Document Body Page Navigation Panel
'Bi o se ri ki eniyan ma ni ireti' 11mins. 22secs. 5
Ncele Kgadima, ti a ju sewon fun ese itiraka lati pa ikoko, se ifojusi
bi o
se ye lati se agbeyewo osi ati eko fun awon obirin.
Awon Obirin na se pataki 10mins. 6
Awon eto awon omode ni a ti sopo pelu ilera ati iwalalafia awon iya.
Leyin Awon Omode Na 3mins. 29secs. 10
Ile-ise Ajo Agbaye fun Awon Asasala Ogun ati Ajo Alasepo lori Akojo Owo
fun Igbala Awon Omode ti gbe eto ise kale lati se iranlowo fun awon omode
ti a ko sile to nwa ibugbe ni ile Europe.
AWON AJO IROYIN
Iyipada Rere ati Awon Ajo Iroyin 4mins. 50secs. 9
Aare Egbe Awon Onise Iroyin ni Iwo-Oorun Afirika ti kilo fun awon onise
iroyin
wipe ki won mase jeki ifitorese nipa lori ibalopo won pelu ijoba.
Awon ti a da lola Nobel soro lori ominira Ise Iroyin 3mins. 16secs. 9
Awon meji ti a da lola Nobel, Dalai Lama ati Bharat Ratan Amartya Sen,
ro awon
onise iroyin lati se ayipada awujo ki won si se ifojusi ero tooro lati se iranwo
lati so
gbogbo agbaye di abule kansoso.
ILERA
Rawlings di Agbenuso Ajo Agbaye lori Iyonda-ara-eni-fun-ise 5mins. 39secs.
9
Aare orile-ede Ghana tele, Jerry Rawlings, ni a fi se Eni Pataki Ajo
Agbaye fun
Iyonda-ara-eni-fun-ise latari ikun ojuiwon ati ifaraji re to jinle si awon oran
ilera
to se koko.
ORO AJE
Ajo UNDP kepe fun ona Iselatiberepepe fun Idinku Osi 11mins. 57secs. 4
Ajo UNDP so wipe idinku osi ni a gbodo koju lati iha ti eda eniyan ati
ti agbaye.
Ile Afirika ninu Igbimo Aabo Ajo Agbaye? 8mins. 22secs. 11
Ifikunlukun lori atunse to jinle ninu Ajo Agbaye.
Ayika
IDOTI
Irokeke Ewu ti a ko le fi oju ri wa ni Muizenberg 10mins. 27secs. 3
Ise Agbese kan ti orile-ede South Africa ti nse apejuwe re bi "emi imo
ero"
le ba afefe je pelu eefin alagbara chlorine.
AFEFE ILE
Iyipada Afefe Ile yio na ni lowo to to Odunrun Bilionu owo Dola Amerika lodoodun.
6mins. 16secs. 8
O seese ki imorusi aye ni agbaye na ni opolopo bilionu owo dola Amerika
lodoodun ayafi ti a ba gbe igbese ni kiakia lati dekun itujade awon eefin
alagbara to nba ayika je. 1
1 Page 2 3
Vol. 11 No. 26 (Yoruba) CHANGE Radio March,
2001
2
ITOJU
Itoju Ayika lo sinu Fiimu 6mins. 27secs. 10
Fiimu ti Elaine Proctor sese se ti a pe ni 'Kin' topinpin itakorawon
to wa laarin
itoju ati eto agbegbe, o si se ayewo imuwalalafia awon eya ni orile-ede Namibia.
Bi mo se rii si
Idajo Ododo fun Awon Omode Orile-ede Saro 10mins. 40secs. 11
Igbimo Ajo Agbaye pari ise lori ipa ti orile-ede Liberia ko ninu egbe
alafowosowopo lori pasipaaro okuta iyebiye dayamondi fun ibon eyiti o nfa
iha iwo-oorun ile Afirika ya. Kini igbese to kan?
A ti gbo
Orile-ede Algeria gba awon Ile-Olomi titun 2mins. 33secs. 12
Orile-ede Algeria ti se akosile awon ile olomi titun mewa to se pataki
kariaye isaami Ojo Ile Olomi ni Agbaye.
Omodekunrin kan to nsaisan lile latari Arun Kogboogun Eedi di 3mins. 6secs.
13
omo odun mejila
Ajafitafita lori Arun Kogboogun Eedi ti ojo ori re kere ju ni orile-ede
South
Africa, Nkosi Johnson, to sese pe omo odun mejila si wa lori idaku olojogbooro.
Eto Awon Omode
Kumbo ati Mhisi 12mins. 7secs. 13
Kunbo olorikunkun padanu emi re sowo akata to nje Mhisi latari aigboran
si awon obi re.
Awon Oro Asokagba
Awon oro manigbagbe die ti awon olori Ile Afirika so ati oro lori
itumo gidi fun ewa. 14 2
2 Page 3 4
Vol. 11 No. 26 (Yoruba) CHANGE Radio March,
2001
3
Iroyin
Ipo Awon Omode Agbaye ni Odun 2001 9mins. 26secs. Awon orile-ede
Afirika lo wa niwaju ninu awon orile-ede to ti fi awon anfaani lati mu awon
omode won
dagbasoke sofo latari awon eto imulo to nfi nkan sofo, awon ogun ti ki nidi
ati jiji awon oro orile-ede.
Ajalu ifi anfaani sofo yi ni o je koko pataki iroyin ti Ajo Akojo Owo ni Agbaye
fun Awon Omode (United Nations Children's Fund (UNICEF) sese gbe jade. Iroyin
na ti a pe ni "Ipo ti Awon Omode Agbaye wa
ni Odun 2001 ni o to awon orile-ede aye leralera gegebi itesiwaju ti won ti
ni lati koju awon ojuse won si awon omode, eyiti won faramo ninu ipade agbaye
lori awon omode ni odun 1990.
Carol Bellamy to je olori ajo fun awon omode na so ninu iroyin na wipe "idoko
owo ninu idagbasoke ati itoju awon omo wa to kere ju ni o je iru ije olori rere
to sekoko julo." Ninu iroyin na, o so wipe titu agbara
ogbon ori awon omo sile nipa awon idoko-owo to munadoko ninu ilera, eko, ounje
to peye, itoju omo ati idaabobo ki ise ohun ti o kanpa ti o si tona nikan sugbon
o tun je oro-aje to mu ogbon dani ti o gbodo sele
ni iberepepe igbesiaye omode. Gegebi o se so, "Ajalu to buru julo ni wipe opolopo
awon to nse ipinnu ni
ko mo bawo ni awon odun meta to siwaju ninu igbesi aye se se koko to -osi ni
igba omode kan de ekeji, lati okan kan de ekeji o ma nyorisi ipadami agbara
eda eniyan."
Awon orile-ede Afirika to wa labe asale Sahara lo jebi ju ninu oran yi, nitori
won nto awon ekun aye to ku leyin, won ko si de oju iwontunwonsi ninu gbogbo
eka ti won to sile. Ile Afirika lo siwaju ninu awon isiro
osi, rogbodiyan ati kokoro-arun HIV ati Arun Kogboogun Eedi ti o si ti da gbogbo
aseyege to ti watele ninu igbelaruge itoju awon omode pada seyin. Ile Afirika
lo ni eyi to poju ninu awon eniyan bi ogoji milionu
ti rogbodiyan ati eto eda eniyan to si nipo pada labe-ile pelu bi awon eniyan
bi milionu mefa ati edegberin ole adoota egberun to sipo pada ni orile-ede Sudan
Angola, Burundi ati Angola.
Ninu oran eko, awon isiro elekunjekun ti Ajo Agbaye fun Oran Eko, Imo Ijinle
Sayensi ati Asa Ibile (U. N. Educational, Scientific and Cultural Organisation
(UNESCO) fihan wipe iko marundinlogota ninu
ogorun ni iwontunwonsi ni ile Afirika to wa labe asale Sahara ko ni afiwe iko
metalelogorin ni Aaringbungbun Ila-oorun, ati Ariwa Ile Afirika, iko mokanleladorin
ni Gusu Ile Asia, iko merindinlogorun ati aabo ni Ila-oorun
Ile Asia ati Pacific, iko mokandinlogorun ati aabo ni Latin Amerika ati Caribbean
ati iko
mokanleladorun ni Aringbungbun ati Ila-oorun Ile Europe ati awon orile-ede Baltic.
Sugbon ohun to dabi enipe o buru julo ninu gbogbo re ni awon milionu milionu
omode to ti di omo orukan latari Arun Kogboogun Eedi ti ojo iwaju won si ti
dipa latari osi. Ni awon apakan iha gusu Afirika, bi
idamewa awon omode ti ojo ori won ko to odun meedogun lo ti padanu iya won tabi
obi mejeji si
ajakaye-arun ti a pe ni ajalu to buru julo ni igba tiwa. Bi ipo awon obirin
ba si wa ni dogbandogba pelu ti awon omode, gegebi iroyin na se tanmo, nigbana
awon
omode ni iha isale asale Sahara, nibiti opolopo milionu awon obirin ti ni
ikolu iwa-ipa abe-ile ati rogbodiyan, ni ona to jin lati lo ki won to le ri
itesiwaju ninu itoju won.
Bi iroyin na ba se e tele, awon orile-ede Afirika si ni lati se nkan pupo
sii lati mu ipo awon omode won dara sii, ki won si tipa be daabobo ojo iwaju
wa.
CFC
Irokeke Ewu ti a ko le foju ri wa lori Muizenberg 10mins. 27secs.
O seese ki ise agbese kan ti Ijoba ibile ti South Peninsula ni orile-ede
South Africa polongo re bi "emi imo ero" ba afefe Cape Riviera je pelu eefin
alagbara chlorine, to je okan ninu awon ayokele pani to buru julo
lorile aye. Nigbati igbimo ijoba ibile na ba pade, a o gbe aba siwaju won
fun idasile ile-ero fun sise ohun 3
3 Page 4 5
Vol. 11 No. 26 (Yoruba) CHANGE Radio March,
2001
4
elo igbalode kan ti a mo si optic fiber ninu Ogba Egan Capricorn ni ile Muizenberg.
Igbimo ijoba ibile na fun ise lori aarin-ilu ati ayika na ti tanmo ayipada ninu
ilo ile lati le se igbekale nkan yi ti yio se alekun ninu
ise si ibikan to je iwon mita irinwo din ladota si itedo kan ti eniyan kun be
faya sugbon ti ijoba ko fowo si ti o si tun wa ni irekoja titi si awon ile olowo
giga ti a nko ni idojuko eti ebute. Gegebi awon alatako se so,
awon itedo eda eniyan mejeji yi ni yio ni idojuko ewu ti a ko le foju ri ti
o le gba won sinu okun kariaye Atlantic lati owo awon eefin alagbara hydrogen
ati nitrogen eyiti a kojo sinu ibudo na ti ise agbese na ba
tesiwaju.
Ohun isoro niyi fun ile Muizenberg to ti figbakan je ibi igbafe aayo fun awon
Ju to wa ni Johannesburg. Ile-ise na ni yio se idasile ise titun ti o to adojo
ati odunrin o din aadota ise miran to ro moo ni apa kini re ninu
eyiti a ti ri ile iso to ga to aja ile mejila. Iseese itujade eefin alagbara
chlorine ati ibugbamu hydrogen ni o ti da iberu sile ni agbegbe. Ijoba ekun
Western Cape to ni ase lori ipinnu iyipada ilo ile, sugbon opolopo
eniyan ni Muizenberg, paapa ni itedo Vygrond ti ko lowo ijoba ninu ati ti Marina
da Gama to wa nitosi, ni ko mo ewu to wa ni enu-ona won lati inu ibi ti won
gbagbo wipe o je "Ogba Imo Ijinle Sayensi" biotilejepe
iyipada wa ninu awon eto ti won koko se kede re ninu ipade ita gbangba akoko
lori oran na ni osu kejila odun to koja.
Ni odun meji seyin, awon iwadi ojutaye lori osi, eyiti Archbishop Njongonkulu
Ndungawe ti ijo Anglican ni Cape Town se alaga won, bere idi re to fi je wipe
awon ile-ise to ni itujade oloro ni won ma nda sile
legbe itedo awon talika paraku laiko gbo tenu awon ara agbegbe. Paapa, ninu
didaba atunse ti a ko pariwo re lati yi ibudo Capricorn pada kuro ni ilo gegebi
agbegbe iwadi lori imo ijinle sayensi ati imo ero si
"agbegbe ile-ise to ni itujade oloro", igbimo ijoba ibile na woye wipe "ni ojo
iwaju, ati nibiti o ba ti ye, ki a
se imulowosi awon ara ilu, ni ona to gboro si." Atako kansoso to nipa lowa lati
odo Egbe fun Eda Abemi Egan ati Ayika ni orile-ede South Africa. Egbe na jiyan
wipe iwe ebe ti won koko kowa fun iyipada ilo ile
ni o je fun ile-ise "Akojopo Imo Ijinle Sayensi" ti ko ni ero alagbara ni
ifegbekegbe pelu awon ile itura, ile itaja aud awon ibudo fun faaji ti won ti
fowosi. Nipa yiyi awon ilana fun ilo-ile pada, egbe na so wipe ijoba
ibile na ti fi awokose lele fun awon ile-ise onitujade oloro miran.
Yato si eyi, oran ti eefin alagbara chlorine "to lewu pupo" wa nile, eyiti iwadi
fihan wipe afefe mimo to ni eroja re to je iko kan ninu egberun le pa eniyan.
Ninu iye re to je iko mewa pere ninu milionu kan, ailera
ati idaamu mimi sele leyin idaji wakati kan. Iwe emi-o-faramo ti egbe na ko
so wipe "Opolopo nkan lo le
mu ki itujade efin alagbara Chlorine lati inu ile-ise na sinu awon itedo to
kun fun eda eniyan bi Vrygrond, fa iparun to po si agbegbe." Bena ni itujade
eefin alagbara Hydrogen to "nsare gbina to si nbugbamu" lati inu
awon agba itoju to le fa ibugbamu ati ina, le yorisi iparun to buaya.
Ni tiwon awon oludasile njiyan wipe ilana igbase ohun elo igbalode Optic Fiber
ntu eefin alagbara chlorine to kere pupo jade, ati wipe afefe ti yio tu jade
lati ile-ise na ni a o fo mo lati yo Chlorine na kuro. Ijoba ibile
na ti yan awon oludaninimoran agbegbe kan lati se iwadi apilese lori ikolu
si ayika lara eyiti itopinpin gbodo waye lori itujade awon eefin alagbara chlorine,
hydrogen, nitrogen ati awon ewu to wa ninu ikojopo won
sinu ibudo na. Mail aud Guardian
Ajo UNDP Kepe fun ona Ise lati berepepe fun Idinku Osi 11mins. 57 secs.
Bi o tile je pe ifenuko wa lori awon ona pataki lati gba de ibi ifojusi
ninu Ipade Egberun odun yi lati din osi
to lekoko ku si idaji nigbati yio ba fi di odun 2015, igbese lati din osi ku
gbodo lo koja ifojusi awon aseyori
oro aje lati dojuko awon abajade osi lori eda eniyan ni agbaye. Eyi ni oro ti
alase Ajo UNDP, Mark Malloch Brown so. O fere to enikan kan laarin marun -awon
bilionu kan o le igba milionu okunrin, obirin
ati omode -to ngbe ninu osi to lekoko, ti won nna owo to din ni owo dola Amerika
kansoso loojo. Awon abajade re buru pupo. 4
4 Page 5 6
Vol. 11 No. 26 (Yoruba) CHANGE Radio March,
2001
5
Idamarun iye olugbe agbaye to talika ju ni o seese ni ilopo merinla lati ku
ni igba ti won wa lomode ju
idamarun to lowo julo laye. Brown ni "osi ati awon olomoge re to je arun ati
rogbodiyan ni a ko le ge kuro lati iyoku aye" O ni won ma nsaba se danu, boya
gegebi iwa odaran kariaye, awon ogun okanjuwa ati
ibinu, itankale kokoro-arun HIV ati Arun kogboogun Eedi ati awon arun miran
tabi ayalu awon asasala ogun ati awon awo-orile-ede lona tiko-bofin-mu lati
awon orile-ede to talika julo ti won nkanlekun awon
orile-ede to lowo waye. Alase ajo UNDP na so wipe "A gbodo ma ranti nigbagbogbo
wipe osi koja aini
owo lowo nikan, o je iduni ni eto eni, iduni ni anfaani ati iduni ni ireti fun
ojo iwaju".
Gegebi o se so, awon oran agbaye meta ti a gbodo dojuko ni aidogba ninu isowo,
bi o se ntokasi wipe bi owo epo robi tile lo soke ni odun to koja, owo ti a
nta awon oja bi kofi, gedu ati ororo agbon lo sile pelu
iko ogoji ninu ogorun tabi jube lo, eyi si ni ikolu to buru pupo lori opolopo
awon orile-ede to sese
ndagbasoke. Isoro na ni awon orile-ede to lowo wa nmu buru si nipa ifaseyin
won lati si awon oja won sile, paapa ninu ise ogbin ati aso. Awon orile-ede
to sese dagbasoke yio ni ere to to ogun bilionu owo dola
Amerika lodun kan pelu imukuro awon owo iderun lori ise-ogbin nikan. Awon
orile-ede to lowo lagbaye ti faramo ati mu awon idilowo to ku kuro fun, o kere
tan, awon orile-ede mokandinladota to ko dagbasoke
rara.
Ogbeni Brown tun kilo wipe "ohun keji ti o tun se koko pupo ni wipe a gbodo
sora ki a ma jeki ife owo to nsan kakiri aye tanna si wa loju" Bi isanwole owo
pupo ba wa ni odun kan, o seese ki isanjade onidagiri
telee ni kiakia. Awon orile-ede to talika ni lati yi oju won si awon agbegbe
ikowojo ati ifunnini eyawo abeele ti a ko kobiarasi, ki a si kobiara si sise
iwuri fun ifowopamo labeele, titu owo sile ni awon agbegbe
bi ile kiko ti ko lowo ijoba ninu ati mimu eto eyawo onikerejekereje gbooro
sii. Lona keta, a gbodo se iwuri fun isan imo-ero lagbaye lona to yara sii si
awon orile-ede to talika. Eyi to se pataki julo ninu awon
wonyi, iyen imo ero nipa Ifitonileti ati Ibanisoro, ma nni agbara lati ran awon
orile-ede to sese ndagbasoke lowo lati di alabasisepo kikun ninu oro-aje agbaye.
Ohun to tun se pataki pupo ni alekun ise lori awon
itoju fun awon arun bi ako iba, iko egbe ati kokoro-arun HIV ati Arun kogboogun
Eedi eyiti o ti da
ilosiwaju opolopo ewadun pada seyin ni awon orile-ede to ni ikolu julo.
Ajo UNDP to je asiwaju ajo agbaye lori osi, ndin ifojusi re ku tooro si fifunni
ni imoran lori isejoba tiwantiwa, agbara isowo ati imo ero lori ifitonileti.
Ajo UNDP tun nse afikun awon oran to jemo o -ti
koko re je ifiagbara fun awon obinrin ati idaabobo ayika nipa awon nkan bi agbara
ina alagbero -sinu
igbejako osi. Itupale oran ati iparowa fun, paapa nipase awon iroyin agbaye
ati ti orile-ede lori Idagbasoke Eda Eniyan ti nse pataki pupo.
Laipe yi, akowe agba fun Ajo Agbaye yan igbimo kariaye kan lati gbe aba sile
lori ati ri owonna fun apero agbaye pataki kan. Aare orile-ede Mexico tele,
Zedillo lo se alaga igbimo, ti Akowe Agba tele fun Ile
Isura ti orile-ede Amerika, Rubin, wa lara awon omo igbimo. O seese ki awon
eyi mo le itesiwaju to ti wa teletele ki won si se agbekale itage to lagbara
fun idagbasoke fun egberun odun titun yi ni isopo taara pelu
awon ifojusi Egberun odun. Brown so wipe: Ere rere nfe idoko-owo rere. "Bi aye
ba si fi oju ojo iwaju wo oro na to si se idoko-owo na laarin awon talika agbaye,
ki o si da won po pelu awon iyipada ti mo ti
to sile loke yi, mo gbagbo wipe o seese fun wa lati bori ija ti a ngbeko osi".
Pan African News Agency
"Ko si Eniti o mo bi o se ri ki eniyan ma ni ireti" 11mins. 22secs. Ni
osan ojo kan ninu osu kejila odun 1996, ni nkan bi odun merin seyin, Ncele Kgadima
ti ara re mo inu
salanga kan lori ile ile kan ni igberiko Ga-Maribana, Moletji, ni eyin odi Pietersburg
ni ekun ariwa. Obinrin
alaboyun na, omo ogun odun ni igba na, bi omo na ninu salanga to ni oorun buruku,
to ni orinrin to si sokunkun. O si rin jade lo. Omo ikoko okunrin na ye. Leyin
itoju die fun igbonatutu ara to lo sile pupo 5
5 Page 6 7
Vol. 11 No. 26 (Yoruba) CHANGE Radio March,
2001
6
ninu ile iwosan, won fi si abe itoju alagbato. Iya re ni a dalebi esun itiraka
lati paniyan ati ti ihuwa lodi si
Ofin Itoju Omode nipa fifi omo na sile. Ni osu kewa odun to koja leyin bi odun
meta to ti se ese na, won ju Kgadima si ewon odun meta.
Ni osu kini odun 1997 ni igba akoko ti awon olopa de ile oga re ni Laudium
nitosi Pretoria lati bere oro lowo re, o jewo wipe on ju omo on nu. Won mu won
si fii sile leyin ti won ti gba iduro eleedegbeta Rand
fun, won si ni ki o farahan ni ile ejo leyin ose meji. Sugbon leyin opolopo
owo sisan ati iwo oko takisi lo si Pretoria, ejo na wo odun keji. Nigbati won
sun ejo na siwaju fun igba ikeje ni odun 1998, Kgadima pinnu
wipe on ki yio lo si ile-ejo mo. On ti gba wipe on jebi, nitorina kilo tun nfa
idaduro. Pelupelu, gbogbo bi won se nse ni ile ejo ko yee, ko si si eniti o
se aniyan lati se alaye ohunkohun fun un. Agbejoro nbaa soro
nipase oga re. Nigbati ko yoju si ile-ejo ni ojo igbejo, oko awon olopa alawo
buluu ati funfun de lati mu lo.
Kgadima ni eto labe ofin orile-ede si igbejo ti a separi "laisi idaduro ti ko
nidi". O tun ni eto si iboyunje. Gegebi o ti wa ninu ofin Ife-inu lati ba oyun
je ti odun 1996, obinrin-ko-binrin le lo si ile-iwosan ijoba ki o
si bere fun iba oyun ti ko iti koja osu meta je. Sugbon lotito, awon obinrin
ma ndojuko ainiye isoro lati je anfani awon eto wonyi. Awon obinrin ti ko ba
mo awon anfaani to si sile fun won yio yan ona eyin
nigbeyin, won a si tipa be fi emi ara won wewu nipa liko ohunkohun lati ose
olomi Jeyes titi de irin igbe-aso-
ko lati fi yo oyun na damu. Awon miran, gegebi Kgadima yio pari oro won sinu
ewon fun itiraka lati pa ikoko won asesebi, ti won si ma nri pa nigbamiran.
Oku keekeeke ti awon ikoko ti a fun pa tabi ti a fi
sile lati ku ninu papo wa lori opolopo abo perese ninu ibi igbeokusi ijoba.
Ni ile ejo, agbejoro ijoba bu enu ate lu Kgadima fun iwa "aini itara ti iya"
Sugbon ohun ti ile-ejo ko gbo ni
igbe-aye ikosile, osi to le pupo, aini anfani eko iwe ati, paripari re, igbekuta
to mu ki Kgadima gbe ikoko asesebi re sile lati ku. Iya on furarare ti o se
apejuwe re bi 'omuti kan', fi on na sile. Kgadima lo aye re ninu
titun ile awon elomiran se lati toju awon omo re keekeeke, ibatan re eleni-odun
mejidinlogorin ti a mo si Rosina ati awon omo re meji, Josiah omo odun meje
ati Selina, omo odun mewa.
Ni ile-ejo, agbejoro ro ile-ejo lati fi aini imo eko Ngadima si ero ati wipe
o seese ki inu re baje sugbon agbejoro ti ijoba ati ile-ejo ko eleyi. O so fun
Kgadima wipe "O mo wipe omo ikoko kole funrarare kuro
ninu iho yen, o si seese ko ku, sibe o rin kuro nibe bi enipe ko si nkokan.
Iru ona iku buruku wo ni eyi!"
Ohun to kan eniyan nipa Kgadima ni wipe o jewo ohun to se o si dabi enipe o
ni ironupiwada. Sugbon nigbati awon osise ijoba pe e nigba igbejo re wipe ki
o gba omo na pada, o ko. O so pelu ibanuje wipe
"ko si eniti o mo bi o se ri laini owo, laini ireti bi emi se ti mo" Oruko
re gangan ko ni a lo.
Mail and Guardian
Awon Obinrin Na se Pataki 10 mins. Eto awon omode ko le kese jari
bi a ko ba fun ilera ati alafia awon iya ni ikobiarasi to ye. Ni opolopo ona
ni awon obinrin fi nkopa to nipon ninu iwalalafia awon omode, nitori idi eyi,
igbelaruge ipo awon obinrin, ati ona ni dogbandogba si eko, igbeko, eyawo ati
awon eto iranlowo miran je ilowosi to niyelori pupo si awon
odo orile-ede. Awon obinrin to ba nsaisan nigbakugba, ti ebi ba npa, ti a ba
nfiyaje ti a si nyasoto ko le
ni okun, ife-inu ati iwuri lati toju awon omo won de oju aami. Apero Agbaye
ti odun 1990 fun Awon Omode na jewo ifarakorawon yi laarin iya ati omo. Ise
pataki imudogba eya fun idagbasoke awujo ni a fi
ese re mule ni odun 1979 nigbati Ipade Gbogboogbo ti Ajo Agbaye gba Adehun
Kariaye lori Imukuro Gbogbo Ifiyasoto si si Awon Obirin wole.
Lati odun 1990, bi o se ye lati fi opin si ifiyatosi ati awon iwa miran to
mu ipanilara wa fun awon obinrin
gegebi ipile fun imudogba eya, idagbasoke ati alafia ni a ti ntenumo nigbogbogba
ninu awon ikede ati adehun ajo agbaye bi Apero Vienna ti odun 1993 lori Eto
Eda Eniyan ati asetele ipade re to waye ni ilu 6
6 Page 7 8
Vol. 11 No. 26 (Yoruba) CHANGE Radio March,
2001
7
New York ni odun 2000. Pelu gbogbo eyi, lodoodun ni awon ajo UNICEF, UNIFPA,
Banki Agbaye ati UNDP ngbe awon akosile isiro to banileru jade eyi to si njerisi
wipe aye si ni ona jijin lati lo ki won to le fi
okan awon obinrin balo lori awon eto won si ilera, imudogba eya ati isabiyamo
ni alafia. Bi a ko tii le fi
okan awon obinrin bale lori awon eto won ninu awon oran yi, bawo ni won se le
toju omo ninu awon ipo lile bayi. Omode yio ni ilera yio si ni eko ti iya re
ba ni ilera to si ni eko. Ilera awon abiyamo, ounje to peye
ati eko se pataki fun iruula ati iwalalafia awon obinrin funrarawon, o si
tun je okunfa pataki fun ilera ati iwalalafia omode nigbati o ba si wa ni ikoko.
O je ohun to dabi oro apara ni wipe bi edun-okan se wa kakiri lori aisi idagbasoke
alagbero ni opolopo orile-ede ni agbaye, o dabi enipe awon olori ijoba, awon
to nse eto imulo ati awon amoye lori idagbasoke
ko riran ri anfani idoko-owo kansoso to je wipe o fun ni idaniloju ere. Eyi
ni sise aridaju wipe awon omode ni ibere to dara ni aye won. Sugbon o se pataki
wipe a gbodo mo wipe ayafi ti awon obinrin ba ni
idaniloju igbe aye rere, awon omode ko ni ibere to dara ni aye. Laifa oro gun
isopo ti o le daindain lo wa
laarin iya ati omo. Ipo ti Awon Omode Agbaye wa ni Odun 2001 fojusi awon omode
to wa lati ojo ibi si odun meta. Nitorina ohun to tona ni wipe ki iroyin na
bojuwo alafia awon obirin ki won le bojuto awon
omode doju aami. Lara awon ohun agbese fun ibere aye awon omode gbodo je lati
se eto eko fun awon obirin ki won le mo nipa ise pataki ounje to dara ati itoju
ilera nigba iloyun. Awon okunrin na gbodo gba
igbeko lori ipa pataki ti won ni lati toju awon iyawo won aboyun ati awon omo
to wa ninu won. Nipa ti
awon omo awon iya ti a ju sewon, awon ijoba gbodo se agbekale itoju pataki fun
awon aboyun ati awon iya ikoko ti a ti da lebi ite ofin won loju. Ni pataki,
won gbodo ri daju wipe a ko ju iya sewon pelu omo re.
Fifi agbara fun awon obinrin ma nyorisi imudarasi ninu igbe aye awon omode.
All Africa. Com
Awon agelowo ati agelese nri ise ati iranlowo ni orile-ede Saro 11mins.
9secs.
Awon olufaragba ninu ipolongo ajalu lati owo awon olote ni orile-ede Saro
ni awon ajo kariaye ngba sise lati se iranwo ninu itoju awon opolopo asasala
ogun to npada bo wa sile lati awon ibudo to wa ni awon
agbegbe ti ko rogbo ni aala pelu orile-ede Guinea Awon agelowo tabi lese meta,
okunrin meji ati obinrin kan, ni won nsise nibayi pelu Ajo kariaye fun Isikiri
(International Organization for Migration (IOM) to se
iranwo ninu pipade ati sise eto awon omo orile-ede Saro to npada bo si Freetown,
olu-ilu.
Okan ninu won ni Mohamed Bah, omo odun medeoogbon, to bere ise ni osu to koja.
Bah wa lati Koidu, ilu kan ni agbegbe Kono nitibi o ti figbakanri sise gegebi
onidiri. Ni osu kerin odun 1998 aye e dara nigbati
olote kan ti a ko damo fi ada ge owo re osi. O so lara itan re fun Chanzy, "Won
ni mo gbodo jiya fun aiko ti won leyin. O dabi enipe won ti ya were, mo si sorire
pupo lati wa laaye leyin ikolu na. Leyin ti won ti ge
mi lowo, mo tiraka rin de ilu kan ti a npe ni Yengema, nibiti dokita kan to
nsise fun Egbe Ogun Iwo-Oorun Ile Afirika fun Iseto alafia (ECOMOG) toju awon
ogbe mi. Mo wa sa kuro ni agbegbe Kono mo si tedo
si ibudo Waterloo fun awon to sipo pada ni ilu Freetown. Ni ojo kefa osu kini
odun 1999, awon olote kolu olu-ilu na won si yinbo pa baba mi ninu ija na".
Fun opolopo osu Mohammed ti nwa ise sugbon nkan o
rogbo. O ni "Yato si agbe sise, anfaani o po fun awon eniyan bi awa. Awa ti
a ge lowo tabi lese ma nlero
wipe a ko wulo. Nitorina ni nko se le gbagbo nigbati won wi fun mi pe mo le
rise. Ohun to dara ni lati wulo ati lati ran agbegbe lowo. Pelu egberun Leone
(Owo Dola Amerika Meje) ti mo ngba fun ise ojumo mo le
se itoju awon aburo mi okunrin ati obinrin merin".
Nigbati yio fi di arin meji osu kinni, ajo IOM ni Freetown ti gba Karatu Bangura.
Obinrin yi, omo odun
marundinlogoji to je iya omo meta nsise gegebi onisowo ni Kamaquay, ilu kan
ni ibuso igba-din-mewa lati Freetown. Ni ojo kefa osu kesan odun 1998 awon olote
ba pade nigbati o npada bo lati oja o si padanu
apa re. Egbe Alagbelebu Pupa ti agbegbe na se eto lati gbe lo si Freetown.
Ni akoko yi, oko Bangura ti 7
7 Page 8 9
Vol. 11 No. 26 (Yoruba) CHANGE Radio March,
2001
8
pada lo si Kamaquay lati ko lara eru won. Ko rii mo. Karatu si wa dawa pelu
awon omo re keekeeke meta. Ni osu kini odun 1999 nigbati awon olote kolu Freetown,
Karatu ni lati salo kuro ni orile-ede Saro
lati wa aabo ni orile-ede Guinea to je alamulegbe won. Leyin eyi o pada si ilu
ti a ti baje. Laipe o ba ara re ni ibudo to wa ni ilu Murray fun awon agelowo-lese.
O ni, "Aye sokunkun dudu. Ohun gbogbo su mi. O soro lati toju awon omo mi".
Ni ibere odun yi, Karatu gbo lati odo Egbe Alasia Pupa ti agbegbe na wipe ajo
IOM ngba eniyan lati sise ni eti ebute. "Lakoko, mo ro wipe nko le ri ise na
gba. Sugbon ore mi kan to nsise fun Egbe Alasia Pupa
wumi lori lati bere fun ise na. Nitorina mo lo, o si ya mi lenu wipe ajo IOM
gba mi. Ise mi ni lati ri daju wipe awon ebi to npada de nwa papo leyin ti won
ba ti sokale lati inu oko" Ohun to je pataki fun Karatu
nisisiyi ni lati fun awon omo re ni eko to dara. Inu re dun wipe won fi ise
yi tan an. On ni agelowo-lese obirin ti ajo kariaye kan yio gba sise.
Titi di idaji osu to koja ibudo ilu Murray je ibugbe fun awon agelowo-gelese
bi odunrun ati ogbon pelu
awon ebi won. Awon olufaragba ipolongo ajalu na si npada bo, bi otile je pe
iye won ti nkere sii. IOM
Iyipada Afefe Ile yio na ni lowo toto Odunrun Bilionu Ow0 6mins. 16secs.
Dola Amerika Lodoodun
O seese ki imorusi aye ni agbaye na ni opolopo bilionu owo dola Amerika
lodoodun ayafi ti a ba gbe
igbese ni kiakia lati dekun itujade efin oloro CO2 ati awon eefin alagbara miran
to nba ayika je, gegebi iroyin kan se so. Iroyin na lati owo awon adojutofo
ati omo egbe eto imusese lori oran isuna ti Ajo Agbaye
fun Eto Ayika (UN. Environment Programme (UNEP) tokasi wipe awon adanu to
nwaye latari iji lile alajayika to nja nigbagbogbo ju ti ateyinwa lo, ipadanu
ile latari giga ti ipele okun nga sii ati ibaje awon
akojopo eja, ise-ogbin ati ipese omi le na ni ni owo to to oodunrun bilionu
(milionu lona egberun) o le
irinwo milionu ati igba egberun owo dola Amerika lodoodun.
Gegebi iroyin na se woye, ni awon orile-ede to wa nibi petele bi Maldives,
awon Erekusu Marshall ati awon apapo ipinle Micronesia, awon adanu to sopo mo
iyipada afefe ile le ju idamewa gbogbo oro orile-ede
won tabi owo gbogbo to nwole labele lo nigbati yio ba fi di odun 2050. Nigbati
o nsoro lori iroyin na,
Klaus Toepfer, Oludari Alase fun ajo UNEP so wipe. "Akoko lati sise niyi. Gbogbo
wa gbodo sise lati din itujade awon eefin alagbara to nba ayika je ku". Sugbon
o woye wipe idinku nikan ko to. Aye ti fekan
juwo si iwe fun iyipada afefe-ile lati owo eda eniyan de ipele kan latari
awon itujade fun akoko to ti ju orundun kan lo lati awon ile-ise ise-nkanjade,
paapa lati iha aye to ti dagbasoke.
Toepfer so wipe iroyin to sese jade lati odo Ajo onijobasijoba lori Iyipada
Afefe Ile (Inter-governmental Panel on Climate Change (IPCC) eyiti ajo UNEP
ati Ajo Awon Awojuojo ni Agbaye (World Unetorological
Organisation (WMO) jijo se onigbowo re na ti tenumo idi fun imusese ni kiakia.
Ajo na, ninu eyiti a ti ri egbegberun awon onimo ijinle sayensi lati kakiri
aye, gbagbo wipe iwontunwonsi igbona tutu jakejado aye
le lo soke lati ipele centigrade kan ati iko merin ninu mewa eyo kan si ipele
marun ati ikomejo ninu mewa
eyo kan laarin orundun to nbo yi.
Toepfer ni "A gbodo tesiwaju pelu igboya pelu awon imo-ero mimo, a si gbodo
bere si gba ara wa di nisisiyi fun ilosoke ipele omi okun, iyipada ninu awon
ilana ojo ati awon ikolu imorusi aye miran". O tun so
siwaju wipe o se koko fun awon orile-ede lati tun bere awon apero lori iyipada
afefe ile to ni idaduro ni
Hague ni opin odun 2000 ki awon orile-ede le gbe awon igbese akoko lati funni
ni awon idinku itujade to ni laari.
Pan African News Agency 8
8 Page 9 10
Vol. 11 No. 26 (Yoruba) CHANGE Radio March,
2001
9
Iyipada Rere ati Awon Ajo Iroyin 4mins. 50secs. Kabral Blay-Amihere to
je Aare Egbe Awon Onise Iroyin ni Iwo-oorun Afirika (West African Journalists
Association (WAJA) ti kilo fun awon onise iroyin wipe ki won mase jeki ifitorese
nipa lori ibalopo won pelu ijoba. O ni niwongba ti awon onise iroyin ba se atileyin
fun igbese laarin orile-ede fun iyipada, won ko ni
ribi sapamo si ti ijoba tuntun na ba kuna lati mu iyipada rere to seleri wa
saye. Ogbeni Blay-Amihere nso oro akoso pataki lori koko oro "Iyipada Rere ati
Awon Ajo Iroyin" ninu ipade gbogboogbo olodoodun ti Egbe
Awon Onise Iroyin ni orile-ede Ghana (Ghana Journalists Association (GJA) ni
ilu Accra ninu eyiti a ti se ibura fun igbimo alase eleni meje ti yio sise fun
odun meji.
Aare WAFA na so wipe: "A gbodo jeki ijoba mo wipe agbara ti awon eniyan fun
won ki ise ipe si ayeye tii mimu" o ni awon onise iroyin gbodo yera fun iwojureyinni
ki won ma ba ba iwulo won je gegebi aja-ode fun
awujo. Ogbeni Blay-Amihere seleri iranlowo egbe GJA fun ijoba Aare Kufuor "ti
o ba nfun awon ajo iroyin ni ifitonileti, to ba pa ofin lori iwa odaran akosile
ibanilorukoje re ti o si se ofin ominira fun ifitonileti". Iyaafin
Gifty Affenyi-Dadzie to je Aare Egbe GJA so wipe alekun imo awon ara ilu lori
agbara awon ajo iroyin gbodo gun awon onise iroyin ni kese lati tubo se aseyori
to ga sii. "A gbodo sora fun itelorun-soni-dole ki a si ma ja
fitafita fun itayo nipa gbigbe asia iwa omoluabi ise wa soke". Iyaafin Affenyi-Dadzie
so wipe Egbe GJA yio gbe eto iwoye kan kale lati ma topase awon iwa to lodi
si iwa omoluabi.
Egbe GJA je okan ninu awon egbe iwo-oorun ile Afirika merin to je anfaani
awon ise ise-idiwon-ara eni eyiti Ajo Alasepo ni kariaye fun Awon Onise Iroyin
(International Federation of Journalists) nse onigbowo re pelu
owo lati owo Ajo Apapo Ile Europe. Accra Mail
Awon ti a da lola Nobel soro lori Ominira Ise Iroyin 3mins. 16secs.
Awon meji ti a da lola Nobel, olori ile Tibet nipa ti emi, Dalai Lama ati
Bharat Ratan Amartya Sen, ti ro ise iroyin lati lo ominira re lati se iyipada
awujo ki won si se ifojusi ero tooro to si nse idiwo fun aye lati di abule
kansoso. Awon mejeji ba ipade ikeji ti Apejo Agbaye ati Ipade Gbogboogbo Aadota
ti Ile-ise Ise Iroyin
ni Kariaye (International Press Institute).
Dalai Lama na woye wipe aye ti gberalerawon pupo sugbon okan eniyan ni 'ero
atijo' si ndari re. O ni ise iroyin le lo ominira re lati mu ki irepo ga si
laarin awon eniyan. Ogbeni Sen nitire so wipe ominira ise iroyin
gbodo je eyiti ko ni ayafi biotilejepe awon ewu bi isi-oro-eniyan-so ati iyawonu-ibi-ikoko-eni
wa. O ni ise iroyin olominira gbodo se aridaju ominira oro eni fun gbogbo eniyan.
O ni ninu ijoba tiwantiwa o ni agbara
lati se idena ajalu bi iyan.
Dalai Lama so wipe eko ko le gbile laisi ise iroyin olominira. O ni ise iroyin
ni eto lati wadi awon olori esun,
awon oloselu ati awon ti a da lola Nobel paapa. The Independent (Banjul)
Ajo Agbaye yan Rawlings latari Ikun-oju-iwon 5mins. 39secs. Sharon
Capeling-Alakija, Oludari Alase ti Awon Ayonda-araeni funse ti Ajo Agbaye (UN
Volunteers
(UNV), so wipe Aare orile-ede Ghana tele, Jerry Rawlings ni won yan gegebi Eniyan
Pataki Ajo Agbaye fun Iyonda-ara-eni-funse latari ikun-oju-iwon ati ifaraji
re to jinle si awon oran ilera to se koko. Osise Ajo
Agbaye na so ninu apejo ifitonileti kan fun awon oniroyin ni ilu Accra wipe:
A tun ro wipe a nilo ogboju ati olooto onsoro gegebi Rawlings lati so fun awon
eniyan iru awon iwa ti won ni lati mu kuro ki won le yera
fun ako iba ati ikolu kokoro-arun HIV ati Arun kogboogun Eedi, Rawlings fi edun-okan
to jinle han lori ako iba ni pataki. O si tun ti bo ajaga ise isejoba sile,
nitorina o ni aaye lati se ise ti a fi fun.
O se alaye wipe ipa ti a fun Rawlings gegebi Eniyan Pataki ki ise igbanisise
lati owo Ajo Agbaye sugbon anfaani kan ni fun lati tesiwaju ninu igbejako re
si awon arun apani bi Arun Kogboogun Eedi ati ako iba ni
ipo iyonda-ara-eni sugbon ni ona to gbooro sii. Iyaafin Capeling-Alakija so
wipe "pelu iriri re gegebi aare 9
9 Page 10 11
Vol. 11 No. 26 (Yoruba) CHANGE Radio March,
2001
10
tele ati ajafitafita ni idojuko awon arun ni orile-ede re, a gbagbo wipe ilowosi
re yio mu awon akitiyan wa le si ni ikoju awon arun apani mejeji yi". O tesiwaju
wipe ninu ipo re titun, Rawlings yio se asiwaju ninu
awon akitiyan ajo UNV ni igbejako Arun Kogboogun Eedi ati ako iba ni ile Afirika
labe eto ise pataki, pelu afikun wipe ojuse re yio tan lo si awon ekun aye miran
labe eto Ajo UNAIDS kan. O ni olori orile-ede
Ghana tele na bere ise ni owuro ojo aje, ojo karun osu keji, yio si tesiwaju
titi di opin odun yi nigbati yio ni aaye lati se atunse ifaramo re tabi beko.
Osise Ajo Agbaye na fikun wipe "Ni ipo re laipe Rawlings
yio bere eto kan ninu eyiti yio ti ma ba awon apero kariaye ati awon awujo agbegbe
soro loni bawo ni a se
le koju Arun Kogboogun Eedi ati ako iba lona to munadoko". Pan African News
Agency
Itoju Ayika lo sinu Fiimu 6mins. 27secs. Ijakadi lati se imubadogba
aisiki eda eniyan ati itoju eda abemi egan ni o je ipilese fiimu ti oludari
fiimu
omo-bibi orile-ede South Africa, Elaine Prector sese se. 'Kin' topinpin itakorawon
to wa laarin itoju ati awon eti agbegbe, o si tun se ayewo imuwalalafia awon
eya pelu ara won ni orile-ede Nambia loni. Fiimu
na so itan Anna, odomode olutoju awon eda abemi egan kan to ngbe ni ekun Nambia
kan to jinna rere. Pelu arakunrin re, Marius, Anna ja lati gba akojopo kekere
ti awon erin kan to ma nmumi lalaale ninu
kanga re la. Fun Anna ati Marius awon erin na lo je ibatan dipo awon eya Himba
ti itedo won wa legbe
oko won, ti ihuwasi Anna ati arakunrin re nyalenu. Sinu igbesi aye Anna to jinna
si awujo ni Stone omo ile Afrika kan to ngbe orile-ede Amerika, to si wa sise
fun igba die ni orile-ede na, gbese wole. Pelu mimu
omo Himba kan ni agbegbe na fun ijiodese, eniti opolopo awon eniyan agbegbe
ro wipe ko jebi, lojiji aye Anna jasi inu okun idaru dapo, ninu ipo to ti soro
lati ri idahun kokan.
Gegebi Proctor se so, "okunfa fun iyipada iriri Anna ni ife to ni fun alejo
to wa lati ode to si ran an lowo lati da ohun gbogbo mo".
A le ri 'Kin' ni opolopo ona gegebi iranpo fun eto ibalaja. Ona eyiti orile-ede
na si nsise ginniginni pelu
irora lati la koja.
Proctor fe ki fiimu na ni imolara fiimu agbegbe nitorina ni o se lo opolopo
awon eniyan ibile lara eyiti awon omo eya Himba wa ki won le gbe ara won yo.
Igbe ara won yo ni idojuko awon oran ti won ntiraka ni
lowolowo lati wa ojuutu si ni o fun 'Kin' ni emi otito re.
Fiimu na da awon oran oloselu po mo awon itan to takoko ni ona to dara lati
se ifojusi awon itakorawon
to wa lode oni ni iha gusu ile Afirika. O pari sa pelu igbagbo wipe ohun gbogbo
yo dara. Kin tanmo wipe kiise wipe eda eniyan le wa ona lati gbe ni ibamu pelu
iseda aye nikan, sugbon, boya, ju eyi lo, a tun le ko
lati gbe pelu eda eniyan elegbe re. IPS
Leyin Awon Omode Na 3mins. 29secs. Awon asoju Ile-ise Ajo Agbaye fun
Awon Asasala Ogun (United Nations High Commission for Refugees
(UNHCR) ati Ajo Alasepo lori Akojo Owo fun Igbala Awon Omode (Save the Children
Fund) ti gbe iroyin kan jade lori eto ise kan lati koju oran awon omode it a
ko sile to nwa ibugbe ni ile Europe. Iroyin
na se agbeyewo bi nkan se wa ninu awon orile-ede meedogun ti ajo Apapo Europe
ati Norway, o si wa se
agbekale awon imoran fun ise ni ipele ti ile Europe ati ti orile-ede kokan.
O kaju awon omode ati awon odo ti ojo ori won din si odun mejidinlogun to ngbe
leyin odi orile-ede abinibi won laisi obi, ibatan tabi
enikeni ti yio ran won lowo, to si je wipe, ni opolopo igba, won ti sa kuro
ni orile-ede won lati jajabo kuro lowo inunibini, iteloju eto eda eniyan, rogbodiyan
ologun ati aisi aabo ni gbogbo ona, ikokiri fun ilonilokulo
nipa ibalopo, tabi osi to le pupo. 10
10 Page 11 12
Vol. 11 No. 26 (Yoruba) CHANGE Radio March,
2001
11
Gegebi ajo UNHCR se so, awon omo ti a ko sile yi to nwa ibugbe ko ni aabo labe
ofin tabi itoju to peye.
Ni ipele ti ile Europe, awon oran yi ko ri amojuto yala nipa ti ofin tabi ilana
imulo besi ni ipile fun ise sise ni agbegbe yi gbelege. Nitori idi eyi ni iroyin
na se nparowa fun agbekale ati imulo awon eto imulo to tona
ninu ajo Apapo Ile Europe ati ni awon orile-ede omo egbe. The Courier
Ilo si ipo fun Ile Afirika ninu Igbimo Aabo Ajo Agbaye? 8mins. 22secs.
Biotilejepe Apejo Egberun odun ti yio wonu iwe itan ti o waye laarin ojo
kefa ati ikojo osu kesan odun 200
fojusi isoro osi ni agbaye ni pataki, aye tun wa fun ifikunlukun lori atunse
to jinle ninu Ajo Agbaye lati mu wa ni ibamu pelu aye to nyi pada ki o si di
irinse to munadoko fun iko-bi-ara-si ifojusona orisirisi awon
orile-ede. Bi o se sese gba omo-egbe re ogosan ati mesan wole pelu dide Tuvalu,
ajo na ni lati se atunse
ninu awon ohun imulo re fun ise-ipinnu gegebi iroyin na ti Lakhdar Brahimi to
ti figbakanri je minisita orile-ede Algeria fun oro ile okeere gbekale fun Ajo
Agbaye se so. Iroyin yi, ti awon olori orile-ede fi owo si
awon isori-isori re, ni o si ariyanjiyan lori mimu Igbimo Aabo to nse kokari
imuwalalafia gbooro si.
Nipa bibere fun ipo fun Ile Afirika lori igbimo yi, awon olori ile yi nireti
lati se alekun ipa re ninu Ajo Agbaye, ko si si owon ariyanjiyan ni isegbe fun
iru igbese be. Ni odun 1945, nigbati a da Ajo Agbaye na
sile, iko meji ninu meta awon omo-egbe re loni ni ko wa gegebi orile-ede olominira,
gbogbo olugbe aye nigbana si je bilionu meji ati aabo pere. Loni o wa ni ekun
bilionu mefa. Ile Afirika nikan ni awon olugbe
edegberin milionu, lara won ni a si ti ri awon orile-ede metalelaadota ninu
orile-ede ogosan o le mesan to je omo egbe ajo na. O ju idameta awon oro ti
igbimo yi ngbe so lo to kan ile Afirika gbongbon. Awon
miran ni ero wipe ilana ise-ipinnu tooro yi gbodo yipada lati se afihan iru
isojueni titun to wa ni ogboogba.
Bawo ati lati owo tani a o se se isojueni ti ile Afirika yi nigbati a ba jaja
gba aba na wole? Ibeere yi, gegebi awon asoju ile Afirika se fi tayotayo kede,
ko gbodo mu isoro pupo wa. Boya Ajo Apapo Ile Afirika to
waye ninu Apejo ti Ajo OAU ni osu keje odun to koja, yio fun ile Afirika ni
ipa to po si ni Kariaye?
Awon olori orile-ede na tun soro lori imulagbarasi awon oro ajo Agbaye lori
isuna, ologun ati eto ise lati
jeki ajo na le se awon ise re ni aseyori, paapa awon ise imuwalalafia re. Opolopo
ipade ni won tun se, ti won si se ibasoro olorile-ede-sori leede pelu orisirisi
awon olori orile-ede ni ode Apejo na ninu itiraka lati
wa ojuutu si awon isoro pataki kan. Bi awon ipade na se nlo si opin, ibere
kan duro lori ete gbogbo eniyan. Nje awon ipinnu rere ti a ko sile ninu Ikede
ti Apejo Egberun Odun na ni a o mu lo? Ohukohun
yio wu ko sele, bi opolopo iru ipade yi se ma nje, awon ipinnu yi yio da pupo
lori ife-ninu oloselu ti awon
to se won. The Courier
Bi mo se ri si
Idajo Ododo fun Awon Omode Orile-ede Saro 10mins. 40secs.
Igbimo Ajo Agbaye to nse iwadi lori ipa ti orile-ede Liberia ko ninu egbe
alafowosowopo lori pasipaaro okuta iyebiye dayamondi fun ibon, eyiti o nfa iha
iwo-oorun Ile Afirika ya, ti pari ise re. Orile-ede Liberia
ti Charles Taylor ni orisun awon ipaya. Ijewo yi ati awon ise agbese ti won
tanmo dabi ebun keresimesi lati odo eda aye to mu ise re lokunkundun si awon
omode ati eniyan orile-ede Saro. Igbimo na, laarin awon
miran, fe ki a gbesele irin-ajo ofurufu ati irinajo miran fun ijoba orile-ede
Liberia. O nfe igbesele lori awon
okuta oniyebiye dayamondi to nbo lati orile-ede Liberia. O tun nfe ki a gbesele
gedu re. Awon igbese yi ni a gbagbo wipe yio fi aami to lagbara ranse si awon
odaran to wa ni orile-ede Liberia wipe opin won lati
ma lo iselu fun awon nkan ifojusi ti ko bofin mu ti de tan. 11
11 Page 12 13
Vol. 11 No. 26 (Yoruba) CHANGE Radio March,
2001
12
Awon awari ati aba igbimo na lo wa lara awon igbese akin taara ti o waye lati
igbati Charles Taylor, pelu atileyin orile-Libya, Cote D'Ivoire, Burkina Fasso
ati awon odaran abele ni kariaye ti bere ilana fifo iwo-oorun
ile Afirika si wewe labe ibori awon ibeere oloselu. Boya ti a ba ti gbe awon
igbese yi ni odun mewa
seyin, awon egbegberun lona mewa omode lati orile-ede Liberia, Saro ati nisisiyi,
Guinea, iba ti ruula. Sugbon a gbagbo wipe akoko ko iti pe ju lati ya ijera
to nfi aso boju bi ijoba tiwantiwa yi soto. A gbe
oriyin fun igbimo na.
Fun akoko to koja ewadun, awon akitiyan oro aje ni orile-ede Liberia ati Saro
ni o ti duro patapata.
Awon agbe ti ni lati fi awon abule won sile ki won si wa ibugbe labe ago lati
ma je onje awon oninure. Oga patapata ti ajo UNCHR to nlo, Iyaafin Sadako Ogata,
ti woye wipe laiko se agbekale awon ohun ti a nilo
fun lilo kuro ni ipo pajawiri si igbokanle-ara-eni, awon ogun ati isoro na
yio ga sii. Otito ni wipe igbekale iru awon ipo be rekoja ipa awon ijoba to
wa lori aleefa ni ile Afirika nisisiyi, opolopo ninu awon ti igbimo
Ajo Agbaye na daruko gegebi olugbowo. Lati reti wipe won o gbe awon igbese to
ye lati gba awon
eniyan na la ni ilodisi ife-inu ti ara won je ala ibanuje. Idi niyi ti awujo
kariaye, isoro yiowu to le wa nibe, di ireti nla kansoso na.
Awon to njiyan ni tako itilekunmo fun awon 'adete' buruku wonyi, nipa lilo
ariyanjiyan ayebaye wipe itilekunmo yio se jamba fun awon eniyan ilu, gbodo
wo orile-ede Liberia Taylor bi on funrarare se lowo to
ti orile-ede re ko si ni. Ile-iwosan kansoso to wa lorile-ede na ni won ti ti
pa. Awon onisegun meedogbon pere lo si wa fun gbogbo ise ilera ni ifiwe si irinwo
ki idibo to waye. Ise ijoba, nibiti o ba si wa, ti pada si
akoko igba ki awon olujegaba to de. Fun apeere, Ile-ise fun Isuna ko ni oko
irinna, nitorina ko le se aridaju owo osu sisan fun awon osise to wa leyin odi
olu-ilu Monrovia. Bi awon osise to wa ni olu-ilu tile
ni iwe sowedowo won lowo, ko si owo ni awon ile ifowopamo si nibiti won o ti
le gbowo jade.
Nigbeyingbeyin won a ma se pasipaaro iwe sowedowo na fun awon onipasiparo owo
loju titi ni edinku to ga. Gbogbo eyi nsele labe okunrin to seleri wipe on yio
lo owo dola Amerika gegebi owonna ni orile-ede
Liberia, ti o si seleri fun gbogbo omode lati fun okookan won ni ero asisebiopolo
Komputa bi ko tile si ina ilentriki, omi tabi aga ijoko ati bebelo fun awon
ile-eko. Ju eyi, eniyan kan le bi awon omode orile-ede
Saro ni itumo ijiya nitori ijiya wo lo tun le ga ju didu omo odun marun ni awon
apa tabi ese re ni oruko
awujo rere -ipinnu egbe RUF ti Taylor. Awon awari ati ipinnu igbimo ajo Agbaye
na, ti a ba mu won lo ni gbogbo ona, lo fun awon omode orile-ede Saro ni akoko
lati rerin. A lero wipe a o lo awon awari na. Inu
wa dun rekoja. A gee ku lati inu Oro Olootu inu iwe iroyin The Perspective
A ti gbo
Orile-ede Algeria gba awon Ile Olomi titun 2mins. 33secs. Orile-ede
Algeria ti se akosile awon ile olomi titun mewa to se pataki kariaye ni isaami
Ojo Ile Olomi ni
Agbaye eyiti o waye ni ojo keji osu keji odun yi, gegebi iroyin se roo ni ile
Algiers. Lara opo awon ibudo na ninu asale ni iha gusu orile-ede na, ni a ti
ri Afonifoji Iherir (ekun Illizi), Ile Abata Gueltates ti Isskarassene
(Tamanraset), Chott Meronane, Qued. Khrouf (El-Qued), Ould Said Oasises, ati
Tamentite ati Sid Ahmed Timmi (Adrar). Nisisiyi, Algeria ni ile olomi metala
ti o nipo Kariaye ti o si gba ile lati sare hektari edegbaata
si eyi to ju milionu kan ati egberun lona egberin o le mokanlelogota sare hektari,
tabi iye kanna si gbogbo oju ile olomi ni orile-ede Amerika, gegebi isiro awon
osise Ajo Akojo owo ni Agbaye fun Iseda Aye.
Ojo Olomi ni Agbaye ni a saami re ni Algiers pelu fifi iwe eri fun awon ile
olomi mewewa fun orile-ede Algeria.
All Africa. com 12
12 Page 13 14
Vol. 11 No. 26 (Yoruba) CHANGE Radio March,
2001
13
Omodekunrin kan to nsaisan lile latari Arun Kogboogun 3mins. 6secs.
Eedi di omo odun mejila Bi ajafitafita lori oran Arun Kogboogun Eedi, Nkosi
Johnson se sese di omo odun mejila, ko si idi fun
ayeye. Omodekunrin na, to ti wonu okan awon milionu milionu eniyan kakiri
aye, ni o nsaisan lile ni ile re ni ilu Johannesburg laisi idarasi kokan ninu
ipo re. Nkosi ti a bi pelu aami kokoro-arun HIV ni o subu lule
ni osu kejila odun to koja latari ibaje opolo to jemo arun Kogboogun Eedi ati
ikolu awon kokoro-arun.
Awon eniyan bi igba, lara awon ti a ti ri awon omo orukan Arun Kogboogun Eedi
ati awon eniyan to ngbe pelu kokoro-arun HIV ati Arun Kogboogun Eedi ni won
wa si ayeye kan ti a se fun Nkosi ni ile-eko
Alakobere ti Melpark ni Melville nibiti o ti ka iwe kerin ni odun to koja. Ninu
ile eko yi kanna ni omode na ni odun 1997 ti koko wa si ifojusi awon ara ilu
nigbati awon obi tiraka lati dena igbawole re nitori ipo re
gegebi eniti o ni kokoro-arun HIV ati Arun Kogboogun Eedi.
A ranti Nkosi julo fun gigori itage ni sisi Apero agbaye to tobi ju lori Arun
Kogboogun Eedi ni ilu Durban ni odun to koja ti o si kepe Aare orile-ede South
Africa, Thabo Mbeki lati fi aaye gba egbogi agbejako-Eedi
ti a mo si AZT fun awon aboyun. Africa Online
Eto Awon Omode
Kumbo ati Mhisi 12mins. 7secs. Nigbakan okunrin kan wa, on ati
iyawo re, ti won ti gbe fun opolopo odun ni abule kan pelu omo won,
Kumbo. Ni akoko itan yi, awon obi na pinnu wipe o to akoko lati si lo si abule
miran, nitori won ti gbe ninu ile won atijo pe to. Won soro lori igbese yi pelu
omo won kansoso, enu si ya won nigbati o wipe: "O ti o,
eyin obi mi. Eyin le lo sugbon emi ki yio lo. Mi o ri idi ti e fi fe fi ile
to dara bayi sile." "Sugbon, omo mi," iya re dahun, "a le ko ile miran to tura
bi eleyi furara wa laisi wahala." "O ti o" omo
olorikunkun na taku... "Bi eyin ba tile lo, emi yio duro nihin."
Awon obi na ti pinnu lokan won. Ile won atijo ti su won won si fe kuro. Omo
na si ti pinnu lokan re. Inu re dun nibiti o gbe wa, o si ti ko lati lo. Nitorina
won fohun sokan lati pinya. Awon obi na ko eru won lo
si abule titun nigbati Kumbo da nikan duro si ile atijo na.
Ile titun awon obi na ko jinna, nigbati o si di irole ojo na gangan, iya pada
wa sodo Kumbo o si wipe: "Nko le jeki ebi pa omo mi kansoso nitori a ti si lo,
nitorina ngo ma gbe ounje re wa lojoojumo. Wa mo wipe emi
ni mo de nigbati o ba gbo ti mo korin bayi:
'Ni-vi-yi Kumbo
Ni-vi-yi Kumbo Se Kumbo niyen? '
Eto ti won se niyi, iya na si npada wa lojoojumo lati fun Kumbo ni ounje.
Ni ojo kan, Mhisi, akata, to nsinmi ninu igbo nitosi, ri nkan to sele, o si
gbo orin na.
"Ah-ha:, o wi fun ara re, On ti mo ni lati se ni lati ko orin na ki nle ni omo
na fun ara mi nikan lati se ohun to ba wu mi pelu re .. dajudaju wo si mo ohun
ti mo fe lati se pelu okele adidun bayen."
Leyin ti iya ti lo, Mhisi lo si ile na o si korin leyin ilekun. 13
13 Page 14 15
Vol. 11 No. 26 (Yoruba) CHANGE Radio March,
2001
14
'Ni-vi-yi Kumbo Ni-vi-yi Kumbo
Se Kumbo niyen? '
Ninu ile omokunrin na sun sori eni re, o si wa mo wipe ohun yen ki ise ti iya
on. Paapa, iya re sesee mu ounje re wa ni ojo na ikun re si kun. Nitorina o
dake titi ti Mhisi fi jawo ti o si lo.
Ni ojo keji nkan kanna sele, omodekunrin na si kigbe "O nfi akoko ara re sofo,
eni yio wu koo je. Mo mo
wipe o kiise iya mi, nitorina nko ni jeki o wole.
Mhisi yo gologolo lo sinu igbo o si wa bere si rori ona lati fi wonu ahere
na.
Ni ojo keji o de saaju iya Kumbo, o si wa korin na bi o se le koo dun to.
'Ni-vi-yi Kumbo Ni-vi-yi Kumbo
Se Kumbo niyen? '
Nisisiyi, Kumbo nreti iya re ni akoko na, ebi si npa gidigidi. Ka so otito,
ninu ikanju re lati jeun, o ti gbagbe eda to ti ngbiyanju fun bi ojo meta lati
wonu ile na. Nitorina o fo soke o si si ilekun.
Mhisi gba apa re mu o si wo lo. "O Akata," omokunrin na kigbe pelu eru. "Nibo
ni a nlo? Mo ndurode iya mi lati mu ounje wa. Yio de
laipe."
'Ma foya Kumbo," Mhisi dahun. "Iya re lo ran mi wa sibi. On lo ni ki nlo mu
o wa." Nitorina ifoya Kumbo role, o si dake bi Mhisi se gbe lo sinu igbo to
jin. Nigbana, ki Kumbo to mo ohun
to nsele, Mhisi paa o si jee.
Kumbo ode! Se o ro wipe omode lemo ju awon obi re lo ki o si tako ipinnu won?
Shangani Folk Tales
Oro Asokagba
Awon oro manigbagbe lati owo awon olori Ile Afirika.
Lori idagbasoke Aini idagbasoke to to je irokeke ewu to tobi julo si alafia.
Ohun aigbodomase wa kinni ni lati pa
osi, ainimo ati arun run, ki a si se agbekale awon ona orisirisi ti olukuluku
eniyan le gba lati gberu, lori anfaani olokan-oju-okan fun okunrin ati obirin.
Sam Nujoma Aare orile-ede Namibia ninu Apejo Egberun Odun.
Lori Ilujarawon-aye Ti a ba fe gba awon anfaani ilujarawon-aye mu ki a
si dena awon ikolu ti ko dara ninu re ni igba
kanna, nigbana a gbodo ko lati se ijoba to dara si ki a si se ijoba papo. Kofi
Anan
Akowe Agba Ajo Agbaye ninu Apejo Egberun Odun. 14
14 Page 15
Vol. 11 No. 26 (Yoruba) CHANGE Radio March,
2001
15
Lori Rogbodiyan Eniti o ba sun lebi yio ji pelu okan to kun fun ikorira.
Pierre Buyoya Aare orile-ede Burundi ninu Apejo Egberun Odun.
Lori Eko Eko ki ise ona lati fi jajabo kuro ninu osi orile-ede sugbon ona
lati fi gbejako o.
Julius Nyerere Ologbe Aare orile-ede Tanzania.
Si ranti.........
Ewa ma nwa ju ohun gbogbo lo, lati inu okan, lati inu ilera okan ati ipeye
eniyan funrarare. Nawal El Sadaawai
Onkowe: Oju Eefa ti o pamo. 15
© 2002 Communicating for Change. All Rights Reserved
Developed by George Mbuagbaw