi orisun omi igberiko bi igba o le merinleladota ati ogbon koto omi fun awon eran-osin ni o baje, nigbati edegberin o le mejilelogoji yara itaja ati ile itura tabi ile itaounje mejidinlogota lo parun tabi
baje." Awon ajo ilera ati eko na ni ifaragba, gegebi ajo INGC ti so, pelu bi ile eko igba o le marundinladota se baje ti eyi si kan egberun merinleladorin o le egberin ati ogbon akeko ati egberun kan ati mokanlelogbon
awon oluko. Ile-eko meji to ni awon ibugbe nibiti awon edegberun o le mejidinlogota akeko wa ni o
parun, bena ni ibudo mokomooka merindin-ladota to nko awon egberun meji o le egberin o din merinla akeko ni o baje. Iroyin na fikun wipe awon ajo ilera, ninu eyiti a ti ri ile-iwosan kan, ibudo ilera mejo ati

ibudo igboogun mokanla ni o parun.
Nigbati o se atunso oro Minisita orile-ede Mozambique fun Ise Ode ati Ile Gbigbe, Roberto White, iroyin
na so wipe omiyale-yaona na mu adanu milionu marundinladota owo dola Amerika latari ipadanu ifieru ranse si okeere ati owo to ju igba o le milionu marundinladota owo dola Amerika latari adanu ise, nigbati

ibaje si awon ohun ini ni ti ijoba ati di aladani ju igba o le adorin owo dola Amerika lo. Integrated Regional Information Network

Awon Oludije Olympic lati Ile Afrika se atileyin Ipolongo lati 3mins. 9secs. koju Arun Ako Iba
Awon asiwaju egbe oludije olympic fun orile-ede Tanzania, Restituta Joseph ati Fokasi Wilbroad Fullah ni awon oludije akoko to fowo si iwe fun ipolongo kan jakejado ile Afirika lati ru imo soke lori ako iba,
gegebi Ajo Agbaye fun oro Ilera se so. Awon oludije Olympic lati ile Afrika ni won nse iwuri fun lati 12
12 Page 13 14
Vol. 11 No. 21
October, 2000 (Yoruba)
CHANGE Radio

13
seatileyin fun egbe Ka Ako Iba Pada Seyin (Roll Back Malaria (RBM) ninu ipolongo kariaye kan ti yio se
afihan bawo ni o se dara julo lati se itoju ati lati dena arun na to npa ju milionu kan eniyan lo lododun, eyiti pupo won je ni ile Afrika

Ni afikun si awon oludije orile-ede Tanzania, o fere je wipe gbogbo egbe awon oludije ti orile-ede Uganda lo ti gba lati fowo si iwe fun RBM ki won si fi ohun won sinu igbese na. Awon elere idaraya asoju RBM
yi wa ninu ipele to kehin ninu igbeko won fun ere Olympic ti yio waye ni ilu Sydney lati ojo keedogun osu kesan. Gbogbo awon igbimo Olympic jakejado ile Afrika ni won ti kan si lati kopa ninu ipolongo na.

Adele alakoso ise fun RBM Awash Teklehaimanot so wipe ere Olympic fun ni ni anfani fun okan ninu awon ero iworan to poju jakejado aye laarin odun yi. Awon akoni orile-ede lokunrin ati lobirin ni yio dide,
a ko si gbodo ko iyan agbara ti oro won ni kere. Oro isiri lati enu awon gbajumo elere idaraya ni agbara lati mu ogogorun egbegberun gbagbo ninu anfani to wa ninu apo efon ati gbigba itoju lesekese fun aisan
ako iba. Pan African News Agency

Igbogunti Arun Kogboogun Eedi Gba Igbelaruge Ni Orile-Ede Naijiria 2mins. Igbogunti idaloro kokoro ati arun HIV ati Eedi ti gba igbelaruge si, bi ajo ti ko lowo ijoba ninu kan ni orile-ede
Geesi, Ise ati Iranlowo Ojo Isegun (Action/ AID Tuesday) se ikede iranlowo oni milionu meje owo poun orile-ede Naijiria. Owo na ni a o fa jade lati inu apoopo milionu mokandinlogbon owo poun ti ajo na
ti yasoto fun ile Afrika.
Nigbati o nkede iranlowo na ni ilu Abuja, oludari ajo na fun orile-ede Naijiria, Ogbeni Charles Abani so wipe ajo ACTION/ AID yan orile-ede Naijiria fun awon ise asewo re latari iye olugbe orile-ede na ati
ogooro awon isoro re ti a ko kobiara si. O ni: "Pelu bi o se je pe okan ninu marun omo ile Afrika lo je omo orile-ede Naijiria, ko si aniani wipe awon inilo wa laarin orile-ede Naijiria ti a gbodo dojuko".
Post Express

Ojo ati Akoko....
Orile-Ede Canada Yio Gba Alejo Apero Lori Isenkanjade Lona to mo si i. 1min. Ipade Ile Afrika kinni lori Isenkanjade to mo si i, eyiti o waye ni orile-ede Kenya ni osu kejo, ni o je eka
Oro Kokanlelogun (Ori Kerin) lati Ipade Ile Aye to waye ni ilu Rio de Janeiro ni odun 1992, ati apero
awon Minisita ile Afrika lori ayika (AMCEN) to waye ni ilu Abuja ninu osu kerin odun 2000. O je asesiwaju Apero Alagbara kefa ti ajo UNEP lori Isenkanjade to mo si i eyiti yio waye ni ilu Montreal orile-ede

Canada ni osu kewa odun 2000. Ifojusi re ni lati yi awon ilana iraja ati isenkanjade pada.

Eto Awon Omode
Ologbon Ehoro ni Idojukoju Pelu Erin at Erinmi 9mins. 5secs.
Ni igbakan ri, Erin to nje Lalap ati Erinmi to nje Nneg ngbe nitosi Ehoro to nje Izum. Ori ehoro ma nwu nitori agbara ati titobi Lalap, Erin to ngbe ni ori ile, to si je oba fun gbogbo awon eranko nitori agbara re.

Nneg, Erinmi ngbe ninu omi, on na si je eranko to tobi to si lagbara.
Izum, Ehoro ma nronu wipe ewo lo lagbara ju ninu awon mejeeji. O pinnu lati mo otito ibe. O lo sodo
Lalap, Erin, o si so fun wipe eranko lasanlasan ti o wulo ni pelu ifonnu wipe 'Ti emi ati iwo ba dije fami-n- 13
13 Page 14
Vol. 11 No. 21
October, 2000 (Yoruba)
CHANGE Radio

14
fae, ngo bori re". Lalap, Erin bu serin, o ni "ko tile se ro fun mi wipe eranko tintin bi iwo, Izum ntami laya si idije fami-n-fae".
Izum tenumo wipe on le se be, nigbeyingbeyin, Lalap, Erin gba lati fun ni anfani. Izum mu okun gigun kan
jade o si fi opin e kan fun Lalap, Erin lati di mu. O so fun wipe on o kigbe si ti o ba ti ya lati bere fifa. Izum, Ehoro rin lo pelu opin keji okun na lowo re. O rin lo si odo nibiti Nneg, Erinmi ngbe. O ta Erinmi laya si

idije fami-n-fae bo se se fun Erin. Erinmi wo, o ni:
"Iru egbin wo leleyi! Iru eranko kekere bi iwo Izum, lati tamilaya si idije".
Izum fi igboya so fun wipe on o bori. Leyin igba die, Nneg, Erinmi gba italaya na. Izum, Ehoro, fun ni opin keji okun owo e, o wa so fun wipe on yio kigbe lati so igba ti idije na yio bere. O lo si ibi to jinna die, o wa
kigbe lati bere idije na. Awon mejeji beresi fa okun nireti wipe fifa die yio mu Izum fo ninu afefe. Won fa fa fa sugbon won ko le lo. Okokan won fa pelu gbogbo agbara to ni sugbon nkankan o sele. O dabi enipe
Erin pinnu lokan e lati mo boya lotito Izum, Ehoro lo nfa on. O rora di okun na mo ara igi nla kan. O wa rara lo sona ibiti opin okun na wa. Nigbati o de itosi odo, o ri Nneg, Erinmi, to nfa opin keji okun na dipo
Izum, Ehoro. Lalap, Erin wa kigbe,
"Mo mo wipe ki ise Izum lo nfa mi. Izum ko le ni iru agbara be".
Erinmi gboju soke o si ri Lalap, Erin leba odo. O wa han si lojiji wipe a ti tan on je. On na dahun wipe on na ko gbagbo wipe Izum lo nfa on si idurosojukan ninu idije fami-n-fae. Awon eranko mejeji ba ara won
laja, won si so wipe awon yio fiya je Izum, Ehoro, fun titan to tan won je, sugbon Izum, Ehoro, salo. Tarok Folk Tales

Oro Asokagba
Se ayeye ogbon iriri ile Afrika pelu awon owe manigbagbe wonyi.
Lori Iwa Etu ki i wo bata Erin
Orile-ede Ghana
Omo ti a ba wulori a ma dagba pelu igboya Orile-ede Uganda

Lori Isokan
Isokan laarin awon maalu ni nmu ki kiniun dobale ninu ebi. Orile-ede Naijiria

Ika kansoso ko le gbe eru Orile-ede Sierra Leone
Lori Akoko Eso to ba pon ko le duro laelae sori eka igi
Orile-ede Liberia African Proverbs/ More African Proverbs 14

Page Navigation Panel

1 2 3 4 5 6 7 8 9
10 11 12 13 14

 

© 2002 Communicating for Change. All Rights Reserved
Developed by George Mbuagbaw