Go Back
Communicating for Change

Document Body Page Navigation Panel

Pages 1--16


Page 1 2
1
Vol. 11 No. 24 CHANGE Radio January, 2001.
Idagbasoke
AWON IJO IROYIN
A ti kede awon to gba Aami Eye ti Ajo Ile Europe fun Ise Iroyi 3mins 19secs. 3
Ajo Alasepo ni Kariaye fun Awon Onise Iroyin ti kede oruko awon to gba
Aami Eye Lorenzo Natali ti Igbimo Apapo Europe fun Ise Iroyin.

IDAJO ODODO LAARIN AWUJO
A nilo Idaabobo ni Kariaye fun Awon Eto Eda Eniyan 13mins. 6
Gegebi Iwe Iroyin ti a mo si Eso Eto Eda Eniyan se so, gbigbooro awon isoro
eto eda eniyan lagbaye lode oni ti koja ipa awon ajo Kariaye lati koju won.

ILERA
Ajo Agbaye saami Ojo Arun Kogboogun Eedi ni Agbaye bi iye ikolu arun na 7mins. 8
se nlosoke si i.
Awon okunrin gbodo yi ihuwasi won lori ibalopo pada ti aye yio ba fi dekun itankale
apani Ajakaye-arun Kogboogun Eedi, gegebi Ajo Agbaye se kilo nigbati o nse ifilole
Ojo Arun Kogboogun Eedi ni Aye.

Gbigbogunti Arun Kogboogun Eedi ni Ile Afirika. 8mins. 13secs 10
A se ifojusi bi o se ye lati koju ajakale-arun Eedi bi igba ti eniyan njagun nipa lilo
gbogbo awon olukopa pataki ni ipele ti orile-ede ati ni kariaye ninu Apero Odun
2000 lori Idagbasoke Ile Afirika.

Awon Olori Ile Afirika se atunso Ifaramo won si Igbogunti Arun Kogboogun Eedi. 11mins. 9
Awon Olori ile Afirika faramo igbejako Kokoro-arun HIV ati Arun Kogboogun
Eedi ninu Apero Keji lori Idagbasoke Ile Afirika ni ilu Addis Ababa.

Ayika
IDOTI
Orile-ede Zimbabwe gbejako Idoti 4mins. 17secs. 3
Ipinnu orile-ede Zimbabwe lati yan ijiya fun awon onimoto to ndoti ayika lati osu
kini odun 2001 ni o ti gba ifaramo to gbooro.

Apero nlo lowolowo ni orile-ede South Africa lori awon Kemikali Oloro 8mins. 3
Apero karun ti Ajo Agbaye fun Adehun Kariaye, eyiti yio pese anfani ti iru re sowon
pupo lati gbesele patapata tabi ki won se idinku repete lori isejade ati ilo awon kemikali
to lewu taara si eda eniyan, waye ni ilu Johannesburg ni osu kejila odun to koja.

Aye npadanu orisi meji ipinsiyeleyele Eran-Osin losoose. 10mins. 4
Gegebi Ajo Agbaye fun Oran Ounje ati Ise-Ogbin (Food and Agriculture
Organisation (FAO) se so, aye aye npadanu orisi meji ipinsiyeleyele awon eran-osin
to niyelori pupo losoose.

Ajalu ba Awari ti yio wonu iwe itan je 8mins. 7
Won ti se awari eja coelacanth oni-irinwo odun ni etikun St. Lucia ni agbegbe
KwaZulu-Natal ni orile-ede South Africa, sugbon awari na ni ipadanu emi baje.

AFEFE ILE
Ailefenukosibikan waye ninu Apero lori Iyipada Afefe Ile 6mins. 10secs. 4
Apero lori Iyipada Afefe Ile to waye ni ilu Hague wo pale leyin ose meji idunadura to
lekoko, nitori awon minisita ati awon asoju orile-ede ko le fenuko lori bawo ni a se
le mu ki Akosile Ilana Ise Kyoto di lilo.

Bi mo se ri si
IJOBA TIWANTIWA ATI ISEJOBA RERE
Ile Afirika npongbe fun Ijoba Tiwantiwa 13mins. 10
Akowe Agba Ajo Agbaye, Kofi Anan, so iriri tire lori oran ijoba tiwantiwa,
paapa bi orile-ede re se nla ilana idibo ti yio wonu iwe itan koja.
1
1 Page 2 3
Vol. 11 No. 24 CHANGE Radio January, 2001.
2
A ti gbo......
ILERA
Kokoro-arun Ebola pa Ogojo Eniyan ni orile-ede Uganda 4mins. 5secs. 12
Awon eniyan ti Kokoro-arun Ebola apani ti kolu ti to irinwo, lara eyiti ogojo ninu
won ti ku ni orile-ede Uganda lati owo arun na to nyara ran eniyan pupopupo.

AWON OBIRIN ATI ODO
Awon odomobirin gbe igbese lati dekun Ige Abe Obirin nigekuge. 2mins. 8secs. 12
Awon odomobirin orile-ede Kenya meji ti gba iwe ase ile-ejo to da baba won lowoko
lati fi ipa mu won ju ara sile fun ige abe obirin nigekuge.

O gbodo Teriba: Ipe Miran si Ise 5mins. 12
Ijakadi fun imudogba eya ni a se ifojusi re ninu iwe kan lori ifiagbara-fun awon obirin,
eyiti Ada Okere Agbasimalo ko ti akole re je "O Gbodo Teriba"

Ojo ati Akoko
Ipe fun ifiorukosile 4mins. 50secs. 13
Igbimo Agbaye lori Ilera ti kepe fun ifi oruko awon eniyan sile fun Aami Eye Jonathan
Mann fun Ilera ati Awon Eto Eda Eniyan ni Agbaye.

Orile-ede South Africa yio gba Ipade Ile Aye ti Odun 2002 lalejo 6mins. 22secs. 13
Eka Ile-ise orile-ede South Africa fun Oran Ayika ati Irin-ajo Afe ti kede yiyan
orile-ede South Africa lati gba Ipade Gbogboogbo ti Ajo Agbaye lori Ayika ati I
dagbasoke Alagbero (United Nations General Assembly on Environment and
Sustainable Development (UNCED) lalejo.

Awon Isiro
Fifi opin si Idakejeje lori Iwa-ipa si Awon Obinrin. 3mins. 10secs. 14
Bi ojo Alaso-teere funfun ti nkoja lo, awon akosile to mu irewesi bani se ifojusi bi
o se se pataki lati dekun iwa-ipa si awon obinrin.

Eto Awon Omode

Ketu, kilo panilerin tobe? Itan Isedale Eya Neur Kan 21minutes 14
Itan Ketu, okunrin kan to ni erin pupo ninu re, ati bi eleyi se ko sinu wahala.

Awon Oro Asokagba
Awon oro manigbagbe to nse ayeye iriri Ile Afirika ni atijo ati isisiyi. 15 2
2 Page 3 4
3
Vol. 11 No. 24 CHANGE Radio January, 2001.
Iroyin
Orile-ede Zimbabwe gbejako Idoti 4min. 17secs.
"O je iroyin to darajulo ti mo ti i gbo lati opolopo odun ti a ti npolongo," gegebi oro Emmanuel Toro, olugbaninimoran pataki kan lori ayika, lori ipinnu ijoba orile-ede Zimbabwe lati yan ijiya fun awon onimoto

to ba ndoti ayika lati osu kini odun 2001. On je lara awon egbe awon afenifere kekere kan ti, leyin opolopo odun ipolongo laibojuweyin, o ti fi agbara mu ijoba lati kobiara si isoro ti awon alase ti nfokansi
tele wipe o jinna tobe ti ko ye fun ikominu lori re.
Titi di odun die seyin, orile-ede Zimbabwe ko ni ofin kokan lori idaabobo ayika, nisisiyi paapa awon ofin to wa, ilana won tako ara won. Sugbon fun egbe ogun kekere ti awon akegbajare lori ayika na,
igbesekigbese ti ijoba ba gbe lori idinku idoti ati ibaje ayika, gegebi ofin titun lori awon oko irinna yi, je aseyorisirere to ye ki won gba ilu ati ijo fun. Minisita lori Isuna Owo, Simba Makoni lo se ifihan owo ori
na ninu eto isuna re ni osu kokanla odun to koja, igbese ti awon akegbajare nireti wipe yio se iranwo lati din idoti ku, sugbon ju gbogbo eyi lo, yio ru imo awon ara ilu soke lori idi ti o fi ye ki a mu ayika wa wa ni
mimo.
Igbese ni ona to dara niyi, biotilejepe awon ijiya na funrarawon ko to lati dena awon eniyan lati ma ba ayika
je laibikita. Toro to nsise fun Ajo Itoju fun Oro Ile Afirika (African Resources Trust) so wipe: "Ohun ti a nilo ni ona igbasekan to gbooro lara eyiti a ti ri eko ati ifojuwo awon oran ayika lona isedale. A ni lati so

oran idaabobo ayika mo igbe-aye ojojumo awon eniyan."
Iwadi Ajo Agbaye kan laipe yi ri wipe afefe ni Harare, olu-ilu Zimbabwe, lewu pupo fun eda eniyan lati ma
mi, eyi si waye latari eefin ti awon oko ayokele ilu na, ti a siro won si egberun lona irinwo, ntu jade lojojumo. Awon olupolongo lori ayika tokasi awon oko ayokele gegebi olugbedotijade to tobi julo lorile-ede

na, eyiti awon aloku ati itujade ile-ise isenkanjade nlanla powole girigiri. Panafrican News Agency

A ti kede Awon to gba Aami Eye ti Ajo Ile Europe fun Ise Iroyin 3mins. 19secs. Ajo Alasepo ni Kariaye fun Awon Onise Iroyin (International Federation of Journalists (IFJ) ti kede oruko
awon to gba Aami Eye Lorenzo Natali ti Igbimo Apapo Europe fun Ise Iroyin. Aami Eye Natali na, eyiti a fi oruko oloogbe Alakoso fun idagbasoke ati olupolongo fun awon oran eto eda eniyan so, ni a ma nfun
awon onise iroyin to nroyin lori ijoba tiwantiwa ati awon eto eda eniyan gegebi awon koko idagbasoke lodoodun.

Lodun yi aami eye onipokinni meji eyiti owo okokan je egberun mewa owo Euro -okan fun awon onise iroyin lati Ajo Apapo Europe, ati ekeji fun awon onise iroyin lati iha Gusu -ni won pin laarin awon olubori
marun to dayato. Awon olubori lati iha aye to sese ndagbasoke ni Atiya Achak Ulwisut ti Iwe Iroyin The Nation ni orile-ede Thailand ati Fariah Razak Haroon to ma nta awon iroyin re fun Iwe Iroyin Atigbadegba
ti a mo si Dawn ni orile-ede Pakistan. Aami Eye onipokinni ni ipele ti Ajo Ile Europe lo lo sodo Marco Bello ati Paolo Moiola ti awon mejeji nsise fun iwe iroyin Mondo e Missione ni orile-ede Itali ati Astria
Prange ti on na ma nta iroyin re fun Deutsches Allgemeines Sonntagsblatt.
Gegebi Aidan White, Akowe Gbogboogbo fun Ajo IFJ to nseto ifunni olododun na se so: "Awon nkan keekeeke yi nfihan wipe ise iroyin to le koko pelu ikosemose nko ipa pataki ninu fifi han bi awon ife-inu-rere

ti awon ikede eto eda eniyan se nfowoba aye awon eniyan. Awon onidajo na se ayewo finnifinni laarin awon iwe idije lati orile-ede merinlelogoji. Iwoye won lori gbogbo oran na ni wipe awon ajo iroyin, paapa
ni awon orile-ede to ti dagbasoke ni iha ariwa, gbodo fun iru ise iroyin yi ni ipo to dara." International Federaton of Journalists 3
3 Page 4 5
Vol. 11 No. 24 CHANGE Radio January, 2001.
4
Aye npadanu orisi meji ipinsiyeleyele Eran-Osin losoose. 10mins. Gegebi Ajo Agbaye fun Oran Ounje ati Ise-Ogbin (Food and Agriculture Organisation (FAO) se so, aye
aye npadanu orisi meji ipinsiyeleyele awon eran-osin to niyelori pupo losoose. Ninu iroyin to ko jade, o ni: "Awon itesi fun ekun ile Afirika banileru. Ipo ti awon eya eye wa tile buru pupo pelu bi iye awon eya eye
to wa ninu ewu iparun se lo soke lati idamarun ni odun 1995 si iko merinlelogun ninu ogorun ni odun 1999.
Awon awari yi ni o wa ninu atejade eketa ti "Itosile Eso Aye fun Ipinsiyeleyele Eran-Osin" (World Watch
List for Domestic Animal Diversity) eyiti ajo FAO jo ngbe jade pelu Eto Ayika ti Ajo Agbaye. Laarin ewadun to koja, ajo FAO ti se iranwo lati se akojo ifitonileti lati orile-ede bi adosan lori awon eya eran-osin

ati ti eye to fere to egbaa meta o le edegbeta, lara eyiti a ti ri maalu, ewure, agutan, efon, maalu-egan, elede, esin, emo, adiye, tolotolo, pepeye, ogbugbu, eyele ati ogongo paapa. Gegebi oro Keith Hammond,
Osise Agba kan ninu Egbe ti Oro Ajogunba Eya Eranko: "Laarin ogorun odun to koja, a ti padanu awon
eya bi egberun. Awon iwadi wa titun fihan wipe awon eya eran-osin ntesiwaju lati wa ninu ewu, ti idameta won si wa labe ewu iparun ni lowolowo yi."

Ibi Akojopo Ifitonileti ti Ajo FAO fun Awon Oro Ijogunba Awon Eranko ni ifitonileti lori orisi bi egbaata o le odunrun ati mokandinlogorin awon eya eranko ati eye. Ifitonileti lori iye akojopo wa fun orisi bi
egbaaji o le metalelogosan, lara eyiti orisi bi ojileledegberin ti parun ti orisi bi egberun o le odunrun ati marundinlogoji, tabi iko mejilelogbon ninu ogorun, wa labe ewu ipadanu ati iparun. Gegebi Hammond se
so, lati odun 1995, iye awon orisi eranko to ti wa labe ewu iparun ti losoke lati iko metalelogun ninu ogorun si iko marundinlogoji ninu ogorun, bi awon orile-ede ti nmu awon iwadi won gbooro si ti won si nmu
ifitonileti lori oro ijogunba awon eranko won ba akoko dogba. Ipo ti awon eye wa tile tun buru ju eyi lo,
pelu bi iye awon to wa labe ewu ki a padanu won se losoke lati iko mokanleladota ni 1995 si metalelogota ni odun 1999. O se afikun wipe "O banileru wipe bi a ko ba se ise doju aami, opo ninu awon orisi eran-osin

to wa labe ewu iparun (ti a siro si orisi bi egbaa kan o le igba ati marundinlogota) ni a le padanu won laarin ewadun meji to nbo. Bi imo ero tuntun lori eranko ti le tiraka lati se imudarasi orisi won to, ko seese
lati se imupadabo ipinsiyeleyele ti o ba ti sonu. Ipadanu ipinsiyeleyele wa titi aye ni."
O so wipe irokeke ewu to ga ju si ipinsiyeleyele eran-osin ni ikolo awon eranko lati awon orile-ede to ti dagbasoke si awon to sese ndagbasoke, eyiti o nyorisi imu eya bisi wonu tabi ropo awon orisi ti isedale. Bi
awon eniyan ni awon orile-ede to sese ndagbasoke si ti ro wipe awon orisi eya lati awon orile-ede to ti dagbasoke ni ibisi to ga ju, gegebi akojade na se so, Hammond ni isoro ibe ni wipe awon eranko yi wa ni
ibamu pelu bi awon orile-ede ti won ti wa se wa, won si ma nni wahala lati faramo ayika to ma nsaba ganilara to wa ni awon orile-ede to sese ndagbasoke. Awon ayika to ma nsaba le pupo to wa ni awon
orile-ede to sese ndagbasoke pelu afefe ile to gbona, to gbe, to si mooru pupo, nilo awon oro ijogun eya eranko ti a mu wa ni dogbandogba pelu won." Ni iha isale asale Sahara, awon orisi bi edegberin o le
mejidinlogoji ni a ti kosile lara eyiti bi iko meedogun ninu ogorun wa labe ewu. Panafrican News Agency

Ailefenukosibikan waye ninu Apero lori Iyipada Afefe Ile 6mins. 30secs. Apero lori Iyipada Afefe Ile to waye ni ilu Hague wo pale leyin ose meji idunadura to lekoko nitori awon
minisita ati awon asoju orile-ede ko le fenuko lori bawo ni a se le mu ki Akosile Ilana Ise Kyoto di lilo.
Won tun kuna lati fenuko lori bawo ni won si le mu ifowosowopo lori isuna ati imo-ero lagbara si laarin awon orile-ede to ti dagbasoke ati awon to sese ndagbasoke lori awon ilana imulo ati imo-ero to je ore

ayika.
Nigbati o nse apejuwe isuni re, Jan Pronk to je Alaga Apero ati Minisita orile-ede Netherlands, so wipe "o
je ohun to dojutini wipe awon olori oloselu ko le se aseyori ki won fenusi awon itoni fun idinku awon 4
4 Page 5 6
5
Vol. 11 No. 24 CHANGE Radio January, 2001.
itujade to nba ayika je, paapa nigbati awon eniyan ti ni awon ifojusona to ga pupo. Mo gbagbo pe ife-inu ti oloselu lati se aseyori si wa laaye, o si da mi loju wipe a o le tun korajo papo laipe ojo ki a si se asepari
adehun ti yio yori si awon imuse to munadoko lati se idari awon itujade ati lati daabobo awon orile-ede to le tete ni ifaragba julo kuro lowo ikolu imorusi-aye.

Apero na ni itesiwaju nipa sise ilanasile akopo iranlowo owo ati ififunni imo-ero to se iranlowo fun awon orile-ede to sese ndagbasoke lati lowosi ise ni kariaye lori iyipada afefe ile. Sugbon awon oran oloselu to
se koko lara eyiti a ti ri ilana pasipaaro itujade ni kariaye to je "ohun imusese fun idagbasoke mimo", awon ilana fun isiro idinku itujade lati inu awon "koto iwole si" fun eefin oloro bi awon igbo, ati ilana fun ifaramo
awon ilana gbogbo -ni won ko le yanju won laarin akoko to wa.
Oludari Alase Eto Ayika ti Ajo Agbaye so wipe "Apero na se ifojusi isepataki ati isoro lilo sinu awon oro
aje ti eefin oloro won lo sile. O dara ki a dawo awon ifikunlukun na duro ki a tun bere ti o ba ya ki a le se aridaju wipe ona to dara lo siwaju ju ki a gbe igbese ni kanjukanju lo si ibiti to ye". Adehun ijuwolefunraeni

ti ogbeni Ponk filele ni won yio fi ranse gegebi ilowosi si ipade kefa Apero awon Egbeegbe si Apero nla ti Ajo Agbaye fun Ilana lori Iyipada Afefe Ile. O seese ki a se awon ipade yi ni opin osu karun ni ilu Bonn to
je ibujoko fun ile-ise fun iyipada afefe-ile. This Day

Apero nlo lowolowo ni orile-ede South Afrika lori awon Kemikali oloro 8mins. Apero karun ti Ajo Agbaye fun Adehun Kariaye, eyiti yio pese anfani ti iru re sowon pupo lati gbesele
patapata tabi ki won se idinku repete lori isejade ati ilo awon kemikali to lewu taara si eda eniyan, waye ni
ilu Johannesburg ni osu kejila odun to koja. Awon amoye so wipe awon oludunadura ninu ipade fun adehun kariaye lori Awon Kemikali Oludoti Igbagbogbo (Persistent Organic Pollutants (POPs) lero lati

fenuko lori adehun ti yio se imukuro mejila ninu awon kemikali to lewu julo ni aye. Ipade na tun wa fun igbekale awon ilana imulo imukuro awon miran sii, ki o si pese iranlowo owo ati imo-ise fun awon orile-ede
to sese ndagbasoke lati ran won lowo ki won le gbese lo si awon ohun elo miran ti ko lewu.
Sugbon Ajo Akojo Owo ni Agbaye fun Iseda Aye (World Wide Fund for Nature (WWF) so wipe lati le mu ki adehun na sise, imukuro, ki ise isakoso, awon kemikali ati egbogi na ni o gbodo je koko ifojusi, ni
idapo pelu iranlowo owo ati imo-ise fun awon orile-ede to sese ndagbasoke . Gegebi oro Clifton Curtis to je Oludari fun Eka ise Ajo WWF lori awon kemikali oloro ni Agbaye, "anfani niyi fun awon oludunadura
lati duro gboin tako ibaje lati owo awon kemikali oloro ki won si se asepari adehun kariaye pataki kinni ninu egberun odun titun yi".

Awon POP je awon kemikali to ma nyoro diedie ninu ayika, to ma nlo fun egbegberun ibuso ninu afefe ati omi, ti o si loro pupo fun eda abemi egan ati eda eniyan. A so wipe awon lo nfa aleebu to ma nba ikoko
waye, arun idibaje eya ara ati awon isoro idagbasoke. Sugbon isoro pataki kan ni wipe a ma nri awon oludoti na ninu ago ara gbogbo okunrin, obinrin, omode ati eranko to wa lori ile aye.

Orile-ede South Afrika ti mo awon POP bi melo kan ti won gbodo mukuro. Lara awon eleyi ni ati ri awon oogun ipakokoropaeku ati kemikali bi aldrin, endrin, chlordane, hexaclorobenzene, mirex, toxaphene
ati heptachlor,
gbogbo awon ti ati yo oruko won kuro ninu iwe ijoba. Yato si ikolu ti ko dara ti POP ma nni lori ilera ati ayika, won tun nni ikolu lori oro aje ati isowo. Imukuro awon igbejade ti a ko lero re bi
awon dioxin, furan ati PCB, ti o je awon nkan to njade lati inu awon ilana isenkanjade na ni o wa lori akosile fun imukuro. 5
5 Page 6 7
Vol. 11 No. 24 CHANGE Radio January, 2001.
6
Ajo Alasepo ni Agbaye fun Awon Iloropo Ijonkannina (Global Alliance for Incineration Alternatives (GAIA) gbagbo wipe a gbodo mu ijonkannina kuro ni isediedie fun adalu awon iloropo, lara eyiti a ti ri atunlo, ati
igbedide awon imo-ero ti ko lewu lati fi se kokari awon egbin oloro ati ti isegun. Asepo kariaye to fokansi idekun jijo awon egbin nina ni ati fi lole ni orile-ede South Afrika lati se pekinreki pelu oro asokagba laarin
awon orile-ede. O ju awon adorin ajijagbara agbegbe fun ayika ati ilera ara ilu lati orile-ede metalelogun lo ti parapo lati se igbelaruge awon iloropo fun ijonkannina ninu igbiyanju lati daabobo ayika ati ilera ara ilu.

Awon egbeegbe afenifere ayika fi ehonu won han ni igba isipade apero na, won si kepe fun adehun kariaye to munadoko lati se imukuro die ninu awon kemikali oloro to lewu julo ninu imo eda eniyan.
all Africa. com
A nilo Idaabobo ni Kariaye fun Awon Eto Eda Eniyan 13 mins. Gegebi iwe iroyin ti a mo si Eso Eto Eda Eniyan se so, gbigbooro awon isoro eto eda eniyan lagbaye lode
oni ti koja ipa awon ajo kariaye lati koju won. Ninu iwadi re olodoodun lori ipo ti eto eda eniyan wa kakiri
aye, ajo na kepe fun ilana "itopo aye to lagbara sii" lati le koju awon italaya wonyi.

Iroyin Agbaye ti Eso Eto Eda Eniyan fun odun 2001, eyiti a gbe jade siwaju Ojo Eto Eda Eniyan ni ojo kewa osu kejila odun 2000, se apejuwe idagbasoke eto eda eniyan laarin odun to koja ninu adorin orile-ede.
O tun se itupale idahunsi awujo agbaye si awon iteloju to le si eto eda eniyan. Isowo kariaye ati
idoko-owo gbodo se ipese idaabobo to ga sii fun eto eda eniyan, gegebi Iroyin Agbaye ti Eso Eto Eda Eniyan na se so. Iroyin na tesiwaju lati tanmo wipe Ajo Agbaye nilo awon oro to po sii lati le se iranwo lati

fopin si rogbodiyan ologun ati isoro awon asasala.
Ilana idajo ododo ni kariaye to sese nyoju yi, lara eyiti ile-ejo fun iwa odaran ni kariaye wa, gbodo gba
atileyin to nipon sii lati odo orile-ede gbogbo, ati orile-ede Amerika. Gegebi Kenneth Roth to je oludari alase ti Eso Eda Eniyan se so, "Aye ko ni ipa ati agbara to to lati koju awon oran eto eda eniyan to nfe

amojuto kariaye ni kiakia ni akoko tiwa. A ni lati se atunse awon ikuna lori iru ajo wonyi". Lara awon rogbodiyan ti a koju ninu iroyin na ni ti orile-ede Russia ati ihuwasi re ninu ogun to ja ni orile-ede Chechnya
pelu aibikita to ga pupo fun ijiya awon ara ilu. Biotilejepe Ajo Agbaye ba orile-ede Russia wi, orile-ede na
ko ni ifaragba ijiya kokan latari ihuwasi re ni Chechnya.

Awon iwa ika titun lo tesiwaju ninu ogun abele olodun mesan ni Sierra Leone biotilejepe won mu ogunna gbongbo ogagun awon olote kan. Akitiyan ajo agbaye lati se ifilole ile-ejo pajawiri lori awon iwa odaran
ologun ni ko yara to bo ti ye. Awon ologun ni orile-ede Columbia ko ti ija okun to so on ati awon
alafarajo-ologun ti a dalebi fun opolopo iteloju eto eda eniyan to buru pupo. Idariji lori oran eto eda eniyan ti Aare Clinton fi sinu "Eto Columbia", opo yanturu iranlowo yio fere se aridaju ilosoke awon iteloju na.

Ijoba orile-ede Indonesia ko iti da awon ologun iha West Timor to se isekuse orisirisi ni East Timor ni odun 1999 lekun. Awon olote adihamora ogun ni Ambon ati Aceh ndan ase ijoba ara-ilu lori awon ologun wo.
Orile-ede Israeli dahun si iwode awon omo-ile Palestine to nfi ehonu won han lori ijegabale ologun lori awon agbegbe kan ni West Bank ati Gaza pelu agbara to saba ma npoju ti ko si bikita, to si tipa be yori si
opolopo awon ara-ilu to faragbogbe.
Bi ayeye adota odun ile-ise Ajo Agbaye fun Awon Asasala-ogun (United Nations High Commission for
Refugees (UNHCR) ti nsunmo ni ojo kerinla osu kejila odun 2000, die ninu awon orile-ede ti ko dagbasoke rara lo nru eru itoju awon asasala-ogun. Awon orile-ede to ti dagbasoke to se ifilole Ajo UNHCR ni

iberepepe gbodo gbe eru to poju nipa inawo ki won si silekun won sile fun awon asasala-ogun. 6
6 Page 7 8
7
Vol. 11 No. 24 CHANGE Radio January, 2001.
Eso Eto Eda Eniyan so wipe oro-aje aye ti gbe opolopo ola, anfani ati ise jade. Sugbon awon ifiehonuhan ni awon opopona laarin odun to koja ni Seattle, Prague, Washington D. C ati nibomiran nse afihan ikominu
to ngbile lori awon aisedeede to wa pelu oro aje na gegbebi ilosoke ninu iye awon eniyan to ngbeninu osi
ati ilokulo awon osise to nlo kaakiri. Ninu ariyanjiyan to ti pin si meji lori ilujarawonaye, eto eda eniyan funni ni ilana pataki to si ni ileri rere lati koju opolopo awon isoro gegebi itesi awon ijoba ati awon ajo ijoba

die lati figagbaga nipa jijere ninu ifiagbaratemole.
Nibi ise, ibowo fun ominira lati ba elomiran sepo gbodo gba awon osise laaye lati parapo ninu egbe osise
bi won bafe lati se imudarasi ninu owo oya ati ipo ati iriri ibi ise won. Bakanna, igbesele iyasoto ni a gbodo lo lati se aridaju wipe awon ti a ti sati si apakan lati ojo pipe wa na je eso ise owo won lori aleefa kanna

pelu awon yioku.
Ni ipele ti awujo, ibowo fun awon eto awujo ati ti oloselu, lara eyiti eto lati yan ijoba eni wa, ni o gbodo se
aridaju wipe awon otosi ni awujo na ni ohun ninu idari idagbasoke awujo ati ti oro-aje orile-ede won, lara eyiti a ti ri awon oran to je mo afikun owo oya to kereju, idaabobo awon ajafitafita ninu egbe osise kuro

lowo igbesan, igbofinro, igbesele iyasoto, isediwon awon ise to nse iwakusa, tabi sise aridaju wipe a se idoko-owo ni ibamu pelu awon eto awujo. Itenumo lori awon eto yi ko ni se aridaju wipe owo oya yio wa
ni awon ipele kan pato, tabi wipe ipo bayi ni ayika ile-ise yio wa, tabi awon ilana ise kan pato. Bena ni ko
le mu aidogba ninu agbara idunadura kuro tabi ko pa gbogbo aidogba awujo re. Sugbon igbowo awon eto yio fi aye sile fun awujo to jafafa ninu eyiti a le gbo ohun awon ara ilu ki a si fun awon eniyan jakejado

aye ni anfaani lati ni enu ninu igbese ati idari idagbasoke kakiri aye. Human Rights Watch

Ajalu ba Awari ti yio wonu iwe itan je 8mins. Won ti se awari eja coelacanth oni-irinwo odun ni etikun St. Lucia ni agbegbe Kwazulu Natal ni orile-ede
South Africa. Eja na, eyiti a pe ni eranko aye-gbaani ti inu ibu -nitori awon iwo ati iriri re to je ti aye igbaani -ni won ti ro wipe o ti parun patapata tele ki o to di wipe won ri oku eja kan ninu awon oko apeja
nla kan ninu okun agbegbe East London ni South orile-ede South Africa ni odun 1939. Awari na jade
gadagba loju awon iwe iroyin kakiri aye. Awon omuwe to nlo irin-ise fun mimi labe omi mookun lo sabe omi jinle bi iwon mita marundinlogofa nibiti won ti ya aworan fidio, ti iru re ko sele ri, ti awon eja coelacanth

mefa -ti o gun to iwon mita meji -nitosi ibi isinmi afe na to gbajumo pupo.
Awari iyanu yi ni ibere ose yi ni o baje nigbati okan ninu awon omuwe na, Dennis Harding, eni odun
merinlelogbon, ku nigbati o nya aworan eja na. Omuwe keji, ti a ko daruko re, na bo si sinu idaamu to ga ti won fi ni lati gbaa la. Ni odun meji seyin, omuwe miran, Riaan Bouwer, ku ni agbegbe kanna nigbati o

nwa eja na kiri.
Amoye kan nipa eja coelacanth ni orile-ede South Africa, Dr. Phil Heemstra, to wo aworan fidio na, ti
jerisi wipe coelacanth ni awon eja na. Ni osu kejila odun to koja, won ko oruko St. Lucia sile gegebi Ibudo Ajogunba Aye kinni ni orile-ede South Africa. Awari to sese yoju yi ni a lero wipe yio fun ilu na ni alekun

to ga ninu irin-ajo aje. Awon eja coelacanth na, to ti ruula ni iran-iran bi ogbon milionu, lo je apeere ikeyin ti awon eda abemi ti a npe ni crosspterygians, ti irun imu won to ni eran lara bi apa ati ese ni o fere je
awasiwaju awon apa ati ese.
O je opin ila ti awon onimo ijinle sayensi gbagbo wipe o se okunfa igbedide awon eda abemi akoko ti a mo si tetrapods tabi awon eda abemi elese merin to ni eegun eyin to si ngbe ni ori ile. Awari eja ara-oto na 7
7 Page 8 9
Vol. 11 No. 24 CHANGE Radio January, 2001.
8
ninu omi orile-ede South Africa ni odun 1939 ni a ka si dogbandogba pelu ki eniyan ri eranko afayafa omiran aye igbaani ti a mo si dinosaur laaye. Onimo ijinle sayensi kan ni orile-ede South Africa, J. L. B.
Smith, nigbati o gbo iroyin wipe won ti ri eja na nitosi awon erekusu Madagascar ati Comoros to wa ninu okun nla India, le iwe ikede kakiri awon erekusu na ti o fi so wipe on yio fun enikeni ti o ba le fun on ni iru
eja na kan ni ogorun poun. Akitiyan re ko mu ere kokan wa titi di odun 1952 nigbati won tun mu eja coelacanth keji ninu okun nitosi erekusu Comoros kan to nje Anjouan.

Ijoba orile-ede South Africa ya Smith ati egbe re ni oko baalu ologun Dakota kan lati fo lo si erekusu na ki o si gba eja na. Eja coelacanth ti won nmu beresi po si ni iye titi di odun 1980; opolopo won ni won fi
ranse si awon ibudo itoju awon ohun isenbaye ati awon odo eja agbelero fun iwadi; Ominu ko awon onimo ijinle sayensi wipe ninu ere ije ri awon apeere eja na fun iwadi, awon nfi awon eya na sabe ewu iparun. Titi
di ose yi a ko iti ri eja coelacanth miran ninu omi orile-ede South Africa. Eya marundinladoje eja coela-canth lo wa ninu akosile awon eri awon eda abemi aye igbaani sugbon eya kansoso ni a mo pe o si wa,
okansoso na si wa labe ewu iparun to ga. Panafrican News Agency

Ajo Agbaiye saami Ojo Arun Kogboogun Eedi 7 mins. ni Agbaye bi iye ikolu arun na se nlosoke si i
Awon okunrin gbodo yi ihuwasi won lori ibalopo pada ti aye yio ba fi dekun itankale apani ajakaye-arun
kogboogun eedi, gegebi Ajo Agbaye se kilo nigbati o nse ifilole ojo Arun kogboogun Eedi aye. Kokoro-arun na ti la iha gusu Afrika koja, o si ti ndi ile Asia mu sinsin, o si nse irokeke lati tan laarin awon orile-ede

to loro ti won le ra awon egboogi agbejako kokoro-arun to sowon pupo. O ju awon eniyan bi milionu merindinlogoji lo jakejado aye to ni Arun Eedi tabi kokoro-arun to nfaa lara, Ajo Agbaye si so wipe awon
ogun milionu eniyan mi i si ni arun na ti pa kakiri aye. Arun na to ma nkolu ilana igbogunti-arun ninu ara, ni
o ma nlo lati odo enikan si enikeji nipa isanwonu-ara-won oje ara, paapa ni akoko ibalopo, ifi-eje-sini-lara ati ipinlo abere laarin awon to nlo egboogi oloro. Ile Afrika lo ni ikolu to buruju sugbon ile Asia ati Russia

na ti dojuko ki ikolu na di ajakale-arun ni odo won.
Ipolongo ti odun yi ti a pe ni "Awon okunrin mu Iyato wa," ni a nlo lati fi ranse si awon okunrin ati awon
odomokunrin wipe biba opolopo obirin lopo, ibalopo lai lo apo ato ti mo si Condom ati aisi itoju ilera ni awon ilana fun ajalu. Ni opolopo igba ikolu si okunrin kan ma nyorisi ipade gbemigbemi fun awon obirin

ti o je pe awon ni won le tete ni ifaragba julo lati owo kokoro-arun HIV, gegebi Ajo Agbaye fun igbejako Arun kogboogun Eedi (UNAIDS) se so.

Agbenuso kan fun Ajo UNAIDS so wipe, "Ifojusi laye ni wipe awon okunrin gbodo ni agbara, ki won ni okan, ki won laya ki won si ni okun-inu. Die ninu awon ireti yi ni o nyorisi ona irero ati ihuwasi to nfi ilera
ati iwalalafia awon okunrin ati awon onibalopo won sabe ewu," eyi ni oro ti agbenuso ajo na so nigbati a si ti gbo pe Akowe-agba fun Ajo Agbaye, Kofi Annan na so wipe "Awon okunrin le mu iyato wa ...... nipa
bibikita, nipa sisa fun ewu ati didojuko oran Arun Kogboogun Eedi lokunkundun". Iroyin kan ti a gba
jade lati odo Ajo Agbaye ni ale ojo Eedi ku ola so wipe ireti pataki to wa fun dide oju aami ifojusi na ni didaduro itankale arun na si iran to nbo nipa ipolongo to lagbara lori eko nipa ibalopo ati igbelaruge ilo apo

ato (condom).
Ojo Arun Kogboogun Eedi ni Aye jeyo lati inu ipe Ipade Agbaye ti Awon minisita fun Ilera lori Awon Eto
fun Idena Arun kogboogun Eedi ni odun 1988. Lodoodun, on ni ojo kansoso ti ajosepo ise ni igbejako Arun kogboogun Eedi nwaye.

CFC 8
8 Page 9 10
9
Vol. 11 No. 24 CHANGE Radio January, 2001.
Awon Olori Ile Afrika se atunso Ifaramo won 11mins. si Igbogunti Arun Kogboogun Eedi
Awon olori ile Afirika ti se atunso ifaramo won lati gbejako kokoro-arun HIV ati Arun kogboogun Eedi
nigbati nwon nsoro ni ojo to kehin ninu Apero keji lori Idagbasoke Ile Afirika ninu osu kejila odun to koja. Laarin ifikunlukun lori awon italaya kokoro arun HIV ati Arun Kogboogun Eedi si idagasoke ile aye na,

awon olori na tenumo pataki ipa ti imugbogbo-eniyan orile-ede kopa nko, bi ijoba se nsiwaju ipolongo ni idojuko idaniloro ajakale-arun na. Aare orile-ede Uganda, Yoweri Museveni gbagbo wipe iru ipolongo
be yio mu "idaniji to tobi ju to si pariwo ju lori awon ewu arun na dani". Apero awon olori orile-ede ati
ijoba na ninu eyiti olori kokan ka oro akosile tire, ni Akowe-agba Ajo OAU, Salim Ahmed Salim se alaga re. Akowe agba na so wipe ajakaye-arun Eedi na ti di italaya to ga si ise olori gegebi akori ipejopo na se

toka. Orile-ede Ethiopia, Botswana, Rwanda, Malawi, Chad ati Senegal na lo asiko tiwon lati so ifaramo orile-ede won lati dekun Arun kogboogun Eedi.

Olori ijoba orile-ede Ethiopia, Meles Zenawi, so wipe ko si idi ti ile Afirika ko le se aseyori ninu ohun ti o sapejuwe re bi ogun fun ojo iwaju ile aye na. O ni, "ohun ti a nilo ni ikopa to munadoko lati odo gbogbo
origunrigun awon eniyan wa ninu gbogbo eka igbejako ajakaye-arun na" Museveni, ti a ti gboriyin fun gegebi olori ile Afirika kinni to gbe igbese asiwaju ninu itako ajakaye-arun na, so wipe nipa kikeboosi nipa
Arun kegboogun Eedi ninu awon apejo oloselu, nipase igbesafefe lori ero asoromagbesi ati amohunmaworan
ati ninu awon apejo agbegbe, orile-ede Uganda ti mu ki gbogbo omo orile-ede na mo nipa ajakaye-arun na.

Aare Mogae ti Botswana so wipe a gbodo jirebe si "awon alabasisepo wa" ninu awon orile-ede to ti dagbasoke ni aye lati parowa fun awon ogunna gbongbo ajo oloko-owo elegboogi lati jeki owo awon
egboogi agbejako Arun kogboogun Eedi lo sile, ko le se ra fun awon omo ile Afirika. Aare orile-ede Rwanda so nipa Igbese Awon Adagun Nla lori Arun kogboogun Eedi ti a gbekale ni odun 1999 ninu eyiti
awon orile-ede to wa ni ekun na nfowosowopo ti won si nse ajose akitiyan lati gbejako ajakale-arun na. O tesiwaju lati woye wipe biotilejepe iko meji pere ninu ogorun awon omo orile-ede Rwanda lo ni ikolu
arun na leyin ipaeyarun to waye ni odun 1994 isiro na ti lo soke si iko mokanla ninu ogorun ni odun 1998.
O se afikun wipe ijoba on npese egboogi agbejako Eedi ni owo to lo sile fun awon to ni ikolu arun na. Igbakeji Aare orile-ede Malawi so wipe ilosoke ati maa ri awon egboogi agbejako-Eedi se koko, o si

gbodo je ohun agbese fun awon olori ile Afirika, oro yi na ni iwe ebe awon odo to pese ninu apero na tun so. O wa so siwaju, "A gbodo gbe ipolongo dide fun ifagile gbese, ki ise iderun gbese" bi o se ntokasi
wipe gbese eyin odi iha isale asale Sahara ti di bilionu (milionu lona egberun) igba o le metadinlogbon owo
dola Amerika nisisiyi.

Aare Yamassoum ti orile-ede Chad so fun apejo na wipe iye awon eniyan to ni arun na ni orile-ede on ti lo soke lati eniyan meji pere ni odun 1986 si egberun mejila. O tile so wipe tente ori apata yinyin ni eleyi
paapa nitoripe awon amoye ti siro iye awon alaisan Eedi ni Chad si lati oke meji si oke meji ati aabo. O ni,
"A wa si apero yi lati ko lati inu iriri awon elomiran ninu igbejako arun na."

Aare Niasse ti orile-ede Senegal kepe fun ise to "nipon to si je ajumose" ni idojuko ajakaye-arun na. Akowe-agba ajo OAU so wipe o se pataki wipe ki ise apejo na de odo "awon eniyan ile Afirika ati awon
alabasisepo wa ti a jo wa ninu ijakadi ni kiakia". O ro awon olukopa lati fi oju won si "ikede alajose ti
apejo na yio se ki won si fi Addis Ababa sile pelu ifaramo patapata lati mu lo. "Salim so wipe ikede ajumose na ni won yio mu lo si ipade gbogboogbo pataki ti ajo OAU lori Arun kogboogun Eedi ati awon

oran miran to ro mo, eyiti yio waye ni ilu Abuja, orile-ede Naijiria" ni osu kerin odun yi. CFC 9
9 Page 10 11
Vol. 11 No. 24 CHANGE Radio January, 2001.
10
Gbigbogunti Arun kogboogun Eedi ni Ile Afirika 8mins. 13secs. O ye ki a koju ajakale-arun kokoro-arun HIV ati Arun kogboogun Eedi bi igbati eniyan ba njagun nipa
mimu idahunsi arun na yara si ati lilo gbogbo awon olukopa pataki ni ipele ti orile-ede ati ti kariaye. O se pataki lati da ajosepo otito sile pelu gbogbo awon ti oran na kan, paapa awon agbegbe, awon ebi ati awon
eniyan kokan, ti a gbodo fi agbara fun lati koju awon oran to je mo kokoro-arun HIV ati Arun kogboogun Eedi. Nitorina o di dandan fun awon ajo lati topase ona miran patapata si isoro kokoro-arun HIV ati arun
kogboogun Eedi niti iyipada nipa iwa ati ti ajo.
Awon wonyi ni ifenuko to waye ninu Apero fun idagbasoke Ile Afirika (African Leadership Forum (ADF) ti odun 2000 to pari laipe yi. Apero na ti a pe ni "Kokoro arun HIV ati Arun kogboogun Eedi. Italaya

olori to ga julo" ni Igbimo Ajo Agbaye fun oro Aje Ile Africa (ECA) seto re. Awon olukopa ninu apero na fenuko wipe ija ni idojuko kokoro-arun HIV ati Arun kogboogun Eedi gbodo gba anfani lati inu awon iriri
ogun. Awon agbegbe mo ona lati tako ajakale-arun na, o si ye ki a fun won ni anfaani lati se be. Awon ona ti ibile ati eyiti ki ise ti ibile ni a gbodo lo lati ko owo jo, awon ijoba si gbodo se iyasoto awon oro abele lati
ba ajakale-arun na ja.
O ye ki awujo kariaye se atunse ninu awon eto imulo won ati koju isele bi ti ogun yi. Ijirebe lo sodo Banki Agbaye lati ma se ayewo awon ohun to je mo iwa omoluabi ati iwa rere to ro mo eyawo fun awon ise

agbese lori Arun kogboogun Eedi, awon onsoro bi melo kan si kepe fun ifagile gbese ati iyipada awon eyawo na si ebunwo. Won ro awon ijoba lati se igbekale awon ona igbagbeowosile ti yio jeki igbeowo fun
awon agbegbe rorun. Ise pataki ajosepo ni kariaye ni idojuko Arun kogboogun Eedi ni ipele ti orile-ede ni won tenumo, won si fojusi awon oran to je mo imusese wonyi. Ilowosi awon agbegbe, ajopin ifitonileti,
ifuniagbara awon eniyan to ni Arun kogboogun Eedi lara (People Living with Aids (PLWA), bi o se ye ki awon obirin ati agbegbe se aridaju agbero, itoju ati atileyin ati ona lati ma ri egboogi fun awon to ni arun
kogboogun Eedi lara.
Won tenumo bo se ye lati kuro ninu oro asotunso si ise sise lati ibere de opin apero na. Gbogbo awon ti oran na kan ni won fun ni iwuri lati tubo teramo idahun won si ajakale-arun kokoro-arun HIV ati Arun

kogboogun Eedi. Opolopo itesiwaju ni o ti sele ni awon ipele ti orile-ede ati ni kariaye lati igba ti a se ifilole Ajosepo Kariaye ni idojuko kokoro-arun HIV ati Arun kogboogun Eedi ni osu kini odun 1999. Koko
awon aseyori ni ipele ti kariaye ni imulowosi ni awon ipele to ga ju niti oloselu. Fun apeere, oro nipa Arun kogboogun Eedi waye ninu ipade Igbimo Abo ti Ajo Agbaye nigbati Akowe-Agba se ifilole Ajosepo
Kariaye ni idojuko kokoro-arun HIV ati Arun kogboogun Eedi ninu osu kesan odun 1999. Ilosoke ti wa
ninu akojo oro lati odo awon ti oran na kan ni ipele ti kariaye. Ni awon ipele ti orile-ede idasile Ajosepo kariaye ni idojuko kokoro-arun HIV ati Arun kogboogun Eedi ti yorisi ilosoke ninu ife-inu ati ifaramo ti

oloselu, imudarasi awon ilana igbesese, ipinkiri idahun ti orile-ede si awon ipele agbegbe ati adugbo, ati ilosoke ikojo oro lara eyiti a ti ri awon ona titun lati fi ko owo jo.
CFC
Ile Afirika npongbe fun Ijoba Tiwantiwa 13mins. Awon eniyan mi ni orile-ede Ghana ma nsoro kan: ori kansoso pere ko to lati fi se ipinnu. Eyi ma nsaba wa

sokan mi nigbati mo ba gbo ti awon eniyan ba so wipe ijoba tiwantiwa sajeji si ile Afirika tabi wipe awon omo ile Afirika ko "iti setan" fun ijoba tiwantiwa. Lotito, awon awujo ile Afirika lati abule lo soke, lati
isedale wa, ni won ti nse ipinnu lori ona igbe aye won nipase ifikunlukun laisi idalowo kokan, fifi pelekutu gbe ero gbogbo sori osunwon titi ti gbogbo eniyan yio fi fenu ko sibi kan.

Nitorina, awon omo ile Afirika ni opolopo eko lati ko lati inu asa ibile won ati nkan lati fi ko awon elomiran nipa itumo otito ati emi ijoba tiwantiwa. A ni lati mo wipe ohun to ro mo ijoba tiwantiwa koja wipe tani tabi
egbe wo ni o ni atileyin to poju. Eyi paapa ko tile rorun gegebi okan ninu awon orile-ede onijoba tiwantiwa
to saseyorirere julo se fihan wa. Sugbon awon isoro orile-ede Amerika ko gbodo mu iyemeji kokan wa 10
10 Page 11 12
11
Vol. 11 No. 24 CHANGE Radio January, 2001.
lori iwulo ijoba tiwantiwa funrarare. Dipo eyi, won nran wa leti bi o se se pataki to wipe ki a di ibo laarin idije to gbooro latari awon ajo ati igbe aye. Ijoba tiwantiwa da lori imu-ofin-bori-laarin-awujo, nitoripe bi
ko ba si ibowo fun ofin, ko seese lati di ibo ti ko ni idanilowoko, ti a seto re laisegbe, tabi lati yanju aawo nipa ilana idibo na.

Beeni, ijoba tiwantiwa nse itoka si ijoba awon to ba poju sugbon eyi ko jasi wipe awon ti ko to nkan na ko gbodo ni ohun rara ninu awon ipinnu. A ko gbodo pa ohun awon ti ko to nkan mole. Awon ti ko to nkan
gbodo ni ominira lati so ti won ki awon eniyan le gbo ti apa mejeji ki won to pinnu tani o tona. Bawo ni awon eniyan se le ko nipa awon imo na? Ni ipele ti abule won le ko taara, ni ifojukoju. Sugbon ninu awujo
ode oni to po lo yanturu, awon eniyan gbarale awon orisun iroyin. Ki idibo kan to leto, awon egbegbe ati oludije orisirisi gbodo ni aaye ni dogbandogba si awon orisun iroyin. Agbara ijoba tabi agbara owo ko
gbodo tumo si wipe egbe kan ni anfani lati rojo tire nigbati a du omiran ni anfaani yi. Awon ajo iroyin
gbodo ma fi gbogbo ipa wa otito jade nitori awon eniyan ilu, ki won si ni ominira lati soo bi won se rii. Nigba pupo, paapa ni akoko rogbodiyan, eyi na nkepe fun onise iroyin lati fi ara re sinu ewu gidi. Opolopo

ti padanu emi won ninu wiwa otito. A je won ni gbese to tobi pupo. Ju be lo paapa, a je awa funrara wa ni gbese lati fun won ni idaabobo to dara sii. Anfaani wa ati ominira wa ni won ngbero.

Ninu awon orile-ede to ni ijoba tiwantiwa to ti balaga, awon egbegbe ma nlo lati inu ipo agbara si ipo atako, bi ero awon ara ilu ba ti nyi, awon ti ko nkan a si ma di awon to poju. Sugbon ki ise gbogbo awon
awujo lo ri bayen. Ki ise gbogbo awon ti ko to nkan lo je wipe awon to wa ninu re ni awon ti oro won ko
ta ni awujo mo. Opolopo lo je awon ti ko to nkan nitooto -awon eniyan to je wipe ni ona kan won je egbe oto, eyiti a le damo nipa eya, awo, isedale tabi igbagbo. Bi a ba da egbe oloselu sile lori ilana awon

idanimo egbegbe bayi, idibo ninu eyiti eniti o ba bori lo ni gbogbo nkan ko fun awon ti ko to nkan ni aabo kokan rara. Awon ti ko to nkan to ba wa ninu ijoba ko ni fe padanu agbara na, besi ni awon ti ko to nkan
ti ko ni agbara ko le ni ireti lati gba agbara.
Ijoba tiwantiwa le sise ti gbogbo egbegbe to wa ninu awujo kan ba ni imolara wipe awon je ti awujo na awujo na si je ti awon. Nigba pupo eyi tumo si wipe a gbodo se aridaju, lona kan tabi omiran, wipe awon

ti ko to nkan ni a fun ni ipin agbara lailai. Ni awon ibi die, a le se eyi nipa ipinkiri ase, ti o fi je wipe awon ti ko to nkan ni ipele orile-ede le gba agbara agbegbe, ni awon ekun ti won ti poju. Nibomiran, a le se e
nipa fifun awon ti ko to nkan ni awon ipo asoju ninu ile igbimo asofin ni ipele ti orile-ede tabi ti eka isakoso ijoba tabi mejeji. Ohun to se pataki ni abajade, ki ise bawo ni a se see.

O rorun lati fi awon ilana be lele sugbon ko rorun lati mu won se, paapa ni orile-ede ti o sese kuro ninu rogbodiyan, tabi ti awon eniyan re je ojulowo talika tabi awon ti ebi npa gidi. O ma nrorun fun awon to nfi
ipa gba agbara lati lo iru awon eniyan to ba wa niru ipo bayi nigbati won ba njiyan wipe eto ofin ilu je igbadun olowo ti orile-ede to talika ko ni anfaani re. Emelomelo ni a ti ngbo iru ariyanjiyan bayen. "Ijoba
tiwantiwa bere pelu ounje aaro," tabi "ikun ti ebi npa ko reti gboran". Sugbon leralera ni a ti kogbon,
paapa ni ile Afirika, wipe ikun awon eniyan ko le kun lati owo awon olori to ba ko lati fi ara won sile fun idajo awon eniyan. A ti mo wipe ijoba tiwantiwa bere pelu ounje aaro -wipe a gbodo pin agbara ninu ile

laarin awon obirin ati okunrin ati ni oke lohun ni awon ipele to ga julo ni orile-ede, ati paapa ninu ilana kariaye.

Iteloriba ki ise ifiropo osi. Bena si ni idagbasoke ki ise ifiropo fun ominira. Osi ati iteloriba ma nlo lowoowo ni, nigbati idagbasoke nitoto jasi ominira kuro ninu mejeji. Iran temi ni ile Afirika ti keko, lona to
lera, wipe ko si orile-ede to to so wipe on nse ijoba tiwantiwa, ti ko ba fun awon eniyan ni ona abayo kuro ninu osi, ati pe ko si orile-ede to le dagbasoke fun iwongba ti aba du awon eniyan re ni agbara.

Kiko awon orile-ede ile Afirika ti je ijakadi olojo-gbogboro ni idojuko osi, ainiimo, arun ati rogbodiyan. Ko yanilenu wipe ijoba tiwantiwa ni ile Afirika ti ni opolopo ifaseyin. Ohun to yanilenu nibe ni orungbe to 11
11 Page 12 13
Vol. 11 No. 24 CHANGE Radio January, 2001.
12
lekoko to si npo sii fun ijoba tiwantiwa ti awon omo ile Afirika fihan, igboya alailegbe won lati sorikunkun si ijoba ateniloriba, ati aseyori si rere won, ni opolopo orile-ede, lati fi ake kori wipe ijoba gbodo ma siro
ise iriju re. Iran mi ri ala ominira re se, sugbon ala wa lori ijoba tiwantiwa tuka yanga. A dupe lowo Olorun wipe a wa laaye lati ri ijoba tiwantiwa to ntan ka ile Afirika lekan si lode oni, to si nfidi mule.
Akowe Agba, Ajo Agbaye kofi A. Annan Ghana Mail
A ti gbo Iye awon olufaragba kokoro-arun Ebola ti di irinwo 4mins. 5secs.

Iye eniyan ti kokoro-arun Ebola apani ti kolu ti to irinwo, lara eyiti ogojo ninu won ti ku lati owo arun na to nyara ran eniyan, gegebi osise ilera kan se so. Gegebi Dokita Alex Opio to je igbakeji oludari Ibudo orile-ede
fun idari arun, se so, eniyan meji lo ti ku ni Gulu, ilu kan ni iha ariwa, nigbati meji miran ku ni Masindi, to je ibuso marundinladoje si Kampala ni iha ila-oorun ariwa. Laarin akoko kanna, Opio so wipe isele
meje titun ni won damo ni Gulu to je arigbungbun ibesile na. Titi di isisiyi arun na ko koja awon agbegbe Gulu, Masindi ati Mbara.

Ibesile na ti gbe wahala nla le ori awon osise ilera ni Gulu. Opio ni, "Nibayi, awon osise ilera mefa ni
kokoro-arun na ti kolu. Ninu awon metala to ti ku ni Gulu, mokanle je awon olutoju alaisan, okan je dokita, okan si je osise ilera ......... olutoju alaisan meji ati dokita kan si wa lori eni arun na.

Iba na ti kokoro-arun Ebola ma nfa, ni o ma nlo lati ara enikan si ikeji. Arun na le fa iba lile to nmu idaejenu lowo, nigba pupo o ma nyorisi iku. Sugbon awon olufaragba ti won ba nfun ni isan-bi-omi lati koju
igbetan-omi-ninu ara ni aaye to dara lati ruula. Associated Press

Awon odomobirin gbe igbese lati dekun Ige Abe Obirin nigekuge 2mins. 8secs. Awon odomobirin orile-ede Kenya meji ti gba iwe ase ile ejo to da baba won lowo ko lati fa ipa mu won
ju ara sile fun ige abe obirin nigekuge. Ile-ejo da baba na Pius Kandie, agbe kan ni Simotwo to wa ni agbegbe Keiyo, ni bi ibuso odunrun le mejila ni iha ariwa Nairobi, lekun lati mu awon odo mobirin na lo si
ayeye idabe ti ibile to ye ko waye ni ojo kesan osu kejila 2000. Adajo ile-ejo Majisret to ngbe ni Keiyo, Daniel Ochenja, pase fun Kandie ati awon onigbowo re lati ma dabe fun awon odomobirin na to nlo si ile-eko
giga -Edna Jebet Kandie, omo odun metadinlogun, ati Beatrice Kandie, omo odun meedogun titi ti on
o fi gbo ejo na ti on o si da ejo na. Awon omobirin na ti pe ejo lati ipase agbejoro kan, Nixon Sifuna, to jiyan wipe Kandie ko gba ase awon odomobirin na lati faragba ige abe obirin nigekuge (Female Genital

Multilation (FGM) labe ofin ibile ti Keiyo. Kandie ti hale wipe on ko ni san owo ile-eko awon omobirin na mo ti won ba ko lati faramo idabe ibile na.
Panafrican News Agency
O Gbodo Teriba: Ipe Miran si Ise 5mins. Ijakadi fun imudogba eya gba igbelaruge miran ni ojo keji osu kokanla odun 2000. O je igbejade "O

gbodo Teriba," iwe kan lori ifiagbara fun awon obirin eyiti Ada Okere Agbasimalo ko. Igbejade na fa opolopo eniyan pataki ni orile-ede na wa, won si wa lati se ajopin iran ibuyi kun aleefa awon obirin.

Ninu "O gbodo Teriba", Agbasimalo yi iriri re kakiri ode gegebi Oludari eto pelu ile eko giga Yunifasiti John Hopkins pada si itan to mini lokan to si wunilori nipa awon iwa aiseto ti won nhu si awon obirin ni iha
aye to sese ndagbasoke. Ni ona ewe, iwe na se ifojusi awon oran to da lori idanilaamu lori ibalopo, iyasoto, iduniniogun, awon isesi opo to panilara ati bebe lo. "O gbodo Teriba". ni itan Meriye, iya kan to
nsise karakara, iyawo, olori egbe awon obirin to je wipe bi awujo ti baje to ni ayika re, o ko lati teriba sugbon dipo eyi o yan lati se ayipada. Dipo ki o fi oju irewesi wo oran na, iwe na fojusi mimu ayipada wa,
ayipada iyanu ti egbe awon obirin se asiwaju re. Ayipada iyanu yi mu ijidide titun wa ninu awujo: igbe aye to dara fun awon okunrin, obirin ati omode -awujo ti iwa-ipa inu re lo sile, ti iwa ibaje inu re lo sile, nibiti
awon eya ti nsaba ara won iwa mimo ati awon isesi to dara. 12
12 Page 13 14
13
Vol. 11 No. 24 CHANGE Radio January, 2001.
Ninu "O gbodo Teriba, Agbasimalo ta awujo laya lati se sii lati buyi kun ipo awon obirin pelu bi eleyi yio se ni ikolu to dara lori awujo. O je ipe si ise, ipe si gbogbo awujo, ipe to mu ibere na wa pe. "Nje dandan
ni ki o teriba?
Ojo ati Akoko Ipe fun Ifiorukosile 4mins. 50secs.

Igbimo Agbaye fun Ilera nkepe o lati fi oruko awon eniyan sile fun Aami Eye Jonathan Mann fun Ilera ati Awon Eto Eda Eniyan. Anfani niyi fun o lati fi oruko akikanju kan ti a ko ti sunrere re sile, eniyan kan tabi
ajo kan -ti o wu ni lori pupo ninu ise gegebi asiwaju osise ninu ilera ati eto eda eniyan, fun Aami Eye Jonathan Mann. Awon to nsise ni ipele igberiko ati awon to nsise ni ipele ti orile-ede tabi ti kariaye lo ni eto.

Aami Eye na ni a fokansi wipe yio je iye owo to joju kan, lati fun awon to ba gba a ni ominira lati koju mo ise won.
Jonathan Mann je eniyan kan pataki ninu ogun orundun to duro, lati dojuko osi ati aisan ni kariaye. O je ajifitafita ni igbogunti arun kogboogun Eedi, o si je asiwaju-ija lori eto eda eniyan. O ku lairotele ni odun 1988 ninu ijabo

oko ofurufu Swissair Ifo kokanleladofa. Ni iranti igbe aye ati ise re, Ajo Association Francois-Xavier Bagnoud, Awon Dokita Agbaye, ati Igbimo Agbaye fun Ilera pelu ebi Mann, se ifilole Aami Eye Jonathan Mann fun Ilera
ati Awon Eto Eda Eniyan ni kariaye. A o se ififunni Aami Eye Jonathan Mann olododun iketa ni ojo kokanlelogun
osu karun laarin Apero olododun ikejidinlogbon ti Igbimo Agbaye fun Ilera ti yio waye lati ojo kokandinlogbon osu karun si ojo kinni osu kefa ni ilu Washington D. C, orile-ede Amerika.

CFC
Orile-Ede South Africa yio gba Ipade Ile Aye ti odun 2002 lalejo. 6mins. 22secs. Eka Ile-ise orile-ede South Africa fun oran Ayika ati Irinajo Afe ti kede wipe Ipade Gbogboogbo ti Ajo

Agbaye lori Ayika ati Idagbasoke Alagbero (United Nations General Assembly on Environment and Sustainable Development (UNCED) ti yan orile-ede South Africa lati gba ipade Ile Aye ti odun 2002
lalejo. Ninu akojade oro kan, Rejoice Mabudafhasi Adele Minisita fun Oran Ayika ati Irinajo Afe, so wipe orile-ede South Africa tewogba ipinnu lati mu apero na wa si ile Afirika. Apero na ni yio waye ni
Johannesburg. Mabudafhasi ni, "mimu Ipade Ile Aye wa si orile-ede South Africa je igbelaruge pataki fun
ile Afirika nitori apero pataki na lori idagbasoke alagbero ti yio waye lori ile wa yio mu awon oran ati ariyanjiyan duro lori awon ohun agbese fun ile aye wa." Ni osu keji odun 2000, Aare Thabo Mbeki gbe

ibere re siwaju Ajo Agbaye lati gba Ipade Alagbeyewo olodun-mewa na ti a mo daradara si Ipade Ile Aye ti Odun 2002 lalejo. O je ohun pataki wipe yio waye ninu iha aye to sese ndagbasoke. Opolopo awon
olori orile-ede ni yio wa si ipade na nibiti a ti nreti awon olukopa bi oke meji. O ju adoje awon olori orile-ede
lo to kopa ninu ipade ti odun 1992, a si lero wipe opolopo ninu awon omo egbe Ajo Agbaye to je ogosan o le mejo ni yio ran awon asoju wa si apero odun 2002 na. O ju egberun meedogun awon ajo

amuludun ti ko lowo ijoba ninu (NGO) lo ti won ni asoju ninu ipade ti odun 1992.
Ninu iroyin to farajo eyi, ile-ise Ajo Agbaye na ti gbe ifitonileti yi jade lati Ipade Gbogboogbo ti Ajo Agbaye. Ayeye Rio ati Mewa yio ni akole "Ipade Agbaye lori Idagbasoke Alagbero." Awon igbimo

oluseto merin ni won ti gbe dide fun Rio ati Mewa. Igbimo kinni ni yio pade lati ogbonjo osu kerin si ojo keji osu karun odun 2001 ni New York, leyin eyi ni awon ipade miran yio waye ni odun 2002. Isele na ati
ilana igbaradi fun un ni yio ni ikopa awon NGO ati awon egbe pataki miran lara awon ti a ti ri ifikunlukun awon ti oro na kan lona pupo. Isele na yio tun silekun ifuniwe ase fun awon NGO titun to nife lati lowo si
Rio ati Mewa. CFC

Awon Ajo Amuludun ti ko lowo ijoba ninu (NGO) ni won 4mins.
ti gbe ise igbogunti iwa ibaje le lowo
Asopo awon Ajo Amuludun ti ko lowo ijoba ninu (NGO) ti orile-ede Naijiria se eto apero olojo-meji kan

laipe yi lori "Awon oran to je mo Iwa Ibaje ati Ise Ijoba Daada: Eto awon NGO fun igbogunti Iwa Ibaje." 13
13 Page 14 15
Vol. 11 No. 24 CHANGE Radio January, 2001.
14
Opolopo eniyan lo pese si apero na pelu awon eniyan pataki-pataki bi Eniti a da lola Nobel, Wole Soyinka, Ojogbon Ransome Kuti ati awon loruko-loruko omo orile-ede Naijiria lati inu awujo oko-owo ati imo
ijinle to kopa ninu idanileko oni-ifiroweoro na. Akojade abajade ti a gbe sode ni opin apero na so wipe iwa ibaje je isoro ti o takoko ti a ko le se apejuwe tabi ki a soro nipa re ni kikun ninu akojade kansoso,
sugbon biotiwu-ki-o-ri, o je idalowoko fun idagbasoke, o si lo lati isedale kan si omiran. O tun woye wipe osi ma nse atileyin fun iwa ibaje. Nitori eyi apero na tanmo wipe a gbodo ma san owo oya to to fun igbe
aye fun awon osise loorekoore bi o ba se ye, awon osise ijoba ti a dibo yan gbodo ma siro ise iriju won fun
awon agbegbe to yan won, a si gbodo da awon agbegbe wonyi leko lori awon koko ilana ati ona igbasenkan ninu ijoba tiwantiwa. Akojade ologbon-koko na wa ro awon NGO lati je asiwaju ninu igbogunti iwa

ibaje, ninu ijafitafita fun imubori-ofin-ni-awujo, awon ile-ejo olominira ati pe ki awon NGO na ma siro ise iriju won.

Apero na, eyiti Eto fun Ijoba tiwantiwa ati Isejoba rere ti Ile-ise Asoju ijoba orile-ede Amerika ni orile-ede Naijiria se onigbowo re, pari pelu ireti bi NGO kookan to kopa se nseleri lati mu awon adehun wonyi lo si
agbegbe won. CFC

Awon Isiro
Fifi opin si Idakejeje lori Iwa-ipa si Awon Obirin 3mins. 10secs.
Ni ojo keedogbon osu kokanla odun 2000 awon eniyan kaakiri aye darapo mo awon gbajumo eniyan kariaye bi Annie Lennox, Dawn French, Ainsley Harriott and Gaby Roslin lati polongo Ojo Aso teere

funfun ti odun 2000 lati fi ehonu han lori iwa-ipa si awon obirin. Awon isiro wonyi ni won gbe sori afefe:
Okan ninu awon obirin merin lo ma nni iriri iwa-ipa ni akoko kan ninu aye won.
Ajo Alasepo Awon Onise Isegun ti orile-ede Britain 1998

Ni kariaye, iwa-ipa awon okunrin nfa iku ati isodialaaboara laarin awon obirin ti ojo ori won ko to merinlelogoji ju arun idibaje eya ara, ako iba ati ogun lo.

Iwe Ifikunlukun Nomba 225 ti Banki Agbaye
Awon olopa ni Ile Geesi ma ngba ipe eedegbeje lori ero ibanisoro lati odo awon olufaragba iwa-ipa ninu ile lojoojumo: iko mokanlelogorin ninu ogorun eyi lo nwa lati odo awon obirin ti okunrin dojujako.

Eto Iwadi lori Iwa-Ipa ti Ile-eko giga Yunifasiti ilu London ni odun 2000.
Dajudaju ipolongo ni igbogunti iwa-ipa si awon obirin le ya ohun kan lo lati inu ipolongo Ajo Agbaye lori
Arun Kogboogun Eedi. Isoro kan niyi ninu eyiti AWON OKUNRIN le MU NKAN YATO. CFC

Eto Awon Omode
Ketu, kilo panilerin tobe? Itan Isedale Eya Neur kan 21mins. Ni ile Afirika nitosi awon Oke Osupa, okunrin kan wa ri to nje Ketu. Oninudidun eniyan ni. Erin nla wa

ninu re. Sugbon eyi na lo ko sinu wahala. O sele bayi.......
Ni ojo kan Ketu gbo ti aja re nkigbe, kao, kao, kao, leyin ahere. O se iwadi o si ri wipe aja na nda ejo kekere kan ti ko lewu laamu. O ba aja na wi, iyen si yo gologolo lo pelu iberu. Ejo kekere na gbe ori re

soke o ni, "O seun ogbeni. Alaanu ni o. Ngo fun o bi ebun kan." Ketu rerin, tu-e, tu-e, tu-e! "Kini eda kekere bi iwo le fun mi?" o bere. "Ebun onidan," ejo na dahun. "Lati isisiyi lo, o o ma gbo bi awon eranko
se nro ero. Sugbon o ko gbodo so fun enikeni, bikosebe kiku ni o ma ku." Ketu o ni idaniloju wipe on fe iru ebun be. O tiraka lati ko, sugbon ejo kekere na ti pare! 14
14 Page 15 16
15
Vol. 11 No. 24 CHANGE Radio January, 2001.
Ni ale ojo yen, iyawo Ketu, Nyaloti, te omo won sinu apere ibusun re. O ki omo-ma-sunkun kan ti a fi enu akeregbe kekere kan se bo enu omo na. O fi owo re omo na titi o fi sun. Ketu wa ti ilekun. On ati Nyaloti
si wa sun sori ibusun won to wa ni egbe ogiri ahere na. Laipe won gbo ti efon kan nkun nibi ilekun. Ketu si gbo to nso fun ara re, "Mo mo wipe won wa ninu ile nibe! Awon eniyan sisanra ti o si ni oje pupo!
Sugbon nko ri iho to tobi to!" Ketu rerin tobe ti o fi yi kuro lori ibusun-GU-MAPP! Nyaloti pariwo "Kilo fa erin totobe, Ketu?" "Ko si nkankan" Ketu dahun bi o se gun ori ibusun pada. Ko le so fun.

Laipe eku kan dan ilekun na wo. On na ko le wole. Sugbon o ri iho kan labe orule, o si gba ibe wole. Ta, ta, ta ni ese eku kekere na ndun bi ose nlo to nbo lori ile. Ketu wa gbo to nba ara re soro. "Olorun lo mo
ibiti obirin yi nfi ora re si!" Ketu bu si erin, kye, kye, kye! O rerin to be ti o fi deruba eku na o si fo sori ibusun Nyaloti -Twum -si agbedemeji Nyaloti! "A-a-a-a!" o pariwo. "Mu eku yen kuro lori mi!" Eku na
fo sara ogiri o si sare gba inu iho na lo.
Nyaloti dide joko lori ibusun. O ni, "Ketu, mo ro wipe erin re lo jeki eku yen fo le mi lori. Ki lo npa o lerin?" Ketu ni "Ko si nkankan"

Ni owuro ojo keji, Ketu mu maalu won lati inu aba o si so mo igi kan ki Nyaloti le fun wara re. Laipe o ri
ti iyawo re nbo pelu igba nla kan. Maalu na ri, Ketu wa gbo to nba re so wipe "O nbo lati wa ji wara mi!. Loni yi nko ni fun ni wara kokan. Omo mi ni yio mu to ba ya! Ketu rerin, ge-e, ge-e, ge-e! Erin na po debi

ti o fi deruba maalu na to si sa.
Nyaloti gbe igba na sile ko le ri aye fi owo mejeji lu oko re O ni "Kilo pa o lerin tobe, Ketu? Nisisiyi, o ti deruba maalu yen pelu erin buruku e! Se emi lo fi nrerin?" "O ti o" Ketu dahun bo se nrin lo. "Ko si

nkankan." Maalu na ko fun won ni wara kokan. Nyaloti ko ri ekan kansoso ninu igba re. Sugbon omo maalu na mu omu laya iya re titi ti iku re fi tobi to si ri rubutu. O dabi enipe o mo nipa oro to so wipe "Ki
ounje daradara maa baje, e jeki ikun be." Ni irole ojo yen ni akoko ifunwara, maalu na ko tun fun won ni wara kokan. Nyaloti pe Ketu O ni, "Wo," Ko tun si wara. Omo wa ti nsaare nitori e. Omo maalu yi npa
omo wa!"
Maalu na yi ori re nla pada lati wo Nyaloti, Ketu gbo to nba ara re so wipe "Paga! Omobirin mi npa omobirin won!" Ketu tiraka lati da erin na pada. Sugbon o bu jade laarin awon ika re, gug. gug, gug! Eru

ba maalu na to be to fi tapa re ti o si gba igba na siwaju to fi nyi lo nile. "Se o ri nkan to se!" Nyaloti kigbe. "Iwo ati erin buruku yen. Mo nlo so fun baale." Nyaloti so fun baale. Baale pe Ketu ati awon amoye
okunrin abule sidi Igi Idajo Ododo ni aarin abule na. Nyaloti na wa, pelu ikoko na ninu apeere kan lori re.
Opolopo eniyan na lo si wa, ki won kan wa gbo kilo fa rogbodiyan.

Baale ni, "Ketu, iyawo e so fun mi wipe o ma nrerin nigba ti ko ba si nkankan to panilerin. Se otito ni?" Ketu dahun, " O tio, baale nki rerin laisi idi. Sugbon nko le so idi re. Ti mo ba so, ngo ku! "Oro radarada!"

baale kigbe. "Oro siso ki ipa enikeni." Nyaloti ni, "emi lo ma nfi rerin baale nitori emi nikan lo wa nibe." "Beko," Ketu dahun. "Ki ise be!"

"Bi ki iba se iyawo re lo fi nrerin, kilo npa o lerin?" baale bere. Enikan kigbe, "So fun wa Ketu. Awa na fe rerin!" Baale ni, "Ketu, ti o ko ba so fun iyawo re, yio mu omo re yio si pada lo ma gbe pelu baba re."
Ketu dorikodo. O fi ika ese re wale ninu iyanrin. Ko mo ohun to le se. Igba yen ni omo re beresi ke, ke-yaa, ke-yaa, ke-yaa! Ketu wo bi Nyaloti se so apeere na kale ti o si gbe omo won to dara bi egbin jade.
Omo-ma-sunkun si nro sile lati orun owo omo na to ki popo. Lojiji, Ketu ri wipe ko si ohun to le sele, on o le jeki iyawo ati omo on lo. Nitorina o so nipa ejo kekere na, ebun idan na ati awon ero apanilerin awon
eranko.
Biosesotan, KWAM! le, o ku! "Wo o!" okunrin amoye to dagba ju kigbe. "A ti mu se ohun ti ko ye ko se. O si ti fi emi re di i!"

Nyaloti ati opolopo awon obirin beresi sokun, wolu, wolu, wolu! Baale mi ori re pelu ibanuje. 15
15 Page 16
Vol. 11 No. 24 CHANGE Radio January, 2001.
16
Laipe, ejo kekere na de. O fi ori re didan si ori Ketu. Ketu la oju re. O yi ori re o si ri ejo na to nwo wogowogo wonu oko lo. O si wa gbo to nba ara re so wipe "ki lon npa o lerin to be?" Baale kigbe, "Ma
bi lere mo!" Nyaloti si ni, "Rin gbogbo erin to ba fe. Nko ni fa ijangban kokan lori re mo!"
Nigbana ni gbogbo eniyan beresi rerin. Won rerin tobe ti won fi deruba omo kekere na. Bori gbogbo ariwo erin won, won gbo igbe omo na KE-YAA, KE-YAA, KE-YAA!
Atunso lati owo Verna Aardema

Aworo Oro Asokagba
Awon oro manigbagbe lati odun 2000 to sese pari.
Ninu akoko ifitonileti ati imo-ero yi, e je ki www je agbara imunisise wa. Ti a ba ni ifaramo ati ifaraji, WWW, a o segun!

Kenneth Kaunda, Aare orile-ede Zambia tele, to nse iwuri fun awon omo ile-Afirika ninu igbejako won si
Arun Kogboogun Eedi. Eyawo iba se itewogba laisi Arun Kogboogun Eedi sugbon won ko se itewogba ninu aye to ni Arun

Kogboogun Eedi. Michael Kelly, olukopa kan ninu Apero Ile Afirika lori Idagbasoke ti odun 2000, nigbati o nsoro lori
iderun gbese fun awon orile-ede Afirika.
Inu nbi awon odo lori osi, gbese, iwa ibaje ati aisi idajo ododo laarin awujo. Genevieve -Ajo Awon Odo lagbaye -okan ninu awon olukopa ninu Apero ti awon odo ninu Apero lori
Idagbasoke Ile Afirika ti odun 2000.
Ati ogbon atijo ile Afirika die ..........
Awon to ba ko lati mu ninu kanga imo yio ku ninu asale ainiimo. Orile-ede Guinea.

Ti o ba fetisi ohun aara ojo ko ni pa o Orile-ede Ghana
More African Proverbs

Ajo CFC ngbadura fun gbogbo awon oluka Change Radio wipe ki akoko yi mu ohun to dara julo wa fun won. E ku ewu odun titun. 16

Page Navigation Panel

1 2 3 4 5 6 7 8 9
10 11 12 13 14 15 16

 

© 2002 Communicating for Change. All Rights Reserved
Developed by George Mbuagbaw