Document Body Page Navigation Panel
Awon asoju ile Afirika ninu Apero karun ti awon Egbeegbe Adehun lori Ipinsiyeleyele
Eweko ati Eranko to
waye laipe yi ni ilu Nairobi lati ojo keedogun si ikerindinlogun osu karun odun
yi ti tenumo bi o se ye lati dabobo eto awon agbegbe ati awon agbe kuro lowo
ijilo-laigbase nipa akitiyan alajose pelu awon ajo to
nmojuto iru awon oran bee.
Ninu akojade oloju-ewe meji won, eyiti asoju kan lati orile-ede Egypt ka jade,
Egbe Ile Afirika na tun kepe fun
ifi ipo asiwaju fun awon agbegbe ninu itesiwaju itoju ati ilo alagbero ti ipinsiyeleyele
eweko ati eranko ati ilowosi won ni kikun ninu ipinnu sise. Egbe Ile Afirika
na wa lara awon asoju bi egberun kan ati aabo to pese
sinu Apero ilu Nairobi na lori Adehun lori Ipinsiyeleyele Eweko ati Eranko
eyiti a pe ni COP 5.
Egbe na tun kepe fun igbelaruge ise-ogbin alagbero ti awon agbegbe to nlo awon
ona ibile ati ti ode oni lati se
alekun ilo ipinsiyeleyele eweko ati eranko dapo mo ise ogbin ati lati lo awon
agbara imusise ti ilolupo eda abemi ni agbegbe won lati se alekun si ati lati
dabobo igbejade. Egbe na tun se iwuri fun igbekale awon ofin orile-ede
to wa ni ibamu pelu Ofin Awokose ti ile Afirika fun Idabobo Eto Awon Agbegbe
Ibile, Agbe ati Awon Olohun-osin ati fun isekokari ona si Awon Oro Eweko ati
Eranko (ti Ajo OAU gbejade ni odun 1998).
Ninu akojade won, won woye: "Gegebi ohun to je oro ikanigbongbon, oro to je
mo gbigbe awon oro ajogunba eya eda ti ile Afirika lo sile okeere, ona sii,
ati pinpin awon anfani to jeyo ninu ilo awon ajogun eya eda ti ile
Afirika gegebi ilana Adehun lori Ipinsiyeleyele Eweko ati Eranko (Convention
Biological Diversity CBD) ni a gbodo mojuto." Egbe ile Afirika na tako idabobo
imo to je mo ti awon orisi emi labe ofin pelu siso wipe o ye
ki a teramo ati muwasaye lagbaye ipo to dara fun ipinsiyeleyele eweko ati eranko
ninu igbo, itoju ati ilo
alagbero ninu awon apero to tona. Awon asoju ile Afirika na jirebe si gbogbo
awon ajo fun idagbasoke ati igbeowosile ni itele emi Adehun ti a mo si Oro Agbeso
kokanlelogun (Agenda 21) lati se ipese atileyin imo-ise
ati owo fun awon orile-ede Afirika ati awon ise agbese to je mo ikojopo agbara
lati sise ni awon eka Adehun CBD to kannigbongbon.
All Africa News Agency
Ajo kan fun Ire ati Alafia Eranko bu enu ate lu isode
awon Eran-omi Seal ni orile-ede Namibia. 4 mins. 30 secs. Ajo Akojo Owo
ni Kariaye fun Ire ati Alafia Eranko ti fi edun-okan re han lori ikede aipe
yi lati odo ijoba orile-ede
Namibia wipe yio se imugboorosi ninu ise-okowo isekore re ninu eran-omi seal.
Igbimo awon minista ti orile-ede Namibia fowo si aba kan ti minisita fun ise
ipeja gbekale lati se alekun awon to ni iwe ase lori eran-omi
Seal lati meji si merin. Iyamboa ti so tele ni odun yi na wipe "ijoba ngbero
lati se alekun to ga pupo" ninu
ipinfunni isekore eran-omi Seal ni odun 2000, nitori alekun to nyara de si akojopo
awon eran-omi Seal ninu awon omi orile-ede Namibia nmu irokeke ewu ba ise ipeja
ti agbegbe. Akoko isode eran-omi Seal ni orile-ede
na yio bere ni ojo kini osu kejo.
Sarah Scarth to je oludari ajo na fun iha gusu Afirika so wipe ajo na ti nfojusi
idagbasoke ninu isode ododun na
fun opolopo odun, ko si ti ri eri -lona imo ijinle sayensi tabi omiran -lati
se atileyin imugboorosi isekore eran- 1
1 Page 2
Vol. II No. 19 (Yoruba) CHANGE Radio August, 2000
4
omi seal ni orile-ede Namibia. O tun fikun wipe awon ibere to le pupo wa lori
agbero fun isekore awon agbalagba eran-omi na tabi lati mo alekun won ni ododun.
Yio je ohun to lodi lati se alekun ipin lati faramo
imugboorosi oko-owo lori eran-omi seal laisi iru ifitonileti be.
O ni: "A ko si mo eri imo ijinle sayensi kokan to le se igbelese wipe isekore
eran-omi seal ni orile-ede Namibia
yio je anfani fun ise ipeja. Awon iwadi imo ijinle sayensi kakiri aye, paapa
orile-ede Canada, ti fihan wipe ipejaju lo nfa ilosile akojopo eja, ki ise pipa
lati owo awon eran-omi seal. Ti a o ba se alekun awon ipin,
ifitonileti lori agbero isode be ni a gbodo muwa fun ayewo awon elomiran"
Awon ipin isode ni orile-ede Namibia fun odun 1999 je fun oke kan ati abo awon
omode eran-omi seal ati
egberun marun awon agbalagba eran-omi na. Gegebi akosile ajojopo ti a se gbeyin
ni osu kejila odun 1997,
gbogbo akojopo awon omode eran-omi seal ni a siro si oke marun o din egberun
marun. Ko si akosile iye awon agbalagba eran omi seal.
Panafrican News Agency
Ile ise Simenti ni a ti ro lati kobiara sii si Ayika 2 mins. 30 secs.
Awon ile-ise simenti ni ile Afirika ni a ti talaya lati nawo sii ninu isakoso
ati idabobo ayika lati le dabobo awon
eniyan to ngbe agbegbe won ati ayika kuro lowo idoti to ga.
Minista orile-ede Kenya fun irin-ajo afe, isowo ati idoko-owo, Nicholas Biwott,
so wipe awon ajo oloko-owo na gbodo jawo ninu fifokansi ere jije laibikita nipa
ayika ati ilera eda eniyan. O so eyi ninu apero kan lori imo
lori awon ikolu simenti. Biwott so wipe ki awon ogunna gbogbo ile-ise simenti
ni orile-ede Kenya ko ipa asiwaju ninu imubosipo awon ayika ti won ti lo. O
ro awon oluse simenti na lati tele awokose ile-ise simenti ti
Bamburi to wa ni ilu Mombasa eyiti o gbajumo fun imubosipo ayika. Minisita na
so nigbati o nro awon ajo oloko-owo na lati se ohun otun wipe "Yio dara fun
awon ile ise simenti
lati nawo sii lori idabobo ayika. Apero na, eyiti Ajo orile-ede Kenya fun awon
Idiwon (Kenya Bureau of Standards) se kokari re, ni o se akopo awon ti oro na
kan gbongbon.
Nibayi, orile-ede Kenya nlo iwon tonnu metric simenti to ju oke medogbon milionu
lo lododun, eyi si tumo si iwon adota kilo fun enikokan lododun.
Panafrica News Agency
Orile-ede Ghana: Fifi opin si Idakejeje. 7 mins.
Iwa-ipa si awon obirin je otito, sugbon awon obirin die lo setan lati soro
nipa iriri won. Ni opolopo igba, awon
obirin ma nni opolopo idena eyiti o nmu irewesi ba won lati soro.
Nigbati won ba yan lati soro nipa iriri won paapa, won ki i iso o fun awon
ajo ijoba, sugbon won ma nyan lati royin na fun ebi, awon ore tabi awon eniyan
agbegbe.
Eyi ni awon awari iroyin titun kan lori iwa-ipa si awon obirin ati omode.
Iroyin na ti a pe akole re ni "Fi fi opin si Idakeje ati Italaya awon Aheso
lori Iwa-ipa si awon Obirin ati Omode ni orile-ede Ghana." je ise ajumose
lati owo Ibudo Ikosile fun awon Iwadi lori Eya ati Eto Eda Eniyan (Gender Studies
and Human Rights Documentation Centre (GSHDRC), Ajo Apapo Egbe Osise, Ibudo
fun Idagbasoke awon Eniyan, Ajo Iranlowo 2
© 2002 Communicating for Change. All Rights Reserved
Developed by George Mbuagbaw