Document Body Page Navigation Panel
Awon ipolowo Apo-ato ni a so wipe o se ponyonwu ju. Olugbohunsafefe
7mins. 6secs. 5
ijoba ni orile-ede Zambia mu awon ipolowo apo-ato kuro lori afefe.
Ijoba so wipe won ti se ponyonnwu ju.
AWON OBIRIN ATI AWON OMODE
Ifi-pa-ba-omode-lopo nlosoke sii ni orile-ede Zimbabwe 10mins 5secs. 6
Ifi-pa-ba-omode-lopo nlosoke sii ni orile-ede Zimbabwe, isele ti orile-ede
na ko le fenuko sibikan lori awon ohun to faa ati bawo ni won se le koju re.
ISE-OGBIN ATI AABO LORI ORAN OUNJE
Iyan tun nrokeke latari ikolu awon kokoro alajerun 5mins. 8
Bi orile-ede Tanzania se sese nyorun kuro ninu okan ninu awon owongogo
ounje re to buru ju, orile-ede na tun ti wa labe ewu iyan miran latari ikolu
awon kokoro alajerun.
Ayika
OJU-OJO
Itankale Oju-ojo to dara sii ni orile-ede Kenya ni odun 2002. 6mins. 6secs.
3
A o so orile-ede Kenya po mo itankale oju-ojo lati inu oko-inu ofurufu
ti igbalode lati se aridaju isotele to munadoko lori oju-ojo ati lati se imu
darasi imunadoko awon ilana itetekini nilo.
IDOTI
Ipinle Akwa Ibom ni orile-ede Naijiria se iwadi lori itudasile epo robi 3mins.
8secs. 4
Ijoba ipinle Akwa Ibom ni iha ila-oorun orile-ede Naijiria ti gbe igbimo
ise eleniyan-mejila kan dide lati se iwadi lori itudasile epo robi ti a so
wipe o sele ni ipinle na ni osu kokanla odun 2000.
Epo iderun fun ero agbokorin ti won ti lo tele nda isoro sile ni awon 6mins.
7secs. 7
agbegbe aarin ilu
Titipa ti won ti ajo oloko-owo British Petroleum Zambia Plc pa ti yorisi
aise idanu lona to dara fun awon epo iderun ero agbokorin ti won ti lo,
eyi si nse irokeke ewu si ayika ni orile-ede Zambia.
ITOJU
A ko awon Rakunmi lo si Oke Kenya 5mins. 4
A ti pe ipe kan fun ikokuro ogogorun awon rakunmi lati oke Kenya
lati yago fun ajalu ilolupo awon eda abemi ni agbegbe na.
Aye Ile olomi -Aye to wa fun awari 9mins. 11
Ogbon odun leyin Adehun Kariaye lori awon Ile olomi, ajo Ramsar
polongo ojo keji osu keji odun 2001 gegebi ojo ile olomi ni Agbaye.
Agbegbe iyasoto Iseda-aye ni orile-ede Seychelles gba ifojusi kariaye 5mins.
5secs. 6
Nipa jije agbegbe iya soto iseda-aye akoko ti yio farahan ninu Odun
ifojusi Ipinsiyeleyele Eda Abemi ni Kariaye, Erukusu Cousin ni orile-ede
Seychelles ti gba idanimo kariaye fun irinajo afe ati isakoso etikun.
1
1 Page 2 3
Vol. 11 No. 25 CHANGE Radio February, 2001.
2
Bi Mo se ri si
AWON OBIRIN
Imudogba Eya dara fun Ijoba Tiwantiwa 17mins. 6secs. 8
Agbejoro kan ni orile-ede Zimbabwe, Yvonne Malhunge, soro lori ojo
iwaju awon obirin ninu ijoba tiwantiwa, o si se iwuri fun ilowosi to
ga sii ninu ijoba.
Awon Eniyan wa O! Igbeowosile fun igboraeniye to dara sii. 6mins. 9
Awon obirin onkowe merin ni a ti fun ni Igbeowosile Akoki ti "Awon Eniyan
wa o ! fun igboaraeniye to dara sii."
OUNJE
Orile-ede Democratic Republic of Congo gbe awon orisi gbaguda titun jade.
3mins. 5secs. 10
Ile-ise orile-ede Democratic Republic of Congo fun iwadi lori Imo ijinle
Sayensi
ati Oro aje lori Igbejade Irugbin ti se igbejade igba orisi gbaguda ti won ti
danwo
ni Ile-ise kariaye fun Ise-ogbin ni ile-olooru to wa ni ilu Ibadan ni orile-ede
Naijiria.
Ojo ati Akoko
OHUN IMUSAGBARA
Ohun imusagbara alalotunlo, to si se gbero gbelege ninu egberun odun yi.
4mins. 5secs 10
Gegebi oludari Alase Ajo UNEP, Klaus Toepfer, se so, awon ohun imusagbara
to
je ore ayika bi agbara lati inu oorun, agbara ategun, ati agbara igbi omi
okun lo je okan ninu awon oran to kannigbongbon to nkoju eda eniyan ninu
egberun odun titun yi.
Eto Awon Omode
Ode na 17mins. 12 Jamina fe di ode sugbon nigbati o sonu sinu
igbo, o ri awon ore titun to yi
okan re ati bo se nwo aye pada.
Awon Oro Asokagba Se ayeye ayo iriri ile Afirika pelu awon
owe manigbagbe. 13 2
2 Page 3 4
3
Vol. 11 No. 25 CHANGE Radio February, 2001.
Iroyin
Ayewo tipatipa lori kokoro-arun HIV 9mins. 12secs. fun awon odomobirin
ile-eko ni orile-ede Malawi
Awuyewuye ti waye lori ipinnu ijo onigbagbo to powole eyiti o tobi julo
ni orile-ede Malawi lati ye awon odomobirin to nfe iranlowo owo lati keko ninu
ile-eko girama re fun awon obirin wo lori kokoro-arun HIV
. Ijo onigbagbo ti a mo si The Church of Central African Presbyterian (CCAP)
so wipe enikeni to ba fe gba iranlowo owo re ti yio kaju owo ile iwe, owo ile
gbigbe ati awon ohun elo fun imototo ati igbeko
gbodo jurasile fun ayewo lori kokoro-arun HIV. Awon alase ijo na tun so siwaju
wipe awon to ba yege ninu ayewo akoko ti won si gba si ile-eko na yio ma ni
ayewo na ni ododun fun odun mererin ti won o fi wa
ninu ile-eko girama na ni ekun aala Mwanza. Awon ti won ba ni kokoro-arun ni
igbakigba laarin odun
merin na ni yio padanu anfani eko ofe na. Ti won ba si fe wa ni ile-eko na,
gegebi ijo na seso, won yio ni lati san gbogbo owo igbeko won funrarawon.
Eto orile-ede fun Idari Arun Kogboogun Eedi (The National AIDS Control Programme
(NACP) ti se apejuwe isele na gegebi eyiti o "koninirira to si nse iyasoto."
Oludari ajo NACP, Owen Kalua so fun awon
onise iroyin wipe eto imulo ijoba ni wipe a ko gbodo ya enikeni soto nitori
wipe won ni kokoro-arun HIV. O ni "Eyi yio kan fi abuku kan awon ti koba yege
fun owo iderun fun akeko na". Sugbon Eni owo Daniel
Gunya, Akowe Agba fun ijo CCAP ti ekun Blantyre tenumo wipe ko si ifiyasotosi
kokan ninu ilana fun owo iderun fun awon akeko na. O ni lotito, awon ti ko ba
fee yio ni lati sanwo fun eko won sugbon awon
to ba fe yio faramo awon ilana na. Nitorina ko si oran ifiyasoto nibe rara."
Sugbon Kalua ti ajo NACP na
tenumo wipe o dabi enipe ijo na so kokoro-arun HIV po mo iwa ibaje ati isekuse.
O ni awon odomobirin to ti ni arun na nipa ifipabanilopo tabi ifunninieje yio
jiya lainidi.
Charles Gunsaru to je oludari fun igbeko ni ipele girama ati ile-eko giga
ni Ile-ise ijoba fun Eko, Imo Ijinle Sayensi ati Imo Ero so wipe ipinnu ijo
na ya ile-ise na lenu. O ni "O yawa lenu nitoripe ko si eniti o tii lo ipo
nini kokoro-arun HIV lati fi funni ni ohunkohun, biotileje ise, ni orile-ede
Malawi." Sugbon ile-ise na to je wipe ipa alabotujo nikan ni tire, kan le gba
ijo na nimoran ni. Won ko le fi agbara muu lati yi ipinnu re pada.
Eni owo Gunya so wipe o tile ya on lenu wipe iduro ijo on fa iru awuyewuye
be dipo iyin fun iduro ilowosi ninu eto orile-ede fun igbejako kokoro-arun HIV
ati Arun kogbogun Eedi. O ni awon asiwaju ijo so wipe
eyi yio je ona kan lati fi mu awon odomobinrin wa ni mimo nipa ibalopo ki o
si dena won lati ko arun apani na." O tenumo wipe, "Ayewo eje olodoodun na yio
le awon omo wa sa kuro ninu isekuse yio si fun awon
omo wa ni idi kan pato lati yera fun iwakiwa to le yori si kiko arun apani na."
Orile-ede Malawi lo ni okan ninu awon iye ikolu Kokoro-arun HIV ati Arun kogboogun
Eedi to ga julo ni
aye. Gegebi awon isiro to sese jade lati odo ajo Eto Orile-Ede fun Idari Arun
Kogboogun Eedi, o to iko merinla ninu ogorun awon omo orile-ede Malawi bi milionu
mewa to ni kokoro-arun to le fa Arun kogboogun
Eedi. Africa Online
Itankale Oju-ojo to dara sii ni orile-ede Kenya ni odun 2002. 6mins. 6secs.
A o so orile-ede Kenya po mo itankale oju-ojo lati inu oko-inu ofurufu ti
igbalode ni odun to nbo. Itankale
titun na, ti yio sise fun awon orile-ede to sese ndagbagba soke marundinlaadota,
ni a fi lole ni Erekusu Guyana to wa ni ilokuro ni etikun ila Iwo oorun ile
Afirika. A lero wipe itankale na yio se aridaju imunadoko
awon ilana itetekinimilo. Ogbeni Ajub Shaka to je adele Igbakeji oludari Eto
Iwoju-ojo so wipe, "A o le
fun awon onibara wa ni ifitonileti to peye ti a si se ni ibamu pelu inilo won."
Nigbati o nba iwe iroyin The 3
3 Page 4 5
Vol. 11 No. 25 CHANGE Radio February, 2001.
4
Nation soro ninu yaara ise re, Ogbeni Shaka so wipe imo ero titun lori isotele
yio pese imo lori oju ojo ni iyara ilopo meji ti ilana isisinyi, eyi yio si
jeki a le ma topase awon iyipada oju-ojo. Itankale oko inu ofurufu
titun na, eyiti yio sise fun Europe ati Afirika, yio ma gbe imo jade ni iseju
meedogun meedogun dipo idaji
wakati bi o se wa nisisiyi.
Eka Ile-ise Orile-ede Kenya fun Iwoju-ojo ni yio se akoso akoso akoko imurasile
fun ise agbese na awon orile-ede Afirika, Caribbean ati Pacific to nkopa ninu
re. Gegebi Ogbeni Shaka se so, Ajo Ile Europe ti
fowosi igbekale owo lati jeki awon orile-ede na mu awon ibudo oju-ojo won ba
ode oni mu. Orile-ede
Kenya yio se igbekale ibudo kan fun gbigba imo lati inu oko inu ofurufu ki o
si ko irin-ise titun si awon ibudo akojo-imo re kakiri orile-ede na lati le
mu won wa ni ibamu pelu imo-ero titun na. Ise agbese na yio
da awon onimo ijinle ati onise-ero nipa oju-ojo leko gegebi ara eto kan to
ti nlo lowo fun odun meta seyin. Ibudo Itopinpin Ogbele ti orile-ede Kenya,
eyiti nsise fun ekun IGAD, ni yio ni anfani bakanna lati ara
alekun agbara lori imo-ise ati imo-ero. Gegebi Egbe ile Europe fun awon Oko
inu Ofurufu fun Iwoju-ojo
se so, itankale titun na ni a lero wipe yio fun ni ni ifitonileti ilopo ogun
ju eyi ti oko inu ofurufu Meteosat nfunni nisisiyi. Yio ni ibudo imo mejila
dipo meta ti Meteosat ni, eyiti yio si ma gbe aworan to ja gaara sinu
afefe lori awon isele oju-ojo ni awon agbegbe kokan . Ajo fun oju-ojo ni ile
Europe na so wipe awon imo ti o ba gbejade ni a le lo lati fi mu idari fun awon
Oko Ofurufu lagbara sii, ati idabobo fun awon oko irinna
oju omi.
Itankale oko inu ofurufu titun na, eyiti a lero wipe yio ti ma se gbogbo ise
to ye ko se ni odun 2005, ni yio ma se ilowosi si itopinpin awon isele ayika
bi isodiasale, iyipada afefe ile ati awon ina.
The Nation
Ipinle Akwa Ibom ni orile-ede Naijiria se iwadi lori itudasile epo robi.
3mins. 8secs. Ijoba ipinle Akwa Ibom ni ila-oorun orile-ede Naijiria ti
gbe igbimo-ise eleni-mejila kan, ti ojogbon Etie
Akpan onimo ijinle sayensi lori ilana ile ni abe omi, je olori won dide lati
se iwadi lori itudasile epo robi ti a so wipe o sele ninu osu kankanla odun
2000 ni ipinle na .Alakoso ile-ise ijoba ipinle na fun Ayika, Obong
Isidore Akpan-Ebe, nigbati o nba awon oniroyin soro, so wipe "iroyin to nde
ile-ise yi toka si wipe nitoto itudasile to po gididgidi sele ni awon etikun
ipinle na."
O ni won ti fun igbimo na ni ose mefa lati fi gbe iroyin re fun ijoba. O tun
so wipe "Ni afikun, igbimo tun
nsise lori awon aworan lati inu oko ninu ofurufu ti a gba lati awon ibudo itopinpin
eyiti a gbekale ni awon ibiti o se pataki lati le ma fi topinpin ayika ipinle
Akwa Ibom to gbelege".
Awon alase-ajo Exxon ati Mobil ni osu kokanla odun to koja ti so, leyin ti
won mu awon oniroyin lo ninu irin-ajo kan lori okun ati etikun, wipe ko si itudasile
kokan ni ipnle na. Alakoso na to daruko ajo Exxon ati
Mobil, Elf ati Shell gegebi awon ogunna gbongbo ajo to nsise epo robi ni
awon etikun ipinle Akwa Ibom, so wipe Igbimo-ise lori awon itudasile na yio
so laipe eni to ni awon ibudo-ise nibiti awon itudasile na ti nsele. Obong Akpa-Ebe
fi da awon ara ilu loju wipe bi igbimo Ojo gbon Etie
Ben Akpan ba ti pari ise re, gbogbo abajade re ni a o gbe jade fun awon ara
ilu. all Africa. com
A ko awon Rakunmi lo si Oke Kenya 5 min.
Alakoso Egbe Afenifere Ibori Igbo (The Greenbelt Movement). Ojogbon Wangari
Maathi ti kepe fun ikokuro awon ogororun rakunmi kuro ni Igbo Oke Kenya. Ojogbon
Maathai ti kowe si olori awon osise
lori awon darandaran. O ni awon eranko na yio da ilana ilolupo awon eda abemi
agbegbe na to se pataki pupo je. O ni ilana ilolupo agbegbe yi to je ile eti
odo ni a gbodo dabobo ni onakona. O ni, "Ikolo awon
eranko na sinu igbo na lo nso kikankikan wipe isodiasale ni orile ede Kenya
ti de ibi to derubani. Eran
asale ni awon rakunmi". 4
4 Page 5 6
5
Vol. 11 No. 25 CHANGE Radio February, 2001.
O ni iyan ati ebi yio di isele ojojumo ni orile-ede Kenyna ti a ko ba dabobo
awon igbo, nitoripe awon lo nfa ojo to nse atileyin ise ogbin, pupopupo. O nso
ero re lori iroyin wipe awon darandara ti nda ogogorun
rakunmi si iha Gathiuru ninu igbo oke Kenya lati wa papa ijeko. Ifilodi si be
tun wa lati odo asoju agbegbe
Kieni ninu ile igbimo asofin, Dokita Chris Murunguru ni agbegbe eniti Gathiuru
wa. Sugbon kiakia ni ijoba fesi awon darandaran na. Oga awon olopa ni Nyeri,
Elijah Shamalla se ibewo si agbegbe na lati se agbeyewo
ipo ti idaabobo wa leyin awon iroyin to so wipe o nseese ki ija sele laarin
awon darandaran ati awon agbe to ngbe ni agbegbe na.
Ojogbon Maathai fesi si oro Igbakeji oga olopa Agbegbe Laikipia, Omar Sallat
to so wipe awon darandaran na kan nda eran na kiri ninu ipaya ni. O ni "O ye
ko mo wipe awon miran wa to ni ipaya lati dabobo awon
iparun awon igbo na. Ojo ati Irugbin ti kuna latari iparun awon igbo, eyi lo
si fa a ti ebi fi npa awon omo orile-ede Kenya."
The Nation
Awon Ipolowo Apo-ato ni a so wipe o se ponyonwu ju 7mins. 6secs. Ipolongo
lati koju kokoro-arun HIV ati Arun Kegboogun Eedi ni ifaseyin nigbati olugbohunsafefe
Ijoba ni
orile-ede Zambia mu awon ipolowo apo-ato ti ijoba so wipe o se ponyonwu ju
koro lori afefe. Awon asiwaju ijo onigbagbo lati inu Igbimo Kristeni ni orile-ede
Zambia to je egbe oluparowa to lagbara lara
eyiti awon ijo alagbara bi melo kan wa, ti gbe ohun awuyewuye soke wipe awon
nkan ipolongo ni ikoju Arun Kogbogun Eedi ti Ajo orile-lede Zambia fun igbohunsafefe
(Zambia National Broadcasting
Corporation) gbe sori afefe laarin awon osu bi melo kan seyin ni ko tona to
si nse iwuri fun isekuse.
O dabi wipe ijoba funrarare ko fenuko lori oro naa. Minisita fun ilera, Enoch
Kavindele so ni ose to koja pe o ye ki awon asiwaju esin Kristeni " dojuko otito
bi ikan se wa" lori bi ajakalearun Eedi na ti gbile to,
sugbon minisita fun Eko, Godfrey Miyanda gbe leyin awon eniyan Olorun na.
Aare Frederick Chiluba,
eniti o kede Zambia gegebi Orile-ede Kristeni ni odun 1991, so wipe on ro wipe
ilo apo-ato je aami ailekoraeninijanu lori ibalopo. Ipinnu ajo ZNBC lati fagile
awon ipolowo na -ti won se ibowo fun ero
awon ara ilu -ni awon olupolongo ni idojukoArun kogboogun Eedi ti bu enu ate
lu. Masauso Nzima to je alakoso ti orile-ede fun Ajo Alasepo ti Arun Kogbogun
Eedi to fikale si orile-ede Geesi so wipe o dabi
enipe " awon eniyan ko mo bi ikolu Kokoro-arun HIV ati Arun kogboogun Eedi ti
po to ni orile-ede yi" O
fikun wipe: " Apo-ato lo je okan ninu awon ona pataki lati se idena itankale
Arun kogboogun Eedi, mo si ro wipe ko ye ki won kan sonu bayen laiko funni ni
ifiropo.
Isiro iko ogun ninu ogorun awon omo orile-ede Zambia to je agbalagba lo ni
kokoro-arun HIV. Gegebi isiro ti ijoba funrarare se so, o ju edegberin egberun
eniyan lo ti ku latari awon idi to je mo Arun Kogboogun
Eedi lati odun 1980, awon omode to le ni egbegberun lona egbeta o le adota ni
o ti di omo orukan. Ni lowolowo yi, awon omode ti iye won lo lati egberun meedogbon
si ogbon egberun ni won nbi pelu
Kokoro-arun HIV ati Arun kogboogun Eedi, nigbati awon meje ninu mewa awon omode
yi ni a ko nireti wipe yio se ayeye ojo ibi won ikarun.
Bi o se njewo awon eewo isedale lori isoro lori ibalopo ni gbangba, Nzima
so wipe on gbagbo wipe ariwo to waye lori apo-ato na sele nitoripe awon ipolongo
na ni won gbe safefe lakoko ti opo eniyan ngbo redio
" nigbati awon obi njeun ale pelu awon omo won. O seese ki akoko na ma dara
to sugbon mo gbagbo wipe ohun kan wa ti a npe ni itoni obi". Ijo Kristeni ti
nparowa iseraeni gege bi ojuutu si ajakale-arun Eedi.
Nils Gade to je oga agba fun Egbe fun Ilera Ebi ti orile-ede Zambia salaye
wipe Eto Ajo Agbaye lori Arun
Kogboogun Eedi, iyen ajo UNAIDS ti " fowosi apo-ato gegebi ona to munadoko julo
lati yera fun Arun kogbogun Eedi -paapa fun opolopo awon omo orile-ede Zambia
ti ko mo ipo ti won wa, boya won ni
kokoro arun na tabi won ko ni." intergrated Regional and Information
Network 5
5 Page 6 7
Vol. 11 No. 25 CHANGE Radio February, 2001.
6
Ifi-ipa-ba-omode-lopo nlosoke sii ni orile-ede Zimbabwe 10mins. 5secs. O
ju egberun meji ejo ifi-ipa-banilopo pelu awon omode ti ojo ori omiran kere
to osu meta ti won gbe wa
siwaju awon ile-ejo ni odun to koja ni orile-ede Zimbabwe. Awon alase ati awon
egbe ilu gbagbo wipe tente ori apata yinyin si ni eleyi. Ifipa ba awon omode
lopo nlosoke sii ni orile-ede na, isele ti orile-ede na
kole fenuko sibi kan lori kini o faa ati bawo ni won sele fowo mu u. Ni opolopo
igba , awon omode a ni ifipabanilopo lati odo awon ebi to ye ki won ko won le
lowo fun itoju, eyi si ma njeki iwa-ibaje na soro lati
mo. Sugbon ohun to nko awon alase ati awon egbeegbe obirin ajafitafita lominu
ni isele to sese nyoju ninu eyiti iwa odaran na nwaye lati owo awon ti awon
onisegun ibile ti gbanimoran lati fi pa ba omode sun lati le
gba iwosan kuro
ninu aisan ti kogbogun. Igbagbo awon afipabanilopo ati awon onisegun ibile na
ni wipe iwani mimo ara ati okan omode ni anfaani egboogi, nigbamiran ke, won
a ma huwa odaran na ni ireti wipe yio mu orire
bawon.
Abajade re ti je nkan ibanuje fun olufaragba ati awon obi re. Opolopo ninu awon
omode ti won fipa balopo ni won nko arun ti ibalopo ntankale ran, lara eyiti
Arun Kogbogun Eedi wa. Iwadi fihan wipe o to
iko adorin ninu ogorun awon omode olufaragba ifipabanilopo ti won nfun ni orisi
arun ti ibalopo ntankale kan tabi omiran.
Awon isiro tokasi wipe laarin awon egberun marun eniyan to nni ikolu Arun
Kogboogun Eedi losose ni orile-ede naa, iko ogbon ninu ogorun won loje omode
ti yio ti ni iriri ibaje lori ibalopo. Aikitetele mo iba
omode je lori ibalopo, latari ayika ile nibiti opolopo ifipabanilopo na ti sele,
ma nsi awon olufaragba na sile fun ikolu arun. Egbe ajifitafita kan, Ise agbese
lori Omode ati Ofin (Child and Law Project), siro wipe opo
ninu isele ifipabanilopo na ma ndi mimo leyin odun kan, ti olufaragba ko ba
ni ipalara kokan tabi ikolu arun
lati inu iwa ibaje na. Awon iwadi miran tokasi wipe ifipaba awon omode lopo
gbile ni oride-ede na tobe ti o fi je wipe opo ninu awon omodebirin ni Zimbabwe
lo ti ni imolara nipa ibalopo lati igbati won ba ti di omo
odun mejo, to je idaji ojo ori fun ifaramo labe ofin. Igbimo oluwadi kan ti
Aare Robert Mugabe gbe dide di odun meji seyin ri wipe opolopo ninu awon omodebirin
lo ngbe labe irokeke ifipabanilopo nigbagbogbo,
o si wa tanmo awon ofin. to le pupo lati fi daabobo awon omode na. Igbimo na
ninu iroyin re so wipe: "
Isele iru eyi (ilosoke ifipa ba omodelopo) je ohun ikanni gbongbon nitori ewu
to fi awon omode na si lati ko awon ikolu ti ibalopo ntankale (Sexually Transmitted
Infections) ati kokoro arun HIV."
Sugbon orile-ede ko iti mo dajudaju, leyin opolopo iwadi lori ifi-ipa-ba-awon
omode lopo, idi re ganan ti isele ifipaba omode lopo to nsele ni awon igberiko
patapata paapa ti orile-ede na fi nlosoke. Bi eri lati ile-ejo
ninu awon ejo ifipa-ba-omode-lopo se ntokasi ilosoke ilowosi awon ilowosi onisegun
ibile ninu iwa odaran na, awon onisegun na njiyan wipe igbile asa awon oyinbo
lo nfaa. Awon egbe obirin ajatafitata so
wipe iwa odaran na nigbilesi nitori ijiya ti ile-ejo nda fun odaran na ko leto
lati da awon eniyan lowoko kuro ninu ifipa-ba-omode-lopo. Won nkepe fun idajo
iku fun awon afipabanilopo, tabi ju eyi lo, iteloda,
ijiya meji ti won ro wipe o kun oju osuwon bi iwa odaran na se buru to, ti yio
si je idanilowoko toto. Pan African News Agency
Agbegbe Iyasoto Iseda-aye ni orile-ede Seycheelles gba ifoju si kari aye
5mins. 5secs.
Erekusu Cousin ni orile-ede Seychelles ti gba idanimo kariye fun irin-ajo
afe ti ilolupo eda abemi ati isakoso etikun leyin ti o ti di agbegbe iyasoto
fun iseda aye akoko iru re ni ile Afrika ti yio kopa ninu odun
Ifojusi Ipinsiyeleyele Eda Abemi ni kariaye. Awon iroyin to de ilu Port Louis
so wipe Agbegbe iyasoto pataki ti Erekusu Cousin ni won damo gegebi apeere to
dara julo ni bi won se nseto irin-ajo afe to jemo ilolupo
eda abemi ati fun isakoso etikun ati omi okun ninu atejade meji ti awon ajo
kariaye gbe jade laipe yi. 6
6 Page 7 8
7
Vol. 11 No. 25 CHANGE Radio February, 2001.
Agbegbe Iyasoto pataki na, eyiti ajo Birdlife Seychelles nsakoso re, ni
apeere kansoso to wa ninu iwe na ti a pe oruko re ni "Idagbasoke Alagbero ninu
Irin-ajo afe: Akosile awon ise rere lati Ila-oorun Afirika ati
ekun Iwo-oorun okun kariaye ti India." Ninu iwe kan to ko si Minisita orile-ede
Sychelles fun irin-ajo afe ati igbokegbodo oko Baalu, Simone de Comarmond, Akowe-agba
Ajo WTO, Francesco Fragialli so
wipe: "O da mi loju wipe iwe yi na yio se afikun si iyi okowo irin-ajo afe ni
orile-ede Seychilles." Iwe keji -Awon Agbegbe idabobo lori Omi ati ni Etikun
-Itosona fun awon Oluseto ati Alakoso" ni Egbe Isokan
ni kariaye fun Itoju Iseda Aye gbe jade. Erekusu Cousin yo ninu awon isele alafiyesi
meji pataki to wa ninu iwe titun na. Ikinni to se afihan isakoso erekusu na
ni a pe ni " Erekusu Cousin -Agbegbe Iyasoto okun ati
Erekusu ti ajo afenifere ti ko lowo ijoba ninu nsakoso lona imo ijinle Sayensi.
O se apejuwe awon aseyori
ninu iwadi, ibojuto, eko, isakoso ati eto sise.
Nirmal Ji van Shah ti o je oga agba ajo BirdLife Seychelles so wipe itan aseyorisirere
erekusu na tan imole si orile-ede Seychelles lapapo, ati wipe gbogbo omo orile-ede
Seychelles loye ko ma
yangan lori awon aseyorisi na. Shah ni: " Awon eniyan ni orisirisi ero nipa
awon nkan, sugbon okan ninu
awon ona to daraju lati fi se idiwon oriree ati aseyorisi rere ni ifiowosi ati
idanimo lati odo awon ajo kariaye ti aye mo daada. A ko ni sinmi lori aseyori
wa, sugbon a o tesiwaju lati ma fi awon
aseyege titun lele ni Erekusu Cousin ati i bo miran." All Africa com.
Epo iderun fun ero agbokorin ti won ti lo tele 6mins. 7secs. nda isoro
sile ni awon agbegbe arin ilu
Awon epo iderun fun ero agbokorin ti won ti lo tele ndoju ewu titun ko ayika
ni orile-ede Zambia. Teletele, ajo British Petroleum Zambia Plc ma nra awon
epo iderun na pada fun atunse ni ile ero
won to wa ni ilu Kitwe to wa ni aringbungbu agbegbe ti won ti nwakusa fun baba.
Sugbon nigbati won ti
ile-ero na pa, awon ile-ise ati ibudo itun-oko-se kan ma nda awon epo na nu
bo se wu won, ti eyi si nsopo mo orisun omi mimu.
Gegebi Jewitt Masinja to je Akowe Agba ni ile-ise ijoba fun Ayika ati oro
Adayeba se so. " Epo iderun ti ati lo tele gbodo je ohun ikannigbongbon to ga
lori ayika nitori awon eroja kemikali ati ti abuda to wa ninu
re jeki o lewu fun idarasi awon ile, omi ati afefe. " Nitori idi eyi ni ile-ise
fun Isakoso Egbin ni Gusu ile Afrika eka orile-ede Zambia se gbe idanileko oniifioroweoro
kan kale laipe yi ninu eyiti koko oro agbeso
je bi won se nda epo iderun ti won ti lo nu. Awon to tun pese ni awon osise
lati awon ibudo itun-oko-se ati awon ajo oloko-owo to nta epo robi. Ero awon
to gbe idanileko na kale ni lati se ayewo iri ikolu ti epo
iderun ti won ndanu lati awon ibudo itun-oko-se ati awon ibudo ti won nti ta
epo moto nni lori ayika.
Leyin ti won ti ti ile-ero itunse epo ti ajo BP Zambia to wa ni Kitwe ti won
si gbe lo si orile-ede Zimbabwe, awon ibudo itun-oko-se ati ibudo ita-epo beresi
tu epo danu laibikita sinu awon koto idominu gerege ati
awon koto miran. Nigbamiran awon epo yi ma nsan lo si ibi omi mimu, ibi idaegbinsi
ati oko-ogbin ati awon ile to wa legbe awon ibudo itun-oko-se ati ita-epo paapa.
Abajade eyi ni wipe epo na ti ba omi ti
awon eda eniyan ati eran-osin nlo je o si ti pa awon eda abemi ninu omi run,
lara awon ti a ti ri eja ati awon opolo to nje efon.
Nisisiyi, ile-ise na nsowopo pelu awon eka to wa ni orile-ede South Afrika,
Namibia, Zimbabwe, ati Botswana lati se agbekele ilana imusese lati se iwuri
fun atunse awon epo iderun ti a ti lo tele ki o ledi ohun
elo to dara. Ireti ni wipe ona agbero lati din egbin ati ibaje ayika laibikita
nipa dida epo iderun aloku nu ni a o yera fun tabi dinku repete.
Pan African News Agency 7
7 Page 8 9
Vol. 11 No. 25 CHANGE Radio February, 2001.
8
Iyan tun nrokeke latari ikolu kokoro alajerun. 5mins. Bi orile-ede Tanzania
se sese nyorun kuro ninu okan ninu awon owongogo ounje re to buru ju, orile-ede
na
tun ti wa labe ewu iyan miran latari ikolu awon kokoro alajerun. Ijoba ti kede
wipe marun ninu ogun ekun oke-ile orile-ede Tanzania ni awon kokoro alajerun
na ti yabo, ti mefa miran wa labe ewu ikolu. Awon
agbegbe ti oran kan ni Dodoma, Arusha, Mbeya, Iringa, ati Singida, nibiti awon
kokoro na ti nposi lona tobanileru. Meta ninu awon ekun na -Arusha, Kilimanjaro
ati Tanga -ba orile-ede Kenya paala ni iha
ariwa, iberu si ni wipe ikolu na le ya wo inu Kenya. Ifoya tun wa wipe ikolu
lati Mbeya le ya wo awon orile-ede Malawi ati Zambia to je alamulegbe. Bi otilejepe
Ile-ise ijoba fun Ise-ogbin ati Aabo lori ounje
ko le so pato bi ibaje na se to ni idiwon tonnu, isiro re nlo ni ogogorun egberun
iwon tonnu oka ninu awon
oko-ogbin to gba ile bi saare hektari egberun meje o le okoodin legberin ni
awon ekun mararun na. Ijoba orile-ede Tanzania ngbaradi lati bere fun millionu
kan owo dola Amerika lowo Ajo Agbaye fun Ounje ati
Ise-ogbin (UN Food and Agriculture Organisation) ni ilu Rome lati fi dojuja
ko irokeke kokoro alajerun na. Ni akoko yi kan na, Tanzania ti ni idojuko ikolu
lati owo awon esu pupa, eku ati awon eye quelea ti
awon osise ijoba so wipe ti won ko ba daduro o le tubo ba aabo onje orile-edeTanzania
je.
Osise kan ni eka idabobo Ile-ero, Ogbeni Sergei Mutahiwa, kilo fun awon orile-ede
to ba die ninu awon ekun to ni ikolu na paala wipe ki won mura sile nitori irinkiri
awon kokoro na le gba igbelarugbe lati owo
oju-ojo ati ategun. The East African
Bi mo se ri si
Imudogba Eya dara fun Ijoba Tiwantita 17mins. 6secs.
Aibikita awon ondibo lo ti je ohun to ma nsele ninu idibo ni orilede-ede
Zimbabwe lati odun 1985, eyi losi faa ti awon osise to seto ti idibo odun to
koja si ile igbimo asofin fi jewo wipe titujade awon ondibo ya
awon lenu pupopupo. Leyin idibo ti odun 1980, idunusubuluayo ominira poora
bi oju awon eniyan se wale ti won si dojuko bi ikan se wa gangan. Awon eniyan
ko kan ridi lati dibo. Awon obirin, gegebi ara
awon ondibo, na kan tele itesi yi . Pipo ti awon obirin po ju okunrin mu ki
won je ile olora fun enikeni to ba
gbero lati di omo ile igbimo asofin ninu idibo kan. Sugbon nje a tile ka awon
obirin si gegebi ondibo? Abi won ti fi won sipo awon akorin ninu ipolongo awon
okunrin fun idibo ? Se titi laelae ni ati fi won sipo pe
ki won maa korin ki won si maa kunle sori paapa ibale ni Idiko Balu Harare
ki won ma wo gareta ori oko oloko ? Dajudaju asiko ti to lati ka awon obirin
to ni agbara ifobaje si eniyan pataki. Se ko ye ki awon
egbe oloselu ma wa ibo won tagbaratagbara ?
Gegebi ondibo awon obirin gbodo se alekun imo won lati ye itan egbe oselu kan
wo ati eto imulo re lori eya nitorina ohun ti koseyera fun ni wipe bi egbe oselu
kan bati pe si ni akosile re nipa aikobiara si oro eya
ninu ipolongo idibo yio se gun to. Otito kikoro ni orile-ede Zimbabwe ni wipe
to ba je pe gbogbo awon obirin to leto lati dibo ni lo ti forukosile lati dibo,
ti gbogbo si dibo fun egbe kan, egbe na ko nilo ibibo
eyokan soso lati odo okunrin ki o to ni awon omo egbe to poju ninu ile igbimo
asofin. A nso eyi lori wipe ati fokansi wipe ko ni si ese ofin orile-ede to
fun Aare ni ase lati yan ogbon (Okunrin) omo ile igbimo
asofin. Ohun to je otito to banininuje ni orile-ede Ziimbabwe nipe nitori bi
agbekale awon egbe oloselu seri, awon obirin ko ti le kopa ninu igbe aye oloselu
ti orile-ede yi ni awon ona to se pataki bi ti okunrin.
Oran to se pataki julo ni orile-ede Zimbabwe ni wipe ayika ko fararo fun awon
obirin. Iselu ni a ti pe ni ere " Idoti" Jakejado aye ati ti o je wipe okurin
nikan lo nse. Obirin to ni ibowo fun ara re ni a ko lero wipe ko
lowosi ere yi. Lakopo, nigbati enikan bati pinnu lati di osise ijoba, oniyen
funrarare yan, ki ise lati fo awon aso re nita gbangba nikan, sugbon pelu "iranlowo"
awon alatako won ninu oselu, ki won si sa awon ti ko
mo daada ninu awon aso na sita gbangba fun ayewo awon ara ilu. 8
8 Page 9 10
9
Vol. 11 No. 25 CHANGE Radio February, 2001.
Won ti jiyan re wipe ilowosi awon obirin ninu oselu ye ko jeki iselu mu
otito dani si ki o si fojusi awon oran yato si awon eniyan. Ni oride-ede Zimbabwe,
idoti oju-ona ipolongo ma nfi ara re han ni ona to se
wogowogo. Eyi ni nipase iwa-ipa oloselu jakejado orile-ede na. Otito to buru
nibe ni wipe gbogbo ayika na ntenumo wipe eni to ba lagbara julo ni yio ruura.
Bi o se je wipe awon obirin to laapon ninu atako ni won
doju iwa-ipa oloselu na ko, eyi je iranleti fun awon obirin na wipe ki won mase
lowosi iselu. Bi o tun se je wipe awon obirin nkopa ni ipele ti isale ninu awon
egbe alatako, won ki ise awon ti wo ndibo fun, ntenumo
alaigbara won rara.
Ohun miran, ninu igbeyewo temi, ti won tun ti lo fun ipalara awon obinrin, ti
o si mu ki awon
obirin to nwa ipo oloselu dinku, ni eto isedale ati ilana ibuyifun. A ma nmomo
tabi ni aimo tumo eleyi sodi si ipalara awon obinrin. Nitorina a ma nkoko wo
awon obinrin gegebi obinrin ki a to wo won bi eniti a le
fakale. Agbeyewo ipo won ni o nwaye: on nikan lo wa ni tabi o ti loko? ti
ko ba iti loko, idi re ti ko iti loko? Se o ti koko sile tabi beko? Nje o ti
bimo? Okunrin melo lo bi won fun? A kii ibere awon ibere wonyi
nipa awon okunrin oloselu. Lotito, ohun to je itewogba ni fun okunrin oloselu
lati wa lori iyawo keji tabi
iketa. A si rii gegebi enito lowo. Ipo obinrin to ndu ipo ni a ma nso di koko
oro idibo, ki ise agbara re lati koju awon isoro agbegbe na. Ninu aye to wa
ni deede, odikeji ni ohun to tona. Lotito, ninu awon obirin
ondupo die ki itile le rekoja ilana iyaniyan laarin egbe won nitori awon itumo
odi wonyi.
Nipa ilowosi mi ninu idibo sinu ile igbimo asofin, mo mo bi ipolongo fun idibo
se ma nna ni lowo to. Ni
orile-ede Zimbabwe opolopo inawo lo ma nwaye nipase egbe oselu awon oludije.
Ninu Zimbabwe ti o peye, o ye ki omo orile-ede Zimbabwe kokan le gbe owo, akitiyan
tabi ohun ini re miran sile fun egbe
oselu ti o wuu. Ayafi ti egbe oselu kan ba ni awon ona to daju lati fi ri
owo gegebi eyi ti a fi idaniloju si labe ofin egbe oloselu (Isunna), bi beko,
yio soro fun iru egbe be lati ri owo. Pelu e na, otito wipe egbe oselu
kan ti ri owo ko tumo si wipe awon obirin oludije laarin egbe na yio gba igbeowosile
ni dogbadogba pelu
awon okunrin oludije. Eyi ni idi ti o fi se pataki fun awon obi lati fi ara
won sipo to se pataki laarin awon egbe won.
Ijoba to ba gba lati se agbekale ayika fun imudogba eya pelu isejoba rere
ati ijoba tiwantiwa je eniti o sowon fun wa gidigidi, nitorina bi ijoba kan
ba ni obinrin kansoso ni ipo minisita agba, agogo ikilo awon
obinrin ondibo gbodo pariwo ju iro itolerawon oko ayokele to ngbe aare ati awon
emewa re lo. O gbodo je ijoba logun, ki ise lati se igbelaruge ayika to fi oro
eya sero, o nikan, sugbon eyi to tenumo isepataki
asepo onidogbandogba laarin awon okunrin ati awon obinrin ninu awujo olominira
ati ti onijoba tiwantiwa. Ageku Erongba Yvonne Malhunge ninu iwe iroyin Zimbabwe
Independent.
A ti gbo
Awon eniyan wa O! Igbowosile fun Igboraeniye to dara sii 6mins. Awon
obinrin onkowe merin ni a ti fun ni Igbeowosile Akoko ti "Awon Eniyan wa O!
fun Igboraeniye to
dara sii". Igbeowosile na ni a se lati inu owo to wole lati inu "Awon eniyan
wa o!" iwe ti gbajugbaja kariaye onise iroyin omo orile-ede India, Alka Raza,
ati iyawo Asoju orile-ede America si Naijiria tele, Susan
Twaddell, ko lati saami odun awon Agbalagba ti Ajo Agbaye., O se akosile itan
igbesi aye awon agbalagba omo orile-ede Naijiria lati orisirisi eka, lati ogbontarigi
onise iroyin de obinrin to nlu ilu ibile. Gegebi Alejo
pataki, oludari Ekun fun Ajo Amuludun ti Ford, Dr. Akwasi Aidoo, se so, igbeowosile
na je ayeye lati ko
afara saarin awon ewe ati agbalagba omo orile-ede Naijiria, awon to nrekoja
ise ona nitori ise ona funrarare ......... awon ti won nife ninu idagbasoke
........... awon obirin onkowe to dangajiya to si ni ebun .......... to
nife lati so itan ti orile-ede Naijiria." Igbeowosile akoko fun iwe na lo
waye lati odo ajo Amuludun ti Ford. 9
9 Page 10 11
Vol. 11 No. 25 CHANGE Radio February, 2001.
10
Daniel Landry, asoju kan fun Ajo Agbaye fun oran iye Eniyan Ilu (United Nations
Population Agency) tun fi ironu kanna han nigbati o wipe "Awon alejo lati kariaye,
le nigba miran, woye nipa ayika ju awon
olugbalejo won lo nitori eniyan ma nwa ti kosiniri awon iwe to funni ni irisi
ti a ko kun ni awo ti a ko si se pelu isegbe nipa awon eniyan ilu won .....(
iwe na) fi awon aseyori awon eniyan ilu to je eniyan pataki ati
eyiti ko ni oruko lawujo han.
Awon ti a gbe owo fun ni a yan lati soju awon ekun pataki orile-ede na. Nneka
Osakwe je omo iha ila-oorun to nsise oluko ni ile eko giga Yunifasiti Nnamdi
Azikwe ni Awka, o si je eniti o ti gba opolopo aami
eye ti orile-ede ati ti kariaye, o si je ajifitafita fun eto awon omode. Ititaka
lati oke oya ni a jewo re nipase
elewi ati oluko awon itan kuukuku, Binta Muhammed Florence Inokweje ni obirin
aringbugbun ti a yan nitori ise re ninu ewi, ere ori itage, itan awujo ati awon
ipolongo
odo. Iyaafin Kemi Olaitan, olukopa. Ninu ere itage, onkowe sinu iwe iroyin
ati alakojo eto lori redio to je ohun to ga soke ninu ija fita fita fun eto
awon obinrin, soju iwo -oorun. Okankan ninu awon to gba owo
yi ni a fun ni ogorun egberun Naira lati se atileyin akitiyan won ki won s\
i gbe ise won jade ninu imo awujo
ati oro aje. CFC
Orile-ede Democratic Republic of Congo 3mins. 5secs. gbe orisi gbaguda
titun jade
Ile-ise orile-ede Democratic Republic of Congo fun iwadi lori Imo Ijinle
Sayensi ati Oro aje lori Igbejade Irugbin ti se igbejade igba orisi gbaguda
ti won ti danwo ni Ile-ise kariaye fun Ise -ogbin ni Ile-olooru to
wa ni ilu Ibadan ni orile-ede Naijiria. Awon orisi gbaguda na ti o sese ko ba
afefe-ile agbegbe mu ni won yio tunse po sii ti won yio si pin won fun awon
agbe agbegbe. Ile-ise na so wipe ninu eyi, ayewo awon
ibudo itoju ojele irugbin meji to wa ni Mwazi ati Mbakana, ni eyin odi ilu Kinshasa,
ti bere. Ibudo kini ni won gbekale pelu iranlowo ile-ise na, nigbati ikeji gba
atileyin lati odo Ibudo Ise-ogbin fun Idagbasoke
Alasemuwonuarawon to wa ni Mbakana (Mbakana Agricultural Centre for Integrated
Development)
nibiti won gbin egberun lona ogorun awon ege to yege daradara. Igbejade ati
ayewo awon orisi titun yi wa ni ibamu pelu
akitiyan ijoba orile-ede Congo lati pa awon kokoro gbaguda run.
Gbaguda ni ounje to po julo fun awon to ju iko aadorin ninu ogorun lo ninu omo
orile -ede Congo, paapa ni awon ekun Bundudu ati isale-odo Congo, ati ninu ilu
Kinshasa. Awon akitiyan wonyi, eyiti o ni atileyin
Ajo Agbaye fun Ounje ati Ise-ogbin, ni a se laarin ilana ise agbese kan ti
a fokansi lati se igbekale ona ti yio wa titi fun imudarasi aabo ounje.
Pan African News Agency
Ohun Imusagbara alatunlo to si se 4mins. 5secs. gbero gbelege ninu egberin
odun yi
Gegebi Oludari Alase Ajo UNEP, Klaus Toepfer, se so fun ipade kan lori ohun
imusagbara alagbero, awon ohun imusagbara to je ore ayika bii agbara lati inu
oorun, agbara ategun, ati agbara igbi omi okun lo
je okan ninu awon oran to kannigbongbon to nkoju eda eniyan ninu egberun odun
titun yi,, O kilo wipe, "Agbara ina to ba ayika mu ni a gbodo fi sinu aarin
idagbasoke alagbero ti a o ba koju irokeke iyipada
iyipada afefe-ile ati igbogunti osi ati ailera ninu iha aye to sese ndagbasoke
nitooto. "Idagbasoke alagbero
tabi aiseru fun awon omo yin, tumo si awon nkan bi sise aridaju wipe awon ilu
nlanla wa sise bi ibi to wunilori to si dani laraya lati gbe ati lati sise;
ati lati se aridaju wipe awon eniyan to talika ju laye ko ha debi
ti won o fi ge gbogbo igbo nibiti awon eda abemi egan to sowon pupo wa lule
fun igi lati fi dana tabi mu ara won gbona". 10
10 Page 11 12
11
Vol. 11 No. 25 CHANGE Radio February, 2001.
Awon ero wonyi ni a mu siwaju ninu ipade Igbimo Amusese ti Ajo G8 lori
Ohun Imusagbara alalotunlo kan
to waye ninu osu kini odun yi bi awon minisita lati orile-ede Afirika mewa to
pejo ni ile-ise ajo UNEP Nairobi fohunsokan lori ipo kanna lori ilo alagbero
fun ohun imusagbara. Awon minisita na yio gbe awon
abajade won fun ipade kesan ti ajo fun idagbasoke Alagbero ti yio waye ninu
osu kerin odun. Awon imoran Toepfer tun waye ni ifojusi ipade kokanlelogun ti
Igbimo Alase ti Ajo UNEP ninu eyi ti awon minisita jakejado aye yio pade ni
ilu Nairobi lati ojo karun si ikesan osu keji odun yi nigbati ohun imusagbara
alalotunlo to se gbero yio je awon koko oro ti yio wa lori
ise agbese fun igbimo na Pan Africacn News Agency
Aye Ile Olomi -aye to wa fun awari 9mins.
Awon olubere to yege lati mu aseju awon orile-ede mejidinlogun wa si ilu
kekere kan, Ramsar, ni orile-ede Iran, ni etikun Caspian ni ipari osun kinni
odun to je osu olotutu ni idi lati gberaga lori ohun ti won se
nigbana. Adehun Kariaye lori Ile-Olomi ni won sasepari re ninu ipade na ni
ojo keji osu keji. Loni, leyin ogbon odun, adehun na ti di ohun imulo to munadoko
eyiti awon egbegbe olusise metalelogofa nlo lati se
aridaju itoju ati ilo ologbon fun awon ile olomi won. Awon oju ewe die yi to
ni igbese mejila to je akosile
Adehun Ramsar ni o ti yeje lati se idasile igbese lati daabobo okan ninu awon
ilana ilolupo eda abemi to ni ibisi to poju to si wa labe irokeke ewu lori ile
aye yi.
Awon odun to ti koja ti fihan wi pe Adehun Kariaye lori Awon Ile Olomi rekoja
ohun elo ofin kariaye ti a nlo; o je egbe nla kan to ni awon omo-eyin to ti
fi ara ji, iyen awon ajo ijoba , awon awujo onimo ijinle
sayensi, awon ajo kariaye, awon eniyan ibile, awon ajo ti ko lowo ijoba ninu,
laarin orile-ede ati ni kariaye,
awon egbeegbe agbegbe ati awon logaloga ninu awon ile ise adani paapa. Ninu
awujo yi ni a ti ri okun ati imunadoko Adehun kariaye lori awon Ile Olomi, nkan
pataki ti a gbodo naani ki a si mu alagbara sii bi a se
nteriba fun awon ofin ere eyikeyi ninu awon adehun onijobasijoba.
Awon orile-ede to je omo egbe metalelogofa, awon ibudo egberun kan o le metalelogoji
lori itosile awon Ile Olomi to se pataki kariaye eyiti o gba ile to fere to
egberun lona egberin ibuso kilomita ni igun mererin
re ti ile Olomi, to je aayo agbegbe ile olomi awon orile-ede pupo to ni awon
ofin tabi eto ise to dara lori ile olomi, orisirisi awon ohun elo ise ati eto
imulo ti a se ninu ilana adehun na ti a si fi ase si lati owo apero awon
egbegbe. Eyi ni otito to wuni lori nipa Adehun Kariaye Ramsar loni. Sibesibe,
a ko iti le sinmi. Opolopo
awon ibudo Ramsar lo wa labe irokeke ewu, opolopo ninu won ko si ni ilana isakoso
to munadoko nile. Awon ofin imulo lori awon ile olomi ni awon orile-ede bi melo
kan kan wa ni akosile lasan ni, bena si ni
awon Alase ise Ramsar ni awon orile-ede miran ko ni okun rara debi wipe won
tile le mu ayipada wa ninu eto imulo ati ise awon ajo ijoba miran to je wipe
awon ni won ni agbara to poju lori oro ile olomo ni orile-ede
na.
Lati le koju awon aleebu wonyi, a ni lati mu opo eniyan ati awon eka awujo si
i wo inu egbe Ramsar. A ni lati se ju bi a se nse lowolowo lo lati ran awon
eniyan lowo lati se awari iwulo awon ile olomi ati awon ise
won, ki a le ri opo oludaabobo sii ti a le gbekele nigbati o ba de ibi yiyan
awon ijoba ati didari awon ipinnu lori isakoso awon oro adayeba. Eyi ni koko
ifokansi ojo Awon Ile olomi ni agbaye fun odun 2001, eyiti
oro akomona re je, "Aye Awon Ile olomi -Aye to wa fun Awari". Ojo keji osu keji
odun 2001 ni ojo ti o wa fun awon eniyan lati se awari iwulo ati awon ise awon
ile olomi na. Nipa sise eyi a o se ilowosi pataki
kan si mimu ilera ilolupo awon eda abemi lori ile aye wa -ilekansoso na ti a
gbogbo jijo ni -wa ni deede. Delmar Alasco, Akowe Agba fun Ramsar 11
11 Page 12 13
Vol. 11 No. 25 CHANGE Radio February, 2001.
12
Eto Awon Omode Ode Na 17mins.
Ni owuro kutukutu, Jamina ba baba re agba lo lati lo ko oyin. Won tele eye
oyin wo inu igbo jina rere. "Mo fe ri erin" Jamina kigbe, "Baba Agba, se e ro
wipe a o ri won?"
"O le sorire," baba arugbo na dahun. A ki i ri opolopo won mo nisisiyi, paapa
lati igba ti awon ode ti de."
Awon ode! Oju Jamina tanna. "Ode ni emi na yo je". Jamina beresi sere ode, o
yin ibon fun erin nla, o topase agbanrere kan wonu igbo jinjin, o yo gologolo
tele egbe awon kiniun kan, o yi pada lati wo baba re
agba. Sugbon o ti sere wonu igbo lo jinna, baba re agba ati eye oyin na ko
si si nitosi mo. O kigbe soke sugbon gbogbo re palolo. Nigbana, lati inu ategun
jinna rere, o gbo ohun kan, igbe ibanuje ati ipaya to fa
okan re. O seemi o si tetisile. Jamina woke. Awon eye igun wa loke ninu oorun
osangangan na, besi ni o
ni ifura wipe ewu wa ni ayika.
"Ma maa da lo sinu igbo," awon obi re ti ki i nilo sugbon ohun to ngbo na
jo ti ipohunrere ekun tobe ti ko
fi si ohun to le se ju wipe ki o topase re lo. O lo titi titi ....... titi titi
ti o fi de ile gbalasa kan. Nibe ni o ri omo erin kekere to ngbinyanju lori
asan lati ji iya re. Awon ode ti sise won, gegebi Jamina, omo erin na ti sonu,
eru si nbaa. "Ma sokun mo, eni kekere, Jamina soro kelekele. Jamina yi ori
segbe kan lati gbo boya awon erin to ku wa nitosi. Sugbon nkan to gbo ni yun-yun-yun
ariwo awon kokoro ninu ooru na. O mo wipe
ikoko na ko le ruula ni on nikan. O le gbiyanju lati mu lo sile, o si seese
ki won ri awon obi re lona. Sugbon
eru nba ikoko na. "Emi ki ise ode." O soro jeje fun igba pipe, o ba erin na
soro titi ti ara re fi bale ti o si fi owo ija re paa lara. Jamina dide duro
o si gbe igbese bi melo kan. Ikoko na telee, o ntogege ninu ooru
gbigbona na. Nigbana ni ojo de, bi omi si se mu ara re tutu, erin na ni okun
lati tesiwaju. Ni awon igba miran, won a yo, won a si jijakadi sugbon won nrin
lo laarin iji na. Bi oju orun se ka, ara erin na ya, Jamina
si ro, ni akoko na, wipe on ngburo awon erin. Sugbon nigbati o duro lati tetisile
ohun to ngbo ni kikun
ategun ninu awon koriko. Fun igba pipe erin na ko lati tesiwaju. Leyinna, pelu
ibanuje ati idakeje o tesiwaju.
"Ti o ba sonu", baba re agba ti so fun, "tele awon egbe eranko ni osan; won
yio mu o lo si odo. Ile wa ni
odi keji." O pe ki Jamina ati erin na to ri egbe ketekete abila kan to nla ile
perese na koja lo. Nwon rin tele awon eranko na ti ongbe ngbe ni gbogbo osan
gbigbona na. Bi oorun se nlo sile loju orun, nigbeyin gbeyin
won de odo na. Sugbon awon oju to farasin nwo won lati inu odo na, Jamina
si ni ifura wipe ewu wa nibe. "Ibi yi lewu lati koja, eni kekere, a gbodo tesiwaju,"
Jamina so fun erin na . Bi Jamina se yiju pada o ro
wipe on nri awon erin lokeere. O seju o si ranju re, sugbon awon igi acacia
nikan lo wa lokankan ti ewe
won ntan yinrinyinrin ninu imooru ojo na. Jamina ati erin na tun tesiwaju, sugbon
laipe ikoko na bere si fa seyin. "Ko jinna pupo mo," Jamina bebe, sugbon o ti
re ikoko na ju wipe ko tesiwaju lo. Bi Jamina ti duro
pelu re, o ronu nipa iya re. Bo baje pe o le pee. Laipe awon eniyan yio beresi
kominu; Laipe won yio beresi wa kiri. Ikoko na soro kelekele. O fowo pa lara
jeje. Ko ni iya to le pe mo "Tetisile!" Jamina pa
erin na lenu mo. Won ngbo ohun awon eniyan. Awon obi mi! o ro ni okan re. Sugbon
awon ojiji to nri ni
okankan na ki ise awon obi re. "Awon ajiodese !" o rora soro pelu iberu. Nisisiyi
Jamina na dabi okan ninu awon eran-ode. O gbadura wipe ki ikoko na ma ke. Sugbon
erin ni ifura ibi, on na si duro rigidi titi ti
ewu na fi koja. Okunkun de, gbigbo ati hihan awon eda oru si bersi gbe ifoya
wonu egungun Jamina. O kajo sunmo ikoko na, o tun wa di mo pelu iberu bi igbe
to dayafoni kan lati odo nkankan ti ebi npa se dun
nitosi.
Bi Jamina ti nduro fun atako, oro baba re agba tun to wa lekan si . "Nigbakugba
to ba wa ninu ewu, mase
so ireti nu". Nitorina Jamina tetisile fun awon obi re. O di oju re, o si bere
si fi okan fe won. Sugbon dipo won, awon erin ni o ri. Okan re kun fun awon
egbegbe erin atijo. Awon owoija nlanla ti baba re agba ti
ri nigbati o si wa ni odo. Awon erin nlanla to nlo bi anjonu la awon ile perese
na ja. O si ngbo kikun won jeje to rinle nitosi. Nigbati o la oju re, awon erin
po yika, bi enipe o pe won ninu ala re. Eru o ba Jamina. 12
12 Page 13
13
Vol. 11 No. 25 CHANGE Radio February, 2001.
O ni, "mu eni kekere yi kio si paamo lalafia." Nigbati o fi ma di imole
kinni ni owuro, iya Jamina ri nibiti o gbe nsun lori koriko. "Mo nsere ode mo
si sonu." Jamina so fun un. Pekipeki lo sunmo iya re titi ti won fi
dele, nigbati won de abule o so funrara re kelekele. :Ngo ni di ode laelae.
Paul Granty ninu iwe "Ode Na"
Awon oro Asokagba
Se ayeye ayo iriri Ile Afirika pelu awon owe manigbagbe wonyi. Lori
ogbon
Ma se lo irole ninu ile ti o ko setan lati sun si Orile-ede Ethiopia
Mase bu ooni nigbati o ba wa leti odo Orile-ede Uganda
Lori Suuru
Adie ki iwale pelu ese mejeji Orile-ede Equitorial Guinea
Suuru ni eyin to npa eye nlanla Orile-ede Zimbabwe
More African proverbs
................ Nisisiyi, oro kansoso lori itoju Eni to ba ngbin igi feran
awon elomiran yato si ara re
Thomas Fuller, 1723
Ranti............ Okan dabi eweko, o nhu sibi to ba wu u
Orile -ede Zimbabwe African proverbs 13
© 2002 Communicating for Change. All Rights Reserved
Developed by George Mbuagbaw